Home Blog Page 22

Ó ye̩ kí n ti fè̩yìntì nínú isé̩ orin’ – Rudeboy

Ó ye̩ kí n ti fè̩yìntì nínú isé̩ orin’ – Rudeboy

Mary Fágbohùn

Olorin, Paul Okoye, ti a mo si Rudeboy, ti so pe oun ati awon akegbe re ni o ye ki won ti feyinti ninu ise orin bayii.

Eni Odun marundinlaadota naa so pe ninu ilana orin, ko ye ki olorin sise fun igba ti o pe.

Nigba to n soro lori eto Adesope, Rudeboy ni, o je nnkan ti o soro fun okunrin ti o ni idile lati je olorin ti o n sise gidi.

“Ni ilana ti a fi n ko orin tele, awon bii tiwa bayii ye ki o ti feyinti,” gege bi o se salaye.

“Gbogbo nnkan ni akoko wa fun ni aye yi. Awon nnkan a maa sele. Ti o ba je Ilumooka ti o si ro pe gbogbo igba ni awon eniyan yoo maa ri o bii Angeli, gba mi gbo, ko si ibi ti o n lo. Igba kan wa ti awon nnkan ko ni ba o lara mu. Bee lo se maa n ri.

“Gbogbo awon gbajumo olorin ni won ti ni idalebi tabi awuyewuye ri. Koda, awon ti won se n dide bo, pelu, yoo ni ipin ninu re lojo kan. Bii nnkan se ri ni [ninu ile ise alarinrin]. Sugbon, ohun ti o niise ju ni iru eni ti o je ati bi o ba se koju re.”

Rudeboy di olokiki ni 2000 bii okan lara awon olorin P-Square pelu Ikeji re Peter Okoye, ti a mo si Mr P.

Awon egbe naa ni o koko pinya ni 2016 sugbon ti won pada re ni 2021. Ni osu kejo 2024, Rudeboy fi idi re mule pe P-Square tun ti pinya, leyin ti arakunrin re Peter fi esun kan oun ati egbon won, ti o je alakoso won teleri, Jude Okoye pe won fi owo egbe naa si apo ara won.

Sophie Alakija ni irú e̩ni tí mo fé̩ràn – Fairme

Sophie Alakija ni irú e̩ni tí mo fé̩ràn – Fairme

Omole Elegbon Agba Naijiria, abala ‘No Loose Guard’, Fairme ti safihan pe osere tiata, Sophie Alakija ni iru obinrin ti oun nifee si.

Nigba to n ba Elegbon Agba soro, Fairme so pe oun ko si ninu ibasepo ife pelu enikeni ninu ile nitori pe iru obinrin bii Sophie Alakija ni oun feran.

O ni omole bii, Onyeka ti bere lowo oun boya oun feran re, sugbon oun so fun un pe oun ko nifer sii lati wa ninu ibasepo ife pelu re.

“Onyeka beere boya mo nifee re sugbon mo so fun oun naa pe mo kan feran re bii ore lasan ni. Awon obinrin bii Sophie Alakija nikan ni o le mu mi wo inu ibasepo ife,” gege bi o se salaye.

Fairme ati enikeji re lori eto, Mickey, safihan ki won to bere eto pe awon ko tii ni “ibalopo” ri.

Ayra Starr ti bè̩rè̩ eré síse

Ayra Starr ti bè̩rè̩ eré síse

Mary Fágbohùn

Olorin takasufe igbalode, Ayra Starr ti darapo mo awon olorin bii tire ni Naijiria ti won darapo mo ile ise fiimu Naijiria.

Eni odun mejilelogun naa ti a fa sile fun ife eye Grammy ti setan lati farahan ninu fonran ere Prime, ‘Christmas In Lagos’.
Awon alawada ife bii Teniola A. Aladese, Shalom C. Obiago, Rayxia Ojo ati Shaffy Bello, ati Adekunle Gold naa wa ninu won.

Eyi da lori Fiyin (Aladese) ti o ba ijakule ife pade, eni to gba pe ore re timotimo, Elo (Obiago), ni ife aye re.

Fiimu naa ni won ya ni Eko, ti Jadesola Osiberu si dari re.

“Fun emi, Ayra Starr soju ohun ti o tumo si pe ki obinrin je omode, ti o gboya, ki o ma si se beru – ki o je ara re. O wa ni ori atojo naa lati ojo akoko,” Osiberu so fun Variety.

Awon olorin miran ti o wa ninu fiimu naa ni Wurld ati Liya, nigba ti won lo orin awon akoni bii, Sunny Ade, olorin takasufe, Flavour ati D’banj, ati awon miran.

Ọ̀pọ̀ búrẹ́dì tó wà níta kò ní nọ́ńbà— Àjọ NAFDAC

Ọ̀pọ̀ búrẹ́dì tó wà níta kò ní nọ́ńbà— Àjọ NAFDAC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ oúnjẹ, òògùn àtàwọn ohun èlò mìíràn nílẹ̀ yìí, National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC), ti pariwo síta pé ọ̀pọ̀ búrẹ́dì tí wọ́n ń tà káàkiri ni kìí ṣe ojúlówó burẹdi tó yẹ káwọn èèyàn máa jẹ, nítorí púpọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún nílé iṣẹ́ wọn tó jẹ́ pé kò gbámúsé, àgàgà pẹ̀lú bí àwọn tó ń ṣe burẹdi ṣe ń lo èròjà dídùn tí wọ́n ń pè ní saccharine dípò ṣúgà, nítorí bí ṣúgà ṣe ti gbówó ńlá lórí.

Bakan naa ni wọn jawe ikilọ fawọn to n pọn omi mimu inu lailọọnu ati ike ta, awọn to n ta oogun oyinbo, titi mọ awọn to n pese oniruuru ọja mi-in, lati yago fun tita ayederu ọja tabi eyi ti eroja rẹ ki i ṣe ojulowo.

Adari ajọ NAFDAC ni apa iha Iwọ Oorun orilẹ-ede yii, Arabinrin Roseline Ajayi, lo ṣekilọ yii lasiko ipade awọn tọrọ kan ti ajọ NAFDAC ṣagbekalẹ rẹ niluu Ibadan lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

O ni pupọ esi ayẹwo tileeṣẹ awọn ṣakojọ rẹ lasiko ayẹwo tuntun ti wọn ṣe laipẹ yii fihan pe oogun tijọba fofin de atawọn ti ko lontẹ ajọ NAFDAC, ni pupọ awọn to n ta oogun oyinbo n ta kiri.

Ajayi ni pupọ awọn ileeṣẹ to n pese nnkan ni wọn kọ lati tẹle ilana ti wọn la kalẹ lati maa paaki ọja wọn sinu lailọọnu tabi ohun yoowu ti wọn n pọn ọn si, ati ibi ti wọn n ko wọn pamọ si.

“Lẹnu ọjọ mẹta yii, a ri i pe ọpọlọpọ burẹdi ti wọn n ta ninu ọja ni ayẹwo ta a n ṣe fun wọn ko jade daadaa, nitori pe saccharine lawọn to n ṣe wọn n lo latari ṣuga to wọn. Awọn eroja to le ṣakoba fun ilera awọn to n jẹ ẹ ni wọn n lo. A ko ṣai mọ bi gbogbo nnkan ṣe ri niluu latari eto ọrọ-aje to dẹnu kọlẹ, ṣugbọn ileeṣẹ yii ko ni i tori bẹẹ ma ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ.

O ṣe pataki ki a mọ pe a ko le fọwọ yẹẹrẹ mu ọrọ ohunkohun ti wọn ba n pese, ti ajọ yii yoo si ṣamojuto rẹ lati ri i pe o jẹ ojulowo”.

Ajayi fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti ipade ti wọn ṣe yii da le lori ni lati wa ifọwọsowọpọ ati atilẹyin to yẹ lọdọ awọn tọrọ kan fun ileeṣẹ naa lati le jiṣẹ ti wọn gbe lọwọ gẹgẹ bi oludaabo bo ilera araalu.

Èyí le o, ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ májèlé mọ́’nú oúnjẹ

Èyí le o, ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ májèlé mọ́’nú oúnjẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ògédé èèyàn tí Ọlọ́run pamọ́ nìkan ló bọ́ lọ́wọ́ ewu.Àṣamọ̀ yìí kò sẹ̀yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ìlú
ìlú kékeré kan tí wọ́n n pè ní Kaura-Wanke, níjọba ìbílẹ̀ Shagari, níìpínlẹ̀ Sokoto, bóṣe kan gbínrín gbínrín látàrí pé ọ̀fọ̀ nlá ṣẹ wọ́n níbẹ̀. Páropáro nìlú ọ̀hún dá báyìí, nítorí tí ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kan kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ ajílẹ̀ mọ́’nú ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ láìpẹ́ yìí. Láti Ọjọ́bọ, ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ni àwọn ìdílé náà ti wà lọ́sibítù ìjọba ìpínlẹ̀ tí wọ́n n gba ìtọ́jú lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ọjọ́ Ẹtì, ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ni mẹ́ta lára àwọn mọ̀lẹ́bí náà kú. Nígbà tó tún máa fi di ọjọ́ Àìkú, ọ̀sẹ̀ ọ̀hún, ni àwọn méjì mí-ìn bá tún kú síléèwòsàn ìjọba tí wọ́n ti n gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ naa, Abilekọ Hajiya Asaba Balarabe, to fidi iṣẹlẹ ohun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu yii, sọ pe, ‘’Ilu Abuja ni mo wa lasiko ti wọn fọrọ ọhun to mi leti pe idile ẹlẹni meje kan jẹ majele mọ’nu ounjẹ ti wọn jẹ, loju-ẹsẹ naa ni mo si ti ran awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mi lọ sibẹ pe ki wọn gbe wọn kuro lọsibitu ijọba ti wọn wa, ki wọn maa gbe wọn lọ si ọsibitu akanṣe kan to le ṣetọju wọn daadaa, ṣugbọn bo ṣe wu Ọlọrun Ọba lo n ṣe ọla rẹ, awọn marun-un ti pada ku ninu awọn ẹbi naa bayii. Mẹta lo kọkọ ku l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, nigba ti awọn meji kan tun ku lọjọ Aiku, , ọjọ kejidinlogun, niṣoju mi.

‘’Ohun tawọn dokita sọ ni pe kẹmika to wa ninu ounjẹ ti wọn jẹ ti ba ọpọ ẹya ara wọn jẹ kọja atunṣe ko too di pe wọn gbe wọn wa sileewosan awọn’’.

Mọlẹbi awọn to ku ti dupe gidi lọwọ kọmiṣanna naa fun bo ṣe tete gbe igbesẹ gidi lori awọn idile naa, bo tilẹ jẹ pe marun-un lo ti ku ninu wọn bayii, tawọn kan si ti n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba kan to wa nipinlẹ naa bayii.

Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé ọdún méjìdínlógún kò ní lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO mọ́ —– ljoba

Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé ọdún méjìdínlógún kò ní lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO mọ́ —– ljoba

Ṣé wọ́n ní èèyàn tí kò
gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ni yóó pè é lẹ́yẹ aláròyé.
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé odún méjìdínlógún kò ní láánfàní láti kópa nínú ìdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama, NECO àti WAEC mọ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Nàìjíríà, Ọjọgbọn Tahir Mamman lo sọ eyi nigba to n sọrọ pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Channels lọjọ Aiku, ọjọ Kẹdọgbọn, oṣu kẹjọ,. ọdun 2024.

Ọjọgbọn Mamman ṣalaye pe ijọba apapọ ti pa a laṣẹ fun gbogbo ajọ to n risi idanwo WAEC ati NECO lati ri pe wọn tẹ le aṣẹ ijọba yii.

Bakan naa lo ni igbesẹ ijọba apapọ yii kii se igbesẹ tuntun.

O fikun ọrọ rẹ pe iye ọjọ ori fun akẹkọọ lati se idanwo idanwo JAMB ati wọ ile ẹkọ giga fasiti si wa ni ọdun méjìdínlógún.

“Ọdun méjìdínlógún ni ọjọ ori , nnkan ti a sọ ninu ìpàdé wa pẹlu JAMB ninu oṣu keje ni pé a fi ààyè sílẹ̀ ní ọdún yìí láti jẹ́ kí àwọn òbí mọ nípa ìgbésẹ ìjọba .

“Idanwo Jamb gba awọn akẹkọọ ti ojọ ori wọn ko ti to ẹni ọdun méjìdínlógún ni ọdun yii sugbọn wọn o ni igba bẹẹ ni ọdun to n bọ.

“Ajọ Jamb yoo ri pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ti wọn yoo wọ, ile ẹkọ fasiti pe ọdun méjìdínlógún.

“Ti ẹ ba se isiro ọjọ ori to yẹ ki awọn akẹkọọ lo ni ile ẹkọ, apapọ ọdun naa yoo jẹ ọdun mẹtadinlọgbọn ati abọ, bẹrẹ lati igba ewe wọn.

“Ìgbẹ́sẹ̀ yìí kì í ṣe ìgbésẹ tuntun, láti fi tako ọ̀rọ̀ kan tí àwọn èèyàn sọ.”

Destiny Etiko sò̩rò̩ lórí è̩sùn pé ò ń se wo̩lé-wò̩de pè̩lú o̩ko̩ Omotola Jolade

Destiny Etiko sò̩rò̩ lórí è̩sùn pé ò ń se wo̩lé-wò̩de pè̩lú o̩ko̩ Omotola Jolade

Destiny Etiko ti soro lori esun wolewode pelu oko akegbe re, Omotola Jalade, Matthew Ekeinde.

E ranti pe aheso oro kan jade to so pe Destiny Etiko wa ninu ibasepo ife pelu Matthew.

Iroyin yi naa so pe oko Omotola ra oko boginni kan fun Etiko.

Amo sa, nigba to n soro nipa esun yi lori abala womi ki n wo o to se lori Instagram, Etiko sapejuwe iroyin naa bii iro, ati pe won fe fi oro naa ba a loruko je ni.

“Ti e ba fe dena ibukun Olorun ninu aye eniyan, ti e si fe dagba si, ko le seese. Saaju, e ti n fi enu ba mi je. Se awon okunrin maa n fun ni lowo ni? Ti won ba ti le n fun ni, mi o mo.

“Mo sise fun ida mokandinlogorun-un nnkan ti mo ni. Mi o mo idi ti inu fi n bi awon eniyan, boya eru n ba won. Mo ma a n ra oko ayokele ni gbogbo ojo ibi mi nitori pe mo feran lati maa paaro oko ayokele mi ni odoodun.

“Awon eniyan kan ti inu n bi, kan jokoo, won si wa aworan ti mo ya pelu oko Omotola ni odun merin o le seyin, nigba ti mo wa ninu oko ofurufu ti o si je awako naa, awon eniyan n ya aworan pelu mi. O beere pe ki lo sele, won so fun pe osere tiata ni mi.

“O wo mi, mo si ki pelu ibowofun gege bi oko agba akegbe mi. Mo si so pe ko je ki a ya aworan gege bi ibowofun. A si ya aworan naa, o tan.”

 

Bílíò̩nù kan náírà fún ìjo̩ K&S – Davido

Bílíò̩nù kan náírà fún ìjo̩ K&S – Davido

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin takasufe Davido ti fesi lori iwa oninure ti baba re hu nipase sise itore bilionu kan naira fun ijo Kerubu ati Serafu (Centenary Endowment Fund of the Cherubim and Seraphim (C&S) Church).

Eyi waye nitori pe Adedeji Adeleke se itore yi ni iranti iya re, Esther Adeleke, nigba ti won n se ayeye iranti re.

Davido gboriyin fun baba re lori akitiyan ife si omoniyan, o ni o feran lati satileyin fun ile ijosin ati eto eko.

O ko o ni abala oro asoye pe: “Ohunkohun ti o ba niise pelu ile ijosin ati eto eko, e ma se iyonu, e ti ri owo.”

Olorin naa tun safihan iwuyi ti o ni si baba re lori Instagram, wi pe, “Baba mi owon, o je iwuri fun mi lojoojumo. Mo feran okunrin yi.”

Ayeye itore naa ni awon eniyan nla peju pese sibe, awon Gomina ati awo̩n o̩to̩ku ilu.

 

 

Wó̩n ń lépa è̩mí mi o – Adeyinka Alaseyori

Wó̩n ń lépa è̩mí mi o – Adeyinka Alaseyori

Mary Fágbohùn

Olorin ihinrere Naijiria, Adeyinka Alaseyori, ti figbe ta pe awon kan lori ayelujara n wa lati gba emi oun.

Ni ori abala wo mi ki n wo o kan to se lori Instagram, Alaseyori safihan pe orisiirisii iyolenu ni oun n koju lori ayelujara lati bii osu mefa seyin.

Olorin Oniduro naa se’kilo pe awon ti n ro iku kan oun, n fa ibanuje wa sori ara won ni.

“Maa ri oro asoye awon miran, maa rerin. Maa ri epe, maa rerin. Mo ri opolopo to n fe ki nnkan aburu sele si mi, mo rerin. Mo kan n fi yin rerin ni. Nitori pe enikeni to ba ro iku ro mi kan n ka ojo iku fun ara re ni.

“Ti e ba ro iku ro mi, e n pe fun iku gbigbona ni. Ti e ba ro pe ohun ti o to si mi ni iku, eyin naa fe ku.

“Ti e ba fi ateranse sowo si mi tabi ti e pe awon eniyan mi lati sepe fun mi, iku yoo le yin. Ti e ba dide tabi jokoo e n pe fun iku. Mi o fe ateranse yin. Ayanmo mi ko ni ku. Mi o ni di alailegbese. E koo sile, o je eewo fun emi Adeyinka Alaseyori.

“Ti enikeni ba pejo lati ro iku ro mi, ko ni fise bi won ba se po to, koda bi won je wooli, angeli iku yoo maa tele won kiri. Aye yi nika o. O je ohun inira, o si ba ni ninu je. Opolopo nnkan ni o n lo ti enikan o mo,” o ma se o!

Ènìyàn burúkú ni àwo̩n tó̩ò̩gì ìjú Ìshàgá – Portable

Ènìyàn burúkú ni àwo̩n tó̩ò̩gì ìjú Ìshàgá – Portable

Alawuyewuye olorin Naijiria Portable ti figbe ta leyin ti awon omo adugbo se ikolu sii nibi ayeye kan ni Iju-Ishaga, ipinle Eko, ni ojo Aiku.

Nigba to n soro leyin isele naa, olorin naa, ninu fonran kan to n lo kaakiri lori ayelujara, fihan pe oun sese pupo.

Ninu atejade to fi lede lori Instagram, o salaye pe oun wa nibi ayeye naa lati sajoyo pelu ore oun ti o n ta oko ayokele sugbon ti oun kanju pada lo si ile pelu apa lara leyin ti awon kan ri ihuwasi oun gege bi nnkan ibinu.

Portable, eni ti ori ko yo ninu ikolu naa, figbe ta pe won ko tii ri awon omo ise oun.

Nigba to n pe eni to lo ba se ajoyo pe ki o so fun awon omo adugbo naa lati da nnkan ini oun ti won ji pada, olorin naa so pe awon si n wa awon olorin oun.

O safihan pe awon to se ikolu naa ji opolopo ohun eso ara, kaadi igbowo (ATM card), ero agbelowo meji to je ti alakoso re, ati awon nnkan miran.

Ikolu naa waye leyin ti o lo sori ayelujara lati sajoyo ojo ibi omo Babyluv akoko.

O ko o pe: “Wahala laasigbo nla ni Iju-Ishaga. A lo sajoyo pelu @lincon_orn eni to n ta oko. Laarin adugbo nibi ti a ti n sere, nibe ni awon egbon adugbo ti ya bo wa, a o ti ri awon omo ZEHNATION.

“Won se ikolu si awon omokunrin mi leyin ti mo ribi sa asala… @lincon_orn jowo ba mi so fun awo egbon adugbo lati da ero agbelowo @iam_sexyshay’s meji ati kaadi igbowo mi pada. A ti ri ero agbelowo @dullarboi ati oko ayokele re sugbon a o ri oun funra re.

“Mi o ti ri @bamidola_ a gbo pe won se ikolu sii. Awon olorin mi ti a o ti ri niyi o. Olorun ko ni doju ti wa. Eni ibi ni awon eniyan yi, bee ni won se mu mi. Awon Egbon adugbo yi gba egba orun olowo iyebiye mi ati yeeti mi ti won fi wura se leyin ti mo fi ife han won ti mo si fun won ni owo. Won tun fe gba apo mi. Se afenifere ni won tabi ota?”