Home Blog Page 65

Àgbàrá òjò pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀pọ̀ ènìyàn di àwátì l’Ógùn

Àgbàrá òjò pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀pọ̀ ènìyàn di àwátì l’Ógùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní lọ́jọ́ tí ẹ̀dá yóó
bá sọnù, gá gá lara á yáwọn.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàm̀bá omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ni agbègbè kan ní ìlú Sagamu, ìpínlẹ̀ Ogun.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún di àwátì lásìkò tí ẹ̀kúnwọ́ omi ṣọṣẹ́ ní àwọn agbègbè bíi Ajaka, Express Junction, Ogunyanwo, Ọlayinka àti Isale-Ojumele ní ìlú Sagamu lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ọmọ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ girama Agbele gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní orí ọ̀kadà tí ọmọ ọ̀hún wà ni ẹ̀kúnwọ́ omi ti wọ lọ.

Bákan náà ni ìròyìn tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ dúkìá ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ló tún sọnù sínú ìjàm̀bá náà ní agbègbè Makun tí ọ̀pọ̀ ará ìlú sì farapa.

Àwọn ará àdúgbò náà kọminú pé bí nǹkan ìní àwọn ṣe máa ń bàjẹ́ ní gbogbo àsìkò òjò nìyí nítorí kò sí kòtò ìdaminù tó já gaara ní agbègbè náà.

Lára àwọn ará àdúgbò náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé lọ́dún to kọjá tí àwọn sì ké gbàjarè lọ sọ́dọ̀ ìjọba.

Wọ́n ní àìsí ibi tí omi máa gbà kọjá ló ń fà á tí omi fi ń ya wọ ilé àwọn tí àwọn sì rò pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún to kọjá máa mú kí ìjọba tètè dìde sọ́rọ̀ àwọn.

Wọ́n ní ó ṣeni láàánú pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lórí ìjàm̀bá yìí kan náà.

Kọmíṣọ́nà fún ètò àyíká ìpínlẹ̀ Ogun, Ọla Ọrẹsanya nígbà tó ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìwé ìlànà bí àwọn ṣe ń kọ́ ilé ti pọn dandan báyìí.

Ọrẹsanya ké sí ìjọba àpapọ̀ láti ran ìpínlẹ̀ Ogun lọ́wọ́ lórí àjálù ọ̀hún.

Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun náà yóò gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ nípa kíkọ́ kòtò ìdaminù sí agbègbè náà láìpẹ́.

A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó lójijì – LASEMA

A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó lójijì – LASEMA

Fẹ́mi Akínṣọlá

À fi kí Ọlọ́run ṣá à má a pawá mọ́ nínú ewu gbogbo.
Kò dín ní ènìyàn méje tí wọ́n móríbọ́ nínú ilé tó dà wó lulẹ̀ lọ́jọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.

Ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣàdédé dà wó lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.

Ìròyìn ní pé àwọn òṣìṣẹ́ kan mórí bọ́ láì farapa, tí àwọn mìíràn sì farapa kékeré, tí àwọn mìíràn sì tún há sábẹ́ ilé náà.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA ní àwọn ṣì ń wá ènìyàn kan tó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ó há sábẹ́ ilé náà.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní orí àjà kẹfà ilé náà ní àwọn ṣiṣẹ́ dé láti gbé àjà keje le lórí kí ilé náà tó dà wó lulẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde ní ìwádìí fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó ń po sìmẹ́ǹtì ló ṣokùnfà bí ilé náà ṣe dàwó.

Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé náà, Anthony Onah ka àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó ku òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń wá tó sì ṣeéṣe kó ṣì wà lábẹ́ ilé ọ̀hún.

Ó ní iṣẹ́ ń lọ láti ṣàwárí ọkùnrin náà, àti pé gbogbo àwọn ohun èlò tí àwọn nílò láti fi ṣiṣẹ́ ló ti wà níbẹ̀.

Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní ènìyàn méje ni àwọn ti yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa.

Adeseye ní ènìyàn kan ló ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí iṣẹ́ kò sì dúró láti yọ ẹni ọ̀hún.

Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù yíyọ, lásìkò yìí kọ́’

‘Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù yíyọ, lásìkò yìí kọ́’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣéwọ́n ní èèyàn tó wẹjú lẹ̀rùn ń bà.
Àgbà agbẹjọ́rò kan, Itse Sagay ti ké sí Ààrẹ tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu láti jọ̀ ọ́ jàre láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ ètò ààbò tó ti mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè yìí.

Sagay tún rọ Tinubu láti má ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tó bá dórí àléfà nítorí ìpalára tó ma kó bá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba tó wà lóde ti ṣáájú sọ pé nínú oṣù kẹfà ọdún yìí ni àwọn yóò fi òpin sí ṣíṣe ìrànwọ́ epo bẹntiróòlù, alága ìgbìmọ̀ olùbádámọ̀ràn Ààrẹ lórí ìwà àjẹbánu náà ní òun gbàgbọ́ pé ó yẹ kí ìjọba tó ń bọ̀ ṣe ìdádúró ìgbésẹ̀ náà ná.

Ó ṣàlàyé pé nǹkan tí òun lérò pé ó yẹ kí Ààrẹ tuntun gbájúmọ́ tí wọ́n bá ti búra wọlé fún un tán ni láti mójútó ni ètò ààbò.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ètò kan ní Channels TV pé tí ètò ààbò bá ti dúró bó ṣe yẹ, oúnjẹ máa pọ̀ yanturu nítorí àwọn àgbẹ̀ máa lè dáko bó ṣe wù wọ́n láìsí ìbẹ̀rù.

Sagay ní lẹ́yìn èyí ni ó kan ṣíṣe àmójútó ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti pé yíyọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù lásìkò yìí kò ní so èso rere kan fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà.

“Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ fún Tinubu pé kó yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù kàn fẹ́ ba ìṣèjọba rẹ̀ jẹ́ ni.”

Ó ní ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú títí ìjọba ma fi wá nǹkan ṣe sí àwọn ilé ìfọpo rọ̀bì Nàìjíríà.

“Tí àwọn ilé ìfọpo yìí bá ti ń ṣiṣẹ́ owó epo máa já wálẹ̀ dáadáa, ìjọba le wá ronú láti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nígbà náà.”

Lẹ́yìn Ọlọ́run,Ìjọba ló tún kàn—Portable

Lẹ́yìn Ọlọ́run,Ìjọba ló tún kàn—Portable

ỌrẹÒtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní ẹni ojú rẹ̀ kò bá rọ́ràn rí, ẹ jẹ́ ó wáá wí.
Òwe àwọn àgbà ni pé ‘a kì í ti ilé ẹjọ́ bọ̀ káṣọrẹ’, ṣùgbọ́n kò hàn pé òwe yìí ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọ ọkan nínú àwọn olorin hiphop tó gbajúmọ̀ dáadáa nnì, Habib Okikiọla Ọlalọmi, tó kọrin Zah zuh zeh, nítorí àtìmọ́lé ọlọ́pàá tó lọ, tí wọ́n sì tún tibẹ̀ gbé e lọ sí kóòtù ti sọ ọ dọrẹ àwọn agbófinró báyìí. Níṣe ló ń kí wọn ní mẹsan-an mẹwàá, bẹ́ẹ̀ ló sì gbé orin kan jáde nítorí tiwọn. Nínú orin náà ló ti fi hàn pé òun kò ní i ṣejangbọn mọ́, àti pé ẹnikẹni tó bá tọ òun báyìí, tàbí tó bá sọrọ òun lẹyìn, ọlọ́pàá lòun máa fẹjọ rẹ̀ sùn. Bẹ́ẹ̀ ló tún ní lẹyìn Ọlọ́run, ìjọba ló kàn o.

Gbara ti wọn tu u silẹ latimọle lẹyin ti wọn gbe e elọ sile-ẹjọ ni ọmọkunrin olorin to saaba maa n pariwo ‘wahala, wahala’ yii gbe awo orin kekere naa jade, nibi to ti ki awọn ọlọpaa daadaa, o ni oun ti dọmọ ijọba, bukaata ijọba apapọ loun bayii.

Bakan naa lo forin naa sọ fun awọn ọta to n wa iṣubu rẹ pe ki wọn jawọ lọrọ oun, o ni oun ki i ṣe ẹlẹwọn, nitori pe oun ko wọṣọ ẹwọn, ati pe ẹnikẹni to ba ti ṣẹ oun bayii, oun yoo fi ẹjọ rẹ sun ọlọpaa ni.

Ninu ọrọ orin naa ni Portable ti kọ ọ bayii pe, ‘’Ọmọ ologo glorious, ọmọ ologo to logo tuntun batyii, Lati irawọ, si ẹyẹ Idì, ẹ waa wo oore-ọfẹ ti ki i doju ti ni. Emi ọmọ Ọlalọmi ti wọn n pe ni Portable.

‘‘Wọn gbe mi lọ si ọgba ẹwọn, mi o gbaṣọ, wọn waa doju sọ mi

Ẹ jawọ lọrọ mi o, mi o ki i ṣe ẹlẹwọn.

Wọn gbe mi lọ sọgba ẹwọn, mi o gbasọ, wọn waa lọọ doju sọ mi, ẹ jawọ lọrọ mi o, mi o ki i ṣe ẹlẹwọn.

Sọrọ mi lẹyin ki n pe ọlọpaa

Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa

Lẹyin Ọlọrun ijọba lo ku

Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa

Emi bukaata ijọba

Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa

Wahala ti pọ ju lọrun mi

Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa’’.

Bayii ni Portable kọ orin naa, eyi to ti gba ori ayelujara kan, tawọn eeyan si n gbọ ọ daadaa.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, iyẹn lọjọ Aje, ni wọn wọ oṣere naa lọ sile-ẹjọ kan ni ilu Ifọ.

Awon ọlọpaa ni wọn mu-un lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ti wọn sọ ọ satimọle. Latibẹ ni wọn ti gbe e lọ sile-ẹjọ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o kọ lati da awọn ọlọpaa loun nigba ti wọn pe e. Wọn tun ni o di awọn ọlọpaa lọwọ ninu iṣẹ iwadii wọn pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ mu un ti ko gba. Bakan naa ni wọn ni o sakọlu si ọlọpaa kan, to si ṣe e leṣe.

Lara ẹṣun mi-in ti wọn fi kan an ni pe o lu alaamulegbe rẹ.

Ṣugbọn lẹyin ti adajọ kootu ọhun gbọ ẹjọ naa, wọn gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira.

Ó jọ pé ìrírí rẹ látìmọ́lé náà ló sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ àwọn ọlọ́pàá, tó sì sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá ti tọ òun báyìí, òun máa lọ fẹjọ́ rẹ̀ sun ọlọ́pàá .

Ẹ yanjú ẹjọ́ tó ṣú yọ lẹ́yìn ìdìbò kí wọ́n tó gbéjọba sílẹ̀– Agbakoba

Ẹ yanjú ẹjọ́ tó ṣú yọ lẹ́yìn ìdìbò kí wọ́n tó gbéjọba sílẹ̀– Agbakoba

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ bá pẹ́ nílẹ̀,níṣe ló má a ń gbọ́n síi.
̣Olórí ẹgbẹ́ àwọn amòfin nílẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olisa Agbakoba, ti gba iléeṣẹ́ ètò ìdájọ ilẹ̀ Nàìjíríà nímọ̀ràn, pàápàá jù lọ, ẹ̀ka tí wọ́n ti ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ tó ṣúyọ lórí ìdìbò sípò Ààrẹ, láti jíròrò, kí wọ́n sì ṣe ìdájọ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láàrin ọjọ́ méje tí wọ́n bá gbé e déwájú wọn.

L’Ọjọru ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n sọrọ lori tẹlifiṣan Arise TV.

Bakan naa lo tun fi kun un pe oludije sipo yoowu ti yoo ba jẹ aarẹ gbọdọ ni ibo to to ida mẹẹẹdọgbọn, niluu Abuja, ki wọn too le kede ẹ pe oun lo wọle.

O ni, “Gẹgẹ bi emi ṣe mọ o, o gbọdọ tun ni bii ida mẹẹẹdọgbọn ibo lolu ilu orilẹ-ede wa, ṣugbọn iyẹn ki i ṣe fun emi lati sọ. Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ba tibi eto idibo yọ le dahun ibeere yii lai si wahala, laarin wakati kan. Ki i ṣe ibeere to le rara”.

Ọrọ yii waye latari wahala to ṣu yọ lasiko tawọn ọmọ Naijiria fẹ tumọ abala kẹtalelaaadoje iwe ofin ilẹ Naijiria, to sọ pe ki wọn to le kede oludije sipo kan gẹgẹ bii aarẹ, o gbọdọ ni ida mẹrin ibo ti wọn di ni meji ninu ida mẹta awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii, titi to fi mọ ilu Abuja. Ṣugbọn ti agba lọọya yii sọ pe ofin yọ olu ilu orilẹ-ede yii sọtọ gedegbe, labẹ ọrọ naa.

Agbakoba tẹsiwaju pe pẹlu nnkan to n lọ yii, ọrọ oṣelu orilẹ-ede yii ti waa lagbara gan-an. O ni afi ti wọn ba le ṣe nnkan to tọ, iyẹn naa si ni pe ki wọn yanju awọn ẹjọ to jẹ jade latari eto idibo, o ni lẹyin eyi, gbogbo nnkan yoo pada bọ sipo.

“Lọjọ bii meloo sẹyin bayii ni Minisita fọrọ iroyin n naka aleebu si Peter Obi fun ẹsun pe o dalẹ ilu ẹ, ti oriṣiiriṣii ọrọ mi-in si n lọ bẹẹ bẹẹ. Ọpọlọpọ nnkan lo fẹẹ da orilẹ-ede yii ru, awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (DSS) naa n pariwo pe awọn eeyan kan n ṣe kinni kan nibi kan. Nnkan to si n da gbogbo eleyii silẹ ko ju bi wọn o ṣe ti i yanju ẹjọ idibo yii lọ.

Ibeere to wa nilẹ bayii ki i ṣe pe ṣe nnkan to ṣee ṣe ni, ṣugbọn lati bi wọn pe ṣe wọn maa ṣe e. Nitori mo le sọ ọ pe ọrọ eto idajọ orilẹ-ede yii ti to bii ọgọrun-un ọdun, a o si ri ilọsiwaju kankan ninu Naijiria”.

Agbakoba ni awọn orilẹ-ede bii Ghana ati Kenya ti ni idagbasoke debii pe, laarin ọgbọnjọ tabi ko ma tilẹ to bẹẹ, ni wọn fi yanju ọrọ ẹjọ to ṣu yọ latara eto idibo.

“Bawo lo ṣe ṣee ṣe fawọn Ghana lati yanju tiwọn laarin ọgbọnjọ, ki lo de tawa naa o le ṣe e nibi? Ki lo de to jẹ ọọdunrun ati ọgọta ọjọ la fi maa maa ṣeto idibo? To ba jẹ emi ni adajọ ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ibo yẹn ni, wakati meji pere ni mo maa fun awọn olupẹjọ lati mu ẹri wa lori boya o yẹ ki wọn wo ida mẹẹẹdọgbọn lori kikede aarẹ to ba wọle tabi ko yẹ. Ma a fun Ọgbẹni Tinubu naa lakooko lati fesi, nigba to ba si maa fi di aago mẹfa irọlẹ, mo maa ka idajọ seti gbogbo eeyan. Ki ni nnkan to waa le nibẹ, ọrọ imọ nipa ofin pọnnbele leyi, ki i ṣe nnkan to ruju rara”.

O ni ti eyi toun sọ yii ko ba waa le ṣiṣẹ, a jẹ pe ki wọn ṣayẹwo magomago to waye lasiko idibo ni yoo tun yanju ẹ, ati pe iyẹn kan le gba akoko pupọ ni. O ni ti wọn ba le yanju ẹ laarin ọjọ mẹrinla lorilẹ-ede Kenya, ki lo de to jẹ odidi ọdun kan ni yoo gba wa lati ṣe tiwa, abi a o kawe ju wọn lọ ni Kenya ni?

“Ohun to n ka mi lara bayii ni pe ọrọ oṣelu ti n gbona janjan, ọna abayọ to si wa bayii ni lati wo ba a ṣe le ri ọrọ ẹjọ yii yanju, ko too di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti wọn yoo gbe ijọba tuntun kalẹ”.

Agbakoba tún gbójú agan sáwọn tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé lọ síwájú ilé-ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò kò lè yanjú kí ìjọba tuntun tóó wọlé. Ó láwọn tí kò fẹ́ kí Nàìjíríà gòkè nirú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.

Khadi, gbajúmọ̀ oníṣòwò ayélujára kú sílé ìtura n‘Íbàdàn

Khadi, gbajúmọ̀ oníṣòwò ayélujára kú sílé ìtura n‘Íbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní ọjọ́ tí ẹ̀dá yóó bà á rin àrìnsọnù, gá gá lara á yáwọn.
Arábìnrin Ọlayinka Adesina, tó jẹ́ ilumọọka aláṣọ lórí ayélujára tí wọ́n tún mọ̀ sí Khadi, ni wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú ilé ìtura kan ní agbègbè Akobo, ní ìlú Ìbàdàn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ọlayinka, tí ó gbajúgbajà fún àwọn aṣọ aláràǹbarà tó má a ń rán àti báàgì tó má ń tà lórí ẹrọ ayélujára, ni wọ́n ní ó sọ fún ọrẹ rẹ̀ kan pé òun fẹ́ lọ pàdé ẹnìkan ní ilé ìtura kan ní alẹ́ Ọjọ́rú.

Ọkùnrin náà ló jí kúrò ní ilé ìtura náà ní ọjọ́ kejì àmọ́ tí wọ́n sì pé yàrá tí Khadi wà, tó sì sọ fún òṣìṣẹ́ ilé ìtura náà pé àlàáfíà ni òun wà, kí wọ́n tó gbà kí ọkùnrin náà máa lọ.

Àmọ́, òkú Khadi ni wọ́n bá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tó ti yẹ kó jáde, tí wọn kò sì gbúròó rẹ̀ tàbí kó gbé ìpè rẹ̀.

Iná sọsẹ́, ṣọ́ọ̀bù márùn-ún, ilé méjì jó kanlẹ̀ níIlọrin

Iná sọsẹ́, ṣọ́ọ̀bù márùn-ún, ilé méjì jó kanlẹ̀ níIlọrin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjàm̀bá iná ṣọṣẹ́ ní Balogun Afin ní agbègbè Ita-Kure, ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara bí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta ọ̀dà ìkunlé ṣe gbiná ní òru ọjọ́ Ẹtì mọ́júmọ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara, Hassan Adekunle fi léde ní nǹkan bí i aago méjìlá àbọ̀ òru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀.

Adekunle ní ilé alájà kan àti ilé nílẹ̀ kan ni ìjàm̀bá iná náà ṣe àkóbá fún àti pé ó tún ran ṣọ́ọ̀bù márùn-ún mìíràn.

Ó ní ṣọ́ọ̀bù ọ̀dà ni iná náà ti bẹ̀rẹ̀ kó tó di wí pé ó ràn mọ́ àwọn ilé méjì tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

Ó fi kun pé iye dúkìá tí iná náà ṣàkóbá fún tó mílíọ̀nù méjìdínlógójì náírà.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti máa ri dájú pé wọ́n ń ṣàmójútó ilé wọn dada kí wọ́n sì ri pe wọ́n ń pa iná tó bá yẹ kí wọ́n tó sùn, láti dẹ́kun ìjàǹbá.

Pásítọ̀ hùwàa gbájú-ẹ̀ fáwọn tó wá ṣe ìsọjí fún n’Íbàdàn

Pásítọ̀ hùwàa gbájú-ẹ̀ fáwọn tó wá ṣe ìsọjí fún n’Íbàdàn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó sọ pé nígbà tí òpin ayé bá ń bọ, oríṣìíríṣìí ìṣẹlẹ̀ kayeefi ni yóó máa ṣẹlẹ̀. Irúfé ìṣẹ̀lẹ̀ irọlẹ ayé bẹ́ẹ̀ ló wáyé n’Ibadan lalẹ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, tó kọjá nígbà tí odidi pasitọ kó owó, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àti nǹkan ẹ̀ṣọ́ ara àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ lásìkò tí wọ́n dijú, tí wọ́n ń gbàdúrà lọwọ́.

Oun tí a gbọ pe Oluṣọ-Agutan naa, Pasitọ (Dokita) Owen Abraham, to jẹ ọmọ orile-ede Gambia, funra rẹ lo ṣagbekalẹ isọji ọlọjọ marun-un ọhun laduugbo Agbowo, n’Ibadan.

Ohun to si mu ki ero pọ daadaa laarin ọjọ maraarun ni bi Pasitọ Abraham ṣe kọ ọ sibi iwe ikede isọji naa pe oun yoo ṣeranlọwọ owo nla nla fawọn alaini, bẹẹ lawọn ọdọ yoo janfaani ẹbun ẹkọ-ọfẹ.

Lọjọ kọkanlelọgbọn (31), oṣu Kẹta, ọdun 2023, leto ọhun bẹrẹ, to si pari lọjọ Ìṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii kan naa.

Lọjọ ti isọji ọhun maa pari gan-an ni oluṣọ-agutan yii paṣẹ fawọn agutan rẹ pe ki gbogbo wọn ko ohun gbogbo to ba wa lọwọ wọn silẹ, ẹmi Ọlọrun sọ foun pe ko gbọdọ si foonu, owo, tabi ohunkohun to jẹ ti aye kankan lọwọ ẹnikẹni titi ti aṣekagba isọji naa yoo fi pari.

Gẹgẹ bii ilana awọn Onigbagbọ, nigba ti eto adura naa n lọ lọwọ, gbogbo wọn diju, ṣugbọn ki ni wọn gbadura tan si ni, oju ti awọn ọmọ ijọ yoo ya bayii, ati pasitọ, ati gbogbo nnkan ti wọn ko si dokita naa lọwọ ti poora.

Ọkan ninu awọn to padanu dukia wọn sọwọ wolii eke to pera ẹ lojiiṣẹ Ọlọrun yii, Abilekọ Grace Akintọla, fidi ẹ mulẹ pe awọn opó lo pọ ju nibi eto naa, nitori ileri iranlọwọ owo nla nla ti jagunlabi ṣe fawọn alaini.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Obinrin Ibo kan ta a jọ n gbe adugbo kan naa lo pe mi sibi isọji yẹn, o ni pasitọ yẹn ti ṣeleri pe oun maa fun awọn eeyan lowo nla nla, owo ti awọn oloṣelu gan-an ko le fun eeyan. Bẹẹ lo tun ni oun maa fun ẹnikan ninu awa ta a ba wa sibẹ ni odidi ile kan ti gbogbo nnkan ti pe sinu ẹ.

“Pasitọ yii ta ike omi kan fun wa ni ẹgbẹrun marun-un o din igba Naira (₦4,800), ọpọ eeyan lo sí ra omi yẹn.

” Pasitọ Abrahamu fi wá sílẹ̀ sínú aawẹ àti adua, nígbà tó di ọjọ́ aṣekagba ètò, ṣadeede la wá a tì, tí a kò rí i mọ́. Gbogbo ìgbìyànjú wa láti rí i bá sọrọ kò so èso rere, nítorí gbogbo bá a ṣe ń gbìyànjú láti pè é sórí fóònù rẹ̀ tó, aago rẹ̀ kò lọ rárá ”.

Ènìyàn kán kú, méjé farapa nínú ìkọlù agbéṣùnmọ̀mí ní Israel

Ènìyàn kán kú, méjé farapa nínú ìkọlù agbéṣùnmọ̀mí ní Israel

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí àwùjọ ṣe n jèkuru ọ̀ràn kó tán, bẹ́ẹ̀ lalákọrí àwọn agbésùnmọ̀mí tún n gbọnwọ́ ọ rẹ̀ sínú àwo táńganran.
Ènìyàn kan ti kú, àwọn méje míìràn sì farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù ìgbésùnmọ̀mí tó wáyé ní agbègbè etí omi ìgbafẹ́ ní ìlú Tel Aviv, ní ilẹ̀ Israel.

Ileeṣẹ pajawiri ni Israel ni arinrinajo lati ilẹ Italy wa si Israel lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si pe orukọ rẹ ni Alessandro Parini, ẹni ọdun mẹrindinlogoji.

Dokita to ṣaajo pajawiri ninu iṣẹlẹ naa ni mẹta ninu awọn to farapa naa jẹ arinrinajo lati Ilẹ Gẹẹsi.

Awọn aworan iṣẹlẹ naa ṣafihan ọkọ to ti dojubọlẹ, ti ọlọpaa ilẹ isrẹli si ṣina bolẹ.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa nibẹ ni wọn ti yinbọn pa ẹni to ṣekọlu naa ti wọn si pe orukọ rẹ ni Yousef Abu Jaber lati agbegbe Kafr Qasim to jẹ Arabu-Isreli.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni aago mẹsan kọja ni akoko ti ilẹ Isrẹli ni ọkunrin kan wa ọkọ Kia kọja ni bebe odo ti awọn eniyan ti n gbafẹ to si bẹrẹ si ni kọju wọn, ki ọkọ rẹ to doju bọlẹ.

Wọn ni bi o ṣe jade ninu ọkọ naa to dabi ẹni pe o fẹ mu ibọn ni ọlọpaa kan yinbọn pa.

Nibayii, Olootu Ijọba Ilẹ Italy, Giorgia Meloni ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa to si ba wọn kẹdun.

Agbẹjọro ni arakunrin ilẹ Italy, Parini to ku ninu iṣẹlẹ naa.

Ṣáájú ni wọ́n ti ṣekọlù sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó tún jẹ́ ara ilẹ̀ Isrẹli méjì pẹ̀lú ìyá wọn ní àgbègbè West Bank.

Buhari, Tinubu kọrin arò lẹ́yìn ikú ìyàwó Uzor Kalu

Buhari, Tinubu kọrin arò lẹ́yìn ikú ìyàwó Uzor Kalu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báakú là á dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bá Sẹ́nétọ̀ Orji Uzor Kalu kẹ́dùn lórí ìpapòdà ìyàwó rẹ̀, Ifeoma.

Ní orí Facebook ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Abia tí kéde pé ìyàwó òun jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Kalu nínú àtẹ̀jáde náà ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni àwọn yóò ti ṣe ìsìn ìdágbére ráńpẹ́ fún Ifeoma Ada Kalu.

“Pẹ̀lú ọkàn tó gbọgbẹ́ ni a fi kéde ikú Ifeoma Ada Kalu tó papòdà lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ sí afẹ́fẹ́ rere tó sì ń tọrọ àdúrà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn lórí àdánù ńlá yìí.

Ààrẹ Muhammadu Buhari nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ rẹ̀, Femi Adesina bá ẹbí Kalu àti Ifeoma kẹ́dùn.

Ààrẹ Buhari gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ Ifeoma sí afẹ́fẹ́ rere kó sì tu àwọn ẹbí tó fi síllẹ̀ nínú.

Bákan náà ni Ààrẹ tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu náà rọ Kalu láti má bara jẹ́ púpọ̀.

Tinubu ní Ifeoma gbé ìgbé ayé tó ṣe é wo àwòkóṣe nígbà tó wà láyé bí ó ṣe jẹ́ pé ó fi ìgbé ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run àti ọmọnìyàn ni.