Home Blog Page 81

Òkú Gómìnà Akeredolu balẹ̀ sí Nàìjíríà láti òkè òkun

Òkú Gómìnà Akeredolu balẹ̀ sí Nàìjíríà láti òkè òkun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí ohun náà láyé tí òpin kò ní-ín dé bá. Àìsí mọ́ lòpin èèyàn, bí ó ti jẹ́ pé òkú Gómìnà télẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Arákùnrin Oluwarotimi Akérédolú ti balẹ̀ sí orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Ọkọ̀ bàálù tó gbé òkú náà balẹ̀ ní déédé aago mẹ́ta àbọ̀ ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kínní ọdún 2024.

Láti orílẹ-èdè Germany ni wọ́n ti gbé òkú náà wá sí orílẹ-èdè Nàìjíríà,

Ìyàwó Gómìnà tẹ́lẹ̀, Betty Anyanwu-Akeredolu, àwọn ọmọ àti mọ̀lẹ́bí tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Akérédolú léwájú fún ló lọ pàdé òkú náà.

Lára àwọn tó wà pẹ̀lú wọn ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwoolu, ẹni tí ọ̀gá àgbà fún òsìsẹ́ , Tayo Ayinde sojú, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dapo Abiodun, ẹni tí Akọ̀wé ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Tokunbo Talabi sojú fún un pẹ̀lú.

Àwọn yòókù ni alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Òǹdó,Ade Adetimehin, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Gboyega Adefarati, àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ẹni tí akọ̀wé ìjọba, Ọmọọba Oladunni léwájú fún wà pẹ̀lú àwọn tó tẹ́wọ́gba òkú náà.

Omijé bó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lásìkò tí wọ́n gbé òkú náà kalẹ̀ láti ínú bàálù.

Gómìnà Akérédolú jáde láyé ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2023 nílùú Germany.

Wọ́n yóò gbé òkú rẹ̀ sí ilé ìgbé òkú sí títí ètò ìsìnkú yóó fi wáyé

Kín Gan lo gbé nígbá ‘kú?

*Kín Gan lo gbé nígbá ‘kú?*
Eyín ká
Ilé ẹ̀rín wó
Ẹyẹ lọ ìtẹ́ dòfo
Àtàǹpàkò ò símọ́
Ọwọ́ dìlagbà
Etí ò sí mọ́
Orí dàpólà igi
Èdè baba èdè,
Ìjìnlẹ̀ baba ìjìnlẹ̀
Yorùbá lọ!
Ṣàngbà fọ́!
Adérẹ̀mí kùn lọ bí oyin
Ọlọ́fàiná,ó di kọ̀ kọ̀ kọ̀
Omi nlá tú lọ lọ́rùn kèrèngbè
Ẹja ńlá wẹbú
Dẹran olúwẹri
Ìjì jà ó gbódó
Afẹ́fẹ́ ti gbẹ̀mí àtùpà
Erin sùn
Erin ò jí mọ́
Adérẹ̀mí Ọlọ́fàiná
Níbo nikú ká ọ mọ́ pa?
Afọ́fun gbému làlùmúntù yí
Iṣẹ́ kíṣẹ́ ló jẹ́
Àṣìlò àgbára lo lò
Adérẹ̀mí ò ì jíṣẹ́ parí
Tálágídíinú fi fẹ̀mí ẹ̀ pamọ́ sálákeji
Oníwàtútù onínúmímọ́
Òṣèèyàn lakùn bíìlẹ̀kẹ̀
Adérẹ̀mí ikú jẹ̀bi rẹ
Bó o bá dọ́run ṣèrántí rojọ́
Fìjìnlẹ̀ èdè fọhùn
Níwájú Ọba tí kìí gbáre fóníṣẹ́ẹbi
Bíkú ṣe já ọ lókún ẹ̀mí pàtì
Lójú agbami iṣẹ́ t’Ólú rán ọ sí gbogbo wa
B’Édùwà bá gbatótónu èyí
A jẹ́ pé kúrákútá ikú pin
Ikú gbèrè ìtìjú nù-un.
Gbogbo ẹgbẹ́ òṣèré
Gbogbo sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀
Gbogbo agbáṣàga
Bá a bá sùn ká mà dijú wọnú
Bá a bá tòògbé ká má mulẹ̀ oorun
Orí àìsùn la ó wà kánrin
Ó dìgbà táabá gbàdájọ́ òdodo lọ́wọ́ BABA

Àwọn agbébọn n gbà tó 300,000 owó orí lọ́wọ́ wa nípìnlẹ̀ Niger’

Àwọn agbébọn n gbà tó 300,000 owó orí lọ́wọ́ wa nípìnlẹ̀ Niger’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn olùgbé ní àwọn agbègbè kan níìpínlẹ̀ Niger ṣì ń sá kúrò ní ilé wọn, nítorí ìbẹ̀rù àwọn jàndùkú agbébọn tó ń bèèrè owó orí lọ́wọ́ wọn.

Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn ìlú bíi Dagon-dawa, Kurigi, Kangerawa, Mangoro, àti àwọn mìíràn ni ọ̀rọ̀ náà kàn.

Àwọn èèyàn kan ní àwọn ìlú náà sọ pé àwọn agbébọn ọ̀hún ń fi ipá mú àwọn láti san owó orí lórí oúnjẹ, ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ àti àwọn nǹkan erè oko wọn.

Ẹnìkan tí ń gbé ní ìlú Dogon Dawa, ṣùgbọ́n tí a fi orúkọ bò ní àṣírí sọ pé àwọn àtìpó gbọdọ̀ sanwó fún àwọn agbébọn kí wọ́n ó tó lè kúrò nílùú.

“ Ọ̀rọ̀ náà ti burú púpọ̀ débi pé àwọn tó wà ní ibùdó ogúnléndé pàápàá ń san owó orí kí wọn ó tó lè fi àwọn ibùdó náà sílẹ̀ .”

Ó ní àwọn oníkúpani ẹ̀dá náà ti sọ àwọn ìlú ọ̀hún di ti wọn, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ wọn lọ láì sí ìbẹrù.

Díẹ̀ lára àwọn aráàlú sọ fun akọròyìn pé owó tí àwọn agbébọn má ń bèèrè lọ́wọ́ ọkọ̀ tó bá kó àwọn tó ń kúrò nílùú wa láàrin ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà sí ọ̀ọ́dúnrún Náírà. Nígbà mìíràn, wọ́n má ń kó ọkọ̀ mẹ́ta pọ̀, tí wọn ó sì bèèrè mílíọ̀nù kan Náírà lọ́wọ́ wọn.

“Ní ọjọ́ Àìkú tó kọjá, mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ Náírà ni a kó ránṣẹ́ sí wọn, láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọkọ̀ kan tó kó dúkìá àwọn èèyàn. Ìdí ni pé àwọn agbébọn náà sọ pé wọn kò ní-ín kọjá, láì san owó náà.”

Ẹlòmíràn tún sọ fún akọ̀ròyìn pé “ọkọ̀ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tó kó oúnjẹ àti irè oko, ni wọ́n dá dúró tí wọ́n sì ń bèèrè ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà lórí ìkọ̀ọ̀kan wọ́n – á ṣì fún wọn.”

Àṣàyàn inú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́dún tuntun nìyí

Àṣàyàn inú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́dún tuntun nìyí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Bola Ahmed Tinubu ti kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú ọdún tuntun bí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ṣe ń kí ọdún 2024 káàbọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tuntun èyí tí Tinubu ti bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kìíní, oṣù Kìíní ọdún 2024, ló ti ní inú òun dùn láti bá àwọn ọmọ Nàìjíríà yọ̀ pé wọ́n tún rí ọdún tuntun.

Tinubu ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn ìgbésẹ̀ àtàwọn ìrìnàjò tó ti rìn láti ìgbà tó ti wà lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ó ní ohun tó fojú hàn ni pé onírúurú àwọn ìpèníjà ló wáyé lọ́dún 2023, àmọ́ ó tún kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé.
Ó wòye pé ṣíṣe ètò ìdìbò àti pípáàrọ̀ ìjọba láì sí wàhálà tàbí títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ èyí tó ṣo ìjọba àwaarawa di ọdún mẹ́rìnlélógún ní Nàìjíríà jẹ́ ohun ìwúrí tó wáyé lọ́dún 2023.

Ó fi kun pé láti ìgbà tí òun ti gba ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ni òun ti ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí òun sì ń sa ipá òun pé ìlọ̀síwájú àti ìdàgbàsókè tó fojú hàn gbọ́dọ̀ bá Nàìjíríà ní èyí tó ṣokùnfà tí òun fi ṣe àwọn ìpinnu kan.

Tinubu tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú ni òun ń gbọ́, tí òun sì mọ̀, pàápàá lórí ọ̀wọ́n gógó tó bá gbogbo ọjà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti wá mẹ́nuba àwọn ìgbèsẹ́ ti ìjọba rẹ̀ ń gbé láti mú àyípadà ọ̀tun bá àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́dún 2024.

Àwọn kókó márùn-ún ti Tinubu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìyí;
*Iná mọ̀nàmọ́ná*
Tinubu ní lásìkò tí òun rin ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè Dubai láti kópa níbi àpérò COP28 ni òun tí ní àjọsọ pẹ̀lú Chancellor orílẹ̀ èdè Germany, Olaf Schol tí àwọn sì ti fẹnukò lórí bí wọ́n ṣe máa lo ìmọ̀ ẹ̀rọ Siemens Energy Power wọlé èyí tó máa pèsè iná tó dúró ire sí ilé mùtúmùwà.

Ó ní láti ọdún 2018 ni ètò náà ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn sì ti fi orí rẹ̀ gún ibìkan báyìí.

Ó fi kun pé iṣẹ́ ti ń lọ káàkiri Nàìjíríà láti ri pé wọn ri àwọn òpó àtàwọn ohun èlò mìíràn tí yóò mú ètò nàá kẹ́sẹ járí.

“Ìjọba mi mọ̀ pé kò sí àyípadà ètò ọrọ̀ ajé kan tó dára tó le wáyé láìsí iná mọ̀nàmọ́ná tó dúró ire.”

*Ètò ààbò*
Tinubu ní àwọn mọ̀ pé ìpèníjà ètò ààbò kò ì tíì kásẹ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ àwọn ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti lè ri dájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà lè dijú tí wọ́n bá ń sùn.

Ó ní ààbò ẹ̀mí àti dúkìá jẹ́ ohun tó jẹ ìjọba òun lógún gidigidi tí àwọn sì ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri pé ààbò tó péye wà fún gbogbo ènìyàn.

Ó fi kun pé ìjọba ti ń ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ láti yọ àwọn kan kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ajínigbé ṣùgbọ́n àwọn kò tíì lè fọwọ́ sọ̀yà pé ìpèníjà ètò ààbò ti kásẹ̀ kúrò pátápátá.

*Ẹbu ìfọpo (Refinery)*
Ààrẹ tún ṣàlàyé ètò fífọ eporọ̀bì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2024 tí a mú yìí.

Ó ní iléeṣẹ́ ìfọpo ti ìjọba tó wà ní Port Harcourt àti ti aládàni ti Dangote máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni pẹrẹu lọ́dún 2024.

*Ìpèsè oúnjẹ*
Ààrẹ Tinubu fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìjọba ti ń jára mọ́ ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti pèsè ilẹ̀ tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta éékà fún ọ̀gbìn àgbàdo, ìrẹsì, álíkámà (wheat) àtàwọn oúnjẹ mìíràn kí oúnjẹ le pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn ènìyàn.

Ó ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yìí pẹ̀lú eékà ilẹ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà nínú oṣù Kejìlá ọdún 2023 ní ìpínlẹ̀ Jigawa lábẹ́ ètò National Wheat Development Programme.

*Ìdókoòwò*
Ààrẹ tún ṣàlàyé pé ìjọba ti ṣetán láti rí dájú pé àtúntò àti àtúnṣe bá ètò owó orí gbígbà láti ri dájú pé àwọn ènìyàn lè dókoòwò bí wọ́n ṣe fẹ́ ní Nàìjíríà.

Ó ní gbogbo ìrìnàjò tí òun bá rìn, ni òun máa ń sọ fún àwọn olùdókòwò pé ààyè ṣí sílẹ̀ ní Nàìjíríà láti gbé okoòwò wọn wá lójúnà àti pèsè iṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu.

Ó ní ìjọba òun kò ní fi ààyè gba ohunkóhun tó bá le gbégi dínà tí àwọn olùdókòwò kò fi ní gbé okoòwò wọ Nàìjíríà.

Tinubu parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbé orílẹ̀ èdè yìí dé èbúté ògo.

Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀hónúhàn pé wọn ò r’owó àjẹmọ́nú gbà

Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀hónúhàn pé wọn ò r’owó àjẹmọ́nú gbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ọlọ́pàá tó ń gbógunti ìwà ọ̀daràn ní ẹ̀kùn ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fẹ̀sùn kan pé, wọn kò san àwọn owó àjẹmọ́nú àwọn.

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún, ni àwọn tí wọ́n gbé láti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan lọ sí ẹ̀kùn náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn láti lọ mójútó ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń wáyé lẹ́kùn náà.

Wọ́n ní bí àwọn kò ṣe rí àwọn owó àjẹmọ́nú náà gbà ń ṣe àkóbá fún àwọn.

Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún tó bá oníròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé oṣù kẹjọ rèé tí wọ́n ti gbé òun lọ sí ẹ̀kùn náà láti lọ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun láti kojú ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń wáyé ní agbègbè náà.

Ó ní láti oṣù kẹjọ náà, owó àjẹmọ́nú oṣù méjì péré ni wọ́n san fún òun níbẹ̀, tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn sì ń gba ti wọn.

Ó ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni owó oṣù òun ń lọ dédé.

“Ìṣòro tí à ń kojú lórí àjẹmọ́nú wa tí a kò rí gbà kò kéré rárá nítorí owó oṣù wa nìkan ni à ń lò láti fi gbọ́ gbogbo bùkátà wa.

“Nínú owó oṣù yìí ni a ti ń jẹun, tọ́jú ìlera wa, ṣe ìtọ́jú àwọn nǹkan mìíràn tó bá yẹ.”

Ó wá rọ àwọn adarí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti mójútó sísan àwọn owó tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn fún wọn nítorí ibi tó jìnà ni wọ́n ti gbé ọ̀pọ̀ wọn lọ sí ẹ̀kùn náà tó sì ti ń kó ìnira bá wọn.

Gbogbo ìgbìyànjú akọ̀ròyìn láti bá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn yìí lo já sí pàbó nítorí bí agbẹnusọ ọlọ́pàá kò ṣe gbé ìpè rẹ̀.

A kú o̩dún 2024

A kú o̩dún 2024

 

A kú o̩dún

A kú o̩dún

https://www.instagram.com/p/Cm9zag4KYBp/?igsh=MzRlODBiNWFlZA==

Òsèré tíátà Laide Bakare se ìgbéyàwó e̩lé̩è̩ké̩ta

Òsèré tíátà Laide Bakare se ìgbéyàwó e̩lé̩è̩ké̩ta

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata Naijiria, Laide Bakare ti setan lati se igbeyawo fun igba keta leyin meji akoko to kuna.

Eni odun metalelogoji naa se ikede yi ni oju awe Instagram re ni ojo Aje.

E ranti pe osere tiata yi saaju se igbeyawo pelu Olumide Kunfulire eni ti o bi omobinrin re Simi, fun ni 2008.

Ni 2013 Bakare tun se igbeyawo leekeji pelu gbajumo ilu Eko, Tunde Oriowo eni ti o bi omokunrin meji fun.

Amo sa, nigba ti o n kede igbeyawo re keta to n bo wa, osere naa fi fonran ara re pelu afesona re lede.

O fi oro ifori sori fonran naa, o ko o pe: “Ife je ohun to rewa. E darapo mo wa ni ojo Abameta yi, ojo kejo osu kejila ni AMORE GARDEN Lekki phase 1 ni aago marun irole. Mo n reti lati gbalejo gbogbo yin.”

 

 

 

Bí ò̩gá mi se mú ìrè̩wè̩sì bá o̩ko̩ mi láti máse fé̩ mi’ – Helen Paul

Bí ò̩gá mi se mú ìrè̩wè̩sì bá o̩ko̩ mi láti máse fé̩ mi’ – Helen Paul

Mary Fágbohùn

Ilumooka aderinposonu obinrin, Helen Paul ti ranti bi oga re lenu ise se gbiyanju lati mu irewesi ba oko re, Femi Bamisile, lati mase fe tabi se igbeyawo pelu re.

O ni oga oun so fun oko oun pe oun ko dara fun lati fe.

Oluko fasiti to fi ile US se ibugbe naa so pe oga asakoso omoniyan (Human Resources, HR,) re lenu ise gbiyanju lati ba ibasepo to wa laarin oun ati oko oun je.

O soro lori eto The Honest Bunch Podcast laipe yi ti oun pelu ilumooka osere tiata , Chinedu Ani Emmanuel, ti a mo si Nedu jo tuko re.

Paul wi pe, “Oga mi pe oko mi o wi pe, ‘Femi, se iru Helen yi lo fe fe? O ju iyen lo. Sugbon ti o ba fe gbadun re, o dara o!’

“Mo mu Femi lo si ofiisi mi nigba naa ni TVC, alakoso HR mi wo Femi o si wi pe, ‘’wo bi o se mo, agbejoro. Ki lo de ti o yan Helen?’”

E ranti pe Helen Paul ati Femi Bamisile se igbeyawo ni 2010. Ibasepo naa ni Olorun si bukun pelu omo meji.

Mo kó̩ èdè Yorùbá láti orí YouTube’ – Olorin Teni

Mo kó̩ èdè Yorùbá láti orí YouTube’ – Olorin Teni

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin, Teniola Apata, ti a mo si Teni, ti safihan pe o ko ede Yoruba lati ori YouTube.

Eni odun mokanlelogbon naa so pe bo tile je pe awon obi oun je Yoruba, oun ko lati so ede naa nipa wiwo fiimu Yoruba lori YouTube nigba ti oun wa ni Amerika.

O safihan eyi lori eto Zero Conditions laipe yi.

O wi pe, “Se e mo bi mo se ko lati so Yoruba? Nigba ti mo lo si Amerika ni. Mo ko lati ori YouTube. Mo n wo fiimu Yoruba gidi.”

Teni tun safihan ninu ijomitoro oro naa pe oun bere si ni mu oti ni odun 2021.

O ni saaju igba naa oun ko mu oti tabi fa siga ri.

Olorin naa tun fihan pe ipinnu oun lati bere si ni mu oti je “ere”.