Home Blog Page 66

Ènìyàn kán kú, méjé farapa nínú ìkọlù agbéṣùnmọ̀mí ní Israel

Ènìyàn kán kú, méjé farapa nínú ìkọlù agbéṣùnmọ̀mí ní Israel

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí àwùjọ ṣe n jèkuru ọ̀ràn kó tán, bẹ́ẹ̀ lalákọrí àwọn agbésùnmọ̀mí tún n gbọnwọ́ ọ rẹ̀ sínú àwo táńganran.
Ènìyàn kan ti kú, àwọn méje míìràn sì farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù ìgbésùnmọ̀mí tó wáyé ní agbègbè etí omi ìgbafẹ́ ní ìlú Tel Aviv, ní ilẹ̀ Israel.

Ileeṣẹ pajawiri ni Israel ni arinrinajo lati ilẹ Italy wa si Israel lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si pe orukọ rẹ ni Alessandro Parini, ẹni ọdun mẹrindinlogoji.

Dokita to ṣaajo pajawiri ninu iṣẹlẹ naa ni mẹta ninu awọn to farapa naa jẹ arinrinajo lati Ilẹ Gẹẹsi.

Awọn aworan iṣẹlẹ naa ṣafihan ọkọ to ti dojubọlẹ, ti ọlọpaa ilẹ isrẹli si ṣina bolẹ.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa nibẹ ni wọn ti yinbọn pa ẹni to ṣekọlu naa ti wọn si pe orukọ rẹ ni Yousef Abu Jaber lati agbegbe Kafr Qasim to jẹ Arabu-Isreli.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni aago mẹsan kọja ni akoko ti ilẹ Isrẹli ni ọkunrin kan wa ọkọ Kia kọja ni bebe odo ti awọn eniyan ti n gbafẹ to si bẹrẹ si ni kọju wọn, ki ọkọ rẹ to doju bọlẹ.

Wọn ni bi o ṣe jade ninu ọkọ naa to dabi ẹni pe o fẹ mu ibọn ni ọlọpaa kan yinbọn pa.

Nibayii, Olootu Ijọba Ilẹ Italy, Giorgia Meloni ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa to si ba wọn kẹdun.

Agbẹjọro ni arakunrin ilẹ Italy, Parini to ku ninu iṣẹlẹ naa.

Ṣáájú ni wọ́n ti ṣekọlù sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó tún jẹ́ ara ilẹ̀ Isrẹli méjì pẹ̀lú ìyá wọn ní àgbègbè West Bank.

Buhari, Tinubu kọrin arò lẹ́yìn ikú ìyàwó Uzor Kalu

Buhari, Tinubu kọrin arò lẹ́yìn ikú ìyàwó Uzor Kalu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báakú là á dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bá Sẹ́nétọ̀ Orji Uzor Kalu kẹ́dùn lórí ìpapòdà ìyàwó rẹ̀, Ifeoma.

Ní orí Facebook ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Abia tí kéde pé ìyàwó òun jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Kalu nínú àtẹ̀jáde náà ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni àwọn yóò ti ṣe ìsìn ìdágbére ráńpẹ́ fún Ifeoma Ada Kalu.

“Pẹ̀lú ọkàn tó gbọgbẹ́ ni a fi kéde ikú Ifeoma Ada Kalu tó papòdà lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ sí afẹ́fẹ́ rere tó sì ń tọrọ àdúrà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn lórí àdánù ńlá yìí.

Ààrẹ Muhammadu Buhari nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ rẹ̀, Femi Adesina bá ẹbí Kalu àti Ifeoma kẹ́dùn.

Ààrẹ Buhari gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ Ifeoma sí afẹ́fẹ́ rere kó sì tu àwọn ẹbí tó fi síllẹ̀ nínú.

Bákan náà ni Ààrẹ tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu náà rọ Kalu láti má bara jẹ́ púpọ̀.

Tinubu ní Ifeoma gbé ìgbé ayé tó ṣe é wo àwòkóṣe nígbà tó wà láyé bí ó ṣe jẹ́ pé ó fi ìgbé ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run àti ọmọnìyàn ni.

Ọọ̀ni dá sí aáwọ̀ láàrín àwọn Mùsùlùmí àti Olórò

Ọọ̀ni dá sí aáwọ̀ láàrín àwọn Mùsùlùmí àti Olórò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èdè aiyede ṣì ń tẹsiwaju láàrin àwọn ẹlẹsin abalaye àti àwọn mùsùlùmí ní ilé ife pẹlú bí àwọn mùsùlùmí se ṣe ìkọlù sí ojúde or àwọn olórò.

Imaamu àgbà ti ilé ifẹ̀ Abdulsami Abdulhameed ti rọ àwọn ẹlẹsin méjèjì láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba.

Imamu náà ní olúkúlùkù ló ní òmìnira lábẹ́ òfin láti se ẹsìn tó wù u, ó sì rọ àwọn mùsùlùmí láti fọwọ wọnú kí àlàáfíà lè jọba.

Bákan náà, Abdulsamii pàrọwà fún àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ láti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọn tí wọn kò lóye tó, kí wọ́n sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ó ti máa hù wà láwùjọ.

Ẹ̀wẹ̀, Ọbalufe ti ilé Ifẹ̀ Ọba Idowu Adediwura tó jẹ́ aṣojú Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ ní, “Kábíyèsí Ọ̀ọ̀ni ilé Ifẹ̀ jẹ lórí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn tó wà nílé ifẹ ìyẹn ẹsìn Kristẹni, Mùsùlumí àti àwọn Oníṣẹ̀ṣe.

Ọbalufẹ pé fún àláfíà láàrin àwọn ẹlẹsin méjèjì tó ní aawọ, ó sì ní Kábíyèsí Oònirìṣà ṣetán láti tún gbogbo ohun tó bajẹ lásìkò ikọlu náà ṣe.

“Ẹ fọwọ́ wọnú! Báyìí ni Ọ̀ọ̀ni ṣe pàrọwà sí àwọn ọdọ Mùsùlùmí tó fariga nílé Ife, lẹ́yìn ti wọ́n lọ f’iná sójúde Orò

Aṣojú Ọ̀ọ̀ni ní àwọn ẹlẹ́sìn méjèèjì ti wà ní ìrẹ́pọ̀ tẹ́lẹ̀rí fún ìgbà pípẹ́.

Sanwo-Olu sèlérí àfikún owó osù l’Ékòó nígbà tí Umo Eno sèlérí otí mímu ní Akwa Ibom

Sanwo-Olu sèlérí àfikún owó osù l’Ékòó nígbà tí Umo Eno sèlérí otí mímu ní Akwa Ibom

 

Yínká Àlàbí

Nibi ipolongo ibo ni gomina ipinle Eko, alagba Babajide Sanwo-olu ti seleri fun awon osise ijoba ipinle Eko. O ni ti oun ba le wole eleekeji, oun maa mu ileri ti oun ati igbakeji oun, alagba Obafemi Hamzat se se.

Gomina ni ida ogun ninu ida ogorun-un owo onikaluku ni afikun naa yoo je. O ni owo naa yoo si bere ni sisan fun won lati osu keta odun ti a wa ninu re yii nigba ti oun maa san afikun osu kin-in-ni ati ikeji ni osu to n bo.

Bi ajo eleto idibo ti ipinle Eko se kede gomina Sanwo-Olu gege bi eni to ti jawe olubori ninu idibo ojo kejidinlogun, osu keta odun 2023 ni idunnu ti subu lu ayo fun awon osise ipinle Eko, ni eyi ti o ti mu ki onikaluku maa ti gege bo owo won ti won si ti n fi kun un ninu okan won.

Oro buruku tohun ti erin ni, bi awon osise ipinle Eko se n dunnu afikun yii ni ironu ba awon ara ipinle Akwa Ibom bi won se kede oludije du ipo gomina labe oselu PDP, alagba Umo Eno gege bi eni to jawe olubori nibi eto ibo naa.

Eyi si ti fa gbonmi sii omi ko too lori ero ayelujara, bi awon oloti se n dunnu ni awon kan n ko ilaali fun won pe ninu gbogbo nnkan amuyangan laye yii, oti wa ni oro won to si. Awon kan ni ilaji awon olugbe ipinle naa ni ko ni ise lowo nigba ti ebi ti fere lu awon kan pa. Won ni awon to n sise gan-an n sise bi Erin, won si n je ije Eleri ni gomina won wa seleri oti ni aago marun-un si mefa ni gbogbo ojo Eti.

 

 

Fásitì Tech-U pààrọ̀ orúkọ sí Abíọ́lá Ajímọ̀bi –Ṣèyí Mákindé

Fásitì Tech-U pààrọ̀ orúkọ sí Abíọ́lá Ajímọ̀bi –Ṣèyí Mákindé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà ní aríṣe la rí kà, àṣeélẹ̀ gàn-an sì làbọ̀ wá á bá.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , Ṣèyí Mákindé ti dá Gómìnà tẹlẹ tó doloogbe lọlá nípa yiyi orúkọ Fásitì padà sí orúkọ Abiola Ajimobi.

Fásitì ìmọ àwọn oniṣẹ ọwọ́ tí wọ́n pé orúkọ rẹ̀ ní Tech-u ni wọ́n yípadà sí orúkọ Abiola Ajimobi.

Makinde lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akẹkọjade sọrọ ni ibi ayẹyẹ ikẹkọjade ti ẹlẹẹkeji ni fasiti naa.

Gomina ọhun ni gbogbo nnkan ni asiko wa fun asiko lati lawari nnkan, asiko lati wo ohun to padanu.
Bakan naa lo ṣalaye wi pe gbogbo ẹda lo n gbimọ lati mu imọ rere rẹ ṣẹ lagbaye.

O fikun un pe ẹẹmẹta ni oun dije dupo gẹgẹ bi gomina ti oun si fidi rẹmi, amọ ẹlẹkẹrin ni oun jawe olubori.

Gomina Makinde tun ṣalaye fun awọn olugbọ rẹ igbesẹ to gbe lati ri iṣẹ ni ileeṣẹ iwa epo Shell Oil company, lati bi oun ṣe lakaka lati di ipo gomina mu ni ipinlẹ Ọyọ

Gómìnà náà wá rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti fojú sí ìwé wọn kí wọ́n sì tún gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tó ń gbani sí iṣẹ́, kí wọ́n yé é wá iṣẹ́ kiri.

Gbogbo iṣẹ́ Arẹgbẹṣọla tí Oyetọla pa tì ni mo máa ṣe – Adeleke

Gbogbo iṣẹ́ Arẹgbẹṣọla tí Oyetọla pa tì ni mo máa ṣe – Adeleke

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣu6n, Sẹ́nátọ̀ Ademọla Adeleke, ti sọ pé gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe tíjọba Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹṣọla dáwọ lé, èyí tó sì yẹ kí ìjọba Alhaji Gboyega Oyetọla parí, ṣùgbọ́n tí kò ṣe, lòun yóò ṣe láṣeyọrí.

O ni lara awọn nnkan ti oun ṣeleri fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo oun ni pe oun ko ni i pa iṣẹ kankan ti, oun si ti bẹrẹ igbesẹ lori awọn iṣẹ naa.

Nibi eto siṣi ọfiisi iwe irinna, pasipọọtu, eyi tileeṣẹ ọrọ abẹle lorileede yii, labẹ Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla, kọ siluu Ileṣa, to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Adeleke ti sọ pe bi awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ṣe fẹran Arẹgbẹṣọla nigba to jẹ gomina naa ni wọn ṣe fẹran oun naa bayii.

O ni, “Ẹgbẹ oṣelu yoowu ti o ba wa, ti o ba ti ri nnkan itẹsiwaju, o gbọdọ tẹsiwaju ninu ẹ. Ẹni ti awọn araalu feran ni Arẹgbẹṣọla, mo maa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ rere to ṣe silẹ l’Ọṣun”.

Gomina Adeleke waa fi da Arẹgbẹṣọla loju pe ipinlẹ rẹ ni ipinlẹ Ọṣun, ko si si ẹnikankan to le le e nibẹ. O ni oun yoo ko lọ sinu ile ijọba laipẹ, iyẹn ti oun ba ti ṣe awọn atunṣe ibẹ tan, koda, Arẹgbẹṣọla ni yoo ṣi ile naa fun oun.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla dupẹ lọwọ Gomina Adeleke fun apọnle to fun un nipa kiko gbogbo awọn abẹṣinkawọ rẹ wa sibi eto naa niluu Ileṣa, lai sẹ pe awọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa.

O ṣalaye pe ọfiisi naa wa lati ran awọn ọfiisi ti wọn ti n ṣeto iwe irinna to wa kaakiri lọwọ ni, o ni wọn yoo maa ya fọto nibẹ, wọn yoo si maa gba akọsilẹ awọn to ba nilo iwe irinna silẹ nibẹ lati mu ki igbesẹ naa tubọ ya kiakia si i.

Arẹgbẹṣọla rọ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ iwọle-wọde àwọn àjèjì láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, láti lè fòpin sí ìwọlé wọde àwọn àjèjì latawọn orílẹ-èdè míràn wá sínú ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Ohun tá a mọ̀ nípa ìyá ọlọ́mọ kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé ìjọsìn Ondo rèé

Ohun tá a mọ̀ nípa ìyá ọlọ́mọ kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé ìjọsìn Ondo rèé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí òpin aye bá ti ń kànkùn gbọ̀n gbọ̀n gbọ̀n,onírúurú la ó má a gbọ́ sétí,èyí ló bí ìròyìn bí Pásítọ̀ ìjọ Oke-Irapada ní ìlú Alade, ìjọba ìbílẹ̀ Idanre, ìpínlẹ̀ Ondo, Kayode Salami bó ti ṣe kó sí gbagà ọlọ́pàá fẹ́sùn ìfipábánilòpọ̀ àti pípa arábìnrin kan.

Salami, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ti wà ní àháma àwọn ọlọ́pàá báyìí látàrí bí wọ́n ṣe bá òkú arábìnrin kan, Adejoke Oloje ní ilé ìjọsìn rẹ̀.

Olóògbé Adejoke Oloje ni ìròyìn ní ó kó lọ sí ilé ìjọsìn náà láti máa gbé láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kìíní ọdún yìí pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, ọmọ oṣù mọ́kànlá lọ́wọ́.

Adejoke àti àbúrò rẹ̀ kan, Aderonke ni wọ́n ní wọ́n jọ kọ́kọ́ lọ sí ilé ìjọsìn náà fún ìjọ́sìn kí Adejoke tó padà lọ sílé ìjọsìn láti máa lọ gbé.

Nígbà tí ìyá Adejoke tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Deborah ní ọmọ òun, Adejoke wá ṣe ìbẹ̀wò sí òun ní ìlú Idanre ni àmọ́ tó ṣàdédé kó ẹrù rẹ̀ jáde kúrò nílé ní ọ̀sán kan òru kan láìmọ̀ ibi tó lọ.

Ó ní nígbà tí òun ṣe ìwádìí ni òun ṣe àwárí rẹ̀ pé ilé ìjọsìn náà ní ọmọ òun wà àmọ́ nígbà tí òun débẹ̀ ọmọ òun kọ̀ láti tẹ̀lé òun padà sílé.

“Mo pè é ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti mọ ibi tó wà ṣùgbọ́n kò gbé ago rẹ̀ àmọ́ ènìyàn kan sọ fún mi ní ọjọ́ kan pé àwọn ri ní Alade pẹ̀lú Aderonke.”

“Nígbà tí mo pe Aderonke ló sọ fún mi pé ilé ìjọsìn ni Adejoke wà kìí ṣe ọ̀dọ̀ òun.”

“Mo lọ sí ilé ìjọsìn náà láti wa lọ àmọ́ nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó ṣàlàyé pé òun kò ní oúnjẹ nílé mo sì ṣèlèrí láti bá gbé oúnjẹ wá ní ọjọ́ kejì.”

“Mo bẹ́ẹ̀ pé kó kúrò ní ilé ìjọsìn náà ṣùgbọ́n ó kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní tẹ̀lé mi.”

Deborah ní nígbà tí òun máa dé ilé ìjọsìn náà ní ọjọ́ kejì ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí òun ṣe ṣèlérí, òun kàn ń gbọ́ igbe ọmọọmọ òun ni tó ń sunkún rara.

Ó fi kun pé bí òun ṣe súnmọ́ ibẹ̀ láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní òun ri pé ilẹ̀kùn wà ní títì pa, tí òun sì fagbára já ìlẹ̀kùn náà àmọ́ ìyàlẹ́nu lọ jẹ́ fún òun láti rí ọmọ òun nílẹ̀ gbalaja.

“Mo bá ọmọ mi nílẹ̀ tí wọ́n bọ́ pátá nídìí rẹ̀ àmọ́ wọn ò bọ́ pátá náà tán, wọ́n bọ dé ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ tí mo sì ké gbàjarè fún ìrànlọ́wọ́.”

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà tí àwọn dé ilé ìwòsàn, àwọn dókítà sọ fún òun pé ọmọ òun ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí òun sì gba àgọ́ ọlọ́pàá Idanre lọ láti lọ fẹjọ́ sùn.

“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá Idanre nawọ́ gán pásítọ̀ náà, mo sì ṣe àkíyèsí pé ṣòkòtò pásítọ̀ náà ya lábẹ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gan.”

“Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún ìdílé wa nítorí ó ní ọmọ oṣù mọ́kànlá lọ́wọ́ kí ikú òjijì yìí tó dé, ẹni tó bá ṣiṣẹ́ ibi yìí gbọ́dọ̀ fojú winá òfin.”

Nígbà tó ń sọ tẹnu rẹ̀, Pásítọ̀ Salami ní òun kò mọ nǹkankan nípa ikú Adejoke àti pé nípasẹ̀ Aderonke ni òun fi mọ̀ ọ́n.

Pásítọ̀ Salami lẹ́yìn ọjọ́ kejì tí wọ́n wá sílé ìjọsìn òun ni Adejoke padà wá bá òun pé òun fẹ́ máa gbé ní ilé ìjọsìn náà títí tí òun fi máa rí ibi tí òun máa gbé.

Ó ní òun gbà láti fun-un ní ọkàn nínú àwọn yàrá méjì tó wà nínú ilé ìjọsìn àmọ́ òun kò bèèrè nǹkan tó wáyé láàárín òun Aderonke tó fi fẹ́ máa wá gbé ilé ìjọsìn.

“Ilẹ̀kùn àbáwọlé kan ló wọ yàrá èmi àti yàrá tó ń lò nítorí náà mo máa ń ri tí mo bá ń jáde tàbí wọlé.”

Ó fi kun pé òun àti Adejoke jọ ṣe ìṣọ́ òru ní ó ku ọ̀la tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí òun àti ẹ̀ sì tún ríra kí òun tó máa lọ sí ibi iṣẹ́ wẹ́dà tí òun ń ṣe.

“Ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ló wá síbi iṣẹ́ mi láti wá gba iná sí fóònù rẹ̀, tó sì kúrò ní nǹkan bíi aago mẹ́rìn ìrọ̀lẹ́.”

Pásítọ̀ Salami ní tí òun bá ní nǹkan ṣe ni òun máa ń lo yàrá tó wà ní ilé ìjọsìn náà nítorí òun àti àwọn ẹbí òun ní ibi tí àwọn ń gbé nítorí náà òun kò mọ nǹkankan nípa ikú ọmọbìnrin náà.

“Mi ò fipá ba lòpọ̀, mi ò mọ nǹkankan nípa ikú rẹ̀.”

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá Ondo, Funmilayo Odunlami ní ẹjọ́ náà ti wà ní ìlú Akure fún ìwádìí tó péye.

Bánkì àgbà Nàìjíríà taari owó yanturu sáwọn ilé ìfowópamọ́, pawọ́n láṣẹ iṣẹ́ òpin ọ̀sẹ̀

Bánkì àgbà Nàìjíríà taari owó yanturu sáwọn ilé ìfowópamọ́, pawọ́n láṣẹ iṣẹ́ òpin ọ̀sẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bánkì àgbà ilẹ̀ yìí ti gbà sílé ẹjọ́ lẹ́nu pé kí wọ́n má a ná owó Orílẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ àti tuntun di Oṣù kejìlá ọdún yìí, síbẹ̀, igbe kò sí káàsì náà ló sì lógboro pá títí di àsìkò yìí tí àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí sì n kérora lórí owó o wọn to
hà, ṣùgbọ́nlé níbáyìí, ilé ìfowópamọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà, CBN ti kéde pé àwọn ti fi ọ̀pọ̀ owó yanturu ránṣẹ́ sí àwọn ilé ìfowópamọ́ káàkiri orílẹ̀ èdè láti le ko jáde fún àwọn ènìyàn.

CBN ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti le mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú láti rí owó ná.

Bákan náà ni wọ́n tún darí àwọn ilé ìfowópamọ́ náà láti máa ṣiṣẹ́ ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, ìyẹn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta àti ọjọ́ Àìkú títí tí gbogbo àwọn ìṣòro àìsí owó níta yìí máa fi kásẹ̀ nílẹ̀.

Adarí ẹ̀ka ìbánisọ̀rọ̀ CBN, Dókítà Isa Abdulmumin tó fi ìkéde náà léde ní Abuja lọ́jọ́ Ẹtì ní ọ̀bítíbitì owó ni CBN ti fi ṣọwọ́ sí àwọn ilé ìfowópamọ́ láti pín fún àwọn oníbàárà wọn.

Abdulmumin fi kún un pé CBN tún ti pàṣẹ fún àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti kó owó sínú akoto ATM gbogbo, kí àwọn ènìyàn le máa rí owó gbà jáde nínú rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé gómìnà CBN, Godwin Emefiele máa ríi dájú pé àwọn ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti mọ bóyá wọ́n tẹ̀lé àṣẹ yìí àti pé Emefiele fúnra rẹ̀ ni yóò ṣaájú ikọ̀ tí yóó máa ṣe àbẹ̀wò yìí.

Ó tún pàrọwà sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti túbọ̀ lékún nínú sùúrù wọn àti pé gbogbo ìṣòro àti ìpèníjà tí wọ́n ń là kọjá lórí ọ̀rọ̀ owó Náírà yìí ni yóó di ohun ìgbàgbé láìpẹ́.

Ẹ ó rántí pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti ṣaájú kéde pé àwọn yóó ṣe ìwọ́de lọ sí gbogbo ẹ̀ka ilé ìfowópamọ́ CBN tí CBN bá kọ̀ láti wá ojútùú sí ìṣòro ọ̀wọ́n gógó owó náírà.

Àparò kan ò jùkan lọ níjọba a mi- Mákindé

Àparò kan ò jùkan lọ níjọba a mi- Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjinnia Ṣèyí Mákindé, ti fi àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé wíwọlé tí òun wọlé ìdìbò fún sáà kejì nípò Gómìnà yìí yóó ṣi ọ̀nà àṣeyọrí fún wọn.

Níbi àríyá tí wọ́n ṣe láti ṣàjọyọ̀ bí Gómìnà Mákindé ṣe wọlé ìdìbò fún sáà kejì ló ti sọ̀rọ̀ náà níléègbafẹ́ Ìlàjì Hotel and Resort, tó wà ládùgbóò Àkánrán, n’Íbàdàn, lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “Àparò
kan kò ga ju ọ̀kan lọ mọ́ níìpínlẹ̀ Òyọ́ lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn àparò tí wọ́n gorí ebè láti fi han gbogbo ayé pé àwọn ga ju ará yòókù lọ, èmi Ṣèyí Mákindé ti fi òkò nlá lé wọn kúrò lórí ebè, bákan náà ni gbogbo wá rí báyìí.

Ó kan sáárá sí Olùdásílẹ̀ iléègbafẹ́ náà, Ẹnjinnia Dọ̀tun Sanusi, fún ipa tó kó nínú ìdìbò tó gbé e wọlé. Bẹ́ẹ̀ ló dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìnjẹ̀sìn gbogbo fún àtìlẹ́yìn tí wọ́n ṣe fún un lásìkò ìdìbò náà láì fi ti ẹsìn ṣe.

Bákan náà ló fi àwọn èèyàn ti kò dìbò fún un lọ́kàn balẹ̀ pé òun kò ní ín ránró, kódà òun ti ṣetán láti gbà wọ́n mọ́ra nínú ìṣèjọba òun.

Lára àwọn tó péjú síbi ayẹyẹ ọhún ni adarí ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù (CAN), àwọn Mùsùlùmí, ẹgbẹ́ àwọn òǹtàjà, ẹlẹ́ṣin ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààwẹ̀ Ramadan ọdún 2023 dé, bẹ́ẹ̀ kúkú kẹ̀kẹ̀ rẹ̀ sì ti gbòde bí ọ ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú osù kẹta òǹkà ti òyìnbó yìí.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣọ yíyọ oṣù ààwẹ̀ Ramadan ní Nàìjíríà, kéde pé àwọn ti rí oṣù láwọn ìpínlẹ̀ kan.

Gbogbo wà la mọ̀ pé ọgbọ̀n, tàbí ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ọjọ́ gbáko ni ààwẹ Ramdan fi má ń wáyé, èyí tó mú kí ètò jíjẹ àti mímu jẹ́ pàtàkì nínú oṣù náà.

Kìí kàn án ṣe oúnjẹ lásán, ó sẹ kókó láti jẹ oúnjẹ àti mu omi lọ́nà tó yẹ, tó sì bá àgọ́ ara mu, kí okun lè wà fún ààwẹ gbígbà.
Oríṣìí oúnjẹ méjì ni jíjẹ lásìkò ààwẹ Ramadan, lójoojúmọ́.

Àwọn oúnjẹ náà ni wọ́n ń pè ní Suhoor (Yorùbá ń pè é ní Sààrì), àti Iftar (Ìṣínu) ní ìrọ̀lẹ́. Oúnjẹ fún Suhoor gbọdọ̀ jẹ́ èyí tó lè fún ọ ní okun láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́ tí ìṣínu yóó wáyé.

Àwọn nǹkan tó lè mú kí èèyàn já ààwẹ rẹ̀
Lásìkò àwẹ Ramadan, dandan ni fún àwọn Mùsùlùmí láti yago fún jíjẹ àti mímu, tó fi mọ́ àwọn nǹkan fàájì láti àárọ̀ di ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n ṣá, èèyàn lè já ààwẹ rẹ̀ nítorí àwọn ìdí kan.

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nínú Kùràánì, àwọn tó bá ní àìsàn tó sì nílò kí wọ́n ó lo òògùn, àwọn arúgbó, àwọn tó wà lẹ́nu ìrìnàjò, aláboyún, obìnrin tó ń fún ọmọ ní ọyàn, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé tí kò tíì bàlágà, lè yàn láti má gba àwẹ – papàá tó bá lè ní ipa tí kò dára lórí ìlera wọn.

Bákan náà obìnrin lè já ààwẹ rẹ̀ tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ lààrin àsìkò tó ń gbààwẹ̀

Àwọ n tí ọrọ̀ kan sì lè padà gba àwọn ọjọ́ ààwẹ tí wọ́n pàdánù lọ́jọ́ iwájú.

Ìlànà tí àwọn Mùsùlùmí ń gbà ṣínu yàtọ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan
Ní àwọn ibì kan, àṣà wọn ni láti ṣínu ní ilé olórí ẹbí wọn, tàbí ẹni tó dàgbà jù nínú ẹbí.

Oúnjẹ ní wọ́n ní àwọn kan fi má a ń ṣínu. Ṣùgbọ́n, ní àwọn orílẹ̀-èdè bí i UAE, oúnjẹ onípele mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi ń ṣínu.

Oṣù Ramadan gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí oṣù ọlọ́rẹ
Lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí ló má a ń ṣe iṣẹ́ àánú àti ìtanilọ́rẹ bí i fífún àwọn tí kò ní, ní oúnjẹ àti owó.

Ìgbésẹ̀ yìí, Zakat, jẹ́ ọ̀kan lára òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam dúró.

Ọdún ìtúnu ààwẹ, Eid, ló má a ń gbẹ̀yìn Ramadan
Eid al-Fitr, tó túmọ̀ sí ìtúnu ààwẹ, tàbí àsè ìṣínu ààwẹ, má a ń wáyé fún ọjọ́ mẹ́ta tó kẹ́hìn ààwẹ Ramadan.

Ní kété tí wọ́n bá ti rí oṣù tuntun lójú ọ̀run ni ìtúnu ààwẹ má a ń bẹ̀rẹ̀.

Èyí tó mú kí ọjọ́ ìtúnu yàtọ̀ láti orílẹ-èdè kan, sí orílẹ-èdè míìràn ní àgbáyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ju ọjọ́ kan sí méjì tó má a ń wà láàrin wọn.

Ǹ jẹ́ ní báyìí tí àwọn Mùsùlùmí jákèjádò Orílẹ̀ yìí ti wà ní ìkáraró, ó wá yẹ kí à ṣàmúlò ẹ̀kọ́ inú oṣù ààwẹ̀ ọ̀hún, láti fọ tọkàntara wa mọ́ kangá kúò níbi àwọn ìwà burúkú tó lè tapo sí àṣọ àlà a wa gẹ́gẹ̀ bí i ẹlẹ́sìn mùsùlùmí.
Ó yẹ kí á gbìyànjú nawọ́ ìfẹ́ sí àwọn èèyàn ju tàtẹ̀yìnwá lọ ,yálà ni àyíká a wa tàbí ní àwọn agbègbè mìíràn tí a bá ti gbọ́ pé wọ́n nílò ìrànwọ́,kí à sì sà fún ṣekárími, kí láádá a wa lè kún kẹ́kẹ́.
Kí Ọlọ́run Ọba Àlekèọlá gbàá lẹ́sìn lọ́wọ́ ọ wa.