Asojú tí ò ní ṣe ìlérí asán ni mo fẹ́ jẹ́ – Olùdíje du ipò asojú fún ADC ti Alimoshọ

Asojú tí ò ní ṣe ìlérí asán ni mo fẹ́ jẹ́ – Olùdíje du ipò asojú fún ADC ti Alimoshọ

Abilekọ Ola Olusola Motunrayo to jẹ oludije du ipo asoju nile igbimọ asofin ni Abuja lo n salaye ara rẹ fun awọn oniroyin lọsẹ yii.
Olusola ti gbogbo eniyan mọ si Ayekootọ ni “emi ko setan lati maa ṣe ileri ati awawi asan ti awọn oloselu kan maa n se”. O tun tẹ siwaju pe, “gẹgẹ bi oniroyin ti mo jẹ, mo mọ ibi ti bata ti n ta ara ilu lẹsẹ, maa si sa gbogbo agbara mi lati ri i ayipada rere de ba agbegbe Alimosho ti mo fẹ lọ soju”.
O tun ni “mo setan lati gbọ ọrọ si ara agbegbe mi lẹnu, ki n ro awọn ọdọ lagbara, eto ẹkọ to ye kooro, ipese isẹ, eto ilera ati awọn ohun amayedẹrun fun awọn olugbe Alimoshọ”.
Olusola wa rawọ ẹbẹ si awọn ara Alimosho lati pawọpọ dibo fun oun lati gbe ogo agbegbe naa de ebute ogo nibi ibo to n bọ ni ọdun 2027.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here