Home Blog Page 6

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ló ń lọ lu lọjọ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kerin 2025, tírélà kan fi jábọ́ láti orí afárá Pen Cinema, Agege, l’Ekoo, tó sì run ọkọ̀ Kórópe méjì tó jábọ́ lé lórí pa.

Ajọ Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Atẹjade kan ti Adari iṣẹlẹ bi eyi ati ilaniloye ni LASTMA, Adebayo Taofiq, fi sita, sọ pe dẹrẹba to wa ọkọ tirela naa ko ni ikapa lori ọkọ ọhun mọ lasiko ijamba naa.

O ni idi niyẹn to fi jabọ pẹlu ọkọ sisalẹ, to si run awọn ọkọ Korope meji to wa nibẹ womu.

Adebayọ fi kun un pe dẹrẹba to wa tirela ọhun ṣeṣe pupọ nibi ọwọ rẹ mejeeji .

O ni kia ni awọn oṣiṣẹ LASTMA ti fa a le awọn ọlọpaa teṣan Elere lọwọ, ti wọn si gbabẹ gbe e lọ sileewosan jẹnẹra to wa lagbegbe Ile Epo.

GGE 624 YJ, ni LASTMA pe nọmba tirela to kun fọfọ ọhun.

Ọga agba fun LASTMA, Olalekan Bakare-Oki, rọ awọn awakọ, paapaa julọ awọn to n wa tirela, lati maa fi oju ṣọri daadaa.

O ni eyi ṣe pataki, paapaa bi asiko ojo ṣe n sun mọ etile .

O rọ awọn awakọ gbogbo lati tẹle ofin ere sisa, nitori awọn irinṣẹ to n ṣọ awọn awakọ nipa ere asaju, eyi ti ijọba Eko ti fi sawọn agbegbe kiri lati dena ijamba.

Ki wọn si pawọpọ mu oju ọna di ibi arinye.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Omololu Olunloyo jáde láyé

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Omololu Olunloyo jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báa kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n lójú èèyàn láàyè.
Gómìnà ìpínlè Oyo nígbà kan rí, Victor Olunloyo, ti jáde láyé.

Ìròyìn ni àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ Àìkú ni olóògbé náà kú.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn tó súnmọ́ mọ̀lẹ́bí olóògbé náà fi léde, ọjọ péréte ló kù kó ṣe ọjọ́ ìbí àádọ̀rún ọdún rẹ̀ lókè èèpẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó kànkùn bá lálejò.

Atẹjade ọhun ti Oladapo Ogunwusi buwọlu lorukọ mọlẹbi sọ pe “Victor Olunloyo ti lọ sile.”

Atẹjade naa sọ pe “Pẹlu ọgbẹ ọkan ni a fi kede ipapoda Ọmọwe Victor Omololu Olunloyo, gomina ipoinlẹ Oyo nigba kan ri, oluṣiro, onimọẹrọ ati agba ọjẹ nipa eto iṣẹjọba, ni ọjọ diẹ si ọjọ ibi aadọrun ọdun rẹ.

“Olunloyo, to jẹ Balogun ilu Oyo ati Otun Bobasewa Ife, ni olori akọkọ nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Ibadan ati ipinlẹ Ilorin, o tun di awọn ipo mii mu.”
Ṣaaju ni awọn ileeeṣẹ iroyin kan ti kọkọ jabọ pe Olunloyo ti papoda ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2024, amọ nigba ti awọn akọroyin lọ sile rẹ lasiko naa, o ni ṣaka lara oun da,

O sọ nigba naa pe “Mo ṣi wa nibi, mi o tii lọ.”

Gomina tẹlẹ ri ọhun ni inu oun ko si iroyin iku oun nigba ti oun ṣi wa laaye.

O fi kun pe oi si ẹni ti ko ni ku, yala ẹni ti wọn n royin iku rẹ ni o tabi ẹni to n royin iku ẹlomiran.

O ni “Oloriire ni mi, baba mi ku lẹni ọdun mejilelogoji nigba ti iya mi ku lẹni ọdun mejilelọgọrun un, emi naa ti pe ẹni ọdun mọkandinlaadọrun bayii, mo ti lo kọja iye ọdun ti igbagbọ wa pe o yẹ ki n lo laye.”

Yekini Adeojo, àgbà òṣèlú jáde láyé, Makinde àtàwọn èèkàn ìlú ń dárò ikú rẹ̀

Adeojo

Yekini Adeojo, àgbà òṣèlú jáde láyé, Makinde àtàwọn èèkàn ìlú ń dárò ikú rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwáyé è kú ò sí,èrò ọkọ̀ lásán ni gbogbo wa láyé, ibùsọ̀ tí a tí ń bọ́ sílẹ̀ ló yàtọ̀ síra wọn .
Olóyè Yekini Adeojo, Ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú ńlá nílùú Ìbàdàn àti ní Nàìjíríà lápapọ̀ ti jáde láyé.

Aarọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin ọdun 2025 lo papoda.

Oloogbe Yekini Adeojo jẹ ọkan lara awọn to da ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ nipinlẹ Oyo.

O ti figba kan ri jẹ Igbakeji Alaga apapọ ninu ẹgbẹ PDP ni ẹkun Guusu.

Bakan naa lo si tun jẹ oye nla ti i ṣe Seriki Musulumi.

Oloye pataki ni Yekini Adeojo ṣaaju iku rẹ niluu Ibadan.

Oloogbe Adeojo ni baba to bi Ọnarebu Sheriff Aderemi Adeojo, Alaga ijọba ibilẹ Ido, lọwọlọwọ

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, wa lara awọn eeyan to ti n ba idile Adeojo kedun iku naa.

Makinde ṣapejuwe Oloogbe Adeojo bii ẹnikan ṣoṣo to ṣẹku ninu awọn agba asiko rẹ.

O ni iku rẹ fopin si asiko oṣelu ologo igba naa ni.

Gomina rọ awọn ẹbi Adeojo lati ṣe ọkan giri lori iku Oloogbe Yekini Adeojo, ẹni to du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP ni 1999.

O gba a ladura pe Ọlọrun yoo fun wọn lagbara lati gba ohun to ṣẹlẹ yii.

Bẹẹ ni Makinde ba gbogbo PDP ipinlẹ Oyo naa kẹdun ara fẹrraku Oloye Yekini Adeojo.
Oloye pataki ni Oloogbe Yekini Adeojo n’Ibadan, bẹẹ naa lo si tun jẹ oloṣelu.

Ọpọ igba lo ti gbiyanju lati di gomina ipinlẹ Oyo, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe.

Ohun to n fa eyi nigba naa gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ni pe aarin Adeojo ati Oloogbe Lamidi Adedibu ko gun.

Eyi ko si jẹ ki ipo naa ja mọ Adeojo lọwọ bo ṣe gbiyanju to.

Bi Oloogbe Yekini Adeojo ṣe jẹ oloṣelu lo tun jẹ agba ninu ẹsin Islam.

Musulumi ododo to maa n pe fun alaafia ati iṣokan ni. Bakan naa lo si tun maa n kede pe ẹsin o faja.

Ìròyìn òwúrò̩ tuntun

Ìròyìn òwúrò̩ tuntun

Ìròyìn òwúrò̩ t’ò̩sè̩ yí

Ìròyìn òwúrò̩ t’ò̩sè̩ yí

Ìròyìn Òwúrò̩ t’ò̩s̩è̩ yí

Ìròyìn Òwúrò̩ t’ò̩s̩è̩ yí

Awakọ̀ èrò dáná sún òṣìṣẹ́ LASTMA l‘Eko, ọ̀rọ̀ di bóòlọ yàgò fún mi

Awakọ̀ èrò dáná sún òṣìṣẹ́ LASTMA l‘Eko, ọ̀rọ̀ di bóòlọ yàgò fún mi

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ohun tá ó jẹ là ń wá, bẹ́ ẹ̀ ádùrá ká má pàdé ohun tí yóò jẹ wá là ń tọrọ.
Ṣùgbọ́n kò jọ pé àdúrà yìí fi taratara gbà pẹlú
Ìṣẹ̀lẹ̀ à gbọ́ yanu tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí awakọ̀ bọ́ọ̀sì èrò dáná sun òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ náà, LASTMA àti bọ́ọ̀sì rẹ̀.

Ninu fọnran kan to gba ori ayelujara ni ati ri bi ina se mu awakọ bọọsi, oṣiṣẹ LASTMA ati bọọsi ero naa.

Ohun to fa ariyanjiyan laaarin awakọ naa ati oṣiṣẹ LASTMA ni a ko le fidi rẹ mulẹ sugbọn LASTMA ti fi atẹjade sita lori opo ayelujara X pe otitọ ni iṣẹlẹ naa waye .
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣalaye, LASTMA ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Cele lọ ọna Mile 2 lẹyin ti awọn oṣiṣẹ LASTMA da ọkọ ero naa duro fun ayẹwo.

“Iroyin nipa iṣẹlẹ to waye to de ọdọ wa, ti a si ti ri fọnran bi awakọ bọọsi Volkswagen T4 pẹlu nọmba idanimọ LSD355 CK se dana sun ọkọ rẹ ati oṣiṣẹ LASTMA nigba to n gbiyanju lati ma jẹ ki wọn mu oun.

“Isẹlẹ yii waye ni Ọjọ Karun un Oṣu kẹrinla ọdun 2024. A da ọkọ naa duro nitori o ti tapa si ofin oju opopona ni agbegbe Mile 2.

“Nigba ti a fẹ mu, awakọ naa bẹrẹ si ni lo agidi , to si da epo bẹntiroolu si ara oṣiṣẹ LASTMA, to si gbana.

“Oṣiṣẹ LASTMA naa farapa yanayana , ti awọn akẹgbẹ ẹ si sure gbe e lọ si ile iwosan fun itọju.”