Home Blog Page 72

Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Imí ẹran nídìí èèyàn,ọ̀rọ̀ rúnrùn,ó ti wá di sísín fiìmù bí àṣà àwọn olóyìnbó tí kò ṣeé wò tán bí awuyewuye ìjà ilẹ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ nílé-ẹjọ́ Májísírèètì kan nílùú Ìlọrin, láàrin Ẹlẹjù, tìlú Ẹ́jù, Ọba Mathew Idowu Ajíbóyè, àti Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-Ọ̀bà, Ọba Àlàájì Maroof Afọ́láyan Adébáyọ̀, bí fọ́nrán fídíò ṣe ṣàfihàn bí àwọn olùpẹ̀jọ́, Ọba Ajiboye, ṣe rán àwọn jàndùkú kí wọ́n máa lu Ọlọ́bà, tí wọ́n sì ń yẹ̀yẹ́ rẹ̀ lásìkò tí adájọ́ ní òun fẹ́ wo fọ́nrán fídíò ọ̀hún.

Nínú fọ́nrán fídíò náà ni àwọn janduku ti lọọ ká Ọlọ́bà àtawọn alátílẹ́yìn rẹ̀ mọ́lé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n ń lù í, lórí ẹ̀sùn pé òun ló wà nídìí rògbòdìyàn tó ń wáyé nínú ìlú.

Nínú ìlú Ẹ̀jù kan náà ni àwọn méjèèjì wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ni àwọn Ọlọ́bà ya kúrò lára Ẹ̀jù, tí wọ́n sì ń jẹ́ Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-̀Ọbà, èyí tí wọ́n ní àwọn ti dá dúró, tí wọ́n sì ní ọba tiwọn.

Ohun tí ó ṣokùnfà awuyewuye ọ̀hún ni pé Ẹlẹjù tìlú Ẹ́jù, Ọba Matthew Ìdòwú Ajíbóyè, ta ilẹ̀ baba àwọn Ọlọ́ba, tó sì ní ọba òun ba lórí ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n àwọn Ọlọ́ba yarí pé àwọn kì í ṣe ara Ẹ̀jù mọ́, ni wàhálà bá bẹ̀rẹ̀.

Ọba Ajíbóyè, wọ́ Ọlọ́bà lọ sílé-ẹjọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rí fídíò tú àṣírí bí Ọba Ẹ̀jù ṣe ní kí wọ́n máa lu Àlàájì Maroof Afọláyan tó jẹ́ Ọlọ́bà, tí wọ́n sì fà á láṣọ ya, léyìi tí wọ́n ní ó ta ko òfin ilẹ̀ wa. Fídíò náà tún ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe ní kí olórí ẹbí ilé Ọlọ́bà, ìyẹn Rahmọn Ọmọniyì, dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú tipátipá, tí wọ́n sì ń ṣọ̀rọ̀ burúkú sí i. Lẹyìn tí wọ́n wo fídíò ọ̀hún tán ni Onídàájọ Muhammad Adams, gba fídíò náà wọlé gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 yìí.

Ikú oró! Wọ́n gún akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH pa l’Ogbomọṣọ

Ikú oró! Wọ́n gún akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH pa l’Ogbomọṣọ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àdúrà kí màjèṣín má tojú òbí rọ̀run ni gbogbo abiyamọ má a ń gbà ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ kan ti ṣẹ̀ wọ́n nílé ẹ̀kọ́ gíga Ladoke Akintọla University of Technology ( LAUTECH), tó wà nílùú Ogbomọṣọ, níìpínlẹ̀ Ọyọ, báyìí, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gún ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì náà, Adedokun Basit Ọlamilekan, lọ́bẹ pa.

Ija ti akọroyin wa ko ti i mọdi ẹ bayii, la gbọ pe o waye laarin Ọlamilekan pẹlu awọn kan ládùúgbò ti wọn n pe ni Under-G, niluu Ogbomọṣọ, lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.

Oun ta a gbọ ni pe, laarin ọpọlọpọ iṣẹju ni wọn fi n tahùn sira wọn, ti ẹnikan ko gba fẹnikan laarin ikọ mejeeji.

Lẹyin ti igbiyanju lati pari ija naa ko sesoore fawọn eeyan to wa nibẹ lọkan ninu awọn ọkunrin naa gun Ọlamikekan lọbẹ nigbaaya, oju-ẹsẹ lo si ti mẹyin lọ silẹ.

Ni kete t’ọmọkunrin naa ti ṣubu silẹ to bẹrẹ si i japoro iku lawọn eeyan naa ti sa lọ, ti ẹnikan ko si mọ wọn titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Amọ ṣaa, awọn araadugbo ọhun du ẹmi ẹ pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi ibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, ọmọkunrin naa ti dagbere faye.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ ẹni to huwa ọdaran yii gan-an, awọn kan sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn eeyan naa.

Tẹ o ba gbagbe, laduugbo ti wọn pa akẹkọọ LAUTECH yii si naa lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣoro laipẹ yii, eyi to mu ki ibọn ọkan ninu awọn ọlọpaa ti awọn araadugbo naa pe lati waa daabo bo wọn fi ba ọmọkunrin kan, to si tibẹ gbẹmi-in mi.

Akinkanju ọmọ ni wọn pe oloogbe yii, nitori bo ṣe n lọ sileewe lo tun n ṣiṣẹ atóríṣe ládùúgbò Under-G, nigboro ìlú Ogbomọṣọ

Adájọ ní kí wọ́n fi ìwé wọ́ Gani Adams wa sí kóòtù lọ́nàkọnà

Adájọ ní kí wọ́n fi ìwé wọ́ Gani Adams wa sí kóòtù lọ́nàkọnà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá ò bá tíì tán, èèyàn nlá ò níín
tíì sinmi ẹjọ́ bí ó ṣe jẹ́ pé
kò ní í pẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní í jìnnà mọ́ báyìí, tí àwọn akọni ọmọ Yorùbá méjì nnì, Ààrẹ Ọ̀nà-Kakanfò ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams, àti ajìjàgbara fún ìran Yorùbá nnì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo ayé mọ̀ sí Sunday Igboho, yóò kojú ara wọn ní kóòtù pẹ̀lú bí ilé-ẹjọ́ ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìwé ìpẹ̀jọ́ pé Gani Adams wá sí kóòtù.

Sunday Igboho lo pe Gani Adams lẹjọ, o lọkunrin naa ba oun lorukọ jẹ, bi ibanikorukọjẹ ọhun si ṣe ba oun lọkan jẹ to loun ṣe fẹ ki wọn fiya jẹ oun naa to, nitori naa, ki ile-ẹjọ paṣẹ fun olujẹjọ naa, to tun jẹ ọga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, lati sanwo nla, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500 m).

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ohun ti olupẹjọ tori ẹ pẹjọ ko ṣẹyin akasilẹ ohun kan to jẹ itakurọsọ to waye laarin Gani Adams ati ọkunrin kan ti wọn pe ni Nuru Banjọ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021, eyi ti awọn oniroyin kan gbe sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii.

Ninu akasilẹ ohun naa la gbọ pe olujẹjọ ti ṣapejuwe olupẹjọ gẹgẹ bii apaayan to ṣokunfa iku gbajumọ oloṣelu kan lorileede yii, Oloye Bọla Ige.

Ṣugbọn Igboho sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọkunrin naa, n lo ba gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ fiya nla jẹ ọga awọn OPC naa fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Lati oṣu to kọja lolupẹjọ ti pẹjọ naa, o si yẹ ki igbẹjọ ti bẹrẹ lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ṣugbọn eyi ko ṣee ṣe nitori olujẹjọ ko fara han ni kootu, bẹẹ ni ko si agbẹjọro tabi ẹnikẹni to ṣoju ẹ nile-ẹjọ.

Nigba ti igbẹjọ ọhun tun waye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti akọda kootu ṣalaye pe oun ko lanfaani lati fun olujẹjọ niwee ipẹjọ, nitori naa, ko jọ pe ọkunrin naa mọ pe ẹnikẹni pe oun lẹjọ si kootu yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti mo dele olujẹjọ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja, l’Ekoo, aṣọna rẹ to yọju si mi lati inu ile sọ pe ọga oun (Gani Adams) ko si nile”.

Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ M.I. Sule, fun akọda ile-ẹjọ naa lanfaani lati lo ọnakọna mi-in to ba gba lati ri i pe iwe ipẹjọ ọhun tẹ ọga awọn OPC naa lọwọ.

Adajọ ni “Mo ti wo akọsilẹ gbogbo akitiyan akọda lati fun olujẹjọ funra rẹ niwee ipẹjọ, mo si ri i pe iwe ọhun ko ti i tẹ ẹ lọwọ nitori akọda ko ba a nile ẹ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja. Nitori naa, mo pa a laṣẹ pe ki wọn lo gbogbo ọna yoowu ti olujẹjọ yoo fi mọ pe oun lẹjọ i jẹ ni kootu yii, koda, bo gba ki wọn lẹ iwe ipẹjọ naa mọ geeti ile tabi ara ogiri ile ẹ”.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní Chad

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní Chad

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 ni àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Chad yóò dìbò láti yan Ààrẹ tuntun.

Àwọn olùdíje mẹ́wàá ló ń díje, tí wọ́n sì ń jìjàdù kí ipò náà já mọ́ àwọn lọ́wọ́.

Ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè Chad ti ṣe àtẹ̀jáde orúkọ àwọn olùdíje tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn hàn láti díje dupò Ààrẹ náà.

Ètò ìdìbò ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn ikú Ààrẹ àná, Idriss Deby tó dágbére fáyé lórí ipò lọ́dún 2021.

Ọmọ rẹ̀, Mahamat Idriss Deby, tí òun náà ń díje dupò Ààrẹ, ló gba ipò bàbá rẹ̀ láti inú oṣù kẹrin ọdún 2021 tí bàbá rẹ̀ tí jáde láyé.

Ẹni Olúbàdàn kàn ṣàbẹ̀wò sílé Olúbàdàn àná

Ẹni Olúbàdàn kàn ṣàbẹ̀wò sílé Olúbàdàn àná

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọba Olakulehin Owólabí tí oyè Olúbàdàn kan ṣe àbẹ̀wò sí ilé Ọba Mahood Lekan Balogun Olubadan ti ilẹ̀ Ìbàdàn tó gbé ṣe láìpẹ́ yìí.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí àbẹwò náà, Òsì Balógun, Ọba Gbadamosi Adebimpe tó gba ẹnu Ọba Olakulehin Owolabi sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ṣaájú kí Kábíyèsí Ọba Mahood Lekan Baloygun tó gbéṣẹ̀ ni ara Kábíyèsí Olakulehin ò ti le.

Ó ní “ Ní báyìí tí ara wọn ti mú okun ló fàá tí wọ́n fi ṣàbẹ̀wò yìí nítorí pé ọ̀rẹ́ ni àwọn méjèèjì jẹ́ .”

Òsì Balógun tún ṣàlàyé pé ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹni tí oyè Olúbàdàn kan yóò ṣe àbẹ̀wò sí ilé Olúbàdàn tó gbéṣẹ̀ nílùú Ìbàdàn nìyí.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Sẹ́nẹ́tọ̀ Kola Balógun tó jẹ́ àbúrò Olúbàdàn àná fi ìdùnnú rẹ̀ hàn, ó sì ṣàpèjúwe ìṣèjọba Ọba Mahood Lekan Balógun gẹ́gẹ́ bíi èyí tó mú àlàfíà bá ìlú Ìbàdàn.

Ó wá rọ Ọba Owólabí Olakulehin láti jẹ́ kí àlàfíà tó ti ń jọba nílùú Ìbàdàn tẹ̀síwájú lẹ́yìn ìgbà tó bá ti dé orí oyè gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun.

Tí ẹ kò bá gbàgbé, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí ni gbogbo awuyewuye tó ti ń wáyé lórí ẹni tó yẹ kó jẹ oyè Olúbàdàn dópin lẹ́yìn ti àwọn afọbajẹ fọwọ́ sí Owólabí Ọlakulẹhin gẹ́gẹ́ bíi ọmọ oyè tuntun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn pé àgbà ti dé sí Olúbàdàn tó ń bọ̀ lọnà ọ̀hún látàrí bó ṣe rọra ń tẹ̀ kẹ́jẹ́ kẹ́jẹ́ ní ṣe làwọn èèyàn ń kí i ní mẹsan-an mẹ́wàá, tí wọ́n ń ṣàdúrà fún un pé yóó lo ipò náà kánrin.

Wàyí ò, ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn ti fẹnu kò láti fi Ọba Olakulehin Owolabi jẹ Olúbàdàn tuntun, àmọ́ kò tí ì hàn dájú ọjọ́ tí yóó tẹri gba adé Olúbàdàn.

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ awakọ̀ gáàsì tó kó ìgbó

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ awakọ̀ gáàsì tó kó ìgbó

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọ̀kájúà ń dàgbà, ọgbọ́n inú rẹ̀ ń rewájú.
Ojoójuúmọ làwọn tí wọ́n ti sọ gbígbé àti títà oògùn olóró di iṣẹ́
ń wá ọ̀nà tuntun mí-ìn láti tẹ̀síwájú nínu iṣẹ́ tí kò bófin mu tí wọ́n ń ṣe ọ̀hún. Bí àwọn agbófinró sí tí n tu aṣiri wọn nibi kan ní wọ́n tún n dá ọgbọ́n tmi-in.

Aipẹ yii lọwọ ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro laarin ilu, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tilu Abuja tẹ ikọ ẹlẹni mẹrin kan to jẹ pe egboogi oloro lawọn maa n fi mọto tirela gbe kaakiri fawọn onibaara wọn.

Awọn mẹrin naa ni: Efe Abel Mikel, ẹni ọdun mọkandinlogoji, Eebigide Cyril ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Ejechi Monday, ẹni ọdun mọkanlelogoji ati Benson Chukwudi, ẹni ọdun mọkanlelogoji.

ohun ti a gbọ ni pe, inu tanki nla ti wọn fi n gbe afẹfẹ gaasi ni awọn afurasi ọdaran ọhun tọju obitibiti apo egboogi oloro si. Ipinlẹ Ondo ni wọn ti gbera, ti wọn si n lọ siluu Abuja, lati gbe e fawọn onibaara wọn, ṣugbọn tọwọ tẹ wọn lojuna marosẹ Abuja si Abaji, nigba to ku diẹ ki wọn debi ti wọn n lọ.

Alukoro ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafemi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn oṣiṣẹ ajọ naa da mọto tirela nla kan ti wọn fi n gbe gaasi, iyẹn afẹfẹ idana duro. Inu tanki nla ọhun lawọn oniṣẹ ibi naa tọju obitibiti apo egboogi oloro ọhun si. Lẹyin ti wọn yẹ ara ati inu mọto ọhun wo daadaa, wọn ri ẹru ofin naa ninu tanki gaasi naa, wọn si fọwọ ofin mu wọn.

Alukoro ni awọn maa ṣewadii nipa awọn afurasi ọdaran ọhun, tawọn si maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Afurasí tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn kó sí gbaga ọlọ́pàá Ekiti

Afurasí tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn kó sí gbaga ọlọ́pàá Ekiti

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ gbogbo ni ti olè,ọjọ́ kan ni ti olóhun.
Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì ti tẹ ọkùnrin kan tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìjọsìn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Sunday Abutu ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn.

Abutu sọ pé ọwọ́ tẹ afurasí náà lẹ́yìn tó ti jí fóònù méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ijọ Christ Apostolic Church kan ní Ayegbaju-Ekiti.
Ọlọ́pàá ní “afurasí náà lọ sílé ìjọsìn ọ̀hún, ó díbọ́n bíi ọ̀kan lára àwọn olùjọ́sìn láti ṣọ́ àwọn olùjọ́sìn ọ̀hún dáadáa kó tó jí fóònù méje lasiko ti wṣn n kọ orin ìyìn.

“ Afurasí ọhun jẹ́wọ́ nínú ifọrọwanilẹnuwo pé ó ti ṣe díẹ̀ tí òun ti ń ṣọṣẹ lagbegtbe Oye àti Ayegbaju-Ekiti, ilé ìjọsìn sì lóun máa kọlù.

“ Ó jẹ́wọ́ síwájú sí pé òun ti jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn Redeemed Christian Church of God àti New Reality Christian Center, nílùú Oye-Ekiti yìí kan náà .”

Ìwádìí ọlọ́pàá fi hàn pé ìlú Èkó ni afurasí náà máa ń fi àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ tó bá jí ránṣẹ́ sí níbi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan yóò ti lu àwọn fóònù náà ní gbànjo, tí yóò sì fi owó rẹ̀ ránṣẹ́ padà sí lórí ayélujára.

Ẹ̀wẹ̀, ọlọ́pàá ti gba àwọn fóònù méje tó jí gbẹ̀yìn lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì ti késí àwọn tó ni àwọn fóònù náà kí wọn wá gbà á.

Abutu parí àtẹ̀jáde rẹ̀ pé afurasí náà yóò fojú balé ẹjọ́ láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìwádìí lórí ẹsùn tí wọ́n fi kàn án.

l’Ékìtì ,afurasí ìbejì tó ń jalè dèrò àtìmọ́lé

l’Ékìtì ,afurasí ìbejì tó ń jalè dèrò àtìmọ́lé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé ọ̀rọ̀ àwọn ìbejì yìí wọ̀ ní kádàrá ṣe tún kò lé wọ́n lórí fún yíyan olè jíjà gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ́ àmútọ̀run wá bí wọ́n ṣe sọ pé wọ́n fẹ́ràn láti máa já ìlẹ̀kùn ilé onílé àti ṣọ́ọ̀bù láti jalè níbẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti ló kéde síta láìpẹ́ yìí pé ọwọ́ àwọn tẹ ìbejì tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Taiwo àti Kẹhinde Ọlasọji pẹ̀lú àwọn méjì mìíràn, Funkẹ Afọlayan àti Nnaji Aroh lórí ẹ̀sùn olè jíjà.

Nínú àtẹ̀jáde tí ọ̀gá ọlọ́pàá Èkìtì, Adeniran Akinwale gbé jáde, èyí ti Sunday Abutu tó jẹ́ agbẹnusọ buwọ́lù láìpẹ́ yìí ló ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìlú Ado-Ekiti lọ́wọ́ ti tẹ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.

Akinwale ṣàlàyé pé ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹrin tí a wà yìí lọwọ́ pálábá àwọn Ìbejì náà ségi lásìkò tí wọ́n ń gbìyànjú láti já ṣọ́ọ̀bù ìtajà kan ládùúgbò Mathew to wà ní Odo-Ado, Ado-Ekiti.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó tẹ̀síwájú pé àwọn ìbejì náà ti jẹ́wọ́, àti pé bí wọ́n ṣe jẹ́wọ́ ló mú kí ọwọ́ tẹ Funkẹ àti Nnaji tí àwọn máa ń gba ẹrù tí wọ́n bá jígbé lọ́wọ́ wọn.

Ó ní àwọn ìbejì náà ṣàlàyé pé àwọn ni wọ́n lọ fọ́ ṣọ́ọ̀bù mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ́tọ̀ tó wà nínú ọjà Fayẹmi, Agric Ọlọpẹ tó wà nílùú Ado-Ekiti, tí wọ́n sì jí àpò ìrẹsì mẹ́ta, àpò ẹ̀wà méjì àti àwọn ohun jíjẹ mìíràn tí owó wọn dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù kan (N936,750) náírà.

Akinwale ti wá fidi rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo wọn ni yóó fojú bá ilé-ẹjọ́ láti sọ tẹnu wọn.

l’Osun, àwọn ọ̀dọ́ bínútán lórí ọ̀wọ́ngógó epo, iná mọ̀nàmọ́ná àti oúnjẹ

l’Osun, àwọn ọ̀dọ́ bínútán lórí ọ̀wọ́ngógó epo, iná mọ̀nàmọ́ná àti oúnjẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé ara ti kan àwọn ọ̀dọ́ yìí ju ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ báyìí pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ̀ kan tí wọ́n pè ní “Coalition Concern Youths” ti ṣe ìwọ́de lórí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ, iná mọ̀nàmọ́ná àti epo bẹnitiró.

Ìwọ́de ọ̀hún ló wáyé nílùú Osogbo níìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Orin tó gba ẹnu àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún ni pé, “ebi ń pa wá, kò sówó, kò sí ààbò lórí ẹ̀mí àti dúkìá mọ́ ní Nàìjíríà.”

Wọ́n tún ń kọrin pé “Olúwa fa ìjọba tó níwa lára yaa, kí O wó ìjọba ọ̀hún lulẹ̀ pátápátá.”

Owolabi Hassan,tó jẹ́ aṣíwájú àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún ti sọ pé àwọn fẹ́ kì ìjọba Bola Tinubu dá owó epo bẹnitiró àti owó iná mọ̀nàmọ́ná padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ kí ara lè rọ aráàlú.

Wọ́n tún sọ pé àwọn kò fẹ́ owó ìrànwọ́ tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yà àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Hassan tún tẹ̀síwájú pé, owóyàá ọ̀hún kò lè tàn ìsoro wọn rárá.

Ó ní àwọn fẹ́ kí ìjọba Bola Ahmed Tinubu ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára nípa pípèsè isẹ́ fún wọn.

Hassan tún ṣàlàyé pé, ìyà tó n jẹ àwọn ọ̀dọ́ àti aráàlú ní Nàìjíríà ti peléke síi lásìkò ìjọba Bola Ahmed Tinubu.

Ajàáfẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kan, Waheed Lawalda tó wà níbi ìwọde náà ní àwọn ọ̀dọ́ nìkan kṣ ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún kan, bẹ́ẹ̀ ni kìí se ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kó ṣe ìwọ́de.

Waheed sọ pé “gbogbo wa ló yẹ kó se ìwọ́de lórí ìnira tó dojú kọ wá ní Nàìjíríà, kìí ṣe ọ̀dọ́ nìkan.

“Ọ̀nà àbáyọ tí àwa ọmọ Nàìjíríà ní ní kí gbogbo wá jáde fún ìwọde lórí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiró, iná mọ̀nàmọ́ná àti ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ.

Waheed Lawal wá rọ àwọn agbófinró láti máa pèsè ààbò fún àwọn olùwọ́de dípò kí wọ́n máa dá wọn dúró lásìkò ìwọ́de náà.

Agbẹjọ́rò wọ́ Adelabu lọ sílé ẹjọ́ fún pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ́rí

Agbẹjọ́rò wọ́ Adelabu lọ sílé ẹjọ́ fún pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ́rí

Fẹmi Akínṣọlá
Ohun tó kojú sí ẹnìkan, ẹyìn ló k sí elòmíràn.
Agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan tó fi ìlú Eko ṣe ibùjókòó, Kabir Akingbolu ti wọ́ mínísítà fétò ohun àmúṣagbára, Adebayo Adelabu àtàwọn méjì míì lọ sílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ohun tí agbẹjọ́rò náà ń fẹ̀sùn kan Adelabu àtàwọn tó pè lẹ́jọ́ ni pé wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú mọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe pín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ̀rí oríṣìí márùn-ún.

Ó ní kí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n máa fún gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ní iná mọ̀nàmọ́ná bákan náà nítorí pé orí kò ju orí lọ.

Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ tó gbé lọ sí ilé ẹjọ́ ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2024, Akingbolu ní pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ̀rí oríṣìí márùn-ún pẹ̀lú àsìkò tí àwọn èèyàn yóò fi máa lo iná tó yàtọ̀ síra wọn jẹ́ ohun tí kò dára rárá, tí kò sì bá òfin mu àti títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.
Àwọn mìíràn tí Akingbolu tún pé lẹ́jọ́ ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná Nàìjíríà, Nigeria Electricity Regulatory Commission (NERC) àti Ikeja Electricity Distribution Company (IKEDC).

Ó fẹ̀sùn kan àwọn tó pè lẹ́jọ́ náà pé pínpín àwọn àwọn sí ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lòdì sí ìwé òfin Nàìjíríà tí kò fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti dẹ́yẹ sí èèyàn.

Ó fi kun pé wọ́n tàpá sí òfin orí kẹrin, abala kejìlélógójì ìwé òfin Nàìjíríà ti tọdún 1999.

Ìgbésẹ̀ Akingbolu yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná kéde ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹrin ọdún 2024 pé àwọn ti fi kún owó iná mọ̀nàmọ́ná àti pé àwọn ti pín bí àwọn yóò ṣe máa pèsè iná fún àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí A, B, C, D àti E.

Ó ní àwọn tí àwọn iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná náà ń fún ní iná wàkátì méjì sí mẹ́rin lójúmọ́ ni wọ́n ti sọ sínú ìyà pàápàá lásìkò yìí tí ooru àmújù ń bá Nàìjíríà àti gbogbo àgbàyé fínra lórí àyípadà ojú ọjọ́.

Akingbolu ní kìí ṣe ohun tó wu etí gbọ́ pé àwọn kan yóò máa lo iná mọ̀nàmọ́ná fún ogún wàkátì lójúmọ́ nígbà tí àwọn kan kò ní ní ju iná wàkátì mẹ́rin lọ.

Ó wá rọ ilé ẹjọ́ láti pa á láṣẹ́ fún NERC láti ìgbésẹ̀ náà padà kí wọ́n sì máa fún gbogbo ènìyàn ní iná bákan náà àti iye àsìkò kan náà.