Ohun t’ọ́mọ Nàìjíríà sọ nípa Tinubu
Ootọ ni ọrọ awọn agba to sọ wi pe “bi eniyan n gunyan bọ ilu, o maa ni ọta, bi o si n soko si aarin ọja naa, o maa ni ọrẹ”. Bẹẹ gẹgẹ ni ọrọ Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ri ni orileede yii.
Awọn kan ti n pariwo kiri bayii pe Tinubu nikan lo le se, wọn ni oun nikan lo ku ti ko ni baba isalẹ oselu Kankan. Wọn ni oun nikan naa lo si mọ ibi ti wọn di gbogbo ọrọ orileede yii si. Wọn ni ko si ọgbọn tabi ete oselu Kankan to le bori rẹ.
Ahmad Lawan to jẹ olori ile igbimọ asofin agba ni Asiwaju nikan lo lero pupo ni ile igbimọ asofin, oun nikan ni awọn mọ.
Kanu Nwankwo, agbaboolu ti okiki re si n kan kaakiri agbaaye ti o jẹ ọmọ bibi orileede yii sọ pe ninu awọn oloselu, oun ko le tete gbagbe Asiwaju Tinubu nitori iranlọwọ nla to se fun oun ni ọdun mejilelogun sẹyin (22 years ago) nipa itoju arun ọkan (heart Foundation) ti oun da sile.
J j Okocha , agbaboolu to lokiki bi ka si nnkan ni sawawu ni oun ati Kanu Nwankwo naa sọ pe, idi ti ọpọ eniyan fi n pe oun ni ọmọ Eko di oni ko se lẹyin fifa mọra ati ifẹ ere bọọlu ti Asiwaju ni .
Pastor Taribu West naa ni oun ko le ma se adura fun Asiwaju ni ojoojumọ nitori ipa ribiribi to ko ninu aye oun. O ni Tinubu ko tilẹ fi ti ẹsin se e ti o fi ni ifẹ si oun. O si se ileri pe oun setan lati fi adura jagun fun un ki o le baa de ile ileri.
Ọpọ eniyan tilẹ le ma gbo nipa akitiyan Asiwaju ni ilu Chicago. Ọrẹ timọ-timọ rẹ kan ni wọn fẹ se ise abẹ fun ni ọdun 2007 ni kete to kuro lori aleefa gẹgẹ bi gomina Eko. Dokita yii ni o fẹrẹ gbona ju nibi isẹ abẹ naa ni orileede Chicago sugbọn ti ko fẹ ri aaye fun ọrẹ Asiwaju. Asiwaju si bere si ni bẹẹ pe ki o pe iyawo rẹ pe oun ko ni le wa mọ gẹgẹ bi adehun awọn.
Dokita yii ni ko le see se afi igba ti ọrẹ Dokita yii to jẹ ara Amerika wọle ti o bẹrẹ si ni sa Tinubu ni mẹsan-an mẹwaa, eyi mu ki Dokita Chicago naa beere ibi ti wọn ti mọra, Dokita Amerika naa wa salaye pe eniyan bi Nelson Mandela ni Tinubu jẹ ni orileede Naijiria. O salaye iranlọwọ to se fun oun ati mama oun ki awọn to di ara Amerika. Eyi si mu ki Dokita Chicago naa sun irinajo rẹ siwaju nitori ohun ti o gbọ naa.
Tinubu ni oun ko tile ranti pe oun ran Dokita ara Amerika naa lọwọ ri.
Awọn elere ori itage elede Yoruba naa ni “ti ẹnu ba jẹ, oju a ti”. “Wọn ni Asiwaju ti gba awọn ni igba ojo, awọn naa gbọdọ gbaa ni igba ẹẹrun”. Awọn kan tilẹ bẹrẹ si ni yọ suuti ete si wọn ni ori ẹrọ ayelujara lorisiirisii sugbọn wọn ni ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fẹnu rẹ sọ. Koda wọn se fidio kan fun Asiwaju Tinubu lati fihan pe gbọin-gbọin lawọn wa lẹyin rẹ. Ara awọn to kopa ninu fidio naa ni – Jide Kosoko, Adebayo Salami (Oga Bello), Taiwo Hassan (Ogogo), Faithia Williams, Yinka Quadri, Lanre Hassan (Iya Awero) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
“Meloo ni a fẹ ka ninu eyin adipele”… ni ọrọ oore Tinubu ni orileede Naijiria. Eyi si jẹ ki awọn eniyan kan maa fi ọwọ gbaya pe Asiwaju nikan lo le see ti a ba jẹ ki o de ori aga Aarẹ orileede yii.
Eniyan o ki n dara tan, gbogbo bi a se n wi yii, awọn kan naa ni awọn ko nifẹẹ sii ki Tinubu di Aare. Awọn kan ni o lọwọ si bi wọn se gba ile, gba ilẹ awọn ni ilu Eko. Awọn kan ni ọrọ bode Lekki (Lekki Toll Gate) ni ko ni jẹ ki awọn fori jii.
Awọn kan ni oun lo gbe Buhari le wa lori, ni eyi to da Naijiria pada sẹyin ni gbogbo ọna. Awọn kan ni o ti dagba, awọn kan ni bawo lo se maa mu ẹlẹsin musulumi se igbakeji… Hun!
Eyi o wu ki a wi, t’Oluwa lasẹ.