Home Blog Page 46

È̩rín pa ẹ̀ẹ̀kẹ́ Ọbasá lórí Ọ̀ṣẹ̀ Yorùbá

È̩rín pa ẹ̀ẹ̀kẹ́ Ọbasá lórí Ọ̀ṣẹ̀ Yorùbá

Akeem Lasisi

Bi eeyan ba gun esin koja ni inu Agbenuso Ile Igbimo Asofin Ipinle Eko, Rt Honorable Mudasiru Obasa, bayii, esin naa ko ni kose.

Geerege ni yoo lo titi de Kano tabi Enugu.

Eyi yoo ri bee tori pe inu Alagba Obasa n dun sin-in latari bi Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu, se fi ounte lu ayeye Ose Yoruba (Yoruba Week), eyi ti ijoba naa yoo see ninu osu kesan-an odun yii.

Ile Igbimo Asofin Eko, eyi ti Obasa je adari fun, lo gbe erongba Ose Yoruba naa jade, to s gbe e siwaju Sanwo-Olu ninu osu to koja.

Niwon igba ti gomina naa feran oro asa ati ise Yoruba tele, ko ni i lara lati bu ounte naa lu u.

Eyi tumo si pe gongo a so ni Eko ninu osu kesan-an, ti aruputu yoo si hu.

Bi a ko ba gbagbe, Obasa je eni kan to feran ede Yoruba pupo.

Oun ati awon asofin to ku kii ko iyan ede abinibi naa kere.

Eyi lo fa a ti won fi pinnu lati maa so ede naa ni awon ojo kan, ti won ko si fi sere rara.

Bi Gomina se wa je eni to feran, to si n sise takuntakun lori idagbasoke irinajo afe, asa ati ise (tourism, arts and culture), ti Obasa ati awon asofin naa si gbe ede Yoruba soke ni ookan aya won, e ko wa ri i pe Ipinle Eko ko se e fowo ro seyin ti a ba n soro pataki ohun abinibi.

IROYIN OWURO patewo nla fun won lori eleyii.

 

 

 

IDÁN ORÍTA: ÀRÀMÀNDÀ BÍRÍÌJÌ SANWO-OLU TUNTUN NÍ ÌKẸJÀ ṢỌ ARÁ ÈKÓ DI ARÁ OKO

IDÁN ORÍTA: ÀRÀMÀNDÀ BÍRÍÌJÌ SANWO-OLU TUNTUN NÍ ÌKẸJÀ ṢỌ ARÁ ÈKÓ DI ARÁ OKO

Akeem Lasisi

– E tun ka nipa opolopo ona, afara, ile iwosan, ile-iwe, aafin ati bee bee lo ti ijoba Babajide Sanwo-Olu ti se laarin odun kinni isejoba eleekeji rẹ̀

 

Ni agbegbe Ikeja ni Ipinle Eko, orin ti yi, ilu si ti yi pada o.

Paapaa ni opin Awolowo Road si Ikeja Express, eni to ba ti de ibe ti pe, ko kun fun adura ki oun ma sonu ni.

Ki onitohun soji, ko ma sun – gege bi asa ti won maa n da.

Iru eni naa ko gbodo die nu re, ani ki o ma ba a sonu, ki awereko ma lu u ni ilu Ikeja.

Eyi da lori bi biiriji kan ti ijoba Babajide Sanwo-Olu sese ko si ibe se je aramanda.

Afara soji-masun ohun ni won n pe ni Ikeja Overpass, ti won fi sori oko oju irin Red Line.

Ikeja Overpass naa ni won fi ko T, nitori o ya ona ti oko oju irin n gba soto si eyi ti awon moto n gba.

Lai paro rara, opo eniyan to je ara Eko ni biriiji kasiara naa n so di ara oko.

Ti eniyan ba ba ti de adugbo naa tipe, to ba wa sako, ti ko tete beere ona, to ni oun ko sese de Eko, oun kii se ara oke ni Ikeja, onitohun a da ara re lebi.

Idi ni pe awon ona keekee kan ti eniyan maa n ba jade ni agbegbe Ijoba Ibile Ikeja Local Government Area ni biriiji gbankogbi naa ti yi kadara won pada.

Lati jade si ona Iyana-Ipaja tabi Agege bayii, a ni lati gun afara agbayanu yii, yato si yiya bara si awon koro-koro ti a n to nigba kan.

Sugbon ti oju awako ati awon arinse ba ti wa da si idan ti biriiji yii je, fanda-fanda ni oluware yoo maa yan, ti okan re yoo si maa kan saara si Sanwo-Olu.

Ki a ma paro, ka ma se’ke, afara Ikeja Overpass nla yii je okan pato ninu opo aseyori malegbagbe gomina naa.

Sibesibe, ti a ba n wo itesiwaju to ti ba Eko laarin odun kan seyin ti Sanwo-Olu bere isejoba eleekeji re, a yoo ri i pe kii se keremi.

Bi o se n se oniruuru ona lo n se afara moto ati ti elese.

Niwon igba to wa je pe arise ni arika, ti arika je baba iregun, ijoba naa ti so pe ti a ba ka a ni meni, meji, ona eedegberin o le meji (172) ni oun ti pari laarin odun kan seyin o, ti eyi si ja si ona kilomita to le ni 177.

O wa fi kun un pe, pelu aijafira, ise n lo lowo lori ona to je igba o le ni aadota ati meta – 253.

Bi awon yii se n lo lowo naa ni ise afara to maa n gbon owo julo ko duro.

Oludamoran Pataki lori oro Ohum Amudagbasoke ba Ilu (Special Adviser on Infrastructure), Alagba Olufemi Daramola, lo so eyi di mimo lojo Jimoo, ojo keta osu karun-un odun yii.

O se alaye naa lasiko to n ba awon oniroyin soro lori aseyori Ijoba Sanwo-Olu pelu Igbakeji re, Dokita Obafemi Hamzat.

Pelu idunnu ati ifowosoya ni Daramola se ran awon ara ilu leti pe ise si n lo ni pereu lori awon akanse ise miiran, to si mu u da won loju pe, laipe lai jinna, Sanwo-Olu yoo se awon ise naa ni asepe.

Lara awon wonyi ni afara ti yoo so Ojota ati Opebi po (Opebi-Link Road); ti Abiola-Onijemo Link Road, ti yoo so College Road ati awon adugbo bii Ajayi Street, Ogba po mo Aruna/Obawole/Iju-Ishaga ni Ifako-Ijaiye.

Olubadamoran Pataki naa fi kun un pe lara awon ise pataki to tun n lo lowo ni ona Babafemi Dada (onibiriiji) lo si Yinka Folarin-Jamiu Lawal-Shalom Academy Road ni Ijoba Ibile Alimosho; ati awon pataki miran bee ni agbegbe LASU, Iba, Baruwa, Amuwo Odofin, Popona Badagry, Mazamaza, Eti-Osa ati Epe Alaro, Omo Ogunmodede.

Ko tan sibe o. Daramola so pe ise si n lo witiwiti lori atunko osibitu awon omode Massey Street Children’s Hospital, eyi ti yoo ni beedi ogojo o din mewaa (150) ati

ile iwosan gbogbo gboo nla ti General Hospital, Ojo.

Ijoba tun n ba ise lo ni pereu lori kiko ile ise panapana ti Kosofe ati Ijede Fire Stations; ile awon akekoo ti Students’ Union Arcade ni Ojo; kiko abala ikawe Faculty of Management Sciences Complex Phase 1, ile ikawe ti Central Library Phase 2A, atunko ilegbee awon akekoo ti Nigerian Law School Hostel, Lagos Campus to fi mo atunko alasodoge enu abawole ifafiti nla ti Eko, iyen Remodelling of the University of Lagos Main Gate.

Daramola tun menuba ise to n lo kaakiri LASU Business School, LASUSTECH, ati ni Alausa pelu Onikan.

Ohun nla kan ti yoo tun mu inu awon omo Eko dun gidi ni bi ijoba Sanwo-Olu se n so ilu di tuntun ni awon ibi pataki kan. Lara awon yii ni isodoge aafin Oba Ilu Eko – Renovation of Iga Iduganran – ati kiko amusapejuwe aafin Oba Badagry iyen Prototype Oba’s Palace, ni Badagry, nibi ti Sanwo-Olu tun ti n ba ise lo laiweyin lori kiko ile igbafe oniyara meji le laadota 52-Bedroom Hotel ati ibudo awon eniyan pataki-pataki ti VIP Chalets, ni Badagry bakan naa.

 

 

 

 

Ọmọ ‘Yahoo’ márùndínlọ́gbọ̀n kó páńpẹ́ EFCC n’Ílọrin, akẹ́kọ̀ọ́ ló pọ̀ nínú wọn

Ọmọ ‘Yahoo’ márùndínlọ́gbọ̀n kó páńpẹ́ EFCC n’Ílọrin, akẹ́kọ̀ọ́ ló pọ̀ nínú wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí àwùjọ ṣe ń gé àwọn ọ̀dọ̀ wọ̀nyí lọ́wọ́ ni wọ́n ń bọ̀ọ̀ka, bó ṣe jẹ́ pé kò dín ní géńdé márùndínlọ́gbọ̀n (25), tọwọ́ àjọ tó ń gbógun ti ìwà jìbìtì àti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku, Economic Financial and Crimes Commission (EFCC), bà láwọn ìgboro ìlú Ìlọrin, ní ìpínlẹ̀ Kwara, l’ọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 yìí. Wọ́n ní jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára tí wọ́n ń pè ní ‘Yahoo Yahoo’ làwọn ọ̀dọ́ náà ń ṣe.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Alukoro EFCC, Ọ̀gbẹ́ni Dele Oyewọle, fi léde nílùú Ilọrin, ló tí sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn afurasí ọ̀daràn tí wọ́n mú náà ni wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, ṣùgbọ́n kàkà kí wọ́n dojúkọ ẹ̀kọ́ wọn, ìwà gbájú-ẹ̀ ni wọ́n ń jù lórí íńtánẹ̀tì, ó ní àwọn inú ilé tí àwọn afurasí náà fara pamọ́ sí lọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n.

Lásìkò tọ́wọ́ bá wọ́n, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gínní mẹ́fà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fóònù ìgbàlódé, àwọn kọ̀ǹpútà àgbélétan, àtàwọn nǹkan mí-ìn tó lòdì sófin ni wọ́n bá níkàáwọ́ wọn.

EFCC, ẹ̀ka tìlú Ìlọrin tó ṣiṣẹ́ náà tí taari àwọn afurasí ọ̀daràn yìí sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fún ìwádìí tó lóòrìn, kí wọ́n lè fojú wọn balé-ẹjọ́ láìpẹ .

Èyí làwọn òṣèré tíátà tó gba àmì ẹ̀yẹ AMVCA ọdún 2024

Èyí làwọn òṣèré tíátà tó gba àmì ẹ̀yẹ AMVCA ọdún 2024

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbàlagbà bọ wọ́n ní kúuṣẹ ní-ín mórí oníṣẹ́ yá láti tèsíwájú iṣẹ́ rere.
Gbajúgbajà òṣèré tíátà Kehinde Bankole àti Wale Ojo ló gba àmì ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin àti òṣèrékùnrin tó dáńtọ́ jù, tí sinimá Breath of Life sì gba sininmá tó dá a jù níbi àmì ẹ̀yẹ AMVCA ọdún 2024.

Àwọn òṣeré méjèèjì fìdí àwọn akẹgbẹ́ wọn janlẹ̀ láti gba àmì ẹ̀yẹ náà.

Àmì ẹ̀yẹ Africa Magic Viewers’Choice Award ló jẹ́ àmì ẹ̀yẹ kan tó lààmìlaka fún àwọn òṣèré nilẹ Áfíríkà.

Ka ìpele àmì ẹ̀yẹ àti àwọn tó jáwé olúborí
Trailblazer Award

Chimezie Imo OLUBORI
Industry Awards

Esther Idowu Phillips (Iya Rainbow)
Richard Mofe Damiji (RMD)
Best Digital Content

National Treasure – Adebola Adeyela (Lizzy Jay)
Medical Negligence and Copyright Infringement – Isaac
Ayomide Olayiwola (Layi Wasabi) OLUBORI
Hello Neighbour – Elozonam Ogbolu, Lina idoko and Jemima Osunde
The Boyfriend – Maryam Apaokagi-Greene
Best Indigenous Language Film (West Africa)

Mami Wata (CJ Fiery Obasi)
Jagun Jagun (Femi Adebayo) OLUBORI
Ijogbon (Kunle Afolayan)
Orisa (Odunlade Adekola)
Nana Akoto (Kwabena Gyansah)
Best Supporting Actor

Alexx Ekubo (Afamefuna)
Demola Adedoyin (Breath of Life) OLUBORI
Itele d Icon (Jagun Jagun: The Warrior)
Gregory Ojefua (This is Life)
Timini Egbuson (A Tribe Called Judah)
Levi Chikere (Blood Vessel)
Ropo Ewenla (Over the Bridge)
Best Supporting Actress

Joke Silva (Over the Bridge)
Fathia Williams (Jagun Jagun – The Warrior)
Bimbo Akintola (The Black Book)
Genoveva Umeh (Breath of Life) OLUBORI
Eliane Umuhire (Omen)
Tana Adelana (Ijogbon – Chaos)
Ejiro Onojaife (The Origin: Madam Koi Koi)
Best Lead Actor

Wale Ojo (Breath of Life) OLUBORI
Stan Nze (Afamefuna)
Marc Zinga (Omen)
Gideon Okeke (Egun)
David Ezekiel (Blood Vessel)
Richard Mofe Damijo (The Black Book)
Adedimeji Lateef (Jagun Jagun – The Warrior)
Gabriel Afolayan (This is Lagos)
Best Lead Actress

Segilola Ogidan (Over the Bridge)
Lucie Debay (Omen)
Omowunmi Dada (Asiri Ade)
Ireti Doyle (The Origin: Madam Koi Koi)
Adaobi L. Dibor (Blood Vessel)
Evelyne Ily (Mami Wata)
Kehinde Bankole (Adire) OLUBORI
Funke Akindele (A Tribe Called Judah)
Best Cinematography

Mami Wata (Lílis Soares)
Blood Vessel (Gideon Chukwu)
Over The Bridge (KC Obiajulu) OLUBORI
Breath of Life (Ola Cardoso)
Jagun Jagun – The Warrior (Adeoluwa Owu)
Ijogbon – Chaos (Adekunle Nodash Adejuyigbe)
Omen (Joachim Philippe)
Best Editing

Chuka Ejorh And Onyekachi Banjo (Over The Bridge)
Holmes Awa (Breath of Life)
Alex Kamau And Victor Obok (Volume)
Dayo Nathaniel (Ogeere – Earth)
Antonio Ribeiro (The Black Book) OLUBORI
Nathan Delannoy (Mami Wata)
Best Sound Design

Ava Momoh (Over the Bridge)
Daniel Pellerin and Amin Bhatia (Kipkemboi)
Grey Jones Ossai x2 (Breath of Life and Blood Vessel) OLUBORI
Samy Bardet (Mami Wata)
Best Art Direction

Blood Vessel (Victor Akpan)
Over The Bridge (Abisola Omolade) OLUBORI
Breath of Life (Okechukwu Frost Nwankwo, Kelechi Odu)
The Black Book (Pat Nebo and Chima Temple)
Jagun Jagun: The Warrior (Tunji Afolayan)
Mami Wata (C.J Fiery Obasi)
Omen (Eve Martin)
Best Costume Design

Demola Adeyemi (Over The Bridge)
Bolanle Austin Peters, Ituen Basi, Folake Coker and Clement Effanga (Funmilayo Ransome-Kuti)
Lola Awe (Jagun Jagun: The Warrior) OLUBORI
Bunmi Demilola Fashina (Mami Wata)
Daniel Obasi (Breath of Life)
Best Makeup

Francesca Otaigbe (Over the Bridge)
Campbell Precious (Mami Wata) OLUBORI
Hadizat Gambo (Mojisola)
Hakeem Onilogbo (Jagun Jagun – The Warrior)
Feyisayo Oyebisi (A Tribe Called Judah)
Best Writing TV Series

Skinny Girl in Transit (Season 7)
Wura (Season 2)
Visa on Arrival
MTV Shuga Naija
Volume- Mona Ombogo OLUBORI
Masquerades of Aniedo
Slum King
Best Writing in a Movie

Breath of Life (BB Sasore)
Over The Bridge (Tosin Otudeko)
Funmilayo Ransome-Kuti (Tunde Babalola) OLUBORI
Jagun Jagun: The Warrior (Adebayo Tijani)
Afamefuna (Anyanwu Sandra Adaora)
A Tribe Called Judah (Olufunke Ayotunde Akindele, Collins Okoh and Akinlabi Ishola)
Mami Wata (CJ Fiery Obasi)
Best Director

Moses Inwang (Blood Vessel)
Adebayo Tijani And Tope Adebayo (Jagun Jagun – The Warrior)
BB Sasore (Breath of Life) OLUBORI
Johnscott Enah (Half Heaven)
C.J. Fiery Obasi (Mami Wata)
Kayode Kasum (Afamefuna)
Tolu Ajayi (Over The Bridge)
Best Movie

Funmilayo Ransome-Kuti
Breath of Life OLUBORI
Over The Bridge
Blood Vessel
A Tribe Called Judah
The Black Book
Mami Wata
Best Documentary

Ormoilaa Ogol (The Strong One)
Lobola, A Bride’s True Price? OLUBORI
Empalikino (Forgiveness)
The Water Manifesto: Osun (Water for Gold)
Sowing Hope
Best Scripted Series

Volume
Wura (Season 2)
Slum King
Itura OLUBORI
Chronicles
Best Unscripted Series

Lol Naija (Season 1)
Nightlife In Lasgidi
The Real Housewives Of Lagos (Season 2)
Gh Queens (Season 2) OLUBORI
Mutale Mwanza Unscripted (Season 1)
Best Indigenous Language (East Africa)

Where The River Divides
Ormoilaa Ogol (The Strong One) OLUBORI
Wandongwa
Nakupenda
Itifaki
Best Indigenous Language (South Africa)

Service To Heart
Uncle Limbani
Motshameko O Kotsi OLUBORI
Best Multichoice Talent Factory Movie

Grown
Her Dark Past OLUBORI
Somewhere in Kole
Full Time Husband
The 11th Commandment
Mfumukazi
Best Scripted M-Net Original

Slum King OLUBORI
Half Open Window
Itura
The Passenger
Magic Room
Best Unscripted M-Net Original

What Will People Say
The Irabors’ Forever After
Nwuyee Bekee (Foreign Wives) OLUBORI
Date My Family Zambia
Royal Qlique (Season 2)
Best Indigenous M-Net Original

The Passenger
Nana Akoto
Apo
Irora Iya OLUBORI
Love Transfusion (Kiapo Cha Damu)
Best Short Film

T’egbon T’aburo
Broken Mask OLUBORI
Eighteenth Year
Man and Masquerades
A Place Called Forward

Èèmọ wọ̀ọ́lu! Ìbálòpọ̀ akọ sákọ làwọn arákùnrin wọ̀nyí yàn lááyò.

Èèmọ wọ̀ọ́lu! Ìbálòpọ̀ akọ sákọ làwọn arákùnrin wọ̀nyí yàn lááyò.

Ọrẹ Òtìtọ́jù
Bí òpin ayé bá ti súnmọ́lé, gbogbo n tó sèèmọ̀ lojú yóó má rí, bí etí ṣe n gbọ́ ọ èyí náà ló bí ìròyìn òpín ayé yìí ní bí àwọn géndé mọ́kànlá kan, tí gbogbo wọ́n jẹ́ ara ikọ̀ ajínigbé kan, tí kò sákolo àwọn ọlọ́paa ìpínlẹ̀ Eko báyii, agbègbè táwọn olówó pọ sí jù ni Lẹkki lọwọ́ ti bà wọ́n, wọ́n se àpatẹnujẹ́wọ́ pé iṣẹ́ mẹ́ta táwọn yán láàyò, lójoojúmọ́ ni ìfipá bá ọkùnrin ẹlẹ́gbẹ́ àwọn láṣepọ̀, lílọ́nilọ́wọ́gbà àti ìjínigbé gbowó tó jọjú.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii lawọn afurasi ọdaran naa ka boroboro fawọn agbofinro lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko to wa lagbegbe Ikẹja.

Wọn jẹwọ pe ni tawọn o, ko sohun to kan awọn pẹlu obinrin, obinrin ki i wọ awọn loju, awọn ki i si i ṣe akọlu si wọn, amọ awọn ọkunrin to san-angun, to duroo re, to si ri jajẹ lawọn maa n foju si lara lati ṣe ni ṣuta.

Ọkọọkan awọn afurasi yii ṣalaye bi wọn ṣe wa ara wọn kan, ti wọn si da ẹgbẹ abẹya-kan-naa-lo-pọ silẹ, ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ buruku wọn.

Wọn jẹwọ pe nigba ti ọkunrin kan ba ti ko sakolo awọn, awọn maa ba tọhun laṣepọ lati iho idi rẹ, gbogbo erekere ati ibalopọ ọran naa lawọn yoo si ka silẹ ninu kamẹra tabi foonu, eyi lawọn maa lo lati fi gba owo nla lọwọ irufẹ ẹni to ṣagbako wọn bẹẹ, tawọn yoo si tun maa dunkooko mọ ọn lẹyin tawọn ba ti tu tọhun silẹ tan.

CSP Kẹhinde Oni, ti i ṣe ọga ọlọpaa to lewaju ikọ awọn agbofinro akanṣe kan, eyi ti Kọmiṣanna wọn l’Ekoo, CP Fayọade Adegoke Mustapha, da silẹ laipẹ yii ṣalaye pe, “ọkunrin lo daran lọwọ awọn afurasi oniṣekuṣe ẹda wọnyi. O ni niṣe ni wọn maa n fipa mu ẹnikẹni to ba lugbadi wọn lọ si eyikeyii ninu awọn ile olowo nla ti wọn n gbe lawọn agbegbe bii Lẹkki, Ajah, Badore, ki wọn too foju onitọhun ri mabo, wọn aa ba a sun lọran-an-yan, wọn yoo si gba dukia ati owo nla lọwọ ẹ.

O ni niṣe ni wọn maa n dibọn pe ejẹnti lawọn, iṣẹ abaniwale, tabi kiateka lawọn n ṣe, ipolowo yii lori ẹrọ ayelujara ni wọn fi n tan awọn ọkunrin titi ti ẹni to nilo iranlọwọ wọn, ti ko si fura, yoo fi ko sakolo wọn.

Ọkan ninu awọn afurasi yii, Joel Esama, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, to n ṣiṣẹ okoowo POS ni Jakande Estate, ni Lẹkki, sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Edo loun, ileewe sẹkọndiri loun lọ, oun ko si ṣetan nibẹ toun fi wa s’Ekoo, toun si n ṣiṣẹ alase ni otẹẹli kan. Oun maa n ṣe ọṣẹ olomi (liquid soap) ta lawọn otẹẹli, oun si tun n ṣe okoowo POS tawọn ẹlẹgbẹ oun maa n lo lati lu awọn ti wọn ba ja lole ni jibiti. O jẹwọ pe ọkunrin kan to n jẹ Edet lo fọna iṣẹ buruku naa han oun toun fi dara pọ mọ wọn.

O ni, “Ohun ta a saaba maa n ṣe ni pe a o tan ẹnikẹni to ba ko sakolo wa wọ ọkan ninu awọn ile ta a rẹnti, to ba ti wọn yara, awa meji la maa fipa mu un lati ba a laṣepọ, iho idi la maa n ba ṣe kinni, ni gbogbo asiko ta a ba n ṣe e, awọn yooku wa aa rọ wọle lati yara keji, wọn aa si bẹrẹ si i ya fidio loriṣiiriṣii,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.

Ǹ jẹ́ àǹfààní tàbí àlèébù wà nínú kí ìjọba fífi owó kún owó òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè wa?

Ǹ jẹ́ àǹfààní tàbí àlèébù wà nínú kí ìjọba fi owó kún owó òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè wa?

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé kò sí ohun tó dára tí kìí ní àléébù àìdára tirẹ̀, lórí ọ̀rọ̀ àlékún owó òṣìṣẹ́; àwọn òṣìṣẹ́ kì í fẹ́ gbà pé àléébù kankan wá nínú kí àlékún gorí owó ọ̀yà owó oṣù wọn.

Àwọn òṣìṣẹ́ ò lẹ́bi láti bẹ̀rẹ̀ fún àfikún àlékún owó nítorí àwọn bí ọrọ̀ ajé ṣe n sòjòjò tí gbogbo nǹkan gbówó lórí, kódà àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé gan náà fìdí rẹ múlẹ̀ pé àǹfàní tó wà nínú ṣíṣe àlékún owó òṣìṣẹ ju àléébù rẹ̀ lọ.̀

Ní orílẹ̀ èdè wa Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ti fi ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí márùndínlógójì kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ.́ Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nílẹ̀ wa Nàìjíríà ń sọ pé kí ìjọba ṣe àtúngbẹ̀yẹwò owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ, tí wọn sì ń bèèrè fún ₦615,000 gẹgẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ. Èyí kò ṣẹyìn bí gbogbo nǹkan ṣe ń gbówó lórí. Ọ̀
̀wọ́n gógó àwọn ọjà ní Nàìjíríà ti wọ ìdá 33.20 gẹgẹ́́
bí àtẹjáde tí àjọ tó ń rí sí òǹkà ní Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics ṣe gbe jáde. Pẹlú bí àwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí yìí, àwọn onímọ̀ sọ pé ìjọba nílò láti rí pé wọ́n pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn kan kí owó tí wọ́n bá máa fi kún owó òṣìṣẹ le ní ìtumọ̀.

Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Imí ẹran nídìí èèyàn,ọ̀rọ̀ rúnrùn,ó ti wá di sísín fiìmù bí àṣà àwọn olóyìnbó tí kò ṣeé wò tán bí awuyewuye ìjà ilẹ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ nílé-ẹjọ́ Májísírèètì kan nílùú Ìlọrin, láàrin Ẹlẹjù, tìlú Ẹ́jù, Ọba Mathew Idowu Ajíbóyè, àti Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-Ọ̀bà, Ọba Àlàájì Maroof Afọ́láyan Adébáyọ̀, bí fọ́nrán fídíò ṣe ṣàfihàn bí àwọn olùpẹ̀jọ́, Ọba Ajiboye, ṣe rán àwọn jàndùkú kí wọ́n máa lu Ọlọ́bà, tí wọ́n sì ń yẹ̀yẹ́ rẹ̀ lásìkò tí adájọ́ ní òun fẹ́ wo fọ́nrán fídíò ọ̀hún.

Nínú fọ́nrán fídíò náà ni àwọn janduku ti lọọ ká Ọlọ́bà àtawọn alátílẹ́yìn rẹ̀ mọ́lé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n ń lù í, lórí ẹ̀sùn pé òun ló wà nídìí rògbòdìyàn tó ń wáyé nínú ìlú.

Nínú ìlú Ẹ̀jù kan náà ni àwọn méjèèjì wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ni àwọn Ọlọ́bà ya kúrò lára Ẹ̀jù, tí wọ́n sì ń jẹ́ Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-̀Ọbà, èyí tí wọ́n ní àwọn ti dá dúró, tí wọ́n sì ní ọba tiwọn.

Ohun tí ó ṣokùnfà awuyewuye ọ̀hún ni pé Ẹlẹjù tìlú Ẹ́jù, Ọba Matthew Ìdòwú Ajíbóyè, ta ilẹ̀ baba àwọn Ọlọ́ba, tó sì ní ọba òun ba lórí ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n àwọn Ọlọ́ba yarí pé àwọn kì í ṣe ara Ẹ̀jù mọ́, ni wàhálà bá bẹ̀rẹ̀.

Ọba Ajíbóyè, wọ́ Ọlọ́bà lọ sílé-ẹjọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rí fídíò tú àṣírí bí Ọba Ẹ̀jù ṣe ní kí wọ́n máa lu Àlàájì Maroof Afọláyan tó jẹ́ Ọlọ́bà, tí wọ́n sì fà á láṣọ ya, léyìi tí wọ́n ní ó ta ko òfin ilẹ̀ wa. Fídíò náà tún ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe ní kí olórí ẹbí ilé Ọlọ́bà, ìyẹn Rahmọn Ọmọniyì, dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú tipátipá, tí wọ́n sì ń ṣọ̀rọ̀ burúkú sí i. Lẹyìn tí wọ́n wo fídíò ọ̀hún tán ni Onídàájọ Muhammad Adams, gba fídíò náà wọlé gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 yìí.

Ikú oró! Wọ́n gún akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH pa l’Ogbomọṣọ

Ikú oró! Wọ́n gún akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH pa l’Ogbomọṣọ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àdúrà kí màjèṣín má tojú òbí rọ̀run ni gbogbo abiyamọ má a ń gbà ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ kan ti ṣẹ̀ wọ́n nílé ẹ̀kọ́ gíga Ladoke Akintọla University of Technology ( LAUTECH), tó wà nílùú Ogbomọṣọ, níìpínlẹ̀ Ọyọ, báyìí, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gún ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì náà, Adedokun Basit Ọlamilekan, lọ́bẹ pa.

Ija ti akọroyin wa ko ti i mọdi ẹ bayii, la gbọ pe o waye laarin Ọlamilekan pẹlu awọn kan ládùúgbò ti wọn n pe ni Under-G, niluu Ogbomọṣọ, lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.

Oun ta a gbọ ni pe, laarin ọpọlọpọ iṣẹju ni wọn fi n tahùn sira wọn, ti ẹnikan ko gba fẹnikan laarin ikọ mejeeji.

Lẹyin ti igbiyanju lati pari ija naa ko sesoore fawọn eeyan to wa nibẹ lọkan ninu awọn ọkunrin naa gun Ọlamikekan lọbẹ nigbaaya, oju-ẹsẹ lo si ti mẹyin lọ silẹ.

Ni kete t’ọmọkunrin naa ti ṣubu silẹ to bẹrẹ si i japoro iku lawọn eeyan naa ti sa lọ, ti ẹnikan ko si mọ wọn titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Amọ ṣaa, awọn araadugbo ọhun du ẹmi ẹ pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi ibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, ọmọkunrin naa ti dagbere faye.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ ẹni to huwa ọdaran yii gan-an, awọn kan sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn eeyan naa.

Tẹ o ba gbagbe, laduugbo ti wọn pa akẹkọọ LAUTECH yii si naa lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣoro laipẹ yii, eyi to mu ki ibọn ọkan ninu awọn ọlọpaa ti awọn araadugbo naa pe lati waa daabo bo wọn fi ba ọmọkunrin kan, to si tibẹ gbẹmi-in mi.

Akinkanju ọmọ ni wọn pe oloogbe yii, nitori bo ṣe n lọ sileewe lo tun n ṣiṣẹ atóríṣe ládùúgbò Under-G, nigboro ìlú Ogbomọṣọ

Adájọ ní kí wọ́n fi ìwé wọ́ Gani Adams wa sí kóòtù lọ́nàkọnà

Adájọ ní kí wọ́n fi ìwé wọ́ Gani Adams wa sí kóòtù lọ́nàkọnà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá ò bá tíì tán, èèyàn nlá ò níín
tíì sinmi ẹjọ́ bí ó ṣe jẹ́ pé
kò ní í pẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní í jìnnà mọ́ báyìí, tí àwọn akọni ọmọ Yorùbá méjì nnì, Ààrẹ Ọ̀nà-Kakanfò ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams, àti ajìjàgbara fún ìran Yorùbá nnì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo ayé mọ̀ sí Sunday Igboho, yóò kojú ara wọn ní kóòtù pẹ̀lú bí ilé-ẹjọ́ ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìwé ìpẹ̀jọ́ pé Gani Adams wá sí kóòtù.

Sunday Igboho lo pe Gani Adams lẹjọ, o lọkunrin naa ba oun lorukọ jẹ, bi ibanikorukọjẹ ọhun si ṣe ba oun lọkan jẹ to loun ṣe fẹ ki wọn fiya jẹ oun naa to, nitori naa, ki ile-ẹjọ paṣẹ fun olujẹjọ naa, to tun jẹ ọga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, lati sanwo nla, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500 m).

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ohun ti olupẹjọ tori ẹ pẹjọ ko ṣẹyin akasilẹ ohun kan to jẹ itakurọsọ to waye laarin Gani Adams ati ọkunrin kan ti wọn pe ni Nuru Banjọ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021, eyi ti awọn oniroyin kan gbe sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii.

Ninu akasilẹ ohun naa la gbọ pe olujẹjọ ti ṣapejuwe olupẹjọ gẹgẹ bii apaayan to ṣokunfa iku gbajumọ oloṣelu kan lorileede yii, Oloye Bọla Ige.

Ṣugbọn Igboho sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọkunrin naa, n lo ba gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ fiya nla jẹ ọga awọn OPC naa fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Lati oṣu to kọja lolupẹjọ ti pẹjọ naa, o si yẹ ki igbẹjọ ti bẹrẹ lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ṣugbọn eyi ko ṣee ṣe nitori olujẹjọ ko fara han ni kootu, bẹẹ ni ko si agbẹjọro tabi ẹnikẹni to ṣoju ẹ nile-ẹjọ.

Nigba ti igbẹjọ ọhun tun waye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti akọda kootu ṣalaye pe oun ko lanfaani lati fun olujẹjọ niwee ipẹjọ, nitori naa, ko jọ pe ọkunrin naa mọ pe ẹnikẹni pe oun lẹjọ si kootu yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti mo dele olujẹjọ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja, l’Ekoo, aṣọna rẹ to yọju si mi lati inu ile sọ pe ọga oun (Gani Adams) ko si nile”.

Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ M.I. Sule, fun akọda ile-ẹjọ naa lanfaani lati lo ọnakọna mi-in to ba gba lati ri i pe iwe ipẹjọ ọhun tẹ ọga awọn OPC naa lọwọ.

Adajọ ni “Mo ti wo akọsilẹ gbogbo akitiyan akọda lati fun olujẹjọ funra rẹ niwee ipẹjọ, mo si ri i pe iwe ọhun ko ti i tẹ ẹ lọwọ nitori akọda ko ba a nile ẹ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja. Nitori naa, mo pa a laṣẹ pe ki wọn lo gbogbo ọna yoowu ti olujẹjọ yoo fi mọ pe oun lẹjọ i jẹ ni kootu yii, koda, bo gba ki wọn lẹ iwe ipẹjọ naa mọ geeti ile tabi ara ogiri ile ẹ”.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní Chad

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní Chad

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 ni àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Chad yóò dìbò láti yan Ààrẹ tuntun.

Àwọn olùdíje mẹ́wàá ló ń díje, tí wọ́n sì ń jìjàdù kí ipò náà já mọ́ àwọn lọ́wọ́.

Ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè Chad ti ṣe àtẹ̀jáde orúkọ àwọn olùdíje tí wọ́n ti fi èròńgbà wọn hàn láti díje dupò Ààrẹ náà.

Ètò ìdìbò ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn ikú Ààrẹ àná, Idriss Deby tó dágbére fáyé lórí ipò lọ́dún 2021.

Ọmọ rẹ̀, Mahamat Idriss Deby, tí òun náà ń díje dupò Ààrẹ, ló gba ipò bàbá rẹ̀ láti inú oṣù kẹrin ọdún 2021 tí bàbá rẹ̀ tí jáde láyé.