Home Blog Page 7

Tinubu gbósùbà ràbàdẹ̀ fún Bisi Akande ní ẹni ọdún 87

Tinubu gbósùbà ràbàdẹ̀ fún Bisi Akande ní ẹni ọdún 87

Ìròyìn òwúrọ̀

Aarẹ orileede yii, Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu ti ki Oloye Bisi Akande ku oriire ọjọ ibi oni ni ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
O salaye Baba Akande gẹgẹ bi “oloootọ, akikanju ati ẹni to se e fọkan tan”.
“Bisi Akande fẹran orileede yii tọkan-tọkan ni eyi ti ko le jẹ ki ẹni kankan ninu awa oloselu foju pa wọn rẹ”.
Tinubu ni baba Akande ni olori ẹgbẹ APC to fẹyin PDP to n se ijọba lọwọ balẹ. “Ọpọlọ oselu Baba Akande sun mọ ti Oloogbe Obafemi Awolowo “.
Aarẹ salaye bi oloye Bisi Akande se bẹrẹ ni ile epo awọn Oyinbo gẹgẹ bi akọwe owo ki baba to bẹrẹ oselu. Baba ni akọwe agba ni isejọba oloselu ti ijọba ipinlẹ Oyo tẹlẹ ni ọdun 1979 ki wọn to di igbakeji gomina, ki wọn to wa di gomina ni ipinlẹ Osun ni ọdun 1999 titi di 2003.
Aarẹ ki baba pe mi wọn a se ọpọlọpọ ọdun pẹlu ẹmi gigun ati alaafia.

AFCON 2025 : Ìdí tí a ṣe pàdánù bọ́ọ̀lù sọ́wọ́ Morocco – Eric Chelle

AFCON 2025 : Ìdí tí a ṣe pàdánù bọ́ọ̀lù sọ́wọ́ Morocco – Eric Chelle

Yínká Àlàbí

Olori awọn akọnimọọgba fun ikọ super Eagles, Eric Chelle ti salaye idi ti awọn to ko lọ si orileede Morocco se padanu bọọlu naa sọwọ orileede ti ife ẹyẹ naa ti n waye.
Ana ọjọ wẹside ni ikọ Atlas Lion of Morocco gbo ewuro soju super Eagles nibi idije wọmi n gbaa ti a n pe ni pẹnariti, meji pere ni super Eagles le gba wọle nigba ti Atlas Lion gba mẹ́rin wọle.
Pẹnariti waye lẹyin ti ikọ mejeeji ti pa itu meje ti ọdẹ n pa ninu igbo fun ara wọn.
Chelle ni “akitiyan awọn agbabọọlu super Eagles ko da bii ti awọn idije maraarun ti wọn kọkọ gba, ni eyi to mu wọn bori pẹlu ayo mejila nile alatako. Loootọ ni ikọ mejeeji n sọra wọn lọwọ lẹsẹ sugbọn o ja mọ iko Morocco lọwọ. Eyi ni wọn n pe ni ere bọọlu. O le ja si ibi to ba wuu”. Alaye yii ni akọnimọọgba naa se f’oniroyin ni orileede Morocco.

Ọjọ́ tí fọ́ọ̀mù JAMB títà máa dópin àti ọjọ́ ìdánwò

Ọjọ́ tí fọ́ọ̀mù JAMB títà máa dópin àti ọjọ́ ìdánwò

Yínká Àlàbí

Ajọ JAMB to n se kokari idanwo asewọle si ile iwe Fasiti kaakiri orileede yii ti kede lori ẹ̀rọ ayelujara X wọn ni ana ọjọ isẹgun, eyi jẹ pẹlu asẹ ọga patapata ajọ naa, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede.
Ajọ naa ni fọọmu tita maa bẹrẹ si ni wa ni gbogbo ọfiisi awọn to n taa lati ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kin-in-ni ọdun yii (26/01/2026) titi di ọjọ kejidinlọgbọn osu keji ọdun yii (28/02/2026).
Awọn ọjọ idanwo si maa jẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹrin ọdun yii (17/04/2026) titi di ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹrin ọdun yii (25/04/2026).
Ajọ JAMB fi kun pe akẹkọọ to lẹtọọ si idanwo naa gbọdọ pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni ọgbọn ọjọ osu kẹsan-an ọdun yii (30/09/2026).
JAMB ni ọmọ ti ko ba ni pe iye ọdun naa gbọdọ jẹ ọmọ to mowe gan-an. Ọjọgbon Oloyede ni “o ni leta ti o maa ko si ajọ JAMB, o si gbọdọ gba maaki ida ọgọrin ninu ọgọrun-un (80%) gbogbo isẹ to ba se”.

Ìjà àgbà méjì

Ìjà àgbà méjì

Ìròyìn òwúrọ̀

Ero ayelujara ti fọn fọnran ibi ti Oba Adewolu Ladoja to jẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Oba Abimbola Akeem Owoade tii se Alaafin ti Oyo ti nawọ si Olubadan, sugbọn ti Olubadan kọ lati bọwọ.
Orisiirisii isọkusọ lo ti gba igboro kan. Awọn kan ni pẹlu iyatọ ọjọ ori awọn ọba yii, ko yẹ ki Alaafin kọkọ nawọ si Olubadan.
Awọn kan ni ko ye ki Alaafin si wa lori ijokoo maa ki Olubadan to wa lori iduro.
Awọn kan ni ọwọ naa le ma jẹ ọwọ lasan, wọn ni Olubadan ti le funra si ọwọ naa.
Awon kan ni Oba ni awọn mejeeji, o yẹ ki Olubadan gba ọwọ Alaafin.
Gbogbo ohun to wu ko jẹ, Olubadan kọ lati gba ọwọ Alaafin.

Akran ti Badagry wàjà ní ẹni ọdún 89

Akran ti Badagry wàjà ní ẹni ọdún 89

Yínká Àlàbí

Iku pa abiri, abiri ku. Iku pa abiri,abiri naa r’ọrun. Iku naa lo tun wọle ọla mu Oba Akran ti Badagry, Oba Wheno Aholu Menu-Toyi.
Ọba to jẹ ipe awọn baba nla wọn ni ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (90).
Ọba yii ni o fẹrẹ pẹ ju lori oye ninu awọn ọba ipinlẹ Eko. Wọn lo ọdun mẹrindinlaadọta (48) lori aleefa.
Ọba yii wo kaa ilẹ lẹyin aisan ranpẹ.
Gbogbo etutu to yẹ lo ti bẹrẹ nigba ti dokita ti jẹ ki awọn ẹbi mọ pe Ọba ti loọ darapọ mọ awọn baba nla wọn.

🌍 AFCON 2025 : Àwọn akọni ku mẹ́rin

*🌍 AFCON 2025 SEMI-FINAL*
Àwọn akọni ku mẹ́rin.
Egypt 🇪🇬 àti Senegal 🇸🇳
Nigeria 🇳🇬àti Morocco 🇲🇦

Super Eagles ti Nigeria ṣe ìbáwí ayò méjì sí òdo (2-0) fún Foxes ti Algeria

Super Eagles ti Nigeria ṣe ìbáwí ayò méjì sí òdo (2-0) fún Foxes ti Algeria

Yínká Àlàbí

Ikọ super Eagles ti Nigeria fagba han Akẹgbẹ wọn Foxes ti Algeria pẹlu ayo meji si odo.
Eyi maa gbe super Eagles wọ abala ẹsẹ Kan si asekagba (semi finals) pẹlu Morocco.
Eleyii maa lagbara diẹ nitori orileede Morocco ni idije naa ti n waye.
Ikọ Foxes Algeria yii ni super Eagles na ni ami ayo mẹta si odo ni ọdun 1980 lati gba ife ẹyẹ AFCON akọkọ. Lẹyin ọdun kẹwaa ni wọn wa gbẹsan lati gba ife ẹyẹ akọkọ tiwọn naa ni ọdun 1990.

Mo ti gba Jesu sáyé mi, mo ní ìyàwó kan, olorì mẹ́ta – Ọba Tejuoso

Mo ti gba Jesu sáyé mi, mo ní ìyàwó kan, olorì mẹ́ta – Ọba Tejuoso

Yínká Àlàbí

Ọba Adedapo Tejuoso to jẹ Osile ti Oke Ona ni ilẹ Egba ni wọn gba Mo Abudu lalejo ni aafin wọn.
Aafin ni Oba ti n salaye pe “mo ti gba Jesu sinu aye mi ni eyi to mu ki n di oniyawo kan, sugbọn mo ni olori mẹta, awọn mẹtẹẹta naa si ti gba Jesu sinu aye wọn, Jesu lo n ba wa gbe to si n tọ wa sọna”.
Kabiyesi jẹ ki o ye Mo Abudu pe ọrọ ọkan ati ẹmi ni alaye naa fi le ye eniyan. Ẹni ti gbogbo ara rẹ ba wa laye, ko le yee.
Mo Abudu lo da EbonyLife TV silẹ ni ọdun 2013.

ÀBÁJÁDE ERÉ BỌ́Ọ̀LÙ TÒNÍ

ÀBÁJÁDE ERÉ BỌ́Ọ̀LÙ TÒNÍ

*🌍 AFCON 2025*
Mali 🇲🇱 0 Senegal 🇸🇳 1

Cameroon 🇨🇲 0 Morocco 🇲🇦 2

Fásítì fòfin de ìwọ̀kuwọ̀ asọ àti irun

Fásítì fòfin de ìwọ̀kuwọ̀ asọ àti irun

Yínká Àlàbí

Babcock University ti fofin de gbogbo imura lodilodi to gba igboro kan.
Olaniyi Arije to jẹ igbakeji alakoso awon akẹkọọ ni ọgba Fasiti naa lo n salaye ni ọjọ wẹside ọsẹ yii.
O ni “ bẹrẹ lati osu yii ti iwọle ba ti ya, ko si aaye fun akẹkọọ kankan lati gbe irun arugbo wọle nigba to si wa lọdọọ, ko si aaye fun sokoto to gba ori eeyan, ko si aaye fun imura ode iyawo fun yara ikale, ko si aaye fun imura odo wiwẹ wa yara ikawe, ko si aaye fun asọ igbafẹ eti odo ni yara ikawe, ko si aaye fun ọkunrin lati mura bii obinrin, ko si aaye fun obinrin naa lati mura bii ọkunrin, ko si aaye fun orisiirisii nnkan tito mọ ori tabi ọwọ bii onisango lọ si yara ikawe. Akẹkọọ to ba lodi sofin yoo foju wina ofin ile-iwe naa “.
Ọgbẹni Arije ni ofin yii si gbọdọ mulẹ ni gbogbo ibi ti ile-iwe Babcock wa.