Home Blog Page 26

Àwọn tó ní kí Ganduje lọ rọọ́kún nílé kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ APC – Abdullahi Abbas

Àwọn tó ní kí Ganduje lọ rọọ́kún nílé kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ APC – Abdullahi Abbas

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC níìpínlẹ̀ Kano ti sọ pé àwọn yóó gbé ìgbésẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe jáwé lọ rọọ́kún nílé fún Gómìnà tẹ́lẹ̀rí níìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Umar Ganduje, ẹni tó tún jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún lápapọ̀.

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni ikun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Dawakin Tofa, iyẹn nibi ti Ganduje ti jade kede pe awọn ti jawe lọ rọọkun nilẹ fun baba naa.

Ko pẹ ti ikede naa bọ sita ni awọn agbaagba ẹgbẹ APC ni Dawakin Tofa naa sọrọ sita wi pe ala ti ko le ṣe ni ikede ọhun, ati pe ko le fẹsẹ mulẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kano, Abdullahi Abbas nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ni wọn kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa.

Abbas sọ pe awọn to gbe ikede naa sita lo jẹ pe wọn sunmọ awọn oloṣelu to jẹ pe ẹgbẹ NNPP to n ṣakoso.

O ni awọn ti ṣagbeyẹwo iwe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa lati agbegbe ti Ganduje ti wa, to si ni ko si eyi to jẹ oloye ẹgbẹ ninu wọn.

“Mẹtadinlọgbọn ni awọn to wa lati agbegbe kọọkan, a si yẹ wọn wo, a rii pe ko si eyi to jẹ oloye ninu wọn.”

Bakan naa lo sọ pe Haladu Gwanjo to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ti sọ pe oun yoo gba ile-ẹjọ lọ lati lọ ja fun ẹtọ ohun.

Abdullahi Abbas nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “Eléyìí kó ní nnkan ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti wa, ìpinu tí ìjọba Kano àti ẹgbẹ́ òṣèlú wọn gb kalẹ̀ lèyí, a sì ríi pé ọ̀nà láti fi tàbùkù Ganduje ni.”

Bí Ọba Agbábìàká Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ l’Ékòó se papòdà 

Bí Ọba Agbábìàká Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀  l’Ékòó se papòdà

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Kábíyèsí Ọba Kàbírù Agbábíàká, Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó ti jáde láyé; lẹ́yìn ádùrá ìtúnu ààwẹ̀ ní Ọjọ́rú nílùú Èkó.

Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni Kábíyèsí Agbábíàká í ṣe kí ó tó jáde láyé. Ìwádìí fi yé wa pé Ọba Ọsọ́lọ̀ tó wàjà yìí jẹ́ ọba alayé tí kì í ṣe aládàníkànjọpọ́n, tí ó ṣì fi ayé rẹ̀ sin ìlú Ìsọlọ̀ àti ìpínlẹ̀ Èkó títí tí ọlọ́jọ́ fi dé. Ọba Agbábíàká ti fi ipa rere lélẹ̀ léyì táwọn èèyàn kò le gbàgbé láéláé.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀, Họnọrebu Ọlásojú Adébáyọ̀ ló fìdí ìṣẹlẹ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta. Ó sọ pé “Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú ló fún òun láṣẹ láti kéde ìpapòdà Ọba Ìsọlọ̀, Kábíyèsí Kàbírù
Àlàní Adélàjà Agbábíàká Adéọlá Olúṣi Kẹta lọ́jọ́ kẹwàá oṣù Kẹrin ọdún 2024 yìí”.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babájídé Sanwó-Olú ń ṣèdárò Ọba Agbábíàká tó wàjà lọ́jọ́ ọdún ìtúnu ààwẹ̀. Sanwó-Olú sọ pé ”pẹ̀lú ìbànújẹ ọkàn ni òun fi gba ìròyìn ìpapòdà Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀.

Gómìnà Sanwó-Olú kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti àwọn èèyàn Ìsọlọ̀ lórí ìpapòdà Ọba Agbábíàká. Kí Elédùà tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí orúkọ rere tí ó fi sílẹ̀ má bàjẹ́ láéláé.”

Òkùnkùn birimù gbalẹ̀,lẹ́yìn tí ‘jàmbá ‘ná wáyé ní ‘léṣẹ́ tó n pín iná mọ̀nàmọ́ná.

Òkùnkùn birimù gbalẹ̀,lẹ́yìn tí ‘jàmbá ‘ná wáyé ní ‘léṣẹ́ tó n pín iná mọ̀nàmọ́ná.

Gbọ́láhàn Quseem

Iléeṣẹ́ àjọ tó ń rí sí pínpín iná mọ̀nàmọ́ná ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Transmission Company of Nigeria, (TCN) ní í àwọn ti bomi pa ìjàmbá iná tó wáyé ní ẹ̀ka Afam Power Generating Station, èyí tó ṣokùnfà bí ẹ̀rọ tó ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná ṣe bàjẹ́.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ náà fi sórí ìkànnì ayélujára X rẹ ní ìjàmbá iná kan ló wáyé ní aago mẹ́ta kú ìṣẹ́jú mọ́kàndínlógún oru ọjọ́ Ajé tó sì ṣokùnfà dí dẹnu kọlẹ awọn ohun tí wọ́n fi ń pèsè iná ní Afam lll àti Afam Vl.

Adarí ẹ̀ka ètò mọnamọna ará ìlú ti iléeṣẹ́ TCN, Ndidi Mbah sọ pé, ìjàmbá iná náà ló jẹ́ kí àwọn pàdánù mẹ́gáwáàtì tó dín díẹ̀ ní irinwó, tó sì fa òkùnkùn birimù káàkiri àwọn agbègbè tó yẹ kí ẹ̀rọ náà pèsè iná fún.

Mbah sọ pé ẹ̀rọ náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà àti pé àwọn ní ìfarajìn láti ri dájú pé àwọn ń pèsè iná ọba.

Ṣáájú ni ìròyìn ti gbòde pé Iléeṣẹ́ tó ń rí sí pínpín iná mọ̀nàmọ́ná ti kéde pé ẹ̀rọ tó ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná tún ti dẹnu kọlẹ̀ àti pé òun ló fa ìdí tí àwọn ènìyàn kò fi ní iná káàkiri.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde láti ẹ̀ka Independent System Operator (ISO), ǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú méjìdínlógún oru ni ẹ̀rọ tó ń pèsè iná náà bajẹ.

Wọ́n ní ẹ̀rọ náà ti Okpai, Geregu àti Ibom kò máa pèsè ju mẹ́gáwáàtì 64.70 àmọ́ tó tún ti gbéra sí mẹ́gáwáàtì 266.50 báyì .

Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin mẹ́gáwáàtì ni Nàìjíríà máa ń pèsè ṣáájú àkókò yìí ṣùgbọ́n tó máa ń já ní gbogbo ìgbà látàrí afẹ́fẹ́ gáàsì tí kìí tó ní ọ̀pọ̀ ìgbà.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná tẹ̀ka Jos tí àdárí ètò gbogbo fi ránṣẹ́ sí àwọn aníbàárà wọn ni i wọ́n ti ṣàlàyé ìdí tí àwọn èèyàn fi wà nínú òkùnkùn birimù.

Láti inú oṣù Kejì ọdún 2024 ni iná mọ̀nàmọ́ná ti ń ṣe ṣégeṣège ní orilẹ-ede Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀ ilé sì ti ń wà nínu òkùnkùn.

Àdó olóró tó lé ọ̀ọ́dúnrún ni Iran ti fi ráńṣẹ́ sí Israel – Iléeṣẹ́ ológun Israel

Àdó olóró tó lé ọ̀ọ́dúnrún ni Iran ti fi ráńṣẹ́ sí Israel – Iléeṣẹ́ ológun Israel

Gbọ́láhàn Quseem

Iléeṣẹ́ ológun Israel ti sọ pé kò dín ni ọ̀ọ́duúnrún àdó olóró tó ti wá làti orílẹ̀-èdè Iran, Iraq ati Yemen si orílẹ́-èdè Israel nínú ìkọlù tó wáyé láìpẹ́ yi.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ologun, Lt Col Peter Lerner so pe, pupọ awọn ado oloro yi ni awọn ti ja lulẹ.

O fikun pe ileeṣẹ ologun ofurufu Israel ri ‘ranlọwọ gba lati ọwọ orilẹ-ede US, UK, France ati awọn miran.

Eyi ni igba akọkọ tawọn orilẹ-ede mejeeji yoo fi ọmọ ogun bara wọn ja, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n na ‘ka aleebu sira wọn.

Benjamin Netanyahu ti i ṣe Olootu Isrẹli, ti pepade igbimọ ologun ilu rẹ lori ọrọ yi lati mọ igbesẹ to ku gan-an.

Ni bayi naa, Iran ti leri ati gbẹsan lara Isreal lẹyin ikọlu si ileeṣẹ to n ri si ‘rinajo rẹ to wa ni Syria.

Iran fẹsun kan Isrẹli, pe awọn ni wọn kọlu ileeṣẹ naa ti ọga ologun kan fi padanu ẹmi rẹ. Ṣugbọn Isrẹli loun ko mọ nkan kan nipa rẹ.

Atẹjade ti agbẹnusọ ikọ ologun Israel, Rear Admiral Daniel Hagari, fi sita sọ pe ọpọlọpọ ibọn ti Iran n yin l’awọn ti gba silẹ.

O l’awọn tiẹ ri awọn nkan ija kan ni Isrẹli, ṣugbọn wọn ko pa ẹnikẹni.

Amẹrika yóò pè ‘pàdé àwọn olórí ogun (G7).

Awọn alaṣẹ ilẹ Amẹrika pẹlu ijọba Gẹẹsi ti f’ idi ẹ mulẹ pe atilẹyin awọn ni ko jẹ ki ‘kọlu yi ti burẹkẹ.

Aarẹ Joe Biden ilẹ Amẹrika sọ pe,oun yo ṣe ‘pade pọ pẹlu awọn olori (G7), lati mọ ọna ti wọn yo gba yanju iṣoro ọhun.

Eyi ni igba akọkọ ti Iran yo doju ija kọ Isrẹli, o si ti le ni ado oloro ọọdunrun ti wọn ti ju sibẹ.

Ṣugbọn Isrẹli naa ti ni ko ni i pari sibẹ, wọn l’awọn naa ti gbaradi gidi.

Yorùbá Nation yàtọ̀ sí ẹgbẹ́ tí Dupe Onitiri jẹ́ adarí fún – Banji Akintoye

Yorùbá Nation yàtọ̀ sí ẹgbẹ́ tí Dupe Onitiri jẹ́ adarí fún – Banji Akintoye

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ti di pé bí aráalé rẹ bá lẹ́nu, àfi kí ìwọ náà yáa lẹ́sẹ̀ èyí ló mú kí adarí Ìlànà Ọmọ Oòduà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye ó má a lọgun tantan pé ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀pọ̀ àwọn oní ìwéèróyìn ṣe n gbé e kiri pé ẹgbẹ́ Ìlànà Ọmọ Oòduà ló wà nídìí ìkọlù tí àwọn ikọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation kan ṣe sí ọgbà ọ́físì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Akintoye, nínú àtẹ̀jáde kan tó buwọ́lù fún akọ̀ròyìn, sàlàyé pé àwọn ikọ̀ tí wọ́n ṣe ìkọlù yìí ló wà lábẹ́ ìdarí Dupe Onitiri- Abiola, ìyàwó gbajúgbajà olóṣèlú tó ti di olóògbé, M.K.O Abiola.

“Àwọn ajìjàgbara yìí dárúkọ wọn, DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA, ikọ̀ ajìjàgbara tó wà lábẹ́ Arábìnrin Dúpẹ́ Onitiri-Abiola.

“A ní láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí pé, ìlànà YORÙBÁ NATION kò ní nnkan ṣe pẹ̀lú Arábìnrin Dúpẹ́ Onitiri-Abiola àti ikọ ajìjàgbara rẹ̀ .”

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn ajìjàgbara tí wọ́n pe ara wọn DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA ya wọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ológun wọn.

Àwọn ikọ̀ yìí tún pààrọ̀ àṣìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú tí Yorùbá Nation

Ìjàm̀bá iná Èkó: E̩ní kàn ló mò̩

Ìjàm̀bá iná Èkó: E̩ní kàn ló mò̩

Yinka Alabi

Ajalu buruku ni ina to se̩le̩ ni ilu Eko ni o̩s̩e̩ to koja. Eleyii ni o tun buru ju ninu gbogbo eyi to ti n se̩le̩ ni ilu Eko.
E̩ni to kan lo mo̩, bi oja olowo iyebiye se n jona ni ile alaja me̩ta, me̩rin n wo.
Ko ye o̩po̩ onisowo ibi ti awo̩n ti fe̩ be̩re̩, gbogbo e̩ni to ba ni eniyan si ibi ti ise̩le̩ buruku naa ti se̩le̩ ko gbo̩do̩ jinna si iru e̩ni be̩e̩. O̩po̩ awo̩n onisowo yii ni ko ni adojutofo kankan, ogun adaja ni adanu naa je̩ fun awo̩n ati e̩bi wo̩n.
E̩yi to tun wa buru nibe̩ ni ti ijo̩ba to ti o̩ja naa pe̩lu ileri pe atunto maa de ba awo̩n ile ati o̩ja Eko naa. Eyi tun da omi tutu si o̩kan awo̩n ti ise̩le̩ naa kan nitori pe o̩ro̩ ijo̩ba too too fun un. Ijo̩ba amuni moogun, e̩ru n ba o̩po̩ pe, se awo̩n tun le ri awo̩n iso̩ awo̩n pada si mo̩.Bayii ko tii si e̩ni to mo̩ iru o̩wo̩ ti ijo̩ba maa gbe, ko si e̩ni to mo̩ igba ti ayipada naa maa waye.
Yoruba bo̩, wo̩n ni “ko si ifa to ba agba le̩ru bi ifa ti a da ti ko ni etutu”.
Yato̩ si o̩ja Dosumu ti ise̩le̩ naa ti be̩re̩, “o̩ro̩ kanle̩ kan baale, yoo kan je̩je̩ ni mo jokoo mi”, akoba yii ba awo̩ n o̩ja bii Idumo̩ta, Idumagbo, Mo̩shalasi, Nnamidi Azikwe, O̩banikoro ati awo̩n aladugbo wo̩n.
Ki Eledua jo̩wo̩ ba wa dawo̩ aburu duro, ki O si ba awo̩n ti ise̩le̩ kan fofo r’e̩mi.
Fidio ijamba naa wa ni isale̩…

Ìgbéṣẹ̀ àwọn Afurasí Oòduà Nation tó yá wọ ọgbà ọọ́fíìsì Gómìnà Ọ̀yọ́ lòdì sófin — Afẹ́nifẹ́re.

Ìgbéṣẹ̀ àwọn Afurasí Oòduà Nation tó yá wọ ọgbà ọọ́fíìsì Gómìnà Ọ̀yọ́ lòdì sófin —
Afẹ́nifẹ́re.

Gbọ́láhàn Quseem

Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ilẹ́ Yorùbá ti bu ẹnu àtẹ́lu bí àwọn ikọ̀ tí wọ́n pe ‘rawọna ní ajìjàgbara Oòduà Nation ṣe ya wọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní lọọlọ́ yí.

Afenifere, ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Comrade Jare Ajayi fi lede salaye pe, awọn to lọwọ ninu ikọlu naa gbe igbesẹ naa ni ọna ti ọpọ ọmọ Yoruba ti wọn ni awọn n soju lodi si.

O ni ijọba ni lati ṣe iwadi, ko si fiya jẹ wọn ni ilana ti ofin gbekalẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mi to ni i erongba irufẹ bẹẹ.

Bẹ ba gbagbe, ni kopẹkopẹ yi ni awọn eeyan kan to pe ara wọn ajijagbara Yoruba Nation yawọ ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ni Agodi, ni
‘lu ‘badan.

Sugbọn Afẹnifẹre ni ko si nkan to jọ mọ orilẹ-ede Ilẹ Yoruba ni bi-ki-bi.

“Ilẹ Yoruba jẹ ilu kan gboogi to wa labẹ orilẹ-ede Naijiria eyi ti ko le ni ominira tiẹ”

Lọwọ lọwọ bayii, awọn eeyan Yoruba wa ni ipinlẹ Ekiti, Eko, Ogun, Ondo, Osun ati Oyo.

Bakan naa ni wọn ni awọn apa ibi kan ni Kwara, Kogi, Delta ati Edo.

Ajayi ni ọpọ iwa ibajẹ lo wa ninu ọna ti awọn oloselu fi n da ri orilẹ-ede Naijiria.

“Ọna abayọ si awọn iṣoro yi ki ṣe jagidijagan. Ohun to yẹ ka ma ja fun ni pe ka wa bi a ṣe wa ọna abayọ si iṣoro orilẹ-ede yii.

“Afenifere si ni igbagbọ ninu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu to n sapa fun Naijiria ati awọn olugbe rẹ lati ma gbe papọ ni alafia .”

Afenifere ni ilana ti awọn ikọ ajijagbara yii gunle ni ko mu ọpọlọ dani rara.

“Bawo ni eeyan kan tabi ẹgbẹ kan ma ro pe ti awọn ba ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ tumọ si pe awọn ti se idasilẹ orilẹede mii.

“Yoruba ma ronu ki wọn to gbe igbeṣẹ, papa irufẹ igbesẹ bayii. Yoruba ko ki n gbe igbesẹ ni ilana yii.

“Wọn yoo ro ori wọn, ki wọn to ni awọn gunle nkan bayi.”

Agbẹnusọ Afẹnifẹre waa pe fun iwadi, to si rọ ijọba lati f’ iya jẹ awọn afurasi naa ni ilana ti ofin gbe kalẹ, eyi to ni yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn eeyan mii to ni irufẹ erongba bẹẹ.”

Àṣírí wo lówà láàrin Sunday lgboho àti Gàní Adams tí ìkùn sínú fiwà láàrin wọn.

Àṣírí wo lówà láàrin Sunday lgboho àti Gàní Adams tí ìkùn sínú fiwà láàrin wọn.

Ibrahim Adédèjì

Ṣé àwọn àgbà ló sọ pé bétí ò bá gbọ́ yìnkìn,inú kìí bàjẹ́ .
Ọ̀rọ̀ kan tó ti n jà rànìn kiri lórí ayélujára ti fa èdè òyédè láàrin Ààrẹ Ọ̀nàkakanfò Iba Gani Adams, Olóyè Sunday Igboho àti Olórí òsìsẹ́ ìjọba níìpínlẹ̀ Èkó, Tayo Ayinde.

Saaju ni Sunday Igboho ati Tayo Ayinde ti kọwe ẹjọ ransẹ si Iba Gani Adams lati wa wi tẹnu rẹ lori ohun kan to jade nibi to ti n fẹsun kan awọn mejeeji pe wọn ti gba owo lati ṣeku pa oun.

Oun ti agbọni pe awọn agbẹjọro olupẹjọ mejeeji ti ni ti Aarẹ Gani Adams ko ba ko ọrọ rẹ jẹ pada, awọn yoo pade ni ile ẹjọ.
Agbẹjọro fun Ọ̀gbẹ́ni Ayinde, Adeyinka Olumide -Fusika (SAN) ni ohun naa fẹsun kan onibaara oun lọna aitọ.

O ni Gani Adams sọ ninu fọ́nrán naa pe, Tayo Ayinde fun Sunday Igboho ni N45m lati ṣekupa ohun.”

Gani Adams ti wa fesi jade lori ọrọ naa, to si rọ awọn mejeeji lati ma ri idakẹjẹ oun gẹgẹ bi ti ojo.

‘Didakẹ mi ko ṣe bii ti ojo’
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Gani Adam, Kehinde Aderemi fi lede, o sapejuwe fọ́nrán ohun gẹgẹ bii àdọ́gbọ́n si.

Bakan naa lo ni ẹjọ ti Igboho ati Ayinde pe lo jẹ eyi ti wọn lẹdi apo pọ lati fi ja irawọ Adams ni igboro aye.

“O ti han gbangba pe Igboho ati Ayinde ko fẹ ki alaafia jọba lẹyin ti Ooni, Ọba Adeyeye Ogunwusi ti ba wa sọrọ.”

“Idi ti mo fi dakẹ ninu gbogbo rogbodiyan yii ti Igboho ati Ayinde gbe kalẹ kii ṣe nitori mo jẹ ojo sugbọn nitori ọwọ ti mo ni fun Ooni ti ile-ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi ati awọn oriade mii ni ilẹ Yoruba ti wọn dasi ọrọ yii.

“Sugbọn pẹlu bi irọ ṣe n jade lori ọrọ mi, mo ro pe asiko ti to lati jade sita sọ bii nnkan ṣe jẹ.

“Botilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro mi ti ṣe ohun to tọ, mo tun ni lati tan imọlẹ si ohun ti wọn ka silẹ nitori irọ lasan ni, to si jẹ ọrọ kan to waye laarin emi ati aburo ọrẹ mi kan to wa ni America, lọ̀dún 2021..

“Ọmọkunrin ọhun lo da ọrọ naa silẹ pe oun fẹ ki alaafia jọba laarin emi, Igboho ati awọn eeyan kan.

Lasiko ti ijiroro ipẹtu sija ọhun si n lọ lọwọ, ni darukọ awọn eeyan meji naa ninu alaye rẹ.”

Aarẹ Gani Adams fikun pe gbogbo ọrọ nipa Tayo Ayinde to wa ninu ohun naa lo jẹ irọ.

Sunday Igboho, èmi ò mọ nǹkankan nípa ajìjàgbara Oòduà Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Íbàdàn o –

Sunday Igboho, èmi ò mọ nǹkankan nípa ajìjàgbara Oòduà Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Íbàdàn o –

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ajìjàgbara fún òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, ìyẹn Yorùbá Nation, Olóyè Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti sọ pé òun kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú rògbòdìyàn tí àwọn ajìjàgbara kan fa nílùú Ìbàdàn láàrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Igboho ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lójú òpó Sítágírámù rẹ̀.

Ó ní òun kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà, bẹ́ẹ̀ làwọn ajìjàgbara ẹgbẹ́ òun kò ní dá irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ láṣá láíláí.
Igboho sọ pé “Ó ti tó mi létí pé àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní ajìjàgbara Oòduà Nation gbìyànjú láti já ọọ́fìsì Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbà.

“Yóó sì wù mí láti sọ ọ́ di mímọ̀ pé mi ò lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá.

“Àti pé, kò sí ọmọ ẹgbẹ́ Odùduwà Nation kankan tí yóó jẹ́ dán irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ wò.

“Mo rọ ìjọba láti ṣè ìwádìí fínífíní lórí ọ̀rọ̀ náà kò sì fi ojú àwọn aṣebi àti abani lórúkọjẹ́ náà léde.”

Ṣaájú láàárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn èèyàn kan ti kọ́kọ́ kọlu ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà, tí wọ́n sì gbìyànjú láti gba ibẹ̀ kí àwọn agbófinró tó ṣí wọn lọ́wọ́ iṣẹ́.

A gbọ́ pé àwọn èèyàn náà yọ àsìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà kúrò tí wọ́n sì fi àsìá Oòduà Nation síbẹ̀ .

Wàyí ò, ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n dá rúgúdù náà sílẹ̀.

Ajìjàgbara Òduà Nation pẹ̀lú ohun ìjà olóró ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́

Ajìjàgbara Òduà Nation pẹ̀lú ohun ìjà olóró ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé ni àwọn èèyàn kan tí wọ́n furasí pé wọ́n jẹ́ ọmọ lẹ́yìn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Odua Nation yawọ inú ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́ tó wà nílùú Ìbàdàn tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Oun tí akọ̀ròyìn Òwúrọ̀ gbọ́ ni pé àwọn ajìjàgbara náà yawọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ọ̀yọ́, tí wọ́n sì pààrọ̀ àsìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ti Òduà Nation kí àwọn ọmọ ológun tó dé sí ibẹ̀.

Nínú fọ́nrán tó tẹ akọ̀ròyìn Òwúrọ̀ lọ́wọ́, àwọn ajìjàgbara náà ni wọ́n wọ aṣọ ológun lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n.

Bákan náà ní fọ́nrán ọ̀hún tún ṣàfihàn bí ọwọ́ Ilé iṣẹ Ọlọ́pàá ṣe tẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì dá wọn dùbúlẹ̀ nínú ọgbà náà.

Nígbà tó ń fi di ìròyìn náà múlẹ̀, Olùdámọ̀ràn sí Gómìnà lórí ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Fatai Owoseni Rtd ní ọwọ́ ti tẹ afurasí mẹ́rìndínlógún lára àwọn afurasí náà.

Bákan náà O lùdámọ̀ràn sí Gómìnà lórí ìròyìn, Abosede Sodiq náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀, ó ní bí wọ́n se yawọ inú ọgbà ọ́fìsì Gómìnà ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìn ìbọn sókè.

Ó ni ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ púpọ̀ àwọn afurasí ọ̀hún.

“A ti ké sí àwọn aráàlú nítorí àwọn èèyàn yìí ní wọ́n múra nínú aṣọ ológun, pé kí wọ́n fura sí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ .”

Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò, láti olú Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, ilé iṣẹ́ ológun ati àwọn Àmọ̀tẹ́kùn ló ti wà káàkiri agbègbè náà láti ri pé àlàáfíà jọba.

Bákan náà ni wọ́n ti gbé igi dínà àwọn ojú ọnà kan, tí wọ́n sì rọ àwọn aráàlú láti má gba agbègbè tí wọ́n gbé igi dá náà.