Home Blog Page 80

Àsekágbá bọ́ọ̀lù Super Eagle : Ọ̀rọ̀ bí ìmò̩ràn fún àwọn ọmọ Naijiria tí wọn bà ní ẹ̀jẹ̀-ríru.

Àsekágbá bọ́ọ̀lù Super Eagle : Ọ̀rọ̀ bí ìmò̩ràn fún àwọn ọmọ Naijiria tí wọn bà ní ẹ̀jẹ̀-ríru.

Gbọ́láhàn Quseem

Kọmiṣanna tẹlẹ fun eto igbokegbodo ọkọ ati iṣẹ ode nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Rẹmi Ọmọwaiye, ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọmọ Naijiria ti wọn ni aisan ẹjẹ-riru lati ma ṣe wo aṣekagbaa bọọlu AFCON ti yoo waye laarin ikọ agbabọọlu orileede Naijiria ati ti orileede Cote D’ivoire, lọjọ Aiku, Sannde to n bọ yii.
Eleyii ko ṣẹyin bi iroyin ṣe n lọ kaakiri nipa awọn eeyan ti wọn gbẹmi-in mi lẹyin idije to kangun si aṣekagba to waye laarin Super Eagles ati Bafana Bafana, ti orileede South Africa, l’Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Keji, ọdun yii.
Bi ọkunrin oloṣelu kan, Dokita Cairo, ṣe ku nipinlẹ Delta, naa ni ọkunrin oniṣowo kan to jẹ ọmọ orileede Naijiria ku lorileede Cote D’ivoire. Bakan naa ni agunbanirọ kan to n sinru ilu ni Kaduna gbẹmi mi, ọrọ naa ko si yọ igbakeji akọwe Poli Kwara silẹ.
Iku gbogbo wọn ni awọn dokita oyinbo lọdii rẹ mọ bi aya wọn ṣe ja ju lasiko ti ere bọọlu naa n lọ lọwọ pẹlu ifunpa giga ti wọn ti ni tẹlẹ.
Latari idi eyi, Ọnarebu Rẹmi Ọmọwaiye sọ pe ohun to ṣẹlẹ lọjọ Wẹsidee yẹn ko tun gbọdọ ṣẹlẹ lonii nibikibi, idi niyi ti onikaluku fi gbọdọ mọ iwọn ara rẹ.
O ni ṣe loun gan-an bẹrẹ si i gbọn latinu, lasiko ti rẹfiri sọ pe ki awọn Bafana Bafana gba bọọlu goli-wo-mi-n-gba-a sinu awọn (net) Super Eagles lọjọ naa.
Ọmọwaiye sọ siwaju pe dipo ki awọn ti wọn ni ẹjẹ-riru wo bọọlu ọjọ Sannde yii, ṣe ni ki wọn fara balẹ wo atungba rẹ lẹyin ti wọn ba ti gbọ abajade ere bọọlu naa.

Pásítọ̀ Adeboye gégùn-ún ńlá lórí pẹpẹ

Pásítọ̀ Adeboye gégùn-ún ńlá lórí pẹpẹ

Wùmí Adétúyì

Èèyàn tí wọn ṣàdúrà fún, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ì gbọ́, débi ẹni tó forí gba ègún ayérayé.
Àṣamọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni pé, Pásítọ́ àgbà ìjọ Oníràpadà ti Kírístì, ‘The Redeemed Christian Church Of God’ (RCCG), Pásítọ̀ Enoch Adébóyè, ti gbórí pẹpẹ ṣépè ńlá fáwọn agbébọn tí wọ́n ń lọ káàkiri àrin ìlú, pàápàá jùlọ nílẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n sì ń pa àwọn Ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá nípakúpa.

Pásítọ̀ agbta ọ̀ún fi gbogbo àwọn oníṣẹ́ ibi náà ré lásìkò ètò ìjọ náà kán tó máa ń wáyé lóṣooṣù nínú ìjọ ọ̀hún, èyí tí wọ́n pé àkòrí toṣù yíì ni ‘ *Láti* *Orí* *Òkè* *wá* ’, pé iná Ọlọ́run láti orí òkè wá ló máa jó gbogbo àwọn tó ń pa àwọn Ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá run pátápátá.

Bàbá Adébóyè ni, ‘‘Gẹ́gẹ́ bí ohùn Ọlọ́run Ọba, ẹni àmì-òróró ni gbogbo àwọn Ọba jẹ́, pàápàá jùlọ àwọn Ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá, fún ìdí èyí, iná Ọlọ́run láti òkè wá ló máa jó gbogbo àwọn ọ̀bàyéjẹ́ àtàwọn oníṣẹ́ ibi gbogbo tó ní yẹpẹrẹ, àtàwọn tó nípa àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá bayìí.

Bí ẹ ò bá gbàgbé, àìpẹ́ yíì ni àwọn agbébọn kan pa àwọn Ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá mẹ́ta láàrin ọjọ́ mẹ́rin síra wọn.

Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kín-ín-ní, ọdún 2024 yìí, ní wọ́n pa Ọba Onímòjò tìlú ìmòjò-Èkìtì, Ọba Ọlátúndé Olúṣọlá àti Ọba Elesun tiluu Esun-Ekiti, Ọba David Ògúnṣọlá, lásìkò tí wọ́n ní padà bọ̀ láti ìlú Ìrèlè-Èkìtì, níbi tí wọ́n ti lọ ṣèpàdé àwọn lọ́balọ́ba kan. Nígbà tó tún máa fi di Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kín-ín-ní, oṣù Kejì, ọdún 2024 yìí, ni àwọn agbébọn ọhún tún wọ àfin Ọba Olúkòró tìlú Kòró, ìpínlẹ̀ Kwara, wọ́n sì pa Ọba Ṣẹ́gun Àrẹ̀mú dànù. Wọ́n yìnbọn paá mọ́nú ààfin rẹ̀ ní lẹ́yìn náà ni wọ́n tún jí ọ̀kan lára àwọn Olorì rẹ̀ gbé sálọ ráuráu.

Ìlú Koro yìí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà púpọ̀ sílùú méjì àkọ́kọ́ tàwọn agbébọn ọ̀hún tí pa àwọn Ọba ìlú náà láàárín àsìkò díẹ̀ síra wọn.

Ṣé, àwọn aláṣẹ ilẹ́-iṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè wa ti bẹ̀rẹ̀ ìwádíì nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, tí wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ abẹ́nú lórí rọ̀ ọ̀hún. Sùgbọ́n wọ́n ti se àwárí Olórí àti Ọmọ ọ̀dọ̀ náà ọwọ́ sí titẹ awọn amọ òkùnkùn sèkà náà

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfí ọ̀hún to ń wáyé sàwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá yìí ló mú kí Pásítọ̀ Adébóyè fi àwọn agbébọn yìí gégún-ún lórí pẹpẹ.

Amẹ́ríkà ṣetán àti ta bàlúù ọmọogun fún Nàìjíríà

Amẹ́ríkà ṣetán àti ta bàlúù ọmọogun fún Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Abàsíbíòwú ẹlikópítà iléeṣẹ́ ológun òfurufú ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti gbà láti ta àwọn nǹkan ìjà ológun fún Nàíjíríà kí wọ́n báa lè fi kojú àwọn jàndùkú agbébọn àti ikọ̀ Boko Haram.

Ọdún 2022 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìdúnàdúrà lórí nǹkan ìjà ológun yí ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilé aṣòfin Amẹ́ríkà kan tó ní ó yẹ kí Nàíjíríà kájú òṣùnwọ̀n kọ̀ọ̀kan tí wọ́n là kalẹ̀ kí èyí tó lè wáyé.

Bóti lẹ̀ jẹ́ wí pé Nàíjíríà ti gbé iṣẹ́ àgbàṣe ríra nǹkan ìjà ológun mìí síta ṣáájú àsìkò yí, eléyìí ni ó pọ̀ jùlọ nínú àkọsílẹ ìdòwòpọ̀ Nàíjíríà àti Amẹ́ríkà lórí ọ̀rọ̀ nǹkan ìjà ológun.

Iye nǹkan ìjà ológun tí wọ́n fẹ́ tà fún Nàíjíríà lásìkò yí la gbọ́ pé ó jẹ́ bílíọ̀nù dọ́là kan.

Nínú àwọn nǹkan ìjà ológun yí la ti rí àwọn bàálù abàsíbíòwú táa mọ̀ sí ẹlikọ́ptà AH-1Z méjìlá àti àwọn ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà méjìlélọ́gbọ̀n láti ọ̀dọ̀ Northrop Grumman.

Àtẹ̀jáde tó fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ yí jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti túnbọ̀ fagbára fún Nàíjíríà nípa kíkojú àwọn ìpèníjà ààbò.

Ìpèníjà ààbò Nàíjíríà táa ń wí yí ti sọ àìmọye mílíọ̀nù èèyàn di aláìnílélórí tí ó sì túnmọ̀ sí pé ríra àwọn ẹlikọ́ptà yí ní oṣù Kẹfà ọdún 2024 yóò kó ipa ribiribi bá àgbéga irinṣẹ́ nǹkan ìjà ogun Nàíjíríà.

Ọ̀gágun Sadiq Garba tó ti fẹ̀yìntì nídì iṣẹ́ ológun ní Nàíjíríà jẹ́ èèyàn kan tó ti ń fọkàn tẹ̀lé ìdúnàdúrà nǹkan ìjà ológun yí láti ọdún 2022.

Ó ní ”bààlú abàsíbíòwú yí làwọn ológun ti ń lò láti ìgbà ogun Vietnam. Wọ́n máa ń gbe tẹ̀lé àwọn ọmọ ogun oríilẹ̀ tí a ṣì máa ṣáájú la ọ̀nà kí àwọn ọmọ ogun oríilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.”

Ó tẹ̀síwájú pé bàálù yí lágbára ”láti gbé ìbọn ẹlẹ́nu mẹ́ta tó lè yin ọ̀tá dé kìlómítà méjì tí a ṣì máa kó ọta ìbọn 750 sí ìkápá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ó tún lè gbé àwọn àdó olóró bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n lè fi ṣiṣẹ́ lálẹ”

Ó fikun pé àwọn bàálù yí á tún máa gbé ẹ̀rọ kòmpútà kan sára tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè dá ààbò bo àwọn aráàlú.

Èyí ṣe pàtàkì láti dènà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé sẹ́yìn níbi tí wọ́n ti ṣèṣì pa àwọn aráàlú pẹ̀lú nǹkan ìjà ológun.

Ọ̀gágun Sadiq sọ pé látẹ̀hìnwá Amẹ́ríkà ń ṣọ́ra láti ta nǹkan ìjà olóró fún Nàíjíríà torí pé wọ́n á máa fi irúfẹ́ rẹ̀ ṣeku pa àwọn aráàlú.

Ó ní báyìí Amẹ́ríkà yóò ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tí yóò bá a wa bàálù yí.

”Ẹ̀rọ kọ̀mpútà inú bàálù yí yóò jẹ́ kí awakọ̀ bàálù rí nǹkan tó fẹ́ yìnbọn lù. Yóò lè sọ fún bóyá àwọn aráàlú tàbí àwọn jàndùkú ló fẹ́ yìnbọn lù. Ìrètí wa ni wí pé táa bá ní irú nǹkan ìjà ológun yí, kò ní sí irú àṣìṣe tó wáyé tí àwọn aráàlú ń farakásá lọ́wọ́ ikọ̀ ológun”

Wọ́n yìnbọn mọ́ aṣáájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Wọ́n yìnbọn mọ́ aṣáájú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Gbolahan Quseem àti Fẹ́mi Akínṣọlá

Arákùnrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP kan tó jẹ́ olùkọ́ lóílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà,Ọ̀gbẹ́ni Richard ldowu, ẹni tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Adéoríọ̀kín,ló ti padé ikú ójijì lásìkò tí ọlọ́dẹ kan yìnbọn lù ú,tí ó sì kú pátápátá.

Ìlú Èjìgbò, ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun,ni ‘ṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti ṣẹlẹ̀ láàrin aago mẹ́jọ sí mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta,Sátidé,ọjọ́ kẹtádínlọ́gbọ̀n,osù kín-ní-ní,ọdún yìí,ní ‘wáju ilé ọmọ ‘ba, Ẹniọlá Oyèyọdé.

Gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún olóògbé náà tí ‘ṣẹ̀lẹ̀ yí sojú ẹ̀,Afiz Lawal ṣe sàlàyé,ó ní ibi ayẹyẹ kan tí wọ́n ti fi oyè dá Gómìnà Adémọ́lá Adélékè lọ́lá ní ‘pínlẹ̀ Ògún ni gbogbo àwọn gbà darí sí bi ayẹyẹ àádọ́ta ọdún tí Ògìyán ìlú Èjìgbò,Ọba Oyèyọdé Oyèsọ́sìn, gun orí ìtẹ́ àwọn bàbá nlá rẹ̀.

O nì “Ní kété tí wọ́n parí ayẹyẹ náà ni Ọmọọba Ẹniọlá tó jẹ́ ọmọ Ógìyán sọ pé ká kọjá sí ‘lé òun lágbègbè Ìníṣà,ní ‘lú Éjìgbò,fun ìpàdé kékeré kan.”

Àwọn tí wọ́n wà níbi ìpàdé náà ní Ọnarébù Ayọ̀délé Aṣalu,tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Asler, àti Ọnarébù Timothy.Bí wọ́n ṣe parí ìpàdé yẹn ni kálukú bọ́ sínú mọ́tò ẹ. “Mo gbọ́ tí Ọmọọba Ẹniọlá sọ pé “rìlíìsì” (Release),bẹ́ẹ̀ làwọn ọlọ́dẹ (Local Hunters) tí wọ́n wà nibẹ̀ dàbọn bolẹ̀ ,wọ́n n yìn-ín sójú òfurufú.”

“Sùgbọ́n dípò kí ọkan lára wn yin ìbọn tiẹ̀ sójú òfurufú,ilẹ̀ ló yìn-ín sí,ó sì ba Ọ́nárébù Richard ldowu lẹ́ṣẹ̀,wọ́n subú lulẹ̀.Ká tó dé ọsibítù,wọ́n ti pàdánù ẹ̀jẹ̀ púpọ̀.”

“IIé ‘wòsàn alàdàáni kan ni wọ́n kú sí ní ‘lú Èjìgbò,a ti gbé òkú wọ́n lọ sí ‘lé ìgbókùúpamọ́sí tó jẹ́ ti UNIOSUNTH,ni ‘lú Oṣógbo.”

Ohun tí a gbọ́ ni pé lójù-ẹṣẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ làwọ̀n tí wọ́n wà níbẹ̀ ti lu ọlọ́dẹ náà pa, sùgbọ́n Lawal ní oun kó le fi ìdí ìyẹn múlẹ̀.

Kọ̀mándà awọ̀n ọlọ́dẹ l’Ọ́ṣun,Hunters and Forest Security Service, Ahmed Nureni, sọ pé kò sí ọmọ ẹgbẹ́ óun kankan tó wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sì pè fún ìwádìí tó gbọn-n-gbọn lórí rẹ̀.

Ní bàyìí ,Gómìnà ìpínlẹ̀ ,Sẹ́nátọ̀ Adémọ́lá Adélékè,ti pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ìwà ìṣekúni nàà ní kíákiá.

Ninú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ fun Gómìnà,Ọláwámí Rasheed,fi síta ló ti sọ̀ pé Gómìnà ti pàṣẹ fún àwọn agbófinró láti túṣu désàlẹ̀, ‘kókó lórí ‘ṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hun,kí wọ́n sì ri dájú pé wàhálà kankan kó bẹ́ sílẹ̀ lààrin ìlú látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Adélèkè rọ àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé láti mọ́ se gbẹ̀san fúnra wòọn , bẹ́ẹ̀ ló si ti rán kọmísánnà ọlọ̀pàá, kọmísánnà fún ọ̀rọ̀ oyè jíjẹ àti ìjọba ìbílẹ̀, kọmìsánnà fún ètò ìròyín ati olùdàmọ́ràn pàtàkì rẹ̀ lórí ètó àábò lọ síbẹ̀.

Adájọ́ kò gba ìdírẹ̀ẹ́bẹ̀ Udom tó gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n Kiríkirì

Adájọ́ kò gba ìdírẹ̀ẹ́bẹ̀ Udom tó gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n Kiríkirì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìlú tí kò sófin,ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀ làwọn àgbà wí.
Iwájú Onídàájọ Oyindamọla Ọgala, tilé-ẹjọ́ gíga kan tó wà nílùú Ikeja, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Udom, tó gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa lọ. Ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìwà ọ̀daràn ni Agbèfọ́ba, Ọ̀gbẹ́ni Ọla Azeez, tó fojú olùjẹ́jọ́ balé-ẹjọ́ fi kàn án ní kóòtù.

Oun tí a gbọ́ ni pé ọ̀rọ̀ kékeré kan ló dija sílẹ̀ láàrin Udom ati Olóògbé Moses Joseph, lọ́jọ́ kẹrin, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022, nílùú Igando, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Káwọn èèyàn ṣì tóó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, Udom ti fọ̀bẹ gún ẹni kejì rẹ̀ tí wọ́n jọ ń jà pa pátápátá. Látìgbà náà sì lẹjọ rẹ̀ ti wà ní kóòtù, kó tóó di pé wọ́n ṣẹjọ́ rẹ̀ l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí.

Nígbà tó máa sọ̀rọ̀, olujẹjọ lóun kò jẹbi gbogbo ẹ̀sùn tí agbèfọ́ba fi kan òun rárá.

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ ọ̀hún ní kí wọ́n da Udom padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ sí ọjọ́ kẹrin, oṣù Kẹta, ọdún 2024 yìí.

Gómìnà Ayédatiwa kédé igbákejì rẹ̀ lẹ́yìn tó tú ìgbìmọ̀ ìpínlẹ̀ ìsèjọba ìpìnnlẹ̀ Ondo ká.

Gómìnà Ayédatiwa kédé igbákejì rẹ̀ lẹ́yìn tó tú ìgbìmọ̀ ìpínlẹ̀ ìsèjọba ìpìnnlẹ̀ Ondo ká.

Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo ti kéde orúkọ Ọláyídé Owólabí Adélamì gẹ́gẹ́ bi igbákejí rẹ̀.

Ìdéde yi wáyé ní ọjọ́rú lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó tú ìgbìmọ̀ ìsèjọba ìpínlẹ̀ náà ká.

Adélámì jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀wọ̀, ìyẹn ìlú Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rótìmí Akérédolú.

Bákannáà, igbákejì akòwé àgbà ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ Nàíjíríà ní Adélámì tẹ́lẹ̀ kí o tó fipò sílẹ̀.

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ náà fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ náà fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti rí ìwé ọrúkọ Ọláyídé Owólabí Adéláídé tí Gómìnà Lucky Ayédatiwa fi ránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi ẹni tí ó yàn ní igbákejì rẹ̀.

Lọla ni ìrèyí wà pé yo fi ara hàn níwájú ilé aṣòfin náà fún àyẹ̀wò ní ìbàmu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ìwé òfin Nàìjíríà.

Ikú gbígbóná! Bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ márùn-ún jóná kú mọ́nú ilé

Ikú gbígbóná! Bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ márùn-ún jóná kú mọ́nú ilé

Fẹ́mi Akínṣọlá

À fi kí ààbò Ẹlẹ́dàá ṣáà má a dájú lórí i wa tẹbítará.
Kò sẹni tó máa gbọ́ bí iná ṣe run odidi ìdílé kan pátápátá tí omijé kò ní í dà pòròpòrò lójú èèyàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ ọ̀hún wáyé lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ kẹrìnlá, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí, lágbègbè Tudun-Wada, ní ìjọba ìbílẹ̀ Wada-Bompai, ní ìpínlẹ̀ Nasarawa.

Bàbá, ìyá àt’àwọn ọmọ márùn-ún tí wọ́n wà nínú ilé ọ̀hún ni wọ́n kú kó tó di pé wọ́n gbé wọn dé ilé ìwòsàn ìjọba tó wà lágbègbè náà fún ìtọ́jú.

Òun tí a gbọ́ ni pé àṣáálẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù yìí, ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún wáyé, ati pé ojú oorun ni iná ọ̀hún ká gbogbo wọn mọ́. Káwọn aráalé àti àwọn aráàdúgbò sì tóó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, kò sẹ́ni tó lè sún mọ́ iná ọ̀hún, nítorí tó ti fẹjú gidi.

Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná agbègbè Dakata, Alhaji Saminu Abdullah, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún múlẹ̀ fáwọn oníròyìn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kín-ín-ní, ọdún 2024 yìí, sọ pé aráàlú kan tó n jẹ́ Ibrahim Sani, ló pe iléeṣẹ́ àwọn láṣàálẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé, táwọn sì sáré lọ síbẹ̀.

Ó ní nígbà táwọn débẹ̀, àwọn gbé bàbá, ìyá àt’àwọn ọmọ wọn márùn-ún kan táwọn bá nínú ilé náà jáde, táwọn si sáré gbé gbogbo wọn lọ síléèwòsàn fún ìtọjú, ṣùgbọ́n àwọn dókítà sọ pé òkú àwọn èèyàn náà làwọn gbé wá síléèwòsàn yii.

Ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn gbangba pé nígbà táwọn ilé iṣẹ́ NEPA agbègbè náà múná wọn dé lójijì ni iná burúkú ọ̀hún ṣẹ yọ lójijì nínú ilé àwọn olóògbé náà, ṣùgbọ́n nítorí pé ojú oorun ló bá wọn ní wọn kò ṣe mọ ibi tí wọn á sá sí tàbí bí wọn á ṣe tètè paná ọ̀hún kó tóó di ohun ńlá mọ́ wọn lọ́wọ́.

Àwọn dókítà ní èéfín iná tí ọkọọkan àwọn èèyàn ọhún fà símú gan-an ló ṣokùnfà bí wọ́n ṣe kú lẹ́ẹ̀kan náà

Ẹ yéé gba ríbà lọ́wọ́ ọ̀daràn: Alága EFCC kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀

Ẹ yéé gba ríbà lọ́wọ́ ọ̀daràn: Alága EFCC kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀


Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní èèyàn tí yóó fọ àwùjọ mọ́, yóó fọ yóó fọ araarẹ̀ pẹ̀lú mọ́ ọ.
Èyí ló bí bí Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku nílẹ̀ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ṣe ṣèkìlọ̀ pàtàkì fáwọn òṣìṣẹ́ àjọ ọ̀hún tó jẹ́ pé wọ́n máa ń gba r’íbà lọ́wọ́ àwọn afurasí ọ̀daràn gbogbo tí wọ́n ń ṣèwádìí nípa wọn lọ́wọ́ láti lè dójú ẹjọ́ wọ́n rú pé kí wọ́n jáwọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ọla Olukayọde tó jẹ́ adarí wọ́n ló sọ̀rọ̀ ọ̀hún di mímọ̀ lásìkò tó ń ṣèpàdé àkọ́kọ́ nínú ọdún pẹ̀lú wọ́n ni olú ilé-iṣẹ́ wọn tó wà ní Jabi, nílùú Àbújá, l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí.

Ó ní nǹkan ìdójútì gbáà ni pé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ń lọ́wọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀ . Ó fi kún-un pé lásìkò ìṣèjọba tòun yìí, òun kò ní gba irú ìwà bẹ́ẹ̀ láàyè. Olukayọde ni tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ọ̀hún tí wọ́n kúndùn irúfẹ́ ìwà láabi ọ̀hún kò bá sì jáwọ́ nínú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀, ẹni tí òfin bá gbá mú yóó kábàámọ̀ ìwà burúkú tó hù náà.

Ó ní, ‘‘ Ó ti tó àkókò fún mi báyìí láti ṣe ìtẹnumọ́ lórí ìwà kíkọ ara ẹni ní ìjánu, àti fífi ìwà ọmọlúàbí ṣiṣẹ́ wa. Ojú tí àwọn aráàlú fi ń wo ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn wa tó máa ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí kì í ṣe èyí tó dáa rárá. Ìṣọwọ́ bèèrè r’íbà àtàwọn owó tí kò bófin mu bẹ́ẹ̀ ti ń mú ìtìjú bá iṣẹ́ wa, kò sì yẹ kó tẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ń tún fi àsìkò yìí ṣe ìkìlọ̀ gidigidi pé mi ò ní i rò ó lẹẹmeji tí má a fi fi idà òfin gé ẹnikẹ́ni tó bá hu irú ìwà yìí lọ́wọ́ tí ọwọ́ bá ti tẹ̀ ẹ́.

‘‘Mo ti sọ fún ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ abẹ́lé pé kí wọ́n jí gìrì sí iṣẹ́ wọn lórí eléyìí, kí wọ́n sì máa sọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórí ìgbésẹ̀ gbogbo tí wọ́n bá ń gbé nípa iṣẹ́ wọn. Orúkọ àjọ yìí ṣe pàtàkì ju kí òṣìṣẹ́ alájẹbánu kan wá bà á jẹ́ lọ’’

Bẹ́ẹ̀ ló fi kún un pé àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ìgbáyé-gbádùn àwọn òṣìṣẹ́ yìí.

.

KebeN’Kwara Kollington Ayinla wà lọ́sibítù lórí àìsàn tó lè koko

KebeN’Kwara Kollington Ayinla wà lọ́sibítù lórí àìsàn tó lè koko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lásìkò yìí, inú ìbẹ̀rù àti ìpayà ọkàn gidi ni àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn olólùfẹ́ èèkàn olórin Fújì nnì, Alaaji Kọllington Ayinla, táwọn èèyàn mọ̀ sí KebeN’Kwara wà látàrí bí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí kan ṣe dá a gbálẹ̀, ipò tó le koko ló sì wà lọ́sibítù ìjọba báyìí, níbi tí wọ́n ti ń tọjú àwọn tí àìsàn wọ́n le gidi, wọ́n lọ́kùnrin náà kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, afẹ́fẹ́ oxygen ni wọ́n fi rọ́bà fà sí i nínú tó fi ń mi.

Òun tí a gbọ́ ni pé nǹkan bíi àṣálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kínní ọdún 2024 ni àárẹ̀ ọ̀hún fẹ́ gbòdì lára bàbá náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni Kebe, Bàbá Alágbàdo, gẹ́gẹ́ bó ṣe pé ara rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn rẹ́kọ̀ọ̀dù rẹ̀, tí ń bá àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti àìlera kíndìnrín fínra.

Lálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sáré gbé e dìgbàdìgbà lọ síléèwòsàn aládàáni kan, ní agbègbè Alákùkọ, ti kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilé rẹ̀ ní Alágbàdo, ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n ní mí-mí ọkùnrin náà ti di gule-gule, gbogbo nǹkan sì ti fẹ́ dojú rú nígbà tí yóó fi délé-ìwòsàn, èyí ló fà á tí wọ́n fi tètè gbé ẹ̀rọ téèyàn fi ń mí pẹ̀lú atẹ́gùn oxygen sí i lára, láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀.

Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, ni àwọn dókítà ilé ìwòsàn aládàáni ọ̀hún kọ̀wé pé kí wọ́n tètè máa gbé Kollington Ayinla lọ ilé ìwòsàn Jẹ́nẹ́rà tó wà n’Íkẹjà, fún ìtọ́jú tó péyé . Ọsibítù náà sì ló wà títí di bá a ṣe ń sọ yìí.

A gbọ́ pé níṣe ni ẹsẹ̀ àgbà ọ̀jẹ̀ onífújì yìí wú rọbọtọ, tí wíwú náà kò sì rọlẹ̀ rárá. Yàtọ̀ sí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ìyẹn dayabẹ́tììsì àti àìlera kíndìnrín tí iṣẹ́ rẹ̀ kò péye tó, àwọn tí wọ́n sún mọ́ bàbá náà sọ pé ó tún ní àìsàn ọgbẹ́-inú , ulcer, torí ìdí èyí ni kì í ṣe fi oúnjẹ ṣeré rárá, àmọ́ lásìkò yìí, wọ́n ní bàbá náà kò tiẹ̀ lajú, tàbí sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lè jẹun, àfi èyí tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ fà á sí i lára.

Ṣá, ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ti wọlé àdúrà fun Kollington, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin (74), tí wọ́n sì n bẹ Ọlọ́run kó dáwọ́ lé e, kí ara rẹ̀ lè mókun padà.Bẹ́ẹ̀ làwọn onífújì ẹlẹ́gbẹ rẹ̀ náà ti dìde ìrànwọ́ àti àtìlẹ́yìn fún un.

Ẹ ó rántí pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Alaaji Kọllington Ayinla àti ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ rẹ̀, Alaaji Sikiru Ayinde Barrister tó dolóògbé lọ́jọ́sí fi léwájú nídìí iṣẹ́ orin Fújì, tí wọ́n sì jọ figagbágba gidi, títí tí wọ́n fi gbé ògo iṣẹ́ náà dé ìlú òyìnbó, tí wọ́n fi di ìlúmọ̀-ọ́n-ká.

Ọ̀pọ̀ rẹ́kọ̀ọ̀dù àti eré ni bàbá náà ṣe, àkàákàtán sì ni eré òde àti oyè tí wọ́n fi dá a lọ́lá.

Gómìnà Seyi Mákindé ṣàlàyé ohun tó fa ìbúgbàmù ní Ìbàdàn

Gómìnà Seyi Mákindé ṣàlàyé ohun tó fa ìbúgbàmù ní Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní olè ò ní-ín jàgbà kó má ṣe é lójú fìrí, bẹ́ẹ̀ ojúlówó ọmọ onílùú kò ní fẹ́ ó tú.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí nígbà tí Mákindé ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà ti wáyé, bó ṣe ṣàpèwúye ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí èyí tó ba ni lọ́kàn jẹ́ nítorí ó mú ẹ̀mí lọ.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàlàyé pé ìwádìí ti fihàn pé àdó olóró táwọn èèyàn kan tó ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́ kó pamọ́ síbì kan ló ṣokùnfa ìbúgbàmù náà.

Mákindé ní ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, àmọ́ gbogbo ẹni tó bá wà nídìí ìbúgbàmù yìí ni yóó fojú winá òfin.

‘’Lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti lọ síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ àṣekára .

Wọ́n ṣiṣẹ́ láti alẹ́ di àárọ̀ Ọjọ́rùú ni, oríṣìíríṣìí irinṣẹ́ ìdóòlà ẹ̀mí, ọkọ̀ ańbúláǹsì àtàwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ló ti wà níbẹ̀.

Ní báyìí, èèyàn mẹ́tàdín lọ́gọ́rin ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, àmọ́, wọ́n ti gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, wọ́n sì ti padà sílé wọn.

Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé èèyàn méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lọ, kí Ọlọ́run tẹ́ wọn sí afẹ́fẹ́ rere kí Ó sì tu àwọn ẹbí wọn nínú.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóó san owó ìtọ́jú àwọn èèyàn tí wọ́n ṣèṣe níbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Ìjọba tún máa pèsè ilégbèé fáwọn tí kò nílé lórí mọ́ látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí,’’ Mákindé ló sọ bẹ́ẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá rọ gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti pé nọ́ńbà 615 fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, nígbà tí ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n farabalẹ̀ àti pé kí wọ́n jìnà sí ibi tí ìbúgbàmù náà ti wáyé, káwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí lè ráyè ṣiṣẹ́ wọn.