Home Blog Page 92

Ruth Kadiri bo̩wó̩lu Funke Akindele gé̩gé̩ bí igbákejì Gómìnà ìpínlè̩ Eko

Ruth Kadiri bo̩wó̩lu Funke Akindele gé̩gé̩ bí igbákejì Gómìnà ìpínlè̩ Eko

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Ruth Kadiri-Ezerika ti bowolu akegbe re, Funke Akindele, eni to n dije pelu oludije fun ipo gomina labe egbe oselu People’s Democratic Party, Abdul-Azeez Olajide Adediran ti a mo si Jandor.

Lati igba to ti kede ilepa ninu eto oselu, Akindele ti ri atileyin gba lati odo awon akegbe re, paapaa julo awon obinrin.

Nigba ti awon miiran n yapa ti won si kede atileyin won fun Gomina Babajide Sanwo-Olu ati Gbadebo Rhode-Vivour ti egbe oselu Labour Party(LP), Kadiri yan ifowosowopo re pelu Akindele.

Iya omo meji naa, fi aworan ogbontarigi osere ninu Jenifa’s Diary lede, to si tokasi idi ti oun yoo fi dibo fun ni ojo kokanla osu yii.

Ìdí tí mo fi ń kéde ìpinnu mi láti se ìgbéyàwó mìíràn fáyé – JJC Skillz

Ìdí tí mo fi ń kéde ìpinnu mi láti se ìgbéyàwó mìíràn fáyé – JJC Skillz

Mary Fágbohùn

JJC Skillz, oko osere tiata, Funke Akindele teleri, ti so pe ti oun ba sepinnu lati se igbeyawo miiran, oun o ni kede re ni gbangba.

Eyi waye leyin opolopo ojo ti aheso irohin kan jade pe o ti se igbeyawo pelu omobinrin kan lati ipinle Kano.

Sugbon nigba to n soro ninu atejade The Cable ti ojo Aiku, JJC Skillz wi pe ti oun ba sepinnu lati tun igbeyawo se oun yoo fi se bonkele ni nitori pe o je ti oun nikan.

“Bi mo ba sepinnu lati se igbeyawo miiran tabi yan ona ti maa to, yoo je ipinnu temi nikan ati pe mi o ni kede re faye,” ni ohun ti o so.

JJC Skillz kede iyapa oun ati iyawo re ni osu kefa odun 2022.

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ máa da ìbò Ààrẹ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ dì nù – Atiku

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ máa da ìbò Ààrẹ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ dì nù – Atiku

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí nǹkan ṣe rí báyìí, oníkálùkù ló ń ṣe kíyọ̀ ó dun tíẹ̀ látàrí ìbò Ààrẹ tí a dì kọjá.
Olùdíje fúnpò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDD, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pé orílẹ-èdè Nàìjíríà ni yóó jẹ́ orílẹ-èdè ilẹ̀ Áfríkà kẹta tí ilé-ẹjọ́ gígajùlọ yóó ti wọ́gi lé ètò ìdìbò sípò Ààrẹ tí kò kúnjú òṣùwọ̀n , ó lóun nígbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pé Sùpíríímù kọ́ọ̀tù ilẹ̀ wa kò ní-ín ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n, oṣù Kejì tó lọ yìí, ó ní wọ́n máa da ètò ìdìbò náà nù bíi omi ìṣanwọ́ ni.

Atiku sọrọ yii laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii, latẹnu agbẹnusọ fun eto ipolongo ibo aarẹ rẹ, Amofin Daniel Bwala.

Atiku ni kawọn eeyan to n lero pe ikede ti ajọ eleto idibo (INEC), ba ti ṣe lori idibo aarẹ labẹ ge, ki wọn yaa tun inu wọn ro, ki wọn si simẹdọ, tori ko sohun toju o ri ri, bo ba ti ṣẹlẹ nibi kan, o le ṣẹlẹ nibibikibi.

Lori ikanni agbọrọkaye tuita rẹ ni wọn ti fi ọrọ naa lede, o kọ ọ sibẹ pe:

“Nigba ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede Kenya, nilẹ Afrika wa nibi wọgi le eto idibo sipo aarẹ orileede naa fun igba akọkọ nilẹ adulawọ, ohun tawọn eeyan sọ ni pe ọjọ manigbagbe leyi fawọn eeyan ilẹ Kenya, ati fun gbogbo olugbe kọntinẹẹti Afrika lapapọ.

“Fun igba akọkọ ninu itan oṣelu ati iṣejọba dẹmokiresi nilẹ Afrika, ile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ lati wọgi le eto idibo ti ko mọyan lori, wọn palẹ eto idibo rakuraku mọ. Idajọ to laami-laaka yii si fihan pe ijọba dẹmokiresi ti tubọ rẹsẹ walẹ nilẹ Afrika.

“Lẹyin ti Kenya, ile-ẹjọ giga ju lọ lorileede Burundi ti ko jinna si wa nibi naa ti ṣe bii tiwọn, wọn wọgi le eto idibo ti ko kunju oṣuwọn, nibẹ.

“Ẹ lọọ kọ ọrọ mi yii silẹ o, Naijiria ni yoo ṣikẹta tiru ẹ ti maa waye, ẹẹ sọ pe mọ wi bẹẹ.”

Amọ ṣa o, oriṣiiriṣii oju lawọn to kọ ọrọ sabẹ ohun ti Atiku sọ yii fi wo ọrọ to sọ naa. Ọpọ awọn to fesi sọrọ yii ni wọn sọ pe inu awọn iba dun-dun-un-dun biru idajọ ododo bẹẹ ba waye, amọ awọn o nigbẹkẹle ninu ile-ẹjọ giga ju lọ ti Naijiria, wọn ni bii igba teeyan n fẹjọ ika sun ika lọrọ wọn, to ba ti dọrọ idibo, wọn lawọn o reti pe iru idajọ to muna bẹẹ le waye.

Awọn mi-in ni ala ọsan-gangan ni Atiku n la, tori bile-ẹjọ ba tiẹ da ibo naa nu, ti wọn si tun un di, ba a ba ju abẹbẹ soke nigba igba, ibi pẹlẹbẹ ni yoo fi lelẹ, wọn ni Tinubu, iyẹn Aṣiwaju Bọla Ahmed, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ti wọn ti kede p’oun lo jawe olubori naa ni yoo tun jawe olubori, wọn ibaa tun ibo ọhun di nigba mẹwaa.

Bẹ́ẹ̀ sì làwọn mí-ìn ń sọ pé àti Atiku, àti Tinubu o, Peter Obi, ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, lo yege ìbò, wọ́n lóun ní Ifá yóò fọre fún nílé – ẹjọ́ nígbẹ̀yìn, àfi bí ìdájọ náà kò bá lọ bó ṣe yẹ kó lọ.

Àwọn agbẹjọrò tó pe INEC lẹjọ́ lórí Temporary Voter’s Card, TVC, sọ pé àìkójú òṣùwọ̀n INEC ni.

Àwọn agbẹjọrò tó pe INEC lẹjọ́ lórí Temporary Voter’s Card, TVC, sọ pé àìkójú òṣùwọ̀n INEC ni.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Aṣojú àwọn agbẹjọ́rò ọ̀hún, Victor Opatola ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pé INEC kùnà nínú ojúṣe rẹ̀, èyítí kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ aráàlú lè dìbò lọ́jọ́ ìdìbò.

Ọpatọla ni “ Èrèdí tí a ṣe pe INEC lẹ́jọ́ ni pé àwọn èèyàn kan ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ lábẹ́ òfin láti le ní káàdì ìdìbò alálòpẹ́ wọn, PVC, àmọ́ INEC fún wọn ní TVC wọ́n si sọ pé ẹni tí kò bá ní PVC kò lè dìbò .”

“ Ìtumọ̀ eléyìí ni pé àwọn èèyàn náà kò le dìbò bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun gbogbo tó yẹ kí wọn ṣe lábẹ́ òfin.”

“Èrèdí rè é tí a fi lọ sílé ẹjọ́ nítorí àwọn èèyàn náà ti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Nàìjíríà rere láti lè dìbò àmọ́ INEC ló kùnà láti fún wọn ní PVC.”
Ọpatọla ṣàlàyé pé ní wọ̀n ìgbà tí orúkọ, àwòrán àti ìka àwọn èèyàn náà ti wà lọ́dọ̀ ọ INEC, àjọ ọ̀hún kò lágbára láti sọ pé kí àwọn èèyàn náà ma.”

Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé rẹ̀, TVC yìí lè ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ ìdìbò nítorí ohun kan náà ló wà lórí BVAS àti ẹ̀rọ ‘card reader’ tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀.

Ó parí ọrọ̀ rẹ̀ pé iṣẹ́ kan náà ni PCV àti TVC ń ṣe, kò sì yẹ kí INEC dẹ́kun ẹnikẹ́ni láti dìbò nítorí kò ní PVC níwọ̀n ìgbà tó ní TVC.

Ó fi kún un pé ẹ̀tọ́ ọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni láti dìbò, níwọ̀n ìgbà tí irufẹ ẹni bẹ́ẹ̀ bá ti fi orúkọ sílẹ̀, tó sì ní káàdì TVC náà lọ́wọ́, ó yẹ kó dìbò.

Dẹ́rẹ́bà tó wa bọ́ọ̀sì to kọlu rélùwéè l’Eko ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ fún ọlọ́pàá

Dẹ́rẹ́bà tó wa bọ́ọ̀sì to kọlu rélùwéè l’Eko ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ fún ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Dẹrẹba tó wa ọkọ̀ bọọsi BRT tó forígbárí pẹ̀lú reluwé nílùú Èkó l’Ọjọbọ ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fá wọn agbófinró.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu ló sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn ńlá Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó, LASUTH.

Awakọ̀ tó wa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì BRT àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba náà ti kọ́kọ́ sá lọ ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, kí ó tó di pé ó padà fara rẹ̀ hàn.
Gómìnà Sanwo-Olu ní awakọ̀ náà ti wà ní àkóso àwọn ọlọ́pàá báyìí.

Àwọn márùndínlọ́gbọ̀n ti gba ìtọ́jú kíákíá wọ́n sì ti ń gbé wọn lọ sí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba míràn káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó.

Gómìnà Sanwo-Olu tún fi kún un pé èrò márùndín láàdọ́rù-ún 85 ló wà nínú ọkọ̀ b bọ́ọ̀si náà, méjìlélógójìj nínú wọn ni ohun tó ṣe wọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ púpọ̀, mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nínú wọn ló fara ṣèṣe púpọ̀, tí mẹ́jọ nínú wọn sì farapa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.
Èèyàn mẹ́fà ló ti jáde láyé nínú àwọn èèyàn tó farakáásá ìjànbá náà. Méjì nínú wọn ni wọ́n gbé dé ilé ìwòsàn lókùú, ṣùgbọ́n mẹ́rin míràn jáde láyé lẹyìn tí wọ́n gbé wọn dé ilé ìwòsàn.

Ó fi kún un nínú àlàyé rẹ̀ pé àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń lọ pẹ̀lú àwọn òbí wọn tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba Èkó wà nínú ọkọ̀ bọọsi náà nígbà tí ìjànbá náà wáyé.

Adeleke kàn ń gba oríyín fún àṣeyọrí Oyetola ni – APC Ọṣun

Adeleke kàn ń gba oríyín fún àṣeyọrí Oyetola ni – APC Ọṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress APC ìpínlẹ̀ Osun, ti fi ẹ̀sùn kan ìṣèjọba Ademola Adeleke pé kò dẹ̀kun láti gba oríyìn àwọn àṣeyọrí Gómìnà Gboyega Oyetola.

APC Osun ní kò bójúmu bí ìjọba Ademola Adeleke se dáwọ́ iṣẹ́ dúró lórí Fásitì Ilesha, èyí tí wọ́n ní Gómìnà tẹ́lẹ̀, Gboyega Oyetola ti parí gbogbo isẹ́ lórí Fásitì náà.

Alága fìdíhẹẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Tajudeen Lawal ló sọ eléyìí níbi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílùú Òsogbo l’Ọjọru.

Lawal ní owó tó tó àádọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà ni ó wà ní àpò ìjọba nígbà tí Adeleke di Gómìnà l’óṣù mẹ́ta sẹ́yìn.

Kola Olabisi, agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, to lọ sojú alága níbi ayẹyẹ ọgọ́rùn-un ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tí Adeleke ṣe ni kò bójú mu rárá, àti pé aadọrun bílíọ̀nù náírà náà ni ìjọba Adeleke kò rí nawọ́ sí pé nǹkan báyìí ló fi se.

“Adeleke gba iṣẹ́ lọwọ́ àwọn elétò ìlera tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàata níye nígbàtí tí ètò ìlera ṣì mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.

“Adeleke ń lo àwọn jàǹdùkú láti dunkookò mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò tí ètò ìdìbò Ààrẹ àti ilé ìgbìmọ̀ wáyé.

Síbẹ̀, kò tíì sí èsì tí ìjọba Ademola Adeleke fọ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC Osun lọ́ mọ́ ọ lẹ́sẹ̀ yìí.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Tunisia fẹ́ tú ìjọba ìbílẹ̀ ká

Ààrẹ orílẹ̀èdè Tunisia fẹ́ tú ìjọba ìbílẹ̀ ká

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Tunisia, Kais Saied ti kéde pé òun yóò tú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n dìbò yàn ní ọdún 2018 ká.

Ààrẹ Saied tún sọ pé ìjọba fìdíhẹẹ́ tí yóò jẹ́ ìgbimọ àwọn àkànṣe aṣojú.

Àwọn ìgbìmọ̀ yìí jẹ́ ara àwọn ohun àmúyangàn ìjọba tiwa-n-tiwa tí àwọn èèyàn Tunisia lè sọ pé ó jẹ́ èrè àwọn lẹ́yìn ìwọ́de ńlá tó wáyé lọ́dún 2011 èyí tó lé Ààrẹ Zine al-Abidine Ben Ali kúrò nípò.

Àwọn èèyàn tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tó tako ìjọba Ààrẹ Saied ló wà láwọn ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ìbílẹ̀ náà .

Ààrẹ Saied ní àwọn aráàlú ni yóò dìbò yan àwọn ọmọ ìgbimọ yìí ṣùgbọ́n òfin tuntun ni yóò wà nílẹ̀ fún wọn.

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún INEC láṣẹ láti ṣàtúntò BVAS fún ìdìbò Gómìnà

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún INEC láṣẹ láti ṣàtúntò BVAS fún ìdìbò Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó ń gbọ́ àwọn awuyewuye ètò ìdìbò sípò ààrẹ ní Nàìjíríà tó wáyé lóṣù tó kọjá ti fún àjọ INEC láǹfàní láti ṣe àtúntò ohun èlò àyẹwò olùdìbò lọ́nà ìgbàlódé, BVAS tó lò fún ètò ìdìbò sípò ààrẹ.

Èyí tako ẹ̀bẹ̀ tí olùdíje fún ipò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú LP, Peter Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé ka iwájú ilé ẹjọ́ náà pé kó ká àjọ INEC lọ́wọ́ kò pé kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀rọ ìgbàlódé BVAS náà, àti pé ó gbọdọ̀ gba òun láàyè láti yẹ̀ ẹ́ wò.

Àwọn ìgbìmọ̀ adájọ́ mẹ́ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé dídá INEC lọ́wọ́ kọ́ yóó pagidínà ètò ìdìbò sípò Gómìnà àtàwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ ọ Sátidé, ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta.

Agbẹjọ́ró fún INEC ṣàlàyé pé kò yẹ kí Peter Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ bẹrù ohunkohun nítorí pé gbogbo ohun tó wà lórí àwọn ẹrọ BVAS náà ni wọ́n yóò fi pamọ́ sínú agbada ayélujára ‘server’ wọn fún ẹnikẹ́ni láti wò nígbà kúùgbà.

Àwọn agbẹjọ́ró tó ṣojú fún Peter Obi àti Atiku Abubakar, ní àwọn ohun tí àwọn nílò fún ẹjọ́ àwọn ló ṣeéṣe kí wọ́n parẹ́ bí àjọ INEC bá ṣe àtúntò BVAS rẹ̀ ọhún

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mi lọ́rùn fún Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ láṣẹ láti yẹ àwọn ohun èlò gbogbo tí INEC lò fún ètò ìdìbò ààrẹ tó kọjá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà wò fún ẹjọ́ tó pè tako ìdìbò náà.

Sùgbón, àjọ elétò ìdìbò INEC dìde tako Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ lẹ́yìn tó ní òun fẹ́ ṣe àtúntò BVAS fún àti lò lásìkò ìdìbò Gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ Sátidé.

Ohun tí ẹ ní láti mọ̀ nípa ìrìnàjò Gómìnà Babajídé Sanwó-Olú

Gomina Babajide Sanwo-Olu

Gomina ipinle Eko Babajide Sanwo-Olu keko gboye ninu Surveying ati MBA ni fasiti Eko, iyen University of Lagos.O si je akekoo jade ni ile-iwe John F. Kennedy School of Government, London Business School ati Lagos Business School.
O tun je omo egbe Chartered Institute of Personnel Management (CIPM) ati ojugba Nigeria Institute of Training and Development (NITAD).

Babajide Olusola Sanwo-Olu je akapo tele ri fun Lead Merchant Bank lati odun 1994 si 1997 leyin eyi ti o kuro nibe lo si United Bank for Africa gege bi olori owo oja okeere. O tesiwaju lati ibe lo si First Inland Bank, Plc (to ti di First City Monument Bank) gege bi igbakeji olusakoso ati olori eka. O je alaga tele ri fun ile-ise Baywatch Group Limited ati First Class Group Limited.

Babajide Olusola Sanwo-Olu beere eto oselu re ni odun 2003, nigba ti won yan an gege bi oludamoran pataki lori oro ile-ise nla fun igbakeji Gomina ipinle Eko ni igba naa, Femi Pedro. Leyin naa ni won yan an ni Komisanna fun Eto Oro Aje ati Isuna titi di odun 2007, leyin eyi ti won tun yan an fun Komisanna to n ri si oro isowo ati ile-ise lati labe isejoba Gomina igba naa, are ti adiboyan bayii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Leyin eto idibo gbogbo gboo ni odun 2007, Babajide Olusola Sanwo-Olu ni a yan gege bi Komisanna to n ri soro idasile, idanilekoo ati owo ifeyinti fun Gomina Babatunde Fashola. Babajide Olusola Sanwo-Olu ni a so di Adari Olusakoso/Oga Agba fun Lagos State Development and Property Corporation (LSDPC) lati owo Gomina Akinwunmi Ambode ni odun 2016. Leyin naa lo di Gomina Ipinle Eko leyin ti o fi eyin alatako re nale ni odun 2019.

Ta ba nsukun, ka ma riran o, igi imu teri yen, o jina sori. Oro Ipinle Eko, atari ajanaku ni, kii se eru omode.
#SanwooluMustStay #IgbegaIpinleEko #Ajumoseni

Tinubu padà sí Eko, Ó ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Tinubu padà sí Eko, Ó ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àpèjúwe bí ààrẹ tuntun tí ìlú dìbò yàn ṣe padà sí ìlú Èkó ko yàtọ̀ sí pé kí jagunjagun ìgbà a nì bá jàjàyè, tí wọ́n sì fẹ́ wọ̀lú padà lọ̀rọ̀ jọ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kẹta yìí, pẹlu bí òbítíbitì èrò ṣe tú jáde láti kí ààrẹ tuntun, Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu, káàbọ̀ padà sílùú Èkó, láti Àbújá.

Tìlù -tìfọn làwọn o lólùfẹ́ èèkàn olóṣèlú tó ti fìgbà kan jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó náà lọọ pàdé rẹ̀, bi wọ́n ṣe ń kọrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń jó, tí wọ́n sì ń kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi akọni ọkùnrin tó gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́, tó sì gbàwo bọ̀.

Láti pápákọ̀ òfurufú Murtala Mohammed, MMIA, tó wà n’Ikẹja, làwọn èèkàn èèkàn lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ti lọ̀ ọ́ pàdé Jagaban, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pé ọ̀kan nínú àwọn orúkọ oyè rẹ̀.

Lára àwọn tí wọ́n lọ ọ kí i káàbọ̀ ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, Olórí àwọn òṣìṣẹ́ ọba, Ọgbẹni Tayọ Ayinde, Sẹnetọ Musiliu Ọbanikoro, àti àwọn òṣìṣẹ́ ọba mìíràn.

Láti Ikẹja ọ̀hún ni gbogbo wọn ti jùmọ̀ rìn pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì wọn gbogbo, tààrà ni wọ́n mórí lé ààfin Iga-Iduganran, ibẹ̀ ni Ọba Rilwanu Akiola, Ọba ìlú Èkó, ti kí Tinubu káàbọ̀, bẹ́ẹ̀ lẹsẹ̀ àwọn olóyè onífìlà funfun nílùú Èkó pé báákán síbẹ̀.

Ṣé tèwe-tàgbà ní-ín ṣapẹ́ wo líìlí, àti pé bí sìkìǹmidìn bá wọnú ọjà, tẹrú tọmọ ní-ín jó o.
Iṣẹ́ àṣelàágùn làwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò àtàwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣe kí wọ́n tóó jẹ́ kí Tinubu bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ìrìn tí kò yẹ kó gbà ju ìṣẹ́jú péréte náà sì gba àkókò gígùn kó tóó fáàyè wọlé, bó ti ń ṣíṣẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan ló ń juwọ́ sáwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n wá ṣàyẹ́sí i rẹ̀ níbẹ̀.

Láàfin Ọba Akiolu, Tinubu ní ìrìn àjò tóun là kọjá láti àsìkò ìdìbò abẹ́lẹ́ tí wọ́n fi fa òun kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje, títí dìgbà tí ètò ìdìbò náà fi wáyé, tó sì parí lọ́sẹ̀ tó lọ yìí, kò yàtọ̀ sí ìdíje ife àgbáyé bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá tó máa ń wáyé, níbi tó jẹ́ ojú ogun àti eré ẹlẹ́mìí ẹṣin ni, síbẹ̀ ẹgbẹ́ kan ṣoṣo ni yóó gbé ife lọ sílé.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn fún àṣeyọrí rẹ̀, bákan náà ló dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọba Akiolu àtàwọn orí-adé gbogbo fún ádùrá àti ìfẹ́ wọn.

Lẹ́yìn èyí ló ṣàfihàn ìwé -ẹ̀rí i ‘mo yege’ tí àjọ elétò ìdìbò INEC fún un, ó sì ya fọ́tò pẹ̀lú Ọba àtàwọn ìjòyè láti ṣèrántí ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ ọ̀hún.

Ó wáá ṣèlérí pé gbogbo ẹ̀jẹ́ tóun jẹ́ lásìkò ìdìbò lòun yóó ṣiṣẹ́ lé lórí, òun ò sì ní í já àwọn tó rọ̀jò ìbò fóun àti gbogbo ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀ tóun bá ti gbọ̀pá àṣẹ láìpẹ́.