Home Blog Page 73

Inú mi kìí dùn tí wọ́n bá pè mí ní Jubril Sudan – Buhari

Inú mi kìí dùn tí wọ́n bá pè mí ní Jubril Sudan – Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ó ní súúná tí í bá oníkálùkù lára mu, Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ pé inú òun kìí dùn tí àwọn èèyàn bá ń pe òun ní Jubril láti Orílẹ̀ Sudan.

Ó ní àwọn tó ń pe òun lórúkọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú ojú òun kúrò lára iṣẹ́ tó yẹ kí òun ṣe fún ìlú ni.

àrẹ Buhari ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú fíìmù kan tí wọ́n ṣe nípa ìgbésí ayé e rẹ̀ èyí tí wọ́n pè ní “Celebrating a Patriot, a Leader, an Elder Statesman.”

Inú fíìmù ọ̀hún ló ti sọ̀rọ̀ náà àtàwọn ọ̀rọ̀ mí-ìn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀.

Ọdún 2018 ni ọ̀rọ̀ ìkéde ‘Jubril láti Sudan’ náà kọ́kọ́ ṣẹ́yọ nígbà tí Buhari padà dé sí Nàìjíríà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn tó lọ lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ láti tọ́jú àìsàn kan tó ń bá a fínra.

Bó ṣe dé báyìí làwọn kan ń sọ pé Ààrẹ ti kú, àti pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jubril, ọmọ orílẹ̀-èdè Sudan ni wọ́n gbé padà wá sí Nàìjíríà, tó sì ń ṣe bí i Ààrẹ lé wa lórí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Buhari ní ọ̀rọ̀ náà kò pa òun lẹ́rìn-ín rárá, àmọ́ àwọn tí wọn kò fẹ́ kí òun gbájúmọ́ iṣẹ́ ti wọ́n dìbò yan òun fún, ló ń gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ọ̀hún kiri.

O ní “Ohun tó ká mi lára ni bí mo ṣe má a ṣe àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn aráàlú.”

Ààrẹ Buhari tún ti sọ pé méjì lára àwọn ọmọ òun ló bá àìsàn ‘Sickle Cell’ lọ.

Buhari ló fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún léde lọ́jọ́ Ẹtì, níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rin ọdún rẹ̀, èyí tí àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún-un.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí ayé e rẹ̀, ó ní àwọn ọmọ òun méjì tí ìyàwó òun àkọ́kọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Safinatu bí fún òun kú nítorí àìsàn náà.

Ó ní ẹ̀yin tí òun pàdé Aisha Buhari ni òun lọ ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, kí irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ má baà wáyé mọ́.

Ọdún 1971 ni Buhari fẹ́ Safinatu, wọ́n sì bí ọmọ márùn ún fún ara wọn.

Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé ní Kwara náà

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé ní Kwara náà

Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fi ṣìkún òfin gbé àwọn afurasí ajínigbé mẹ́ta èyí tó ń yọ àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Kogi àti Kwara lẹ́nu.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama nígbà tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ṣàlàyé pé ní ìlú Oro-Ago ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí náà.

Odama ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022 ni àwọn ènìyàn méjì kan, Shina Luke Abiodun àti ẹnìkan kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní agbègbè Eruku ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Egbe ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Ó ní àwọn ajínigbé náà dáná ìbọn yá àwọn ènìyàn yìí ṣùgbọ́n orí kó wọn yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa lásán ni tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ.

Ó fi kun pé nígbà tí àwọn ènìyàn náà sá dé ibi tí àwọn ọlọ́pàá wà ní àwọn lọ sí ibi tí ìkọlù náà ti wáyé tí wọ́n sì rí fóònù Tecno kan nílẹ̀.

“Fóònù yìí ni àwọn ọlọ́pàá lò láti fi ṣèwádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì ṣe àwárí rẹ̀ pé Oro-Ago ni àwọn ajínigbé náà wà.”

“Nígbà tí à ń ṣe ìwádìí ni awọn afurasí náà jẹ́wọ́ wípé àwọn ni àwọn ti ń da agbègbè náà láàmú.”

“Ìwádìí tún fi hàn pé àwọn ni wọ́n jí bàbá àti ọmọ kan gbé tí wọ́n sì gba mílíọ̀nù mẹ́fà kí wọ́n tó túwọn sílẹ̀.”

Odama ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ wí pé àwọn ni àwọn pa òṣìṣẹ́ NSCDC kan, Segun Ayegbulu tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ó fi kun pé lára àwọn nǹkan tí àwọn rígbá lọ́wọ́ wọn ni ìbọn méjì àti fóònù méjì.

Bákan náà ló ni iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti nawọ́ gán àwọn ènìyàn yòókù tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn.
Yàtọ̀ sí àwọn wọ́nyí, ọwọ́ ṣìnkú òfin ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì mìíràn ní agbègbè Oke-Ode, ìjọba Ifolodun ìpínlẹ̀ Kwara.

Paul Odama sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ni ìròyìn kan àwọn lára wí pé àwọn ajínigbé jí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún kan gbné ní òpópónà Share sí Oke-Ode.

Ó ní ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Garuba Abubakar tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Elero ti ìlú Lokongoma àti Abubakar Adam ló wà nídìí ìjínigbé ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ ọ̀gá àwọn tó gbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta náírà owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ẹbí àwọn ọmọ tí àwọn jí gbé náà ti na pápá bora.

Bákan náà ní wọ́n ní ni ìbọn tí àwọn máa ń lo láti fi ṣọṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ìgbìyànjú ni àwọn ń sà láti ri dájú pé àwọn nawọ́ gán ọkùnrin náà.

Odama wá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọ̀daràn láti pọ̀ sókè rajà nítorí kò sí ààyè fún àwọn oníṣẹ́ ibi ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ikú tún ṣọṣẹ́ o! Aṣojú Orílẹ̀èdè Naijiria sí Spain, Ademola Seriki, jáde láyé

Ikú tún ṣọṣẹ́ o! Aṣojú Orílẹ̀èdè Naijiria sí Spain, Ademola Seriki, jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bíkú bá ti dé kò sóògùn mọ́.Aṣojú orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀èdè Spain, Ademola Seriki, jáde láyé. Àgbà olóṣèlú ọ̀hún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Èkó ló kú sí ìlú Madrid ni ẹni ọdún Mẹ́tàlélọ́gọ́ta.

Àwọn mọ̀lẹ́bí kéde ikú náà nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn ọmọ olóògbé fi síta fún àwọn akọ̀ròyìn ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ, wọ́n ní Bàbá náà jàde láyé nílùú Madrid.
Nínú àtẹ̀jáde náà; “Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, tí a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni a fi ń kéde ìpapòdà Bàbá, Ọkọ, Ẹ̀gbọ́n àti Ọ̀rẹ́ wa, Ambassador Demola Seriki, ẹni tó jáde láyé lọ́jọ́ Kẹẹ̀ẹ́dógún, ọsù kejìlá, ọdún 2022.

“Ó jáde láyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní àyíká àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní ìlú u Madrid, lórílẹ̀èdè Spain.”

Ẹ fopìn sí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ fún ètùtù ọlà l’Ógùn – Dàpọ̀ Abíọ́dún

Ẹ fopìn sí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ fún ètùtù ọlà l’Ógùn – Dàpọ̀ Abíọ́dún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ó ní n tí í bá kóówá mu láàgọ́ ara, bẹ́ ẹ̀ olójú ò ní-ín lajú ẹ̀ sílẹ̀,kítàlùbọ̀ ó yí wọ̀ ọ́.
Bí ìpànìyàn láti ṣòògùn owó ní ìpínlẹ̀ Ògùn se ń pọ̀ sí i, Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún ti késí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ láti ran ìjọba lọ́wó fi dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ náà.

Gómìnà Abíọ́dún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ẹgbẹ́ àwọn onísègùn ìbílẹ̀ níìpínlẹ̀ Ògùn, Alternate Medicine Board (OGAMB) ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà lórí ìlanilọ́yẹ tako ìwà ìpànìyàn.

Abíọ́dún wá bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà burúkú tí àwọn apànìyan ṣoògùn ọrọ̀ n se, táwọn èèyàn yókù ní Nàìjíríà sí ń fi ojú àìtọ́ wo ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà ní àsìkò ti tó láti gba ìpínlẹ̀ Ògùn kúrò lọ́wó àwọn olòògùn owó lọ́nà àti fún ìpínlẹ̀ Ògùn ni ojú titun.

Bákan náà ni Abíọ́dún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn oníṣègùn àbáláyé láti ran ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n lè dẹ́kun ìwà ìbàjẹ náà.

Ó wá ṣèlérí pé òun yóó fọwọ́ sí ìwé-àṣẹ láti dá àyájọ́ ọjọ́ Ìsẹ̀se sílẹ̀ èyí tí yóó máa wáyé lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún gbogbo àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà ọ̀hún tún ṣèlérí pé ìjọba òun pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ọ̀rọ̀ kan láti ṣètò Ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí yóó mójútó ìdásílẹ̀ ṣíṣe òògùn ìbílẹ̀ nìpínlẹ̀ Ògùn.

Àwọn agbanipa pa olùdíje sípò aṣòfin ẹgbẹ́ Labour, wọ́n tún dáná sunlé e rẹ̀

Àwọn agbanipa pa olùdíje sípò aṣòfin ẹgbẹ́ Labour, wọ́n tún dáná sunlé e rẹ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ní fẹ̀rẹ̀mọ́jú ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún yìí, làwọn agbébọn kan tí wọ́n fura sí pé agbanipa ni wọ́n, ya lọ sílé Ọ̀gbẹ́ni Christopher Elehu, tí í ṣe olùdíje fúnpò aṣojú–ṣòfin tí yóó ṣojú Ìjọba ìbílẹ̀ Onuimo, ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún, láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, tì wọ́n sì dá ẹ̀mí ẹ̀ légbodò.

Lẹyin ti wọn pa a tan, ni wọn lawọn ẹni ibi yii tun dana sun ile ati dukia ẹ, titi kan ọkọ alupupu to wa layiika ile ẹ. Fun bii wakati meji leralera ni wọn lawọn afurasi ọhun fi n yinbọn nidaaji kutukutu, nigba tẹnikẹni o ti i ji bọ sita niluu naa.

A gbọ pe awọn to ṣiṣẹ buruku ọhun tun n ya ile awọn oloṣelu yooku laduugbo ọhun lẹyọ kọọkan ṣugbọn ori ba awọn yẹn ṣe e, wọn ko si nile lasiko akọlu naa.

Ọkan ninu awọn alatilẹyin ọkunrin naa ṣalaye pe “Wọn ti pa Christopher Elehu ti gbogbo awọn eeyan maa n pe ni Wasco o. Nigba aye ẹ, oun ni oludije funpo aṣofin kekere nijọba ibilẹ Onuimo. Nigba ti wọn ri i pe oorun ti wọ awọn eeyan lara ni wọn ya bo ile ẹ, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn fun bii wakati meji. Lẹyin ti wọn pa ọkunrin yii tan, bii pe eyi ko ti i to, niṣe ni wọn tun sọna sile ẹ ti wọn jo o kanlẹ. Gbogbo awọn nnkan-ini ẹ pata tọwọ wọn ba ni wọn bajẹ raurau. Nigba ti gbogbo abule fi maa de ibi ti oku ẹ sun gbalaja si, oju ada ati aake to wa lara ẹ ko ṣeeka”.

Haa-hin-in lọrọ iku ọkunrin naa n ṣe gbogbo awọn eeyan abule wọn, awọn ti ki i ṣe oloṣelu laarin wọn gan-an si n bẹru, nitori boya lo le ti i ju ọjọ mẹwaa lọ lẹyin ti oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party nijọba ibilẹ mi-in to sun mọ wọn, Ọgbẹni Chukwunonye Irouno, ku lojiji.

Irouno yii ti wọn yan gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣakoso eto ipolongo aarẹ ẹgbẹ Labour nipinlẹ naa, lo ṣadeede ṣubu lalẹ ọjọ ipolongo ibo ku ọla. Bo tilẹ jẹ pe wọn sare gbe e digbadigba lọ sile iwosan ijọba apapọ Federal Medical Centre, niluu Owerri, ni kete ti wọn gbe e debẹ lawọn dokita sọ pe ọkunrin naa ti dagbere faye.

Oke pa ọ̀rẹ́ ẹ̀ nítorí ọ̀ọ́dúnrún Náírà

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Oke pa ọ̀rẹ́ ẹ̀ nítorí ọ̀ọ́dúnrún Náírà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní owó níín bojú ọ̀rẹ́ jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú kò mọ̀ pé olówó òun kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Inú àbíjù yìí ló kó bá ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Godstime Oke, tó torí àpò kan ààbọ̀ Náírà rán ọ̀rẹ́ ẹ̀, Allia, lọ sọ́run ọ̀san gangan.
Oke ati ọrẹ ẹ, Ọgbẹni Gaga Allia, ti wọn jọ n gbele ni wọn ni ede aiyede bẹ silẹ laarin wọn latari ọọdunrun Naira owo Nepa ti wọn pin fun ile ti wọn n ya gbe, eyi to wa l’Ojule kejilelọgbọn, Opopona Ole, lagbegbe Okumagba, Warri, nipinlẹ Delta. Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọruu, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun yii, niṣẹlẹ buburu ọhun waye.

Ohun ti a gbọ ni pe ọrẹ timọtimọ ni Oke ati Allia ti wọn jọ n gbe nile oniyara kan ninu ile naa.

Oke ni wọn lo maa n gba owo ina jọ lọwọ gbogbo awọn ara ile, ko le baa rọrun lati ko o ni kiṣi fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna lai ni i mu ariyanjiyan dani nigba ti wọn ba fẹẹ sanwo. Ṣugbọn lọjọ tiṣẹlẹ buburu yii maa waye, Oke ko si nile, nitori bẹẹ ni ọkan ninu awọn ti wọn jọ n gbele ṣe san ọọdunrun Naira (300) owo ina tiẹ fun ọrẹ ẹ, Allia, lati ba a fi jiṣẹ fun un to ba dari wọle. Nigba ti Oke pada dele lalẹ to beere owo ti wọn fi ran ọrẹ ẹ silẹ, niṣe ni Allia kọ jalẹ ti ko fun ọrẹ ẹ lowo ti wọn fi ran an silẹ.

Ọrọ owo yii ni wọn lo dija laarin awọn mejeeji, nibi ti wọn ti n ja ni Oke ti ki ẹkufọ igo mọlẹ, to si fi gun ọrẹ ẹ nibi ọrun. Loju-ẹsẹ ni wọn lọkunrin naa ṣubu lulẹ, to bẹrẹ si i japoro, bẹẹ lẹjẹ n tu yaayaa nibi ọrun ẹ titi to fi ki aye pe o digbooṣe.

Nigba ti oju Oke walẹ to ri wahala to da bọ ara ẹ lọrun lo ki ere mọlẹ, diẹ lo si ku ki ọwọ awọn eeyan tinu n bi ti wọn n leri pe awọn maa pa a tẹ ẹ.

Adugbo Ugborikoko ti ko fi bẹẹ jinna sibi ti wọn n gbe ni wọn lo sa lọ lati lọọ fara sinko, nibẹ naa lọwọ si ti tẹ ẹ l’Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun yii. Nibẹ ni wọn ti fa a le awọn agbofinro teṣan ọlọpaa ‘B’ Division, niluu Warri lọwọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, Bright Edafe, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ lo fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ, awọn si ti n sapa lati mu Tega, to jẹ agbodegba afurasi ọhun

K1 de Ultimate kí Messi kú oríire ife è̩ye̩ FIFA World Cup o̩dún 2023

K1 de Ultimate kí Messi kú oríire ife è̩ye̩ FIFA World Cup o̩dún 2023

E̩ gbó̩ àwo orin náà

Àfojúsùn èmi àti ọkọ ọ̀ mí kó papọ̀ mọ la ṣe túká- Funke Akindele

Àfojúsùn èmi àti ọkọ ọ̀ mí kó papọ̀ mọ la ṣe túká- Funke Akindele

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúgbajà òṣèré tíátà àti Igbákejì olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Funke Akindele tí tú kẹ̀ẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ lórí bí ìpínyà ṣe wáyé láàrin òun àti ọkọ rẹ̀, Abdul Rasheed Bello, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí JJC Skillz.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Legit, Funke ní àfojúsùn òun àti ọkọ òun àná ni kò papọ̀ mọ́.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ó ní gbogbo ohun tí àwọn jọ fojúsùn wò papọ̀ nínú ìgbeyàwó àwọn ni kò báraawọn mú mọ́, ìdí nìyí.

Ó ní gbogbo ìgbìyànjú láti jẹ́ pé ìgbeyàwó náà sì wà láàyè ni àwọn gbé ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ bá ibò mìíràn yọ, tí àwọn sì pinnu láti túka.

“Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ibẹ̀ nipé àfojúsùn wa nínú ìgbeyàwó wa kò papọ̀ mọ́ àti pé gbogbo ìgbìyànjú láti ríipé a sì wà papọ̀ ni ó jásí pàbó. Fún ìdí èyí, kò sì ìdí fún wa láti jọ wà papọ̀.”

Adedoyin ló ní kí ń sọ fún ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sun sílé ìtura Hilton – Ẹlẹ́rìí

Adedoyin ló ní kí ń sọ fún ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sun sílé ìtura Hilton – Ẹlẹ́rìí

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ni bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín tí ì sinmi àròyé é ṣe.
Ìgbẹ́jọ́ tún tẹ̀síwájú lọ́jọ́ Ẹtì nílé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, tó wà nílùú Òṣogbo láti tanná wádìí ikú tó pa Timothy Adégòkè.

Lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà sìi ni ikọ̀ olùjẹ́jọ́ ti kó àwọn afurasí jáde láti wá sọ tẹnu wọn lórí ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Nibi igbẹjọ naa si ni afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa ohun to mọ lori iku Timothy Adegoke.

Adesola ni oludasilẹ ile itura naa, Ọmọọba Rahmon Adedoyin lo sọ fun oun nipa idahun ti oun yoo fun awọn ọlọpaa to wa se iwadii Timothy to di awati.

Obinrin naa, tii se osisẹ nile itura Hilton Hotels nilu Ile Ife, to jẹ ti Adedoyin fikun pe oludasilẹ ile itura naa lo sọ fun oun pe ki oun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.

Nigba to n dahun si ibeere lọwọ awọn agbẹjọro, Adesola sọ fun adajọ pe Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem, lo kọ oun ni ọrọ ti oun yoo sọ naa.

O ni awọn mejeeji lo pe oun wa si ilegbe wọn, ti wọn si sọ pe ki oun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.

Osisẹ-binrin naa ni Roheem Adedoyin tun fun oun ni iwe miran dipo eyi to wa nilẹ tẹlẹ, ti orukọ Timothy Adegoke wa.

O ni iwe akọsilẹ tuntun to fun oun naa lo ni ki oun fi orukọ ẹlomiran rọpo orukọ Timothy, ki oun si fun awọn ọlọpaa ti wọn ba ti beere iwe akọsilẹ orukọ awọn alejo to sun sile itura naa.
keji ọdun 2023
Wayi o, ile ẹjọ giga naa ti sun igbẹjọ iwadi iku to pa Timothy Adegoke siwaju di ọdun to n bọ.

Adajọ Adepele Ojo to n gbọ ẹjọ ọhun lo kede bẹẹ lẹyin ti awọn agbẹjọro Olupejọ ati Olujẹjọ bere ibeere lọwọ awọn ẹlẹrii to yọju si ileẹjọ lọjọ Ẹti

Adajọ Ojo ni igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju lọjọ keji oṣu keji, ọdun 2023.

Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Adéyẹyè Ògúnwùsì sọ ìdí tó fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀

Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Adéyẹyè Ògúnwùsì sọ ìdí tó fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọọ̀ni ìlú Ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọ̀jájá kejì sọ pé òun kò dédé fẹ́ ìyàwó púpọ̀ láti kó obìnrin jọ làáfin bí àwọn ẹni ìṣaájú gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò.

Ninu ọrọ to sọ nibi eto kan to waye lati fi dupẹ fun awọn oṣiṣẹ aafin rẹ, iyẹn ile Oodua, gẹgẹ bi ara ayẹyẹ fun sisami ọdun rẹ lori itẹ ni Ọọni Ogunwusi ti ṣalaye ọrọ yii.

Ọọni ile ifẹ ni kii ṣe lati figagbaga loun tori ẹ fẹ awọn iyawo pupọ bi ko ṣe lati tubọ mu ki ogo ilẹ adulawọ goke si.
Ọlọrun fi awọn iyawo rere ti wọn jẹ ọrẹ tootọ ati alabarin rere ta mi lọrẹ. Eredi fifẹ ọpọlọpọ Olori kii ṣe nitori orogun tabi figagbaga, bikoṣe lati fi aaye silẹ fun igbeleke ogo adulawọ lọna ati lee ṣiṣẹ pupọ sii lọna ati maa ṣe iranwọ to yẹ fun ọmọniyan nipasẹ awọn olori mi ti awọn pẹlu ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin. Akẹkọjade awọn ile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria ati loke okun ni wọn.

“Mo ni dokita niyawo, mo ni agbẹjọro niyawo, mo ni onimọ ẹrọ nipa alumọni inu omi ati aṣaṣọ lẹṣọ niyawo, mo ni akẹkọọjade fasiti Cambridge ati Harvard niyawo, mo ni oluṣiro owo to gba iwe aṣẹ nilẹ Gẹẹsi niyawo ati bẹẹbẹ lọ.

“Yatọ si pe awọn Olori mi rẹwa pupọ pupọ, ọpọlọ wọn gan ji pepe, wọn kawe doju ami, wọn ri ita, wọn si kọ wọn ,wọn si tun gbẹkọ. Ki wa lo de ti emi ko ni dupẹ lọwọ Eledumare?”

Ni oṣu kẹsan an ni Ọọni fẹ akọkọ ninu ohun ti yoo di eto igbeyawo ni ṣisẹ-n-tẹle eyi to ṣi duro lori mẹfa bayii.

Ọpọ lo n woye igbesẹ ti Arole Oodua yoo gbe lẹyin ti Naomi Silẹkunọla kede lori ayelujara loṣu kejila ọdun 2021 pe oun ti fi Ọbalaye naa silẹ.

Amọṣa lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2022 ni ọọni gbe Olori Mariam Ogunwusi niyawo gẹgẹ bii yeyelua tuntun. Lẹyin eyi ni Olori Elizabeth Ọpẹoluwa, olori Tobi, Olori Ashley, Olori Ronkẹ ati Temitọpẹ wọle si aafin Oodua ni ṣisẹ-n-tẹle.
Ọọni Ogunwusi ni gbogbo ohun ti o ku fun oun lati maa ṣe bayii ni lati maa ṣeto iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

“Gbogbo ohun ti mo fẹ da nile aye ni mo ti da bayii. Ohun to ku fun mi ko ju lati maa gbe awọn eeyan ga, ki n si maa ṣe iranwọ to yẹ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ wa ati ṣiṣe iranwọ fun awọn ọdọ ilẹ afirika lati maa dagba sii ni koriya. Eduwa si ti fi awọn obinrin to n gbaruku ti iran mi ti mi. Ki lo de ti n o ni dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba?”