Home Blog Page 73

Ìdí tí ọjọ́ kìíní oṣù Karùn-ún fi jẹ́ ọjọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé

Ìdí tí ọjọ́ kìíní oṣù Karùn-ún fi jẹ́ ọjọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Ọjọ́ àkọ́kọ́, ọjọ́ kìíní nínú oṣù Karùn-ún ni wọ́n yà sọ́tọ̀ láti mọrírì ìgbìyànjú àti ìlàkàkà àwọn òṣìṣẹ́ káàkiri àgbáyé.

Lọ́dọọdún, tí ọjọ́ yìí bá pé, ìfẹ̀hònúhàn máa ń wáyé káàkiri àgbáyé . Àwọn aṣojú oṣiṣẹ gbogbo máa bèèrè ìtọjú tó péye, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ máa ń dá sí i. Àwọn ajàfẹ̀tọ́ọ̀ ọmọnìyàn àtàwọn tí wọ́n ń fẹ́ ayípadà ló máa ń lọ́wọ́ sí àyájọ yìí nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀ẹ̀rẹ̀.

Orílè-èdè Amẹ́ríkà ní wọn ti ń fẹ̀hónúhàn jù lórí àwọn òṣìṣẹ́, ọjọ́ Mọ́ńdè àkọ́kọ́ nínú oṣù kẹsàn-án ni wọ́n máa ń ṣe tiwọn. Ní ọdún 1886, àwọn aṣojú òṣìṣẹ́ l’Ámẹ́ríkà bẹ̀rẹ ìyanṣẹ́lódì, wọ́n ń bèèrè fún wákàtí mẹ́jọ lójúmọ́ láti ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣe èyí ní ìbámu pẹ̀lú àtúntọ̀ tí òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì kan, Robert Owen, gbé kalẹ̀. Robert ló gbé ètò iṣẹ́ àti ìsinmi lẹ́yìn iṣẹ́ kalẹ̀, ó pè é ní Wákàtí mẹ́jọ iṣẹ́, mẹ́jọ ìdárayá àti mẹ́jọ ìsinmi (“eight hours’ labour, eight hours’ recreation, eight hours’ rest”). Ṣé nígbà náà, iṣẹ́ laago ń ṣe kú ni, kò sì sí ààyè ìsinmi rárá ní àwọn iléeṣẹ́ gbogbo.

Ìyanṣẹ́lódì tó lágbára jùlọ, wáyé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ oṣù karùn
-ún, kò sì dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì òṣìṣẹ́ (40,000 workers) tí wọ́n kóra wọn jọ láti daṣẹ́ sílẹ̀. Ní gbogbo ìgbà náà, Chicago ni òkun ọrọ̀ ajé Amẹ́ríkà, ibẹ̀ sì ni àwọn oníléeṣẹ́ pọ̀ sí jùlọ. Ìdaṣẹ́sílẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà kò wáá tu irun kan lára àwọn tó gbà wọ́n ṣíṣẹ́, wọn kò dá wọn lóhùn. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ mì-ín tún darapọ̀ mọ́ ìdáṣẹ sílẹ̀ náà.

Ó padà di ìfẹ̀hònúhàn ti ó wáyé, tí ẹnìkan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà táwọn ọlọ́pàá ṣíná ìbọn bolẹ̀, èèyàn púpọ sì farapa. Ìfìyàjẹni àwọn ọlọ́pàá yìí ló mú àwọn olórí òṣìṣẹ́ ṣètò ìfẹ̀hònúhàn mì-ín, èyí tó wáyé lọ́jọ́ kẹrin oṣù
karùn-ún, ní gbàgede gbajúgbajà ọjà Chicago, Haymarket Square. Níbẹ̀ lẹnìkan tí wọn ò mọ̀ dònìí yìí ti ju bọ́m̀bù lu àwọn ọlọ́pàá, ọlọ́pàá méje (7) kú, mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (67) sì farapa. Bákan náà, mẹ́rin nínú àwọn tí bọ́m̀bù náà bà pàdánù ẹ̀mí wọn, èèyàn ọgbọ̀n (30) mì-ín sì farapa. Lẹ́yìn rògbòdìyàn yìí, èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n dajọ ikú fún nínú àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hònúhàn náà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rídìí ẹ̀ fi múlẹ̀ pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn, síbẹ̀, ẹ̀mí wọn lọ sí i.

Nígbà tó wáá di ọdún 1889, ọdún kẹta lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìpinnu kan wáyé láti ṣèrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́jọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́. Gbogbo àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tọ́rọ̀ náà kàn ló péjú, aṣojú òṣìṣẹ́ sì wá láti orílẹ̀-èdè ogún (20
countries). Rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní Chicago yìí ló jẹ́ ìwúrí àti ìṣípayá fáwọn yòókù tí wọn kò tí ì darapọ̀ mọ́ wọn tẹ́lẹ̀. Àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sàmi ọjọ́ yìí.

Ní Gúúsù orílẹ̀-èdè Yúróópù, àwọn èèyàn Slovenia àti Croats ni wọ́n kọ́kọ́ ṣayẹyẹ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́. Iṣẹ́ àṣelàágùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí pẹ̀lú owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ń san fún wọn, ló mú àwọn èèyàn Serbia ṣètò ìwọ́de tiwọn ní ọdún 1893. Àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ gan-an ni wọ́n gbé ìwọ́de náà sí.

Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé àkọ́kọ́ parí, tí ayípadà rere ti ń bá àwọn òṣìṣẹ́, tí ìdàgbàsókè ti ń dé pẹ̀lú ìyànjú àwọn ajàfẹ́tọ́ọ̀ ọmọnìyàn ní Russia, ó dohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ń bèèrè ohun gbogbo tó tọ́ sí wọn káàkiri ayé. Ní Germany, àyájọ́ òṣìṣẹ́ di ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, ní ọdún 1933, lẹ́yìn ìgbà tí ẹgbẹ́ Nazi gbàjọba. Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, tó di àjàyé, ohun gbogbo yípadà lórí àtẹ àgbáyé. Ètò òṣèlú àti ọrọ̀ ajé dohun tí wọ́n sàmì rẹ̀ dáadáa.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Cuba, Soviet Union ayé ọjọ́un àti China. Wọ́n yà á sọ́tọ̀ bíi ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ ìsinmi pàtàkì. Bí wọn yóò bá ṣayẹyẹ náà, gbàgede tó tẹ́jú ni wọn máa ń lò; bíi irú èyí tí wọ́n ṣe ní gbàgede Red
Square, ni Moscow. Àwọn èèyàn ńlá ńlá nílùú ló máa ń péjú síbẹ̀, ó sì tún dúró bíi agbára ológun àwọn Soviet.
Àwọn ajàfẹ́tọ́ọ̀ gbàgbọ́ pé sísàmì ọjọ́ òṣìṣẹ́ àti yíya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún ìsinmi yóò jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ Europe àti Amẹ́ríkà parapọ̀ láti bèèrè ẹ̀tọ́ wọn. Ní Yugoslavia, àwọn náà kéde àyájọ́ òṣìṣẹ́ ní ọdún 1945. Wọ́n yan bíi ológun ṣájọyọ̀ náà, wọ́n sì kéde rẹ̀ fúngbà pípé. Káàkiri ayé lónìí, níṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ máa ń bèèrè ẹ̀tọ́ wọn ní gbogbo àyájọ́ tí wọ́n fi sọrí wọn yìí. Awọ kò ká ojú ìlù. Ó ṣe pàtàkì láti fún wọn lóhun tó tọ́ sí wọn, pẹ̀lú bí ìṣẹ àti òṣì ṣe pọ̀ nílẹ̀, tí àwọn mì-ín kò sí ríṣẹ́ kankan ṣe.

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jẹ́ pé àfikún owó oṣù tí wọ́n ń san fún òṣiṣẹ kò mú ìyàtọ̀ kankan bá, nítorí ojoojúmọ́ ni ohun tí wọ́n nílò ń wọ́n sí i gẹ́gẹ́ bí àjọ International Labour Organization (ILO) ṣe ṣàlàyé nínú àfojúsùn wọn fún ọdún 2024. Lọ́dún tó kọjá, òǹkà àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì tó lágbára tún gùnkè sí i ni. Àwọn tí ìyà tó ń jẹ wọ́n mọ níwọ̀n nínú àwọn òṣìṣẹ́ ń pọ̀ sí i ni. Ìdá mẹ́jọ ààbọ̀ mílíọ̀nù (8.4m) ni àjọ ILO pè wọ́n báyìí.

Akẹ́kọ̀ọ́ péréte (0.4%) ló gba máàkì tó lé ní 300 nínú ìdánwò JAMB ọdún yìí.

Akẹ́kọ̀ọ́ péréte (0.4%) ló gba máàkì tó lé ní 300 nínú ìdánwò JAMB ọdún yìí.

Ọlámíde Motúnráyọ̀

Àjọ tó ń rí sí ìdánwò àṣewọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàíjíríà, JAMB ti kéde èsì ìdánwò ọdún 2024 tí àwọn
akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lẹ́nu lọ́lọ́ yìí.

Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Ishaq Olóyédé, ló fi ìkéde náà síta ní olú ọ́ọ́fìsì àjọ ọ̀hún nílùú Àbújá. Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, Ó ní 1.4 mílíọ̀nù ni àpapọ̀ iye àwọn tó ṣe ìdánwò náà.

Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì parí rẹ̀ lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin kan náà.

Nínú àwọn 1,989,668 tó forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB ọdún yìí, 80,810 ni iye àwọn tó kùnà láti yọjú sí gbàgede ìdánwò, tí àwọn 1,904,189 sì ṣe ìdánwò ọ̀hún.
Olóyédé ní “nínú àwọn 1,842,464 tó ṣe ìdánwò, ìdá 0.4% péré ló gba máàkì tó lé ní 300 nígbà tí ìdá
24% gba máàkì tó lé ní 200″. Ó fi kun pé ìdá 76% àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló gba máàkì tí iye rẹ̀ kò tó 200. Ó ní àjọ àwọn yóò kéde orúkọ àwọn tí máàkì wọn pọ̀ jùlọ nínú ìdánwò ọ̀hún.

Olóyédé sọ pé obìnrin 982,393, tó jẹ́ ìdá 50.6% ló ṣe ìdánwò náà nígbà tí àwọn ọkùnrin jẹ́ ìdá 49.4% tó ṣé idanwo ọ̀hún. Àtúpalẹ̀ èsì ìdánwò náà fi hàn síwájú si pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ obìnrin pọ̀ ju àwọn akékòó ọkùnrin lọ tó ṣe JAMB lọ́dún 2024 yìí. Ó ní èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn tí iye obìnrin tó ṣe ìdánwò JAMB yóò pọ̀ju ọkùnrin lọ.

Gbọ́ àgbọ́yé ìdí tí CBN fi fòfin de Opay, Palmpay àtàwọn míì láti sí akoto owó fáwọn oníbàárà tuntun

Gbọ́ àgbọ́yé ìdí tí CBN fi fòfin de Opay, Palmpay àtàwọn míì láti sí akoto owó fáwọn oníbàárà tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ kúmólú.
Níṣe ni àwọn oníbàárà àwọn ilé ìfowópamọ́ kan ń kó ọkàn sókè bí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ṣe kéde pé kí àwọn ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára má gba oníbàárà tuntun mọ́.

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára kan tí wọn kò fẹ́ kí àwọn oníròyìn dárúkọ wọn fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn.

Àwọn ilé iṣẹ́ bíi Opay, Kuda Bank, Palmpay àti Moniepoint ni ọ̀rọ̀ náà kàn, tí wọn kò ní ní àǹfàní láti gba àwọn oníbàárà tuntun láàyè láti ṣí akoto owó pẹ̀lú wọn fún ìgbà kan ná.

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ Nàìjíríà ti òfin tuntun CBN náà lẹ́yìn.

Kí ló dé tí CBN fi kéde ìgbésẹ̀ yìí?
Ìwádìí ní ìgbèsẹ́ CBN yìí kò ṣẹ̀yìn tó ń wáyé látàrí bí wọ́n ṣe ń tọná wádìí àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kan kò máa lò wọ́n láti ṣowó ìlú mọ́kumọ̀ku.

Gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí òfin, ni wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà tó ní akoto owó pẹ̀lú wọn.

Èyí ni ìwádìí tí CBN ti ń ṣe láti mọ̀ bóyá àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí ń ni àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye nípa àwọn oníbàárà tó ń ní akoto owó pẹ̀lú wọn.

Láti bíi oṣù mélòó kan ni CBN ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí náà pàápàá lórí ọ̀rọ̀ pé àwọn kan ń lo àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti máa fi gbé owó tùùlù jáde.

Bákan náà ni àwọn kan ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń lo àwọn akoto owó awọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti fi ṣe àtìlẹyìn fún àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Ṣáájú ni ìròyìn sọ pé CBN ti ránṣẹ́ pe àwọn adarí àwọn ilé ìfowápamọ́ náà sí ìlú Abuja lórí ọ̀rọ̀ níní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà wọn.

Iléeṣẹ́ Opay nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sórí X ní àwọn kò gba oníbàárà tuntun mọ́ láti fi ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba lórí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe.

Wọ́n ní gbogbo àwọn tó ti ní akoto owó pẹ̀lú àwọn tẹ́lẹ̀ kò ní ìṣòro kankan gẹ́gẹ́ bí CBN ṣe kéde rẹ̀ àti pé gbogbo àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà àwọn tó ti wà pẹ̀lú àwọn ni ààbò tó péye wà fún.

Aye̩ye̩ o̩jó̩ ìbí àádó̩rùn ún o̩dún Soyinka bè̩rè̩ ní Eko

Aye̩ye̩ o̩jó̩ ìbí àádó̩rùn ún o̩dún Soyinka bè̩rè̩ ní Eko

Yínká Àlàbí

Bi o tile je pe ojo ketala osu keje odun yii ni gbajugbaja onkowe ati oluja fun eto ominyan, Ojogbon Wole Soyinka, yoo di eni aadorun odun – 90 years – ayeye ojo ini naa tib ere ni pereu o.

Ilu Eko ni won ti bere ‘Eko for show’ naa, nigba ti awon akewi oyinbo lati orile-ede bii merin pade, ti won si kewi lori awon ise ti Soyinka ti se.

Banki kan ti a mo si Providus lo se agbateru eto naa to waye ni Eko Hotels, ni Victoria Island.

Lara awon akewi to gori itage ni Akeem Lasisi, eni ti o gbe orin ati ewi UDEME ati ELELETURE jade ni odun die seyin; Uche Uwadinachi, Evelyn Osagie, Oko Owi Ocho ati Ruth Mahogany.

Lara awon to se agbateru eto naa ni Ogbeni Jahman Anikulapo nigba ti awon otookulu bii Ojogbon Wole Soyinka, Iyaafin Taiwo Ajai-Lycett, Joke Silva, Bolanle Austen-Peters, ati Erelu Abiola Dosumu naa si wa nibe.

 

Muyiwa Ademola ń gbé fíìmì ORÍ padà bò̩

Muyiwa Ademola n gbe fiimi ORI pada bo

 

Yínká Àlàbí

Die bayii lo ku ki onifiimu pataki, Muyiwa Ademola, gbe fiimu re to lale gaaraaga nigba kan, ORI, pada si sinimo o.

Ademola ti n sise lori apadabo ORI naa, o se die.

Sugbon a gbo pe ise naa ti fee pari bayii.

Won ti kuro ni lokesan, ti won si ti se atopo re.

Iroyin fi ye wa pe efisi die die ni won kan n fi si I lowo bayii.

Muyiwa Ademola je okan lara awon osere tiata ati fiimu to ti fun orile-ede yii ni oruko daadaa.

O je akegbe awon Saidi Balogun, Odunlade Adekola, Femi Adebayo ati Sanyeri.

Yemi Sodimu so bi Feyikemi se di Asake ninu O LE KU

Yemi Sodimu so bi Feyikemi se di Asake ninu O LE KU

Agba osere fiimu Yemi Sodiimu, tu isu de isale ikoko lojo die seyin, nigba to se alaye bi osere ati asoro lori telisisan, Feyikemi Niyi aya Olayinka, se di eni to se Asake ninu fiimu nla ni, O LE KU, eyi ti Oloogbe Akinwumi Isola ko, ti Alagba Tunde Kelani sig be jade.

Fiimu naa ti won se to dun moraninmoranin wa lati inu iwe itan ti Oloogbe Ishola ko, ti aimoye eniyan si feran lati maa ka.

Nibi ayeye ojo ibi aadota Feyikemi, eyi to waye ni Eko ni bii ose meji seyin, ni Sodimu ti se alaye naa.

O ni nigba ti won ne pete ere naa, won n wa arabinrin kan ti o niwa tutu, to le soro tutu, to si je omo ile.

O ni bi awon se kori si ile iwe giga University of Ibadan niyen.

O ni bi oju awon se kan Feyikemi ni awon gba pe, eni ti awon n wa gan-an ni.

Opo eniyan lo pejo lati ba arabinrin naa se ayeye ojo ibi oun.

Lara won ni awon oloselu, asoro lori redio ati telifisan, to fi mo Alagba Ademola Aremu, pelu oniroyin ati akewi pataki, Akeem Lasisi, awon ti won da awon enmiyan lekoo lori Pataki ede Yoruba ati bi ise telifisan se n gberu sii.

OTUNBA MIKE ADENUGA: O̩mo̩nìyàn ń pàté̩wó̩ bí e̩lé̩yinjú àánú s̩e di e̩ni o̩dún mó̩kànlélàádó̩rin, 71

OTUNBA MIKE ADENUGA: O̩mo̩nìyàn ń pàté̩wó̩ bí e̩lé̩yinjú àánú s̩e di e̩ni o̩dún mó̩kànlélàádó̩rin, 71

– Olùdásílè̩ Globacom s̩e àso̩dúnmó̩dún

– Bí Adenuga s̩e ń soore tó lowó re̩ ń búré̩ké̩ síi

Orin idunnu ni o̩po̩lo̩po̩ eniyan n ba ogunna gbongbo onise̩ okowo, iye̩n Dokita Mike Adenuga, ko̩ bayii o, nitori o ti di e̩ni o̩dun mo̩kanlelaado̩rin – 71.

O̩jo̩ ko̩kandinlo̩gbo̩n osu ke̩rin o̩dun yii ni o̩dun tun pe, ti odun ko, ti Adenuga si tun se ojo ibi miran loke eepe.

Gege bi ise re, ko jo pe Adenuga fe pe elere tabi ko da agbo apeje nla sile.

Eni ti opo eniyan ti mo bi eni mowo ni. Werewere lo maa n saye, kii pariwo, kii sii maa n ti ode kan bo si omiran.

Ni ti Adenuga, ibi gereye laa ba agba ni. Kii se eni to maa n sannani kaakiri.

Dipo bee, awon ohun ribiribi to maa n se ni awon eniyan maa n ri.

A maa n gbo oruko re ni rere lati ara awon ile ise nla nla re, bii Globacom ati Conoil.

Ibi awon ile-ise yii ni o ti n fun opo eniyan ni anfaani lati sise oojo won, ti won si n lo sile pelu owo ribiribi.

Adenuga tun ni ipin pupo ninu awon ile ise miran, to fi mo Julius Berger to maa n se ona nla nla.

Ko tan sibe o: opo awon oludokowo keekeeke ni won ni ajosepo pelu awon ile ise Adenuga, ti awon naa n gba ise lorisiirisii, ti owo si n bo si awon naa lapo.

Eni ba lo si olu ile ise Globacom ni Eko ni yoo mo ohun ti a n wi.

Sugbon kii se awon to n ba Globacom tabi Conoil dase po nikan lo n je anfaani owo Adenuga.

Ohun ti o se pataki ni pe aramanda olowo tabua naa je eni kan to maa n se oore pupo.

Ki a ma fi oro s’abe ahon so, Adenuga lawo – eyi to tumo si pe kii se ahun.

Nigba ti Yoruba ba ni ijo Aguda ko je labe Geesi, tabi ti won ni eni to ba Raji je ni yoo pe ni Alakanse, ti won si ni eni to ba Idowu jeun ni yoo pe ni Animasahun, iru olowo Adenuga ko ni won n ba wi.

Opo eniyan lo n je labe re. Opo eniyan lo n je lati apo re, koda Yoruba nikan ko. Ati Awusa, ati Ibo, ati awon eya miiran ni.

IROYIN OWURO gbo pe loorekoore ni Adenuga maa n nawo si opo eniyan ati awon egbe lobaloba, nijoye nijoye, elesin, egbe awon onsowo ati bee bee lo.

Bi awon kankan ko ba tile le jerii si bi Adenuga se n d’erin peeke won, awon alariya Naijeria kan ko le bo ore Olorun mora.

Irufe awon eniyan bee ni won wa ni ate Glo Ambassadors. Awon alariya yii, gege bii awon onifiimu, akorin gbajugbaja ati aderinposonu comedian, ni Globacom maa n gbe milionu yanturu fun, ti won fi n sise, ti won fi n kole, ti won fi n ra moto, ti won si tun fi n se ohun ribiribi miran.

Lara awon osere ti won ti won ti won ti je Glo Ambassadors ni Wizkid, D’Banj, PSquare, Flavour, MI, Wande Coal, Omawumi, Burna Boy, Ego ati Sani Danja. Bakan naa awon Asake, Kizz Daniel pelu Chike naa ti jeun soke pelu Glo Ambassadors.

Idi niyi ti iru awon alariya naa kii fii ko iyan Adenuga kere. Won maa n korin rere ki awon ile ise re ni, bo tile je pe Baba Olowo naa kii se eni kan to maa n fe ki eniyan ki oun ni akiikitan. Sibesibe, ko si eni ti kii fi owo ran lowo.

A ko le sai fi kun un pe ile ise Globacom naa kii fi iranlowo ilu, iyen Corporate Social Responsibility, sere. Leyin pe o maa n fun awon eniyan ni ile, moto ati awon ebun nla nla miran nigba ti won ba n se tete oriire, Globacom maa n diidi se akanse oore fun elegbejegbe. Bakan naa, ile ise naa n gbe asa ga, nipa gbigbe owo iranlowo fun awon to n se odun ibile.

Lara awon odun akanse naa ni Ojude Oba Festival ati Ofala Festival ni Onitsha.

Bi Adenuga se wa n se fun onile se fun alejo yii, oke, oke lowo afunni gbe ni oro re.

Dukia re ko din ku. O tun n peleke sii ni.

Koda, ni nnkan bii osu meloo kan seyin ni ajo Forbes, to maa n se atejade awon to lowo julo ni agbaye ati ni orile ede kookan, gbe e jade pe Owo Adenuga tun ti bureke pada.

Won ni oun ni eni to lowo julo sikeji ni ile Naijiria, leyin Alhaji Aliko Dangote.

Hmm, ee wa raye lode bi. Nje bi Adenuga se tubo n goke agba yii ni ti ojo ori, to si n se orile ede ati omoniyan loore, adura ti terutomo yoo maa gba ni pe abudi ni ti omi okun, abudi naa si ni ti osa. Eni kan kii riddii omonigedegede. Omo araye ko ni riddi Adenuga o.

Bakan naa, peregun kii ku boro: Otunba Mike Adenuga, eni to je Opomulero Yoruba, Opomulero Naijiria, ati Opomulero Afrika, ko ni ku boro o.

Oba Oke a je ki eni ti apele re n je THE BULL o tun se opolopo odun loke eepe. Ninu ola nla, pelu ilera to peye.

Adenuga @ 71

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ l’Ọ̀yọ́ láì ṣẹ́kankù

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ l’Ọ̀yọ́ láì ṣẹ́kankù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní kò sí n tó n níbẹ̀rẹ̀ tí kìí lópin.
Àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSIEC ti kéde àbájáde ètò ìdìbò sí ipò Alága ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2024, àwọn olùdíje láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló sì jáwé olúborí jákè jádò àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Alága àjọ OYSIEC, Ààrẹ Isiaka Olagunju (SAN), Kọmísánnà àjọ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adebola Hamzat àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí ó kù gbóṣùbà káre fún ètò ìdìbò náà, pẹ̀lú àlàyé pé ó lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ láì sí ìwà ìpáǹle kankan bó ti í wù kó mọ.

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi ọ̀rọ̀ léde pé irọ́ lásán ni pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan tí kò tọ̀nà tó sì lè da omi àlàáfíà ìlú rú ló wáyé nínú ìdìbò náà.

Wọ̀nyí ni ònkà ìbò tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fi wọlé ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ọ̀hún:
1)Irepo PDP: 17,497 APC: 2,638

2) Orelope PDP: 24, 569 APC: 5,519

3) Surulere PDP: 19,493 APC: 1,619

4) Kajola PDP: 11, 232 APC: 9,373 SDP: 1,28

5) Ogo-Oluwa PDP: 9011 APC: 854 LP: 12

6) Olorunsogo PDP: 8,501 APC: 3002 NNPP: 175

7) Ido PDP: 20059 APC: 3059 LP: 498

8) Ibarapa East PDP: 13,896 APC: 1,606 SDP: 08

9) Iseyin PDP:69,896 APC: 8,241 NNPP: 581

10) Saki East PDP: 9,732 APC: 1,571 ADC:36

11) Saki West PDP: 19,621 APC: 4,920 ADC: 1,846

12) Ogbomoso South PDP: 20,102 APC: 3,471
ADC:06

13) Ibadan Northwest PDP: 21,810 APC: 3,848 ADC: 22

14) Ogbomoso North PDP: 13,681 APC: 4,691 ADC: 11

15) Akinyele PDP: 66,325 APC: 3,477 ADC: 147

16) Ibarapa Central PDP: 14,124 APC: 3,500 ADC: 14

17) Ibadan Southeast PDP: 23,220 APC: 4,265 ADC: 27

18) Atiba PDP: 19,259 APC: 5,086 ADC: 06

19) Itesiwaju PDP: 7,303 APC: 3,795

20) Atisbo PDP: 25,336 APC: 6,567 ADC: 139

21) Egbeda PDP: 24,573 APC: 5,637 ADC: 30

22) Iwajowa PDP: 5,610 APC: 2,969 ADC: 150

23) Afijio PDP: 18,662 APC: 198

24) Oyo West PDP: 12,974 APC: 3,712 ADC: 90

25) Orire PDP: 15,301 APC: 5,579 ADC: 12

26) Lagelu PDP: 65,786 APC: 4,172 ADC: 150

27) Oluyole PDP: 17,063 APC: 3,536 ADC: 55

28) Ibarapa North PDP: 17,307 APC: 6,963

29) Oyo East PDP: 27,567 APC: 3,051 ADC: 16

30) Ona-Ara PDP: 13,093 APC: 4,187 ADC: 15

31) Ibadan North: PDP – 73,240, APC – 5,548, ADC – 0

32) Ibadan Southwest: PDP – 25,702, APC – 5,978

33) Ibadan Northeast: PDP – 17,920, APC – 7,958

Bobrisky! Bó ṣé pín àga ọ̀fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ló ń tún p’ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Bobrisky! Bó ṣé pín àga ọ̀fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ló ń tún p’ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà gbà pé èèyàn tí òmìnira rẹ̀ kò sí ní ìkápá rẹ̀, ọ̀wọ́ ọlọ́wọ́ ni onítọ̀hún wà.
Ọkùnrin tó máa ń múra bíi obìnrin, Idris Olanrewaju Okuneye, ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà tí ilé ẹjọ́ dá fún un lẹ́yìn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn títàbùkù owó náírà.

Idris, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky, ló pe ẹjọ́ náà láti ọwọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀, Bimbo Kusanu, pé kí ilé ẹjọ́ yí ìdájọ ẹ̀wọn tó fún òun padà, kó sì fún òun láǹfàní láti san owó ìtanràn dípò ẹ̀wọ̀n.

Ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí ni adájọ́ Abimbola Awogboro ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Èkó ṣèdájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà láì sí ànfààní láti san owó ìtanràn kankan fún Bobsirky lẹyìn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn títàbùkù owó náírà.

Nígbà tó ń dájọ́ ọ̀hún, adájọ́ náà ní ìdájọ́ náà yóó kọ́ àwọn aráàlú tó bá fẹ́ máa wu irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́gbọ́n.

Ṣaájú ìdájọ́ yìí lọ́jọ́ kàrún un, oṣù Kẹrin yìí kan náà ni ọ̀daràn ọ̀hún ti kọ́kọ́ sọ pé òun jẹ̀ẹ
bi ẹ̀sùn tí àjọ EFCC fi kan òun.

Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ kòtẹ́milọ́rùn rẹ̀, ọ̀daràn náà sọ pé ilé ẹjọ́ fún òun ní ìjìyà tó pọ̀ jùlọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ṣẹ bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ní àkọsílẹ̀ kankan ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi arúfin.

Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, ìdájọ́ ọhún wáyé láì sí ojú àánú kankan fún òun, èyítí kò sì ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ òfin Administration of Criminal Justice, ACJA, ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó fi kún pé adájọ́ náà kò tún wo ti pé òun kò fi àkókò ilé ẹjọ́ ṣòfò látàrí bí òun ṣe tètè sọ pé òun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Ẹ́wẹ̀, láàrin nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ méjì péré lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìròyìn tó ń tẹ wá lọ́wọ́ sọ pé Bobrisky ti fi àwọn àga kan ta ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà lọ́rẹ̀.

Nínú àwòrán àga náà tó gba orí ayélujára kankan, wọ́n kọ àkọlé “si iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà láti ọwọ́ idris Okuneye Bobrisky” sí lára.

Ìròyìn tó gba ìgboro nípa àwọn àga náà ni pé ó wà fún agbègbè tí àwọn àlejò yóò máa jókòó sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ọ̀hún.