Góò Saka yọwọ́ kílànkó Madrid láwo
Láti ọwọ́ Yínkà Àlàbí
Ere bọọlu UCL (UEFA Champions League) ti bẹrẹ to ọjọ mẹta. Ikọ agbabọọlu Arsenal lo wako lana ọjọ Tuside pẹlu ikọ Atletico Madrid.
Ifagagbaga naa gbona janjan ki Leandro Trossard to gba ara sọọti ti Bukayo Saka ran an lọwọ lati wọle ni isẹju kẹrinlelogoji ti ere bọọlu naa bẹrẹ.
Goo naa ti gbe Arsenal wọ ipele to gbẹyin. Wọn maa wako pẹlu ẹni to ba jawe olubori ninu Bayan Munich ati PSG ti ife ẹyẹ tẹlẹ wa lọwọ wọn.
Oni ọjọ wẹside ni a maa mọ ẹni to maa faga-faga pẹlu Arsenal ni ọgbọnjọ osu yii ni papa isere Budapest.









