Home Blog Page 70

Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì FUTA gbẹ̀mí ara rẹ̀ l’Akurẹ

Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì FUTA gbẹ̀mí ara rẹ̀ l’Akurẹ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí ò kú ló nigbó òkè ọ̀hún.
Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì ìmọ̀-ẹ̀rọ tìjọba àpapọ̀ tó wà l’Akurẹ, Ọlọna Joseph Oluwapẹlumi, ni wọ́n ló ti bínú pa ara rẹ̀ lórí ìdí tí kò tí ì yé ẹnikẹ́ni.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, akẹkọọ ọun, ẹni to ti wa ni ipele kẹta ni wọn ba nibi to pokunso si ninu yara ile to n gbe lagbegbe Aulẹ, niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja

Awọn akẹkọọ kan ti wọn jẹ ẹgbẹ oloogbe ọhun ni wọn ṣakiyesi pe ilẹkun yara rẹ ṣi wa ni titi pa lasiko ti wọn lọọ ki i laaarọ kutukutu ọjọ iṣẹlẹ naa.

Nigba ti wọn kan ilẹkun titi ti wọn ko ri ẹni da wọn lohun ni wọn pinnu lati ja ilẹkun yara rẹ, iyalẹnu lo si jẹ nigba ti wọn ba a nibi to ti n rọ diro diro lori iso pẹlu bọkẹẹti ipọnmi to fi ti ẹsẹ lasiko to n goke lati pokunso.

Awọn to sun mọ ọmọkunrin ti inagijẹ rẹ n jẹ Black ọhun daadaa ni lati bii ọsẹ diẹ sẹyin lo ti n fi ọrọ iku powe lori ikanni Fesibuuku rẹ.

Ọpọlọpọ igba ni wọn lo si maa n kọ ọ sibẹ pe oun n wa ẹni ti yoo fi owo ran oun lọwọ lori okoowo kan ti oun n ṣe.

Awọn ọrọ wọnyi lo jẹ kawọn eeyan kan maa ro pe ṣe ni akẹkọọ naa mọ-ọn mọ pa ara rẹ latari ironu aroju ati aisi oluranlọwọ fun un.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni oku akẹkọọ naa ti wa ni mọṣuari, ati pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lati fidi ohun to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.

Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Bí ó bá nídìí, obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú. Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ti ṣàlàyé ìdí tí lára àwọn èèkàn léèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú náà bí i Igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọ̀ṣínbàjò, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ àti ètò ìgbanisíṣẹ́, Dókítà Chris Ngige, Mínísítà tẹ́lẹ̀rí fún ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti ìrìnà, Rotimi Amaechi, kò fi kópa nínú ètò ìpolongo ìbó fún Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Aṣíwájú Bọla Ahmed Tinubu, wọ́n ní kì í ṣe tìjà, ọ̀rọ̀ náà ní bó ṣe jẹ́ ni.

Adari eto iroyin ninu igbimọ ipolongo ibo funpo aarẹ wọn, Amofin agba Festus Keyamọ, lo tanmọlẹ sọrọ naa lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu Kin-in-ni yii, o ni aṣẹ ti ọga Ọṣinbajo, iyẹn Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, pa fun un pe ko gbaju mọ ọrọ iṣakoso lasiko yii, tori iwọnba oṣu perete lo ku fun saa ọdun mẹjọ wọn, aṣẹ ọhun ni ko jẹ kawọn eeyan ri Ọṣinbajo bo ṣe yẹ nibi eto ipolongo ibo APC. Ni ti Igbakeji aarẹ, aṣẹ ti wọn pa fun un ni pe ko doju kọ iṣejọba. Tẹyin naa ba si kiye si i, Aarẹ ti n tẹle wa lọ sawọn ibi ta a ti ṣepolongo ibo.

 

O ni: “Rotimi Amaechi, iyẹn gomina ipinlẹ Rivers nigba kan, wa si eto ipolongo ibo ta a ṣe ni Adamawa ati Jos laipẹ yii, o ti bẹrẹ si i lọ sawọn rali (rally) wa kaakiri, ṣugbọn eyi to ba wu u lati lọ lo maa n lọ, ipinnu ara-ẹni ni.

“Bakan naa, Ngige, iyẹn Chris, to jẹ gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, ko sọrọ ta ko ẹgbẹ wa, o kan jẹ pe o ti sọ p’oun ko ni i sọpọọti ẹgbẹ kankan, tabi oludije funpo aarẹ kankan ni toun ni, o loun fẹẹ duro ni danfo gedegbe, oun lo si mọ idi to fi ṣe ipinnu bẹẹ. Amọ ẹnikan ṣoṣo niyẹn jẹ laarin minisita bii mẹtalelogoji ta a ni.”

O waa kadii ọrọ rẹ pe: “Ko si ani-ani nibẹ, iṣọkan ati ajọṣepọ ẹgbẹ APC wa duro digbi ni, ko da bii ti ẹgbẹ PDP ti wọn ti fẹrẹ wogba tan.”

Tẹ o ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan ti n ṣakiyesi pe ẹkọ o ṣoju mimu laarin ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu bawọn agbaagba kan to yẹ ki wọn ṣugbaa oludije funpo aarẹ ẹgbẹ naa, Bọla Tinubu, ṣe n mọ eto ipolongo ibo rẹ loju tẹki. Lara wọn ni Ọṣinbajo, bẹẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ọkunrin naa n jade lọ sawọn ode ayẹyẹ ati ariya mi-in bii ayẹyẹ ọgọrun-un ọdun ti wọn ti da ileewe Baptist Boys High School, Abeokuta, silẹ, eyi ti Ọṣinbajo pesẹ si, to si kopa to jọju nibẹ.

Wọn loju ti ẹgbẹ APC fi gunyan eto ipolongo rẹ kọ lo fi n gbọbẹ lọdọ awọn eekan eekan ẹgbẹ naa lasiko yii, amọ Keyamo ti ni didun lọsan yoo so fawọn nigbẹyin o.

Ìpínlẹ̀ Èkó yóò gbàlejò Ààrẹ Buhari –Sanwo-Olu

Ìpínlẹ̀ Èkó yóò gbàlejò Ààrẹ Buhari –Sanwo-Olu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti kéde pé Ìpínlẹ̀ ọ̀hún yóó gba àlejò Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ọjọ́ méjì ní ọ̀sẹ̀ yìí.

Kọmisọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko Ọgbẹni Gbenga Omotoso, kede eyi lasiko apero kan ti o waye ni Alausa, Ikeja.

Omotoso ṣalaye pe abẹwo aarẹ ti yoo waye laaarin lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun ati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni oṣu ọdun yii jẹ eyi ti Aarẹ yoo ti ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba Sanwo-Olu ti n ṣe paapaa julọ akanṣe iṣẹ ni ibudo okun Lekki Deep Sea, ile iṣẹ ti wọn ti n fọ irẹsi ni Imot ati akanṣe iṣẹ Reluwe ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe.

Kọmisọna fi kun pe Buhari yoo tun ṣe ifilọlẹ iṣẹ akanṣe aladani kan ni Apapa ati pe gomina ati iyawo rẹ, Dokita Ibijoke Sanwo-Olu ni yoo ṣiwaju awọn ti yoo ki Aarẹ kabo.

Ijọba ipinlẹ Eko tun ti kede pe awọn opopona kọọkan ninu ìgboro Eko ati Lagos Island yoo wa ni titipa ni fun awọn ọjọ mejeeji ti Aarẹ Buhari yoo fi maa ṣe awọn iṣẹ yii.

Ni ọjọ aje, ko ni si eto irinna lagbegbe ilẹ iṣẹ to n fọ iresi ni Imota Ikorodu(Lagos Rice Mill)ati agbegbe Ibudo Okun Lekki Deep Port.

Bakan naa ni ọjọ keji ko ni si aaye fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe ile ìtura Eko Hotels ni opopona Ahmadu Bello, J-Randle lọ si Broad street ati Marina lati aago mẹfa aarọ si aago mẹta ọsan.

Frederic Oladeinde ni awọn awako ko ni le gba Opona Ahmadu Bello,Ademola Adetokunbo, ati Akin Adesola si afara Falomo kí wọn si gba opopona Alfred Rewane lọ si ibikíbi tí wọn ba n lọ.

Ẹwẹ, Kọmisọna naa ṣalaye awọn opopona miiran ti awọn awakọ le gba lojuna ati le din sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ku.

Awọn awakọ le dari si Onikan lati opopona Ozumba Mbadiwe ati Bonny Camp gba ori Afara Falomo tabi opopona Awolowo.

Bakan naa ni awọn awakọ lati opopona Awolowo lọ si Onikan, si Tinubu Square tabi awọn agbegbe to yi inu Eko ka le ko oju ọna Falomo lati jade si Alfred Rewane.

Fun awọn awakọ lati opopona King George V, ki wọn gba opopona Moloney si Obalende tabi ki wọn gba opopona Turton lọ si Moloney si Opopona Sandgrouse.

Fun awọn to n bọ lati Eko Bridge lọ si Marina kí wọn gba Elegbata si Ebute ero lọ si police post lati gun afara 3rd Mainland (Adeniji Adele) lọ si ibikíbi tí wọn ń lọ.

Frederic fi kun pe gbogbo opopona to dari si awọn ọna ti aarẹ Buhari yoo gba kọja ni yoo wa ni titipa.

E lọ wo àkọsẹ̀jayé àwọn olùdíje kí ẹ tó dìbò fún wọn – Akinwale Oludije LAbour Party

E lọ wo àkọsẹ̀jayé àwọn olùdíje kí ẹ tó dìbò fún wọn – Akinwale Oludije LAbour Party

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oludije Tawfiq Tayo Akinwale tó ń díje dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party sọ̀rọ̀ ilẹ̀ kún nínú ìpàdé ìtagbangba kan tó wáyé ní gbọ̀ngàn-an Theophilus níwájú géètì lléèwòsàn Fásítí kọlẹ̀ẹ̀jì (UCH) ní ìlú Ìbàdàn.

Taofiq Akinwale ni: “Mo ní ìrírí tó kún nípa ìṣèlú àti ìjọba fún ọdún mejila, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ni ìjọba yóò máa jẹ tí àwọn tó bá wà nípò kò bá ní ìrírí tó.

“Kìí iṣẹ́ gómìnà láti kọ́ gáréjì ọkọ̀, ọjà kí wọ́n sì máa gbowó níbẹ̀, mà á fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn.

“Emi kò faramọ́ dídá ilé ẹ̀kọ́ tuntun sílẹ̀ tàbí kí a sọ èyí tí kò dára tó tó wà nílé dí Fasiti”

“Abẹ́ ìjọba ni ètò ààbò máa wà tí mo bá di gómìnà Oyo lábẹ́ ìgbìmọ̀ tí àwọn orí adé ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ yóò wà ní àkóso ètò ààbò agbegbe wọn.”

Tí Ọkọ mi kò bá ṣe dáadáa, ẹ lé wa kúrò ní Aso Rock- Iyawo Tinubu

Tí Ọkọ mi kò bá ṣe dáadáa, ẹ lé wa kúrò ní Aso Rock- Iyawo Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oluremi, ìyàwó olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu ti rọ àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí láti kọ̀ yín sí ọkọ òun tó bá kùnà láti ṣe dáadáa tí wọ́n bá yàn-án gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ.

Sẹ́nétọ̀ sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó tó ń kópa nínú ìpolongo ìbò àwọn obìnrin fún Tinubu/Shettima nílùú Owerri ní ìpínlẹ̀ Imo.

Oluremi ní ètò ìdìbòtó ń bọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò gbọdọ̀ dálé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn rárá sùgbọ́n ipa tí àwọn olùdíje lè kó nínú i ìdàdagbàsókè Orílẹ̀ yìí .

Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fún olùdíje Mùsùlùmí méjì láàyè gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fún ẹlẹ́sìn Kìrìsìtẹ́nì méjì láàyè.

“Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣìn sí ibì kan, èmi gan-an Kristẹni ni mí. Ń jẹ ẹ ti rò pé ní ijọ́ kan Kìrìsìtẹ́nì méjì kò ní-ín jẹ Ààrẹ.

  1. “A ti dán Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì papọ̀, ẹ jẹ́ ká gbìnyànjú eléyìí náà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, tí wọn kò bá ṣe dáadáa, ẹ lé wa jáde, ẹ kọ̀ yìn sí wọn.”

CBN’ gbéná wojú àwọn báǹkì tó ń kó owó náírà àtijọ́ sínú ATM wọn dánrin

‘CBN’ gbéná wojú àwọn báǹkì tó ń kó owó náírà àtijọ́ sínú ATM wọn dánrin

 

Ọrẹ Òtítọ́jù

Báńkì àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí ti sọ pé òun ò ní-ín bojú fi wẹ̀yìn, láti fimú àwọn ilé ìfowópamọ́ tó ń kó owó o náírà àtijọ́ sínú ẹrọ ATM wọ́n ní ìpínlẹ̀ Ogun dánrin.

Ọdun to kọja ni CBN kede owo igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira tuntun to si sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2023 yii ni opin yoo de ba nina owo naira atijọ.

Ni bayii to ku nnkan bii ọsẹ meji ki gbedeke ti CBN fi lede lori owo atijọ naa pe, ọpọ araalu ni ko tii ri owo naa gba.
Ẹwẹ, adari CBN niluu Abeokuta, Lanre Wahab sọ pe awọn yoo fi imu ile ifowopamọ to ba ṣi n ko owo atijọ sinu ẹrọ rẹ danrin.

O ni “Banki apapọ yoo fi iya jẹ ile ifowopamọ to ba ṣi n fun awọn araalu ni owo atijọ ninu ATM wọn.”

Wahab ni CBN yoo bẹrẹ si n yẹ awọn ẹrọ ATM wo lati ri daju pe owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ lo wa ninu rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2023 ni CBN ti paṣẹ ki awọn ile ifowopamọ dẹkun ati maa fun araalu ni owo atijọ.

O fikun pe “Eyikeyi ile ifowopamọ ti a ba fiya jẹ lori ọrọ yii, iya naa tọ si irufẹ banki bẹẹ, nitori a ti kilọ fun wọn ṣaaju.”

Wahab wa rọ awọn araalu lati maṣe bẹru lati na owo tuntun naa nitori o gba ontẹ ijọba.

Lẹyin naa lo rọ wọn ki wọn tete lọ paarọ owo nairan atijọ si tuntun ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 ti wọn yoo fopin si nina rẹ kaakiri Naijiria.

Odidi agbárí èèyàn mẹ́ta ni Rasaq fìgboyà kó lọ́wọ́, ó ní òun hewọ́n nínú gọ́tà l’Ékóó

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Odidi agbárí èèyàn mẹ́ta ni Rasaq fìgboyà kó lọ́wọ́, ó ní òun hewọ́n nínú gọ́tà l’Ékóó

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ojoojúmọ́ ayé sá à nìròyìn ìrọ̀lẹ́ ayé ń peléke é sí i, à bí báwo lagbárí èèyàn ṣe wá á wínlẹ̀ dohun téèyàn ń rí he nínú gọ́tà, èyí gan-an ló ń ṣe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ni hàà-in, bí afurasí ọ̀daràn kan tí wọ́n porúkọ rẹ̀ ní Rasaki Aṣiwaju, ẹni ọdún márùndínlógójì, táwọn agbófinró mú, pẹ̀lú kòròòfo agbárí èèyàn mẹ́ta lọ́wọ́ ẹ̀, ṣe sọ pé òun ò pààyàn, òun ò sì wú òku olókùú, ó ní inú gọ́tà lòun ti rí agbárí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ọ̀hún he, òun ò mọ bó ṣe débẹ̀, àmọ́ òun nílò o wọn ló jẹ́ kí òun sà
wọ́n.

Wọn ni Rasaki n ko awọn agbari naa lọ sibikan to loun ti fẹẹ lo wọn lo fi ko sakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, lọjọ Aje,ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

Awọn ọlọpaa naa ni wọn da a duro lọna, wọn lawọn fẹẹ wo ẹru to gbe di sinu lailọọnu baagi dudu kan, ṣugbọn o ni ko si ẹru ofin nibẹ, awọn nnkan iṣegun toun fi n ṣe aajo lasan lo wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn fi dandan le e pe ko tu u.

Titu ti wọn lọkunrin naa tu baagi ọhun desalẹ, lo jẹ agbari eeyan mẹta lo ko sibẹ.

Njẹ ko ṣalaye ohun tawọn agbari naa n ṣe, niṣe lo bu sẹkun gbaragada bii ọmọde, o ni ki wọn ṣaanu oun, oun ri wọn he ni o, inu gọta loun ti ri wọn, oun o ji wọn ko o, bẹẹ ni wọn lo n tara para pe aye oun ti bajẹ, oun ti daran.

Ninu fọran fidio kan ti Ọlaoluwa fi soju opo tuita rẹ lori ẹrọ ayelujara, o ṣafihan afurasi ọdaran ọhun bo ṣe bu sẹkun ninu ṣaati alawọ buluu ati turọsa alawọ amọ̀ (brown) to wọ, bẹẹ lo n dọwọ bo oju rẹ, to n pariwo pe aye oun ti bajẹ.

O ni, “Ẹ ṣaanu mi o, baba mi ti ku, baba mi ti ba temi jẹ ko too lọ, mo ri awọn ori oku yii he ninu gọta laaarọ yii ni o, agbegbe Ayọbọ, ni Ipaja, ni mo ti ri wọn he. Haa, aye mi ti bajẹ o, temi ti bajẹ o.

O tun ni: “mi o ko wọn lọ sibi kankan o, emi ni mo fẹẹ lo wọn, mo fẹẹ lo wọn fun ara mi ni o. Mo mọ pe mo ti lufin, ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi, aajo ara mi ni mo ni ki n ṣe o.”

Amọ, ọkan ninu awọn to ri fidio yii kọ ọrọ sabẹ fọran naa lori ikanni tuita ọhun pe kawọn ọlọpaa ṣewadii daadaa, tori itẹkuu kan wa ti ko jinna si agbegbe ti afurasi ọdaran naa loun ti ri ori oku he yii. O ni afaimọ ni ki i ṣe pe niṣe lo lọọ hu awọn ori oku olokuu ninu saare, to waa n dibọn pe inu gọta loun ti ri wọn he.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni Rasaki ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ni Yaba, lori ẹsun yii. O lawọn ti n ba iwadii to lọọrin lọ, ati pe abọ iwadii ni yoo pinnu igbesẹ ofin to kan lori iṣẹlẹ naa.

Ó mà se! o̩kò̩ ayó̩ké̩lé̩ Kunle Afod jóná gúrúgúrú

 

Ó mà se! o̩kò̩ ayó̩ké̩lé̩ Kunle Afod jóná gúrúgúrú

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata Naijiria ati agberejade, Kunle Afod, laipe yii soro ibanuje pelu atejade re kan to fi lede ni oju awe re, nibi to ti dun bii eni ti ofo se to si wa ninu inira lori ajalu buburu to ko lu u.

Afod, fi fonran oko Toyota Hiace re ti ina omo orara jo kanle koja titun se lede. Agberejade naa tun fihan wi pe awako oun gangan farapa ninu ijamba ina naa.

Osere tiata naa, ninu fonran oko re to baje naa eleyii to fi si oju awe re, la ri ti omi le soju re tente to si n gbon ni bi o se n ye oko naa wo lati wo awofin bi oko naa ti se baje to. Fonran naa fihan pe awon eniyan wa pelu re ti won ba n kedun.

Ewe, ko to pe wakati merin-le-ni-ogun leyin atejade akoko lati owo Kunle Afod to n kede isele laabi naa, o tun fi fonran miiran lede lati dupe lowo awon ololufe re, awon akegbe ati awon alatileyin re fun abewo ti won se si i.

Davido gba ife è̩ye̩ márùn ún níbi ife è̩ye̩ ARFIMA 2023

Davido gba ife è̩ye̩ márùn ún níbi ife è̩ye̩ ARFIMA 2023

Mary Fágbohùn

Olorin takasufe Davido ti gba ife eye marun un nibi ife eye All Africa Music Award (AFRIMA) eleekejo iru re.

Meji lara ife eye naa ni orin to ko pelu Adekunle Gold ati Tion Wayne wa lara re.

Oga DMW naa ni o jawe olubori fun’Best Male Act in African Inspirational Music, ife eye fun orin ‘Stand Strong’.

Orin re ‘Champion Sound’ to ko pelu olorin South Africa ni o ti gba ife eye meji miiran eleyii ni o pelu ‘Best Act, Duo or Group in African Electro’ ati ‘Best African Collaboration’.

O tun gba ife eye miiran ‘Best Act in Diaspora Male’ fun orin re pelu Tion Wayne ‘Who’s True’.

Orin Adekunle Gold ‘Born Again’ to ko pelu Fatoumata Diawara naa gba ife eye fun ‘Best Act Duo or Group in African Contemporary’. O si tun gba ‘Best Act, Duo or Group in African Pop’ fun orin High to ko pelu Davido.

Olugbafe eye Grammy fun orin ile Adulawo, Burna Boy naa gba ife eye to se pataki fun, ‘Best Act in Africa’ pelu orin re ‘Last Last’ ati ife eye fun ‘Best Album of the Year’ pelu akojopo orin re ‘Love Damini.’

Pelu Wizkid ti oun naa pada sile pelu ife eye fun ‘Best Male Act in West Africa’ pelu orin re ‘Anoti’.

Asale ife eye AFRIMA yii, ni o waye ninu gbongan to gba eniyan egberun lona marun-din-ni-ogun to wa ni Dakar Arena ni Diniadio, Senegal ti won se papo pelu ajodun orin ti wa fi ki awon olorin Afrika kuuse.

Aseye naa ni awon olorin ati akorin Naijiria ti fi orin won da dundun ara, bii, Tiwa Savage, Sensational Singers, P Square, olorin Ghana Black Sheriff ati awon olorin ile Afika miiran.

Lé̩è̩kan síi, Brymo ti rawó̩ è̩bè̩ fún ohun tó so̩ lórí ò̩rò̩ Aare̩ Igbo

Lé̩è̩kan síi, Brymo ti rawó̩ è̩bè̩ fún ohun tó so̩ lórí ò̩rò̩ Aare̩ Igbo

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Olawale Olofooro, ti a mo daadaa si Brymo, ti bebe ni gbangba leekan sii fun oro to so lori bi o se seese ki Aare wa lati aarin eya ila-orun guusu.

Olorin naa ni awon eniyan ti rojo ina oro si leyin to wi pe ala ti ko le e se ni wi pe ki Igbo je Aare nitori ete won fun Biafra.

“Niwon igba ti awon eniyan pataki ni aarin awon Igbo ba si n soro Biafra, Aare lati eya Igbo je ala ti ko le e se,” ni ohun ti Brymo fi si oju opo Twitter re.

Brymo, eni to n satileyin fun oludije ninu egbe oselu All Progressive Congress, Bola Tinubu, ti so fun awon eniyan ila-oorun guusu pe ki won koko to igbakeji Aare wo naa ki won to beere si ni le ipo Aare gangan.

Oro to so yii ni awon eniyan bu enu ate lu, ti o si fa orisirisi oro kobakungbe ni ori ayelujara, ti opo eniyan fi pe e eleyameya ti won si wi pe “ko feran eya Igbo.”

Leyin oro yii ni Brymo, rawo ebe loju opo Instagram re ni ale ojo Eti.

O lo si ori ayelujara, o si wi pe oro naa suyo leyin ti o so erongba re nipa onkowe, Chimamanda Adichie, eni ti o ko eye orile-ede sugbon to gba oye ti won fi da a lola ni ilu re, Abba, ipinle Anambra.

Nigba to n bebe, o wi pe, “Mi o bu eya, fun awon to ba jo bee leti won, e ma binu. Mo n gbiyanju lati woye oro pataki kan ni.”

Ewe, ni kutukutu owuro ojo Aje, o fi si oju opo Twitter re irawo ebe miiran, “E foriji oro ti mo so nigba eya Igbo eyi to so mi di eleyameya, mi o ro ti aburu kankan, e ma binu!!”

Ebe re akoko wa leyin ti egberun omo orile ede Naijiria ko iwe mo o pe ki won mase je ki olorin naa jawe olubori ninu ifasile re fun ‘eni to morin ko sile julo laarin odun’ ninu ife eye gbogbo orin Afirika.
[