Ìwà ọ̀daràn ni k’óbìnrin gbowó mọ́tò lọ́wọ́ ọkùnrin láì sàbèwò síi – PPRO Rivers
Yínká Àlàbí
Alukoro awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers, arabinrin Grace Iringe-Koko lo n salaye yii lori ẹrọ ayelujara.
O ni ọrọ naa jọ ere sugbọn kii se ere tabi awada rara. O ni “labẹ iwe ofin iwa ọdaran ti orileede yii ni abala 419, iwa ọdaran ni ki obinrin gbowo mọto lọwọ ololufẹ rẹ ọkunrin lati se abẹwo si ile rẹ, ti o wa kọ ti ko yọju, ti iru okunrin bẹẹ ba le fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa pẹlu ẹri to daju, iru obinrin bẹẹ maa foju ba ile ẹjọ”. O tun tẹ siwaju pe “faini owo tabi ẹwọn ni iru obinrin bẹẹ maa fi gbara”.
PRO Rivers ni ofin naa kii se tuntun, o ni ofin naa ti wa tipẹ. O ni boya itiju tabi oju dudu ni ko jẹ ki ọpọ ọkunrin maa mu iru ẹjọ bẹẹ wa si agọ ọlọpaa.
Eyi tumọ si pe ohun ti a ko ba fẹ jẹ, ki a ma fi runmu rara.









