Home Blog Page 69

Ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ san fún wá kò b’ ẹ́rìn-ín dé o, àádọ́tadinlọọdunrun ẹgbẹ̀rún naira la fẹ́ – NLC/TUC

Ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ san fún wá kò b’ ẹ́rìn-ín dé o, àádọ́tadinlọọdunrun ẹgbẹ̀rún naira la fẹ́ – NLC/TUC

Quseem Gbọ́láhàn

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà (NLC) ní òun kò ní faramọ́ owó tó dín ní aadọtadinlọọdunrun ẹgbẹ̀rún náírà (#250,000), gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣeẹ́ tó kéré jùlọ.

Igbakeji akọwe agba ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Chris Onyeka ni ẹgbẹrunmejilelọgọta naira (#62 ,000) ti ijọba fi lọ awọn ko ni jẹ atẹwọgba, bẹẹ lawọn ko ni gba ẹgbẹrunlọnaọgọrun náírà (#100,000) ti awọn eeyan kan ni ki awọn gba.

Ọrọ yi lo n jade lẹyin ti alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọun, Joe Ajaero sọ pe awọn n duro de esi Aarẹ Bola Tinubu lori ọrọ naa ati igbesẹ ti yoo gbe.

Ni lọọlọọọ yi, ni ọfisi akọwe ijọba apapọ jabọ pe, igbimọ to n jiroro lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ naa ti jabọ ijiroro rẹ fun ijọba.

Ṣaaju, lẹyin ipade igbimọ ọun ni ijọba ti kọkọ sọ pe ẹgbẹrunmejilelọgọta ni agbara oun gbe, gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, ti ẹgbẹ oṣiṣẹ si yari pe owo ọhun ti kere ju, ati pe aadọtadinlọọdunrun ẹgbẹrun naira (#250,000) l’awọn o gba.

Ẹwẹ, bi awọn araalu ṣe n jẹ ọrọ naa lẹnu ni ẹgbẹ awọn Gomina ni Naijiria kede pe awọn ko ni le san owo oṣiṣẹ to kere julọ to ba le ni ọgọtaẹgbẹrun naira (#60,000)

Agbenusọ igbimọ ijọba to n jiroro lori ọrọ naa, Segun Imohiosen, sọ pe igbimọ oun ti pari ijiroro rẹ, o si ti fun akọwe ijọba apapọ ni ohun to ba bọ “.

“Wọn yoo fun Aarẹ ni esi ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ, aṣoju ijọba ati awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ aladani ba pada de lati apero ẹgbẹ oṣiṣẹ agbaye ti wọn lọ ṣe ni Geneva, Switzerland.”

Bí EFCC ṣe ń kọlu àwọn ọ̀dọ̀ tako ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn—àwọn ọ̀dọ́ kan

Bí EFCC ṣe ń kọlu àwọn ọ̀dọ̀ tako ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn—àwọn ọ̀dọ́ kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí ẹni tó sọ̀rọ̀ tí kìí fẹ́ ràròjàre, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló péjọ sí Agbègbè Alagbaka ní ìlú Akure láti ṣe ìwọ́de tako ìgbésẹ EFCC bí àjọ ọ̀hún ṣe sàkọlù sí àwọn ilé àríyá méjì lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Awọn ọdọ naa ni wọn bẹrẹ iwọde yi lati First Bank ni Alagbaka ti wọn si pari rẹ si ofisi Gomina n’ilu Akure.

Awọn ọdọ ọhun ke si ijọba lati fopin si iwa ipa ti EFCC n lo lati mu awọn eniyan, bi wọn ṣe sapejuwe igbesẹ awọn ikọ EFCC gẹgẹ bi eyi ti o tako ẹtọ ọmọ eniyan labẹ ofin.

Lasiko to n ba akọroyin sọrọ, ọkan lara olori awọn ọdọ nipinlẹ Ondo Oluwaseun Ogunmola sọ pe ikọlu ikọ EFCC naa jẹ ohun ti ko bojumu, o si pe fun itusilẹ awọn ọdọ ti wọn fi panpẹ ọba mu naa.

Ajafẹtọ awọn ọdọ l’Ondo, Yemi Fash, sọ pe EFCC nilo lati maa ṣe iṣẹ wọn lọna ti o bofinmu.

O salaye rẹ pe, awọn ikọ EFCC naa tẹ ẹtọ awọn eniyan loju mọlẹ bi wọn ṣe nawọ lilu si ọpọlọpọ awọn obinrin to wa nibẹ ati bi wọn se gba nnkan ini awọn eniyan ni asiko naa.

O seleri pe awọn ọdọ nipinlẹ Ondo ko ni faaye gba iru iwa kotọ yi, ti wọn yoo si ri daju pe wọn gba gbogbo ohun ini awọn eniyan ti wọn gba pada, ti wọn yoo si gba itusilẹ awọn ti wọn ko lọ si ilu Ibadan.

Ìjọba sọ ọ́ dèèwọ̀ láti gbé ọmọbìnrin tọ́jọ́ orí rẹ̀ kò tó ọdún méjìdínlógún lọ s’ótẹ̀ẹ́lì

Ìjọba sọ ọ́ dèèwọ̀ láti gbé ọmọbìnrin tọ́jọ́ orí rẹ̀ kò tó ọdún méjìdínlógún lọ s’ótẹ̀ẹ́lì

Fẹ́mi Akínṣọ́lá

Ó jọ pé ọ̀rọ̀ náà ti kan ìjọba ló mú kí
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ obìnrin lórílẹ̀ yìí, Abilékẹ Uju Kennedy Ohaneye, ó sọ pé ìjọba orílẹ̀ yìí kò ní-ín fààyè gba àwọn ọ̀bàyéjẹ́ gbogbo tí wọ́n n gbé ọ̀dọ́bìnrin tọ́jọ́ orí wọ́n kéré jọjọ lọ s’ótẹ̀ẹ́ẹ̀lì káàkiri orílẹ̀ yìí mọ́.
O ni iya nla nijọba maa fi jẹ ẹni yoowu tọwọ ba tẹ pe o ṣe iru nnkan bẹẹ lawujọ wa bayii. Ọjọ Abameta, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo sọrọ ọhun di mimọ nibi eto pataki kan to waye niluu Abuja.

Oun ta a gbọ pe lara ọna tijọba fẹẹ gba lati din bi awọn oniṣẹ ibi ṣe n ko awọn ọmọde tọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọọ fi ṣowo ẹru l’Oke-Okun, ni wọn ṣe ṣofin naa sita bayii.

Aipẹ yii ni fidio kan jade sita, nibi ti aworan awọn ọmọde kan lati ilẹ wa ti wọn ko lọọ ṣowo ẹru lorileede Ghana ti jade, ti ọjọ ori awọn ọmọ naa ko ju ọdun mẹẹẹdogun si mẹrindinlogun lọ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti ni, ‘’O ti deewọ fawọn eeyan lorileede yii lati mu ọmọdebinrin tọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọ si otẹẹli bayii, ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe bẹẹ. Bẹrẹ lati ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, a ti pa a laṣẹ fawọn otẹẹli igbalode gbogbo pe ki wọn gbe patako ipolongo sita pe awọn ko gba pe ki wọn gbe ọmọ t’ọjọ ori rẹ ko to ọdun mejidinlogun wa sọdọ wọn mọ. Ọwọ lile la maa fi mu ọrọ naa bayii, kekere ni ijiya tawọn kan jẹ nipinlẹ Niger, lori iru ọrọ naa, bi erin ba dan an wo bayii, iwo rẹ aa lọ ni. A ko ni i faaye gba iwa palapala mọ laarin ilu, ko yẹ ki won maa gbe awọn ọmọ t’ọjọ ori wọn

Ìjọba Ọ̀yọ́ fẹ́ gba àwọn ọ̀dọ́ siṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn

Ìjọba Ọ̀yọ́ fẹ́ gba àwọn ọ̀dọ́ siṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Látàrí lemọ́lemọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ṣe n wáyé níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, láìpẹ́ yìí, Gómìnà Ṣèyí Mákindé, ti bẹ̀rẹ̀ ètò láti gba àwọn èèyàn tó dá pé, tí wọ́n sì ṣetán àti dáàbò bòlú ṣíṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn.

Makinde fidi eyi mulẹ ninu atẹjade ti oludari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ọgagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, fi sita, eyi to tẹ akọroyin wa lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ninu awọn eeyan ti wọn fẹẹ gba yii la ti ri awọn ọdẹ ibilẹ ti wọn yoo maa wọ inu igbo tọ awọn oniṣẹ ibi lọ.

“Ẹnikẹni to ba nifẹẹ si iṣẹ yii ni lati kan si ikanni igbanisiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ki onitọhun si lo itakun ayelujara isalẹ yii lati forukọ silẹ:

www.jobportal.oyostate.gov.ng

Ikanni igbanisiṣẹ ti wa ni ṣiṣi silẹ bayii lati ọjọ Abamẹta, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, titi di ọgbọnjọ (30), oṣu yii, kan naa.

Amọ ṣa o, oluwaṣẹ gbọdọ ri i daju pe nọmba idanimọ wa lọwọ oke, lapa osi fọọmu rẹ. ‘AMOD’ ni yoo bẹrẹ nọnba naa.

“Awọn eeyan to lalaafia, tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) si aadọta (50) ọdun nìkan ni iṣẹ yii wa fun.

“Ẹ waa gbọ o, kikida awọn ọmọluabi eeyan nikan ni iṣẹ yii wa fun o, ko si fun ẹni to ba ti ṣẹwọn ri tabo to ti ni akọsilẹ iwa ọdaran ri.

“Ẹka aṣọgbo la fẹẹ gba awọn eeyan si. Nitori naa, gbogbo inu igbo ti awọn amookunṣika maa n fara pamọ lati ṣiṣẹ ibi ni ipinlẹ yii, ni gbogbo wọn yoo maa ṣọ kaakiri lati maa daabo bo ẹmi atí dukia awọn araalu, pẹlu ohun alumọọni ijọba to wa ninu aginju igbo gbogbo”.

Alákòóso ìkọ Amọtẹkun ṣalaye siwaju pe, “lẹyin ti awọn oluwaṣẹ yii ba ti kọ gbogbo ohun to ba yẹ sinu fọọmu wọn lori ẹrọ ayelujara tan, ti wọn si ti fi i ranṣẹ lori ẹrọ ayelujara nibẹ, wọn ni lati tẹ fọọmu naa jade.

“Lẹyin naa ni wọn yoo ṣeyẹwo ilera wọn nileewosan to jẹ tijọba, ki dokita to jẹ akọṣẹmọṣẹ si fọwọ si i.

Awọn adari ilu ati alaga ijọba ibilẹ oluwaṣẹ gbọdọ buwọ lu fọọmu rẹ laaye ti a pese silẹ fun olukuluku wọn. Gbogbo fọọmu ti oluwaṣẹ tẹ jade ni alakooso eto ibura nile-ẹjọ to kunju oṣunwọn gbọdọ lu lontẹ. Lẹyin naa ni wọn yoo ko gbogbo fọọmu ti wọn ba ti fọwọ si gẹgẹ bo ṣe yẹ lọ si ibi ti a maa kede fun wọn nigba ti asiko ba to”.

Àmọ́ ṣa, wọn ni ànfàní iṣẹ́ yìí kò sí fún ẹnikẹni tó bá ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Amọtẹkun rí, ṣùgbọ́n tí o jẹ́ pe niṣe ni wọ́n le e dànù.

“Gbogbo ohun tí Fẹmi Jimoh ń sọ nípa iléèjó̩sìn MFM, iró̩ funfun báláú ni”

“Gbogbo ohun tí Fẹmi Jimoh ń sọ nípa iléèjó̩sìn MFM, iró̩ funfun báláú ni”

Ileejọsin Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ti ṣapejuwe ọrọ ti ọkan ninu awọn Pasitọ ṣọọṣi naa tẹlẹ sọ ninu fọnran kan to n ja rain-rain lori ẹrọ ayelujara, gẹgẹ bi irọ funfun balau.

Ṣọọṣi ọhun sọ pe, o pẹ ti ọkunrin Pasitọ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Fẹmi Jimoh ti maa n wu iwa laabi, ni gbogbo ijọ ti wọn ba gbe e lọ ṣe adari. Eyi lo mu ki wọn gbe e pada wa si olu ile ijọsin naa lati fi da sẹria fun, gẹgẹ bi ohun ibawi, nireti pe yoo yi iwa rẹ pada.

Ọrọ ti ọkunrin naa n sọ kiri naa to n jo kiri bi ina, ti n mu awuye-wuye dani, o si mu ki awọn araalu fi oju buruku wo ileejọsin naa.

Ṣugbọn, ninu ọrọ ti ileejọsin naa fi ranṣẹ si awọn oniroyin, lopin ọsẹ to kọja, wọn fi to wa leti pe ọkunrin yii, Jimoh, ati ojugba rẹ, tiyẹn n jẹ Caleb Ọlọruntẹlẹ, ti n gbero bi wọn ṣe maa ja ileejọsin naa lole, ki wọn si gbe owo ọrẹ ti wọn pe ni akọso lọ.

Nigba ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ ni olu ileejọsin naa lọjọ Ẹti, Fraide, Agbẹjọro ṣọọṣi naa, Ọgbẹni Davidson Adejuwọn, sọ pe irọ ti awọn ọkunrin mejeeji wọnyi n pa kiri, jẹ eyi to n kọ ileejọsin naa lominu, nitori ko si ootọ kan nibẹ rara.

Lara awọn irọ ti awọn ọmọkunrin wọnyi n pa kiri, gẹgẹ bi Adejuwọn ṣe sọ fun wa, ni pe; ṣe ladari ileejọsin naa ti oun mọle fun odidi ọdun mẹsan-an, gbogbo ẹbẹ iya oun lọdọ adari ijọ naa, pabo lo ja si.

Adejuwọn tun sọ pe ohun to ṣẹlẹ ni pe ileẹjọ gba beeli rẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ko ri ẹni gba beeli rẹ rara.

“Ohun taa lero pe o yẹ ki Ọgbẹni Jimoh atawọn mọlẹbi rẹ ṣe ni pe ki wọn wa ẹni to maa gba beeli fun wọn, bẹẹ ko sọrọ owo ninu beeli yii rara, gẹgẹ bi awọn lọọya kan ti n gbe e pooyi ẹnu kiri.

“Njẹ ko ya yin lẹnu pe ohun ti wọn n sọ kiri pe Pasitọ Daniel Olukọya, to jẹ olori ijọ MFM lo ti awọn mọle fun odidi ọdun mẹsan-an, nigba to jẹ pe ileẹjọ fun wọn ni beeli, awọn to si yẹ ko gba beeli wọn ko ṣe bẹẹ, ewo ni ti Olukọya nibẹ?

“Ileejọsin to ni laari ni ijọ MFM, wọn si mọ bi a ti n tọju awọn olujọsin gbogbo to wa nileejọsin naa daadaa. Gbogbo igbiyanju wọn lati bu ẹnu atẹ lu ohun ti ileejọsin naa n ṣe ko le bori rara, nitori ijọ Ọlọrun ni.

“Ẹtọ wa ni lati sọ fun awọn agbofinro ohun ti ko ba lẹtọọ to n ṣẹlẹ ninu ijọ naa, ohun ti a si ṣe naa niyẹn. Ohun gbogbo to ṣẹlẹ lẹyin yẹn, kii ṣe ohun to kan ileejọsin naa rara, ọrọ ileẹjọ ni, ọrọ naa ti kuro lọwọ ṣọọṣi, o ti di ọrọ ijọba.

“Kii ṣe Olukọya lo ju Jimoh ati ojugba rẹ sẹwọn ọdun mẹsan-an, iwa rẹ ni, adajọ lo si paṣẹ bẹẹ. Ko si nnkan to kan ṣọọṣi ninu aṣọle to n tojubọle lọ sọdọ awọn babalawo kiri, iyẹn ko kan wa rara.”

Lara awọn ti Jimoh lọọ bẹ lọwẹ pe ki wọn waa darapọ mọ oun lati ja ṣọọṣi lole, ṣalaye bi wọn ṣe ka gbogbo ohun ti wọn jọ sọ silẹ sinu fọnran fun awọn agbofinro.

Akeem Mọmọdu ti wọn n pe ni Ọmọjọmọlọ, Ọgbẹni Adebayọ Fatai, ti wọn n pe ni Aboki ati Ọgbẹni Tajudeen Oseni ti wọn n pe ni Orji ṣalaye fun awọn agbofinro pe Jimoh lero pe awọn fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ninu iṣẹ ibi naa, ṣugbọn ko mọ pe awọn fẹẹ mu u lọrun ọwọ ni.

Ọpẹ́ o! Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹjọ táwọn agbébọn jí gbé ní Kwara gbàdáǹdè

Ọpẹ́ o! Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹjọ táwọn agbébọn jí gbé ní Kwara gbàdáǹdè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kwara, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ́ fijilanté àti àwọn ọmọ ológun ti dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga Fasiti Confluence Science and Technology, tìlúu Osara, ìpínlẹ̀ Kogi, táwọn agbébọn jí gbé ní bíi ọjọ́ mélòó kan ṣẹyin, tí wọ́n sì ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá Kwara báyìí.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, DSP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi sita lọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, to tẹ akọròyìn lọwọ sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa, pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante ati awọn ọmọ ologun, ti doola ẹmi awọn akẹkọọ mẹjọ kan ti awọn ajinigbe ji gbe nipinlẹ Kogi. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ni kete ti olobo ta ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, pe awọn agbebọn wa ninu igbo kan lagbegbe Òrò-Àgọ́, nipinlẹ naa, ni Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Ọlaiya Victor, paṣẹ ṣe ki awọn ẹṣọ alaabo ya wọ inu igbo ọhun, ti wọn si doola ẹmi awọn akẹkọọ mẹjọ kuro lakata awọn ajinigbe naa, o ni mẹjọ ni wọn, obinrin marun-un ati ọkunrin mẹta.

Orukọ wọn ni, Anate Hanifa Oyiza, ẹni ọdun mọkandinlogun, Damisa Rashida Ometere, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Ahmed Tijani Fatimah, ẹni ọdun mọkanlelogun, Obakachi Mashkurah Onyioyiza, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Ọlọruntọba Blessing Kẹmisọla, ẹni ọdun mẹtalelogun, Omojo Godwin, ẹni ọdun mọkandinlogun, AbdulRafiu Abdulmakik Enesi, ẹni ọdun mọkandinlogun ati Musa Oseni, ẹni ọdun mọkandinlogun, ti wọn si ko gbogbo wọn lọ si agọ ọlọpaa ẹka Òrò-Àgọ́. A gbọ pe wọn ṣi maa ko gbogbo wọn lọ siluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, fun ayẹwo ati itọju to peye nileewosan.

O tẹsiwaju pe awọn ẹṣọ alaabo ti n sa ipa wọn lati ṣawari awọn agbebọn ọhun, ti wọn aa si fimu kata ofin.

CP Ọlaiya, ti ni ki gbogbo olugbe Kwara lọọ fọkanbalẹ, aabo to peye wa pẹlu wọn, ti wọn ba si kẹfin iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn fi to awọn agbofinro leti.

O lu ọga ọlọpaa patapata nilẹ yii, Kayọde Ẹgbẹtokun, lọgọ ẹnu pẹlu bi wọn ṣe n ṣiṣẹ takuntakun pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku lati gbogun ti iwa ọdaran ati ijinigbe lorile-ede yii

Ìwà tí ó lòdì sófín ni àwọn tó ń fipá mú àwọn èèyàn láti f’ìdí mọ́lé ń hù- Ààrẹ Tinubu.

Ìwà tí ó lòdì sófín ni àwọn tó ń fipá mú àwọn èèyàn láti f’ìdí mọ́lé ń hù- Ààrẹ Tinubu.

Gbọ́láhàn Quseem

Ààrẹ Nàiìjíríà, Bọ́lá Tinubu, ti sọ ọ di mímọ̀ pé ìwà tí kò bófin mu ni àwọn t’o fipá mú èèyàn kí wọn o f’ìdí mọ́lé nínú ẹgbẹ IPOB n wù
.
Aarẹ sọrọ yi ninu atẹjade to fi kẹdun iku awọn ṣọja marun-un to waye lasiko ti ẹgbẹ IPOB pete ikọlu ni Ila-Oorun orilẹ-ede yii.

Tẹ o ba gbagbe, awọn ṣọja naa n lọ pẹtu si aawọ niluu Aba, nipinlẹ Abia ni lọ́lọ́ yi ki wọn to bọ sọwọ IPOB, ẹgbẹ to n pe fun ominira ẹya Igbo.

Ẹgbẹ to lodi si ijọba Naijiria ni IPOB, o si n fipa mu awọn eeyan Ila-Oorun Naijiria lati ma jade lawọn asiko kan.

Iku awọn ṣọja marun-un yi waye lẹyin oṣu meji ti ologun mẹtadinlogun pade iku ojiji niluu Okuama, ipinlẹ Delta.

Eyi naa jẹ nigba ti wọn n lọ pẹtu si aawọ laarin ilu meji, ti awọn araalu kan si pa wọn.

Ààrẹ Tinubu ṣèlérí láti wọ sòkòtò kan pẹ̀lú àwọn èèyàn pa ṣọ́jà Nàíijíríà ní ‘pakúpa.

Gbọ́láhàn Quseem

Niínuú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Bọ́láTinubu lóti ṣèlérì láti wọ sòkòtó kan pẹ̀lú àwọn èèyàn ti àwọn ti wọ́n n pa àwọn sọ́ja orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ‘pakúpa

‘’ A.wọn ologun ati ọlọpaa lẹtọọ lati da aabo bo wa lọwọ ipayinkeke ati awọn to n da ilu laamu.

‘’Lẹnu iṣẹ wọn ni ọpọlọpọ wọn ti pade iku ojiji, bẹẹ ni awọn ti wọn n da aabo bo tun n foju ọpọlọpọ awọn ologun yi gbole.

‘’ Mo n pe awọn ẹṣọ alaabo gbogbo bayi lati mu awọn to lọwọ ninu ikọlu yi pẹlu awọn ti wọn n fipa mu awọn eeyan lati jokoo sile.

‘’Iwa ti wọn n hu yi ko lorukọ meji ju iditẹ mọ ilu ẹni lọ’’

Tinubu sọ pe agbara ijọba ka awọn amookunṣeka ti wọn n paayan yi, nitori ila ki i ga ju onire lọ.

Aarẹ ba ẹbi awọn ṣọja to padanu ẹmi wọn kẹdun, bẹẹ lo rọ awọn akẹgbẹ wọn yoku lati ma kaarẹ lẹnu iṣẹ wọn.

Ile-iṣẹ ologun paapaa ti koro oju si iku awọn ṣọja marun-un yi, wọn lawọn to ṣiṣẹ laabi naa ko ni i lọ lai jiya.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti Ìjọba fẹnukò lórí owó oṣù tuntun

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti Ìjọba fẹnukò lórí owó oṣù tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti fẹnuko lórí àwọn àdéhùn tuntun tó níí ṣe nípa owó oṣù tuntun fún àwọn òṣìṣẹ́.

Àdéhùn tuntun náà wáyé níbi ìpàdé tí àwọn aṣojú ìjọba, àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe nílùú Àbùjá lọjọ Ajé.

Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà, ní agbarijọ pọ̀ NLC, TUC, NUJ, àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke.

Àkójọ ìròyìn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bíi Ogun, Osun, Oyo, Ekiti, Kwara àti Ondo fihàn pé títí pa ni àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba, tó fi mọ́ àwọn báńkì wà.

Ṣaájú ni ìjíròrò láàrin ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò so èso rere. Ìjíròrò tó kẹhin wáyé lọjọ Àìkú tó kọjá, pẹ̀lú àwọn olórí ilé aṣòfin.

Ìgbà kẹrin nìyí tí ìjọba dáàbá owó oṣù tó lè san – àkọ́kọ́ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta Náírà tí wọ́n kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta Náírà tí wọ́n mẹnuba lọjọ Ìṣẹgun, nígbà tí ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta náírà jẹ́ ìgbà kẹta, kó tó tún wá kan ẹgbẹrun lọ́nà ọgọta náírà tí wọ́n kọ láti tẹwọgba.

Nípa ìpàdé tí wọ́n ṣe lọjọ Ajé, ilé iṣẹ́ agbohunsafẹfẹ tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀, NTA, sọ pé Ààrẹ Bola Tinubu, ti buwọ́lù owó oṣù tó ju ẹgbẹrun lọ́nà ọgọta Náírà.

Nítorí owó oṣù tuntun tí ààrẹ buwọ́lù, ọjoojumọ ni ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ yóó má a ṣe ìpàdé fún ọsẹ kan gbáko, láti fẹnukò lórí owó oṣù tí ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ yóò faramọ́.

Nínú Àdéhùn ti wọ́n, àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ gbà láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka wọ́n ní kíákíá, láti gbé èròngbà ìjọba wò.

Bákan náà ló tún jẹyọ níbi ìpàdé náà pé, òṣìṣẹ́ kankan kò ní fojú winá ìjìyà tàbí ìdúnkookò mọ́, nínú wọn pé wọn kópa nínú ìyanṣẹ́lódì.

Ó dójú ẹ̀! Ọjọ́ Ajé lẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ kọ̀yìnṣíṣẹ́ jákèjádò Orílẹ̀ yìí.

Ó dójú ẹ̀! Ọjọ́ Ajé lẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ kọ̀yìnṣíṣẹ́ jákèjádò Orílẹ̀ yìí.

Ọrẹ Òtítọ́jù

Níbi ọ̀rọ̀ dé báyìí,aráàlú ní tètè wọ́nà àbáyọ kí wọ́n lè máa rí nnkan jẹ, kọ́rọ̀ ó tó bẹ́yìn yọ torí bí ìhàlẹ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ orílẹ̀-èdè yìí, ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), àti àjọ ọlọ́jà orílẹ̀-èdè yìí ‘Trade Union Congress’ (TUC), sọ bá jẹ́ òtítọ́, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba àti ti aláàdáni yóò kọ̀yìn ṣíṣẹ́, olóko kò ní-ín lè roko, olódò kò ní-ín le rodò, gbogbo ẹsẹ̀ gìrì gìrì lọ́fíìsì àti ilé-èkọ́ yóò di gbígbé ti pa latari ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ tí wọ́n kéde pé àwọn yóó gùn lé jákè-jádò orílẹ̀èdè yìí. Ìyanṣẹ́lódì ọ̀hún máa bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀gànjọ́ òru ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kejì, oṣù Kẹfà, ọdún yìí.

Niṣe ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati ti olokoowo, TUC, Kọmureedi Joe Ajaero ati Festus Osifo, n tu bii ejo sebe tinu n bi lasiko ti wọn n sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin ipade pajawiri kan to waye laarin awọn aṣoju ijọba apapọ ati ti ẹgbẹ mejeeji naa.

Ajaero ni o ṣe pataki pupọ fawọn lati gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ, ti ko ni gbedeke ìgbà ti wọn yoo jáwọ ninu rẹ naa nitori bi ijọba orileede yii ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ owo-oṣu tuntun tawọn n beere lọwọ wọn, ati owo ina ẹlẹntiriiki tawọn ni kijọba da pada si bọ ṣe wa tẹlẹ.

Aarẹ ẹgbẹ naa waa rawọ ẹbẹ sawọn araalu gbogbo ti igbesẹ wọn maa ni ipalara gidi fun pe ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn, nitori pe ija gbogbo araalu lawọn n ja.

O ni, ‘Mo mọ daju pe igbesẹ ta a fẹẹ gbe yii maa ṣakoba nla fawọn araalu kan, mo n bẹ wọn ni, pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu wa, ija ilu la n ja bayii, o si daju pe aa so eeso rere nigbẹyin ni. O ṣe pataki pupọ fun wa lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ naa bayii, kawọn alaṣẹ ijọba apapọ orileede yii le mọ pe a ko fọrọ naa ṣere rara, wọn ko da wa lohun awọn ohun taa beere lọwọ wọn gbogbo, a n fẹ owo-oṣu tuntun lọwọ wọn, wọn ko da wa lohun, bẹẹ la n sọ pe ki wọn da owo ina pada si bo ṣe wa tẹlẹ, wọn ko da wa lohun’. Gẹgẹ bi wọn ṣe wí.

Sanusi àti Bayero lórí oyè Emir Kano, nígun nígun lọ̀rọ̀ bóóde

Sanusi àti Bayero lórí oyè Emir Kano, nígun nígun lọ̀rọ̀ bóóde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Eruku ọ̀rọ̀ ń sọ lálá, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ di inú fu àyà fu bí ọ̀rọ̀ oyè Emir ìlú Kano ṣe gba ọ̀nà míì yọ lọ́jọ́ Àbamẹ́ta.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Emir tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Muhammadu Sanusi II àti Emir tí wọ́n yọ nípò, Aminu Ado Bayero ṣe ń pe ara wọn ní ọba Kano.

Emir Sanusi II ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Kano, tó sì ti wà ní ààfin ìlú, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Emir tí ìjọba yọ nípò, Ado Bayero ti wà ní ààfin Nasarawa tó wà nínú ìlú Kano bákan náà.

Sanusi II tó wọ ààfin lórí ẹṣin pẹ̀lú họ̀bùrẹ́là lórí tó ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Emir Kano.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún, 2024 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Abba Yusuf buwọ́lu òfin àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ náà.

Òfin tuntun náà pa ìdásílẹ̀ àwọn igun lọ́balọ́ba márùn-ún ìyẹ Kano, Bichi, Rano, Karaye àti Gaya tí Ganduje dá sílẹ̀ nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.

Lẹ́yìn tó buwọ́lu òfin náà tán, gómìnà Yusuf kéde ìyànsípò Sanusi II padà gẹ́gẹ́ bí Emir Kano lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí Abdullahi Ganduje yọ́ nípò náà.

Ẹ̀wẹ̀, Bayero balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Aminu Kano International Airport ní nǹkan bíi aago mẹ́rin àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, tí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ sì lọ pàdé rẹ̀ tìlù tìfọn.

Nígbà tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń fèsì sí àṣẹ tí gómìnà Yusuf pa pé kí wọ́n fi kélé òfin gbé Emir Ado Bayero, wọ́n ní àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ní kí ìjọba má tù ú àwọn lọ́balọ́ba náà ká ni àwọn máa tẹ̀lé.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kano, Muhammad Hussain Gumel jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri dájú pé ẹnikẹ́ni kò tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀, tó sì àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò máa ri dájú pé ààbò tó péye wà káàkiri ìlú Kano.

Ó ní òfin láà kalẹ̀ kedere pé ẹnikẹ́ni tó b’fẹ́ da omi àláfíà ìlú rú ni kí àwọn fojú rẹ̀ winá òfin, tí àwọn kò sì ní wo bí ẹni náà bá ṣe gàǹgà tó.

Gumel ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó bá ń gbèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ lórí awuyewuye ìfaǹfà ọ̀rọ̀ oyè tó ń lọ ní ìlú náà pé kí wọ́n pa èrò náà rẹ́, kí wọ́n sì so agbéjẹ́ mọ́wọ́.

Ó ní ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ òfin bá bà pé ó da wáhàlá láàárín ìlú máa fi imú gbọ́ òórùn ara rẹ̀ àti pé gbogbo nǹkan ni àwọn ti ṣe láti ri pé àláfíà jọba ní ìlú náà.
Lẹ́yìn tí Emir tí wọ́n yọ nípò, Ado Bayero padà sí ìlú Kano ni àwọn kan ti ń fẹ̀sùn kàn pé olùbádámọ̀ràn ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò, Nuhu Ribadu ló ń ṣe àtìlẹyìn fún Bayero láti padà sí ìlú Kano.

Àmọ́ agbẹnusọ Ribadu, Zakari Mijinyawa ní irọ́ tò jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Mijinyawa tó sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja ń fèsì sí ẹ̀sùn tí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Aminu Gwarzo fi kan Ribadu pé òun ló ní kí Bayero padà sí ìlú Kano.

Ṣáájú ni Gwarzo ti fẹ̀sùn kan Ribadu pé ó ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi dúnkokò mọ́ àwọn èèyàn Kano, tó sì ní òfin tó de oè jíjẹ ní Kano jẹ́ èyí tó hàn gedegbe tí kò yẹ kí ará ìta dá sí rárá.

Agbẹnusọ Ribadu wá sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé Ribadu kọ́ ló pèsè ọkọ̀ òfurufú tí Bayero fi padà sí Kano

Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar ní Emir tí wọ́n yọ nípò ní Kano, Ado Bayero kò ní padà sí Kano tí kò bá jẹ́ pé ó rí àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní èròńgbà láti fi da omi àláfíà ìlú Kano rú kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà àti pé bí ìjọba ṣe da àwọn ọmọ ogun sí ìgboro Kano lórí ọ̀rọ̀ oyè jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin orílẹ̀ èdè.

Atiku ní ìgbésẹ̀ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kano láti mú àtúnṣe bá òfin tó de ọ̀rọ̀ oyè ní ìpínlẹ̀ náà, àti bí gómìnà ṣe dá Sanusi II padà bíi Emir jẹ́ àwọn nǹkan tó bá òfin mu.

Ó ní ó wá jẹ́ ohun fún òun pé Ado Bayero pẹ̀lú àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀ padà sí ààfin Nasarawa ìlú Kano nígbà tí Muhammadu Sanusi wà ní ààfin Gidan Dabo tó jẹ́ ojúlówó ààfinh gangan.

Ó ní ìjọba àpapọ̀ nílò láti rántí pé ìlú àláfíà ni Kano àti pé nígbà tí wọ́n yọ Sanusi lọ́sún 2020 kò sí wáhàlá kankan tó wáyé ní agbègbè náà, tí kò sì gbọdọ̀ sí wáhàlá kankan lásìkò yìí náà.

Bákan náà, ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party (NNPP) ti ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti dènà pé àwọn fẹ́ kéde pé ìlú kò fararọ lórí ọ̀rọ̀ oyè Emir Kano.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Ladipo Johnson fi léde lọ́ja Àbámẹ́ta ní ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi tẹ ìfẹ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.