Ọ̀pọ̀ búrẹ́dì tó wà níta kò ní nọ́ńbà— Àjọ NAFDAC
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ oúnjẹ, òògùn àtàwọn ohun èlò mìíràn nílẹ̀ yìí, National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC), ti pariwo síta pé ọ̀pọ̀ búrẹ́dì tí wọ́n ń tà káàkiri ni kìí ṣe ojúlówó burẹdi tó yẹ káwọn èèyàn máa jẹ, nítorí púpọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún nílé iṣẹ́ wọn tó jẹ́ pé kò gbámúsé, àgàgà pẹ̀lú bí àwọn tó ń ṣe burẹdi ṣe ń lo èròjà dídùn tí wọ́n ń pè ní saccharine dípò ṣúgà, nítorí bí ṣúgà ṣe ti gbówó ńlá lórí.
Bakan naa ni wọn jawe ikilọ fawọn to n pọn omi mimu inu lailọọnu ati ike ta, awọn to n ta oogun oyinbo, titi mọ awọn to n pese oniruuru ọja mi-in, lati yago fun tita ayederu ọja tabi eyi ti eroja rẹ ki i ṣe ojulowo.
Adari ajọ NAFDAC ni apa iha Iwọ Oorun orilẹ-ede yii, Arabinrin Roseline Ajayi, lo ṣekilọ yii lasiko ipade awọn tọrọ kan ti ajọ NAFDAC ṣagbekalẹ rẹ niluu Ibadan lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
O ni pupọ esi ayẹwo tileeṣẹ awọn ṣakojọ rẹ lasiko ayẹwo tuntun ti wọn ṣe laipẹ yii fihan pe oogun tijọba fofin de atawọn ti ko lontẹ ajọ NAFDAC, ni pupọ awọn to n ta oogun oyinbo n ta kiri.
Ajayi ni pupọ awọn ileeṣẹ to n pese nnkan ni wọn kọ lati tẹle ilana ti wọn la kalẹ lati maa paaki ọja wọn sinu lailọọnu tabi ohun yoowu ti wọn n pọn ọn si, ati ibi ti wọn n ko wọn pamọ si.
“Lẹnu ọjọ mẹta yii, a ri i pe ọpọlọpọ burẹdi ti wọn n ta ninu ọja ni ayẹwo ta a n ṣe fun wọn ko jade daadaa, nitori pe saccharine lawọn to n ṣe wọn n lo latari ṣuga to wọn. Awọn eroja to le ṣakoba fun ilera awọn to n jẹ ẹ ni wọn n lo. A ko ṣai mọ bi gbogbo nnkan ṣe ri niluu latari eto ọrọ-aje to dẹnu kọlẹ, ṣugbọn ileeṣẹ yii ko ni i tori bẹẹ ma ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ.
O ṣe pataki ki a mọ pe a ko le fọwọ yẹẹrẹ mu ọrọ ohunkohun ti wọn ba n pese, ti ajọ yii yoo si ṣamojuto rẹ lati ri i pe o jẹ ojulowo”.
Ajayi fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti ipade ti wọn ṣe yii da le lori ni lati wa ifọwọsowọpọ ati atilẹyin to yẹ lọdọ awọn tọrọ kan fun ileeṣẹ naa lati le jiṣẹ ti wọn gbe lọwọ gẹgẹ bi oludaabo bo ilera araalu.