Home Blog Page 62

Tinubu fí ọ̀rọ̀ ìkíni sọwọ́ sí ọba Charles tó gorí ìtẹ́

Tinubu fí ọ̀rọ̀ ìkíni sọwọ́ sí ọba Charles tó gorí ìtẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ tí aráàlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Nàìjíríà,Bola Ahmed Tinubu,ti ránṣẹ́ ìkíni sí Ọba Charles III.

Nínú ìwé ìkíni náà tó kọ, ó ní òun ṣetán láti pawọ́pọ̀ pẹ̀lú orí-adé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì .

Tinubu sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé Ọba náà yóó tọ ipasẹ̀ ìyá rẹ̀ Obabìrin Elizabeth nípa mímú ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn orílẹ̀-èdè “Commonwealth”.

Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn tí òun náà ń gbaradì de ibúrasípò, se é lálàyè pé òun lérò pé ìtẹ̀síwájú yóó bá ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lásìkò tí Charles III wà lórí Oyè.

Lakotan,Tinubu gba a àdúrà àṣeyọrí fún Ọba tuntun títí tí yóó fi parí sáà rẹ̀.

Lọjọ Kokandinlogbon oṣù karùn-ún ni wọn yóó búra wọlé sípò fún Tinubu lẹyìn àṣeyọrí rẹ̀ ninu idibo ààrẹ to waye l’óṣù Kejì ọdún 2023

Ìjọba tuntun yóó mú ọjọ́ ìkànìyàn -Buhari

Ìjọba tuntun yóó mú ọjọ́ ìkànìyàn -Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti yí òhun padà nípa buwọ́lu sísún ètò ìkànìyàn tí wọ́n tí kọ́kọ́ ní yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún yìí síwájú.

Buhari ní kí ìjọba tuntun tí yóò gbà ipò lọ́wọ́ òun ni ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún mú ọjọ́ àti àsìkò mìíràn tí ètò náà yóò wáyé tí wọ́n bá ti gorí ipò tán.

Nígbà tí Ààrẹ Buhari ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ kan àti alága àjọ tó ń rí sí ìyè ènìyàn tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí, Nasir Isa-Kwarra ní ìlú Abuja lọ́jọ́ Ẹtì.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Mínísítà fétò ìròyìn àti àṣà Nàìjíríà, Lai Mohammed fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ó pọn dandan pé kí ètò ìkànìyàn wáyé lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún tí ètò náà wáyé kẹ́yìn.

Ó ní ètò náà yóò fún ìjọba ní àǹfàní láti mọ iye nǹkan tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí lójúnà àti lè pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fún tẹrú tọmọ.

Ààrẹ ní ìgbáradì ti ń lọ gidigidi láti ṣètò ìkànìyàn tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀, tó sì kan sáárá àjọ NPC fún àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣàmúlò láti fi kànìyàn tó péye.

  1. Bákan náà ló wòye pé ètò EAD tó ti ṣáájú wáyé ti ṣàfihàn pé àjọ náà ti ṣetán láti ṣètò ìkànìyàn tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìkànìyàn ní àgbáyé.

Bí àwọn akẹgbé mi se ń kó dúkìá jọ tó ní Canada, Àsà Yorùbá lèmi gbájú mọ́ – Ọmọọba Olaniyi Oyatoye

Bí àwọn akẹgbé mi se ń kó dúkìá jọ tó ní Canada, Àsà Yorùbá lèmi gbájú mọ́ – Ọmọọba Olaniyi Oyatoye

 

Yínká Àlàbí

Yoruba bọ, wọn ni “ẹlẹru lo n gbe e ni ibi to ti wuwo”. Eyi lo difa fun akinkanju Olorin, Akewi, Ajihinrere ati Agbohunsafẹfẹ Ọmọọba Joel Olaniyi Oyatoye to fi mu asa Yoruba ni ọkunkundun.

Gbogbo bi awọn akegbẹ rẹ se n fi owo isẹ inu otutu naa kọ ile alaranbara si orileede Naijiria ni Olaniyi n fi tirẹ gbe asa ga. Awọn  nnkan isẹnbaye bii irukẹrẹ, ọpa asẹ, igba, ẹni isẹnbaye, asọ ibilẹ, iwe itan, foto isenbaye, fila ati gele lorisiirisii ni Ọmọọba yii n ko gbogbo owo rẹ sii. Awọn nnkan isenbaye naa si wa ni gbọngan to gba si orileede naa. O salaye yii nibi ipade to se pẹlu awọn ajọ akọroyin “Guild of Yoruba Media Practitioners” (GYMP) ti alaga Ọgbẹni Samuel Akinrole ati awọn oloye ẹgbẹ se agbatẹru rẹ ni alẹ ọjọ kejidinlọgbọn, osu kẹrin ọdun yii.

O ni “ọmọ to sọ ile nu ti so apo iya kọ”. Ọmọ bibi ipinlẹ Kwara to ka ile-iwe alakọọbẹrẹ ati girama nibe ki iji aye to gbee  lo si orileede Canada lati lo ka iwe to ku. Ki o to di pe akinkanju ọkunrin yii kuro ni orileede yii naa ni ede Yoruba ti gbilẹ lọkan rẹ ti o si n gbiyanju lori awọn ile-isẹ Redio bii Radio Lagos, Paramount FM Abeokuta, Choice F M Lagos ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ki Ọmọọba to kuro niluu yii naa ni o ti kundun Ewi, Oriki, Ijala, Ẹkun iyawo ati Rara. Eyi jẹ ki gbigbe asa laruge rọrun fun un ni awọn orileede bii Canada, United Kingdom ati United State of America. Omooba Oyatoye kawe ni Red River College ati Academic College to wa ni Winnipeg ati Ashton College BC. Ara igbiyanju re lati le ri owo fi mu ala rẹ sẹ lo jẹ ki o sisẹ ni – Impact Security laarin ọdun 2013 si 2015, Epic opportunity 2014 si 2018 ati ni St Amant 2013 si 2020 ti gbogbo rẹ wa ni orileede Canada.

Lara igbiyanju Omooba Oyatoye lati ma jẹ ki asa Yoruba parun lo sun un de ibi gbigba iwe asẹ “Yatniy Comunication” ni ọdun 2018, “Asa Day Worldwide Inc” ni ọdun 2019, “asa Property Management Inc” ni odun 2020, “The Yoruba art and Culture” 2018 si 2019.

Nitori ajakalẹ arun Covid, “Asa Day” waye lori ero ayelujara ni ọdun 2020 ni Winnipeg, Canada. Ọdun 2021 ni Asa Day pelu afọwọ-sowọ-pọ ijọba ipinlẹ Eko ati Oyo tun waye ni ọtọọtọ ni awọn ipinlẹ mejeeji.

“Ẹni ti yoo parọ ni n leleri l’ọrun”, igbiyanju ki asa Yoruba ma se parun yii ti jẹ itẹwọgba awọn ileesẹ iroyin kaakiri Naijiria, lara awọn ileesẹ naa ni – NTA, Channel Television, Lagos Television, Galaxy Television, BCOS ipinlẹ Oyo, Radio Lagos,, Fresh FM, Bond FM/Radio Nigeria, Inspiration FM, Eko FM, Nigeria Tribune, Vanguard, ThisDay, The Sun, The Nation, New Telegraph, Punch, Leadership, Gaily trust, Daily Independent ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọmọọba Oyatoye ko tii duro, o si n tẹ siwaju lori ẹrọ ayelujara lorisiirisii nipa idanilẹkọọ lori Pataki Asa ati Ise Yoruba.

EFCC wọ́ abẹnugan Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo lọ ilé ẹjọ́

EFCC wọ́ abẹnugan Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo lọ ilé ẹjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààyá gbọ́n, ògúngbè gbọ́n ní ọ̀rọ̀ àwọn oníjìbìtì, àti àwọn agbófinró látàrí bí Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìjẹkújẹ àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ mìíràn tó ń se àkóbá fún ọrọ̀ ajé, EFCC ti wọ́ abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo, Rt Hon Bamidele Oloyeloogun lọ síwájú ilé ẹjọ́ gíga nílùú Àkúrẹ́.

Abẹnugan ọ̀hún àti àwọn méjì ni EFCC fẹ̀sùn kan pé wọ́n lu owó ní póńpó, èyí tí wọ́n ní àwọn kòjẹ bi rárá.

Agbẹjọ́rò EFCC, Kingsley Kudus wá rọ ilé ẹjọ́ láti fi àwọn afurasí náà sátìmọ́lé tí tí ìgbẹ́jọ́ yóò fi parí.

Ó ní torí pé àwọn afurasí náà ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀ṣùn kò ní pé kí wọ́n máa lọ ní àlàáfíà lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ sí ń lọ lọwọ.

Ṣùgbọ́n Agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́, Barr. Femi Enodamori ní kí ilé ẹjọ́ wọ́gilé ìpe akẹ́ẹgbẹ́ rẹ̀, tó sì bẹ bẹ fún ìtúsílẹ̀ fún àwọn afurasí náà.

Adájọ́ Adegboyega Adebusoye wá sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kejìdínlógún, osù kàrún un, tó sì fún àwọn afurasí ní ànfàní láti má a jẹ́jọ́ láti ilé.

À ń ṣètò pẹ̀lú ìlẹ̀ Egypt láti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní Sudan – ìjọba àpapọ̀

À ń ṣètò pẹ̀lú ìlẹ̀ Egypt láti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní Sudan – ìjọba àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà sọ pé kò sí kékeré ìdààmú àti pé ogun kìí bímọ ọ re.Ọmọ́ wọn kú sì tún sàn ju ọmọ wọ́n nù.
Kìí ṣe nnkan gidi kí ọmọ ẹni ràjò kó rá sájò Ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè Sudan ni àwọn dá padà sílé.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Geoffrey Onyeama tó sọ àrídájú yìí ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti rí i pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè náà padà sílé láyọ̀ àti àláfíà.

Onyeama ní ohun tó ń dá àwọn dúró láti kó àwọn ènìyàn náà ni pé kò sí ààyè láti lo ọkọ̀ òfurufú ní Sudan báyìí nítorí wàhálà tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ó ní ọkọ̀ ni àwọn fi lè kó àwọn ènìyàn ọ̀hún tí àwọn sì nílò àṣẹ ìjọba Sudan láti kó wọn gba Egypt lábẹ́ ààbò tó péye.
Mínísítà náà ní tí ó bá máa fi tó ọjọ́ méjì sí mẹ́ta àwọn máa ti fẹnukò pẹ̀lú ìjọba Sudan àti ti Egypt tí àwọn yóò si ti mọ bí àwọn yóò ṣe kó àwọn ènìyàn náà kúrò.

Ó tún ṣàfọ̀mọ́ ẹ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé ìjọba Nàìjíríà kò kóbi ara sí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún ń kojú.

“Kò sí ẹni tó mọ̀ wí pé wàhálà tó ń wáyé ní Sudan máa fẹjú tó báyìí, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá gbogbo ọmọ Nàìjíríà nílé lóko jẹ́ èyí tó jẹ ìjọba lógún.”

Ó fi kún-un pé ẹgbẹ̀rún márùn-ún àbọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti fi ìfẹ́ hàn sí pé àwọn ti ṣetán láti padà wá sílé tó sì ní púpọ̀ nínú wọn lọ́ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.

Onyeama tún tẹ̀síwájú pé àwọn àjọ ìjọba tún ti ń gbìyànjú láti pèsè ohun ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn náà, ó ní láìpẹ̀ ọ̀rọ̀ nàà yóó lójútùú.

Sanwo-Olu pàṣẹ kí wọ́n da ilé mẹ́ta wó ní Banana Island

Sanwo-Olu pàṣẹ kí wọ́n da ilé mẹ́ta wó ní Banana Island

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ìlú tí kò sófin, ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀, àti pé èèyàn tó bá ṣe n tẹ́nìkan kò ṣe rí, kò sí n tó burú kójú onítọ̀ún ó rí n tẹ́nìkan kò rí, ọ̀rọ̀ ti jọ
bẹ́ẹ̀ báyìí o,bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babajide Sanwo-Olu ti paá lásẹ pé kí wọ́n da ilé gbè é mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó jẹ́ alájà méjì wó ní agbègbè Banana Island lẹ́yìn tí ilé alájà méje wó ní agbègbè ọ̀hún.

Àṣẹ yìí wá lásìkò tó ṣe àbẹwò sí ibi tí ilé alájà méje ti dà wó ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn.

Ní agbègbè 310 close, Gómìnà ní kí wọ́n da ilé alájà méjì wó nítorí ìjọba kò buwọ́lu àwọn ilé ọhún.

Bákan náà ni 306 close, Gómìnà ní kí wọ́n da ilé alájà méjì tó kọjú sí arawọn wó nítorí abẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná àti omi ní ilé ọhún wà.

Gómìnà ní àṣìṣe àwọn abáni kọ lé àti àwọn aráàlú tí wọ́n ń wá owó òjìji ló fa bí ilé alájà méje se dà wó.

Bákan náà Gómìnà bu ẹnu àtẹ lu bí ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí iṣẹ́ àti ilé gbè é fún bí wọ́n ṣe gbà láti se àfikùn sí àgbègbè Banana Island.

Gómìnà ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó lọwọ́ nínú ìṣẹlẹ náà ni wọn yóò rí ìjìyà lábẹ́ òfin.

Ọkùnrin tó ń bá òkú gbé kó sí gbaga ọlọ́pàá

Ọkùnrin tó ń bá òkú gbé kó sí gbaga ọlọ́pà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín, arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julio ní orílẹ̀ èdè Peru ni ó ti ń wí tẹnu rẹ̀ báyìí ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Atótónu rẹ̀ ọ̀hún níwájú àwọn agbófinró kò ṣẹ̀yìn bí àwọn ọlọ́pàá ṣe bá òkú gbígbẹ kan nínú báàgì tó máa ń mú nǹkan tutù rẹ̀.

Julio ní láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ní òun àti òkú náà ti ń gbé tí òun sì máa ń ṣe ìtọ́jú òkú náà dáradára.

Ó ní Juanita ni orúkọ tí òun fínúfíndọ̀ fún òkú náà àti pé bí ọ̀rẹ́bìnrin nínú ẹ̀mí ni òkú náà jẹ́ sí òun.

Àwọn onímọ̀ ní ó ṣeéṣe kí òkú náà ti kú láti ẹgbẹ̀ta sí ẹgbẹ̀rin ọdún sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí orí rẹ̀ ṣe fi múlẹ̀.
ŃǸ ńǹ m̀
Ohun tí a gbọ́ ni pé ọkùnrin àràmọ̀ǹdà ọ̀hún sì wà ní gbaga ọlọ́pàá níbi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò láti mọ ohun tó fi ìgbésẹ̀ rẹ̀ ọ̀hún sùn.

Ìlú ń bèèrè Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn, Bọla Ahmed Tinubu

Ìlú ń bèèrè Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn, Bọla Ahmed Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ọjọ́ ṣe ń wọnú sí i, ni àwọn èèyàn ṣe ń làkàkà láti fojú gánán ní Ààrẹ wọn.
Ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ni pé níbo ni Ààrẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu wá nítorí ó ti se díẹ̀ tí wọ́n ti gbúròó rẹ̀ mọ́ ní Nàìjíríà

Bọla Tinubu ló ń dúró di Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kàrún-ún tí Ààrẹ Buhari yóò gbé ìjọba fún lọ́nà ìjọba tiwantiwa.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àjọ INEC ṣe kéde pé Tinubu tó díje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló borí gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ nínú ìdìbò sípò Ààrẹ tó wáyé ní Nàìjíríà.
Àwọn mìíràn tilẹ̀ ń sọ pé Ààrẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn náà gba òkè òkun lọ láti lọ ṣiṣẹ́ abẹ́rẹ́, nítorí ìgbà tí wọ́n rí Tinubu kẹ́yìn ní àsìkò ìgbaradì fún ìdìbò sípò Gómìnà ní Ọjọ́ Kejìdínlógún, Oṣù Kẹta , ọdún 2023.

Ní Ọjọ́ Kejìlélógún ní agbẹnusọ rẹ̀, Tunde Rahman fi lédè pé Tinubu ti gba òkè òkun lọ láti lọ sinmi, láti ibẹ̀ lọ sí Saudi Arabia fún Umrah, kí ó tó padà wá sí Nàìjíríà fún ìbúrawọlé rẹ̀ ní Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Karùn ún, ọdún 2023.

Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí àti ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ fún ìsinmi ọdún ìtúnu ààwẹ̀.

Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí àti ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ fún ìsinmi ọdún ìtúnu ààwẹ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógún, àti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù yìí gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi ọdún ìtúnu ààwẹ.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla, ló fi ìkéde ọhún síta nílùú Àbújá.

Arẹgbẹsọla rọ àwọn Mùsùlùmí láti lo àkókò ọdún náà fi gba àlàáfíà láàyè láàrin ara àwọn àtàwọn ọmọlàkejì wọn.

Ó tún rọ wọn láti fi àkókò ọdún ìtúnu ààwẹ ọ̀hún ṣàdúrà fún ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà.

Lẹ́yìn náà ló ṣàdúrà pé wọ́n yóó ṣe ọ̀pọ̀ ọdún náà lórílẹ̀ alààyè.

“Mùsùlùmí ẹ wojú ọ̀run fún oṣù tuntun Shawwal láti parí ààwẹ̀” – Sultan Sokoto

“Mùsùlùmí ẹ wojú ọ̀run fún oṣù tuntun Shawwal láti parí ààwẹ̀” – Sultan Sokoto

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ẹlẹsin mùsùlùmí orílẹ̀ èdè yìí ni wọ́n ti ké sí láti fojú sọ́nà wá òṣùpá Shawwal 1444 AH láti ọjọ́, Ọjọ́bọ̀ èyí tí yóó ṣàfihàn ìfopin sí ààwẹ̀ gbígbà ọ̀rànyàn fún àwọn mùsùlùmí jákèjádò Orílẹ̀ yìí.

Sultan Sokoto , Alhaji Sa’ad Abubakar,ẹni tó tún jẹ́ olórí àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí ní orílẹ-èdè yìí ló fi ìròyìn náà léde látọwọ́ amúgbá lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ tó wà fún ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣìn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sambo Junaidu.

Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún Sultan ni,”Èyí ni láti kéde fún àwọn Mùsùlùmí òdodo pé láti Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yìí, tó tún jẹ́ ọjọ́ tí ààwẹ̀ yóó di ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni yóó jẹ́ ọjọ́ tí wọn ó wo òru Shawwal 1444 AH.

Sultan ṣàdúrà kí Ọlọ́run ka ààwẹ náà sí ìbùkún fún àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí jákèjádò Nàìjíríà.

Rírí òṣùpá ni yóò mú òpin bá ààwẹ̀ gbígbà èyítí ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn Mùsùlùmí,Shawwal jẹ́ oṣù Kẹwàá nínú Kàlẹ́ńdà àwọn Mùsùlùmí.