Home Blog Page 21

Obasanjo fẹ́ dupò ààrẹ Nàìjíríà fún sáà kẹ́ta. Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sàlàyé

Obasanjo fẹ́ dupò ààrẹ Nàìjíríà fún sáà kẹ́ta. Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sàlàyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí ì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé .

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹlẹri, Olóyè Olusegun Obasanjo ti sàlàyé pé irọ́ gbuu tó jìnà sí òótọ́ lọ̀rọ̀ t’áwọn èèyàn kan ti n gbé pòòyì ẹnu pé òun gbìyànjú láti dupò Ààrẹ fún sáà kẹta.

Obasanjo fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ níbi ìjíròrò lórí ètò ìjọba àwarawa tí Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí, Goodluck Jonathan, ṣagbàtẹrù rẹ̀ nílùú Accra, tí í ṣe olu ìlú orílẹ̀-èdè Ghana.

Obasanjo ni ko si ẹni to ni ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe loootọ loun gbiyanju lati dupo aarẹ Naijiria fun saa kẹta lẹyìn toun lo saa meji tan.
“Kìí ṣe pe ori mi o pe. Mo mọ nnkan ti mo le ṣe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta.

Ko si ọmọ Naijiria kan yala eyi to ti ku tabi wa laaye to le sọ pe mo pe oun wi pe mo fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta,” Obasanjo lo sọ bẹẹ.
Aarẹ ana naa fikun ọrọ rẹ pe biba awọn ti Naijiria jẹ lowo sọrọ lati fagile gbese ti Naijiria jẹ le ju ki oun gbiyanju lati dupo aarẹ fun kẹta lọ.

Obasanjo ni “gbogbo igba ni mo maa n sọ ọ pe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun igba kẹta ni toootọ ni, n ko ba ṣe bẹẹ, torí o rọrun fun mi lati lọ fun saa kẹta ju riri idarijin gba fun gbese ti Naijiria jẹ lọ.”
Aarẹ Naijiria tẹlẹ wa kìlọ fawọn olori orilẹede ti wọn kii fẹ fipo silẹ lati jawọ lapọn ti ko yọ.

Obasanjo ni lasiko ti eeyan ba si wa ni abarapa ni eeyan maa lokun lati le ṣiṣẹ daadaa.

“Ti ara ba ti di kujẹ kujẹ, eeyan o ni le ṣe ọpọ nnkan daadaa mọ.

Amọ, mo mọ pe awọn kan maa n ro wi pe t’awọn ko ba si níbẹ, ko si ẹlòmíràn to le ṣe e.

Wọn tiẹ tun máa n sọ pe awọn o tii ri ẹlomiran, mo ni igbagbọ pe ẹṣẹ ni eyi jẹ si Ọlọrun.

Idi ni pe Ọlọrun le gba ẹmi rẹ nigba kugba ti ẹlomiran yóò si bọ si ipo rẹ.

Ẹni to ba si bọ sí ipo rẹ naa le ṣe daadaa ju ọ lọ, o si tun le ma ṣe daadaa to ọ,” Obasanjo ṣalaye.

Agbálẹ̀ ilé ìwòsàn di onísòwò ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọdé jòjòló

Agbálẹ̀ ilé ìwòsàn di onísòwò ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọdé jòjòló

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí èèyàn bá n yọ́ ilẹ̀ dá ohun burúkú a máa yọ́ irú wọn ṣe.
Bẹ́ẹ̀ ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ kan péré ni ti olóhun.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ọ̀rọ̀ rí bí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn kan tí wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọ nínú báàgì kan tó gbé dání.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní, ọwọ́ tẹ obìnrin náà, Rose Mnisi níbi tó ti ń wá oníbàárà fún àwọn olubi ọmọ tó gbé dání náà lẹ́yìn tí èèyàn kan ta àwọn lólobó.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé ní ẹkùn ìlà oòrùn Mpumalanga ní orílẹ̀ èdè South Africa

“Nígbà tí a mú obìnrin náà, a bá àwọn olubi ọmọ púpọ̀ nínú àpò kan tó gbé dání. Ó jẹ́wọ́ fún wa pé agbálẹ̀ ilé ìwòsàn kan ní òun,” iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde.

Ní Ọjọ́bọ̀ ni obìnrin náà, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì, fojú ba ilé ẹjọ́ fẹ́sùn pé ó ní ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà àìtọ́. Wọ́n ti gba àwọn olubi ọmọ náà, tí wọ́n sì ti lọ ṣe àyẹ̀wò wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní afurasí náà ń wá ọkọ̀ ọ̀fẹ́ lọ sí agbègbè Nelspruit nígbà tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tó ń wọ́de ní ìlú Lydenburg tí wọ́n tún máa ń pè ní Mashishing tẹ̀ ẹ́.

Ọlọ́pàá ní àwọn kò lè sọ pàtó iye olubi ọmọ tó wà nínú àpò tó gbé dání nígbà tí wọ́n nawọ́ gán an.

“A ti fi ẹ̀sùn tó tọ́ kàn-án tó sì jẹ́ pé ó ṣeéṣe kí ẹ̀sùn rẹ̀ tún lékún bí ìwádìí bá ṣe ń lọ,” iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ.

Ní oṣù tó ń bọ̀ ni ìrètí wà pé afurasí náà yóò tún fojú ba ilé ẹjọ́ fún ìgbẹ́jọ́ láti gba béèlì rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò sọ ohun tí wọ́n máa fi àwọn olubi ọmọ náà ṣe àmọ́ àwọn kan ní ìgbàgbọ́ pé jíjẹ olubi ọmọ máa ń mú kí omi ọmú jáde fún ẹni tó bá ń tọ ọmọ lọ́wọ́ tàbí jẹ́ kí obìnrin tètè padà sípò lẹ́yìn tó bá bímọ tán àmọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ńsì kò ì tíì fi èyí múlẹ̀.

Ní South Africa, àwọn ìpànìyàn kan ni wọ́n fi orí rẹ̀ sọ lílo ẹ̀yà ara èèyàn fún àwọn oògùn ìbílẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, oníṣẹ̀ṣe Mozambic kan fojú ba ilé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n ká àwọn ẹ̀yà ara kan mọ lọ́wọ́ ní ìlú Tshwane.

Àwọn tó ń ṣe ìwádìí ní, ó ṣeéṣe kí àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n bá lọ́wọ́ oníṣègùn náà jẹ́ ti ọmọbìnrin kan tí wọ́n pa lọ́dún 2023, tí wọ́n sì yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lọ.

Hilda Baci fako̩yo̩ pè̩lú agbada ìre̩sì tó tóbi jù lágbàáyé

Hilda Baci fako̩yo̩ pè̩lú agbada ìre̩sì tó tóbi jù lágbàáyé

Mary Fágbohùn

Gbajumo olowosibi Naijiria, Hilda Baci tun yi dara otun pelu bi Guinness World Records, GWR, tun se de lade fun sise agbada iresi alaropo ti alaragbayida Naijira to tobi ju.

Ninu atejade kan ti won fi lede lori X, Guinness World Records kede pe:
“Akosile tuntun: Agbada iresi Aleppo ti Niajiria to tobi ju – 8,780 kg (19,356 lb 9 oz) ni Hilda Baci ati Gino se ni Victoria Island, Eko, Naijiria”.

Aseyori yi waye lẹyin asayin ounje wiwa ti won se ni Ojo Kejila, Osu Kesan, 2025, ni ile itura Eko Hotels and Suites, Victoria Island, Eko.

Ase naa, ti won pe ni ‘Gino World Jollof Festival’ pelu Hilda Baci, ni ogooro awon eniyan peju sibe..

Hilda Baci, eni to koko fi olokiki lagbaye ni 2023 pelu akosile re ninu iwe Guinness World Record fun alase to dana fun akoko to pe ju, ti bu iyi ku ara re bi okan lara awon olowosibi Naijira to gbayi ju.

Ase nilu Eko ni awon gbajumo bii Funke Akindele, Enioluwa Adeoluwa, Tomike Adeoye, ati Pastor Idowu, ati Bamidele Abiodun, iyawo Gomina ipinle Ogun, ti tunyaya jade lati satileyin fun igbiyanju alase naa.

 

 

Bí e̩ni sisé̩ sí ajádìí àpò ni té̩té̩ títa – Naira Marley

Bí e̩ni sisé̩ sí ajádìí àpò ni té̩té̩ títa – Naira Marley

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Azeez Fashola, ti a mo si Naira Marley, ti se’kilo fun awon odo lori tita tete boolu lapoju.

Olorin ‘Tesumole’ naa ni tete kii se ise to se fi yangan.

Naira Marley gba awon odo Naijira niyanju lati jawo ninu “fifi owo won sofo” sidi tete.

Loju opo X re, o kowe pe, “Tita tete lori boolu kii se ise arakunrin mi. Jowo jawo ki won to run o.”

Imoran Naira Marley yi waye laarin bi awon ti n kerora nipa ipa ti tete tita ni lori awon odo Naijiria.

Ijabo awon ajo onisowo Afrika (Business Insider Africa) ni Naijiria lo leke tente ninu tete boolu tita kaakiri ile adulawo ni ibere odun 2025.

O to 168.7m awon eniyan ti won n ta tete ni Naijira bi Ijabo naa se so, to tun so pe ida aadorin awon ara Naijiria to je eni ogbon odun tabi kere si ni won lowo ninu iwa naa.

 

Lóòótó̩ lo̩wó̩ gbá Davido lórí ní Warri

Lóòótó̩ lo̩wó̩ gbá Davido lórí ní Warri

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin Naijiria, Davido ti so pe aheso oro lasan ni oro to n lo kaakiri lori ayelujara pe won gbaa lori laipe yi niilu Warri, ipinle Delta.

Fonran to ja lo jakejado lori ayelujara safihan olorin naa laarin awon eso alaabo ati awon ololufe, pelu afihan akoko kukuru kan nibi to ti jo pe won gbaa lori.

Eyi lo mu ki enikan soro lori X, #AsakyGRN, eni to so pe: “Awon eniyan Warri ko layo o. E wo bi won se gba Davido lori.”

Nigba to n salaye ohun to sele gan an lori ikanni X ni ojo Aje, Davido tan imole si oro naa pe okan lara awon eso alaabo re lo seesi fowo gbaa, kii se okan lara awon ero to wa nibe.

“Mumu eso mi ni… o seesi fowo gba mi ni… alailayo,” olorin naa kowe.

Esi re yi lo fi opin si oro to tan kale naa, to si yanju gbogbo awuyewuye to yi fonran naa ka.

Ìjọba Kwara gbé àgọ́ Àgùnbánirọ̀ lọ sí Kwara Poly

Ìjọba Kwara gbé àgọ́ Àgùnbánirọ̀ lọ sí Kwara Poly

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ohun tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí wọ́n ti í ṣe é.
Lójúnà àti dènà ikọlù láti ọwọ́ àwọn agbébọn tó ń da àwọn agbègbè kan láàmú ní ìpínlẹ̀ Kwara, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti gbé àgọ́ Àgùnbánirọ̀ tó wà ní Yikpata, níjọba ìbílẹ̀ Edu, kúrò níbi tó wà, wọ́n gbé e lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Kwara Poly, Ilorin.

Alaboojuto ajọ NYSC ni Kwara, Joshua Onifade, sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ ana, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.

Onifade fidi iṣipopada agọ naa mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ n’Ilorin, pẹlu alaye pe ijọba gbe igbesẹ naa lati ṣẹgun idunkooko awọn agbebọn lagbegbe Yikpata ti agọ naa wa tẹlẹ.

O fi kun un pe aabo awọn agunbanirọ jẹ ijọba logun lo mu ki wọn gbe agọ naa lọ ojuna Jebba atijọ, nibi ti ile ẹkọ Poli Ilorin wa.

“Awọn alaṣẹ ajọ NYSC n dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Kwara ati awọn ẹṣọ alaabo lati ṣẹgun iṣoro eto aabo.
“Bi wọn ṣe agọ yii kuro wa fun ki ọkan awọn agunbanirọ to ba n bọ le balẹ. Paapaa julọ, awọn ti wọn n bọ ni Kwara fun igba akọkọ.”

Alabojuto ajọ NYSC ni Kwara lo ṣalaye bẹẹ.

O gboriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, fun gbigbe igbesẹ to le dena ikọlu.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Agunbanirọ 1,800 ni wọn n reti lati sinru ilu ni Kwara fun ti saa ọdun 2025 yii, isọri B.

Ọjọ kerinlelogun oṣu Kẹsan-an yii ni eto naa yoo si bẹrẹ kaakiri Naijiria.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn iroyin ikọlu awọn agbebọn kan bẹrẹ si i wa lati ipinlẹ Kwara.

Iroyin naa ṣalaye bi awọn akọluni naa ṣe bẹrẹ lati ilu kan ti wọn n pe ni Ganmu Ahileru, ti wọn wọle pa awọn eeyan ti wọn si n gbe awọn miran lọ.

Bakan naa ni ilu kan ti wọn n pe n Baba Nla, koju awọn agbebọn laipẹ yii. Wọn pa eeyan, wọn si tun gbe awọn kan lọ, bẹẹ ni wọn n beere ọgbọn miliọnu naira owo itusilẹ.

Awọn eeyan ilu Patiki naa ko gbẹyin ninu ilu ti awọn agbebọn ti ṣọṣẹ, ti wọn pa baba ati ọmọ, to bẹẹ ti araalu n rawọ ẹbẹ pe ki ijọba ba awọn rọjo ado oloro si ibuba awọn ajinigbe naa to wa ninu igbo kan niluu naa.

Bo si tilẹ jẹ pe ijọba ni ko si ilu to di ahoro nitori ikọlu, awọn fidio kan to gba ori ayelujara kan, ṣafihan aisi ohunkohun niluu naa mọ, titi kan awọn nnkan ọsin.

Ọsẹ to kọja lọhun-un ni awọn ọdọ ilu Isanlu-Isin, nipinlẹ Kwara kan naa, ṣewode tako ikọlu to sọ eeyan meji di awati, ti ọkada mẹẹẹdọgbọn to jẹ ti awọn fijilante si ṣe bẹẹ jona lati ọwọ awọn agbebọn bi wọn ṣe sọ
L’Ọjọru ọsẹ yii, iroyin sọ pe fijilante kan padanu ẹmi rẹ, nigba ti awọn agbebọn yawọ Abule Kakafu, nijọb ibilẹ Patigi, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ.

Awọn agbebọn naa ṣina ibọn bole, fijilante ti wọn pe orukọ rẹ ni Tetengi naa ni wọn lo jade lati koju wọn, nibẹ ni wọn si ti yinbọn fun un, to ku.

Araalu naa kan ti ko darukọ rẹ, sọ pe inu ibẹru ni awọn n gbe.

O ni afi ki ijọba tete dide si ọrọ ai si aabo yii, nitori ko si ifọkanbalẹ fun araalu mọ.

Awọn agbegbe ti ikọlu naa n kan ju bi a ṣe gbọ ni Patigi, Edu ati Kaiama .

Ni ti agọ Agunbanirọ ti wọn ṣi nipo pada yii, ijọba Kwara ti ko awọn ẹṣọ alaabo sibẹ lati mojuto bo ṣe n lọ lasiko eto ọlọsẹ mẹta ti yoo waye nibẹ.

Ki wọn si kapa ohunkohu to ba fẹẹ di alaafia ibẹ lọwọ.

Gbogbo igbiyanju lati ba agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kwara, Mallam Rafiu Ajakaiye, sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ni ko kẹsẹ jari.

Bakan naa ni agbẹnusọ NYSC ni Kwara, Oladipo Morakinyo, ko fesi si ibeere wa.

Ìpínlẹ̀ Kano lékè èsì ìdánwò NECO 2025

Ìpínlẹ̀ Kano lékè èsì ìdánwò NECO 2025

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe àwọn àgbà sọ pé ìrẹ́jẹ kò sí nínú fọ́tò, bí oníkálùkù bá ṣe jókòó ni yóò ṣe bá ara rẹ̀.
Ajọ National Examinations Council (NECO) ti fi abajade idanwo oniwe mẹwaa fun ti ọdun 2025 yii sita lẹyin ọjọ mẹrinlelaadọta ti wọn ṣe idanwo naa.

Alakooso idanwo NECO, Dantani Wushishi, to fidi esi idanwo naa mulẹ ni Minna, ipinlẹ Niger, ṣalaye pe akẹkọọ to le ni miliọnu kan, (1,367,210) lo ṣe idanwo oniwe mẹwaa NECO ni 2025.

Tẹ o ba gbagbe, idanwo NECO ọdun yii waye laaarin ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹfa, si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje.

Wọn bẹrẹ si i maaki awọn esi naa lọjọ kẹrinla oṣu Kẹjọ, wọn si pari rẹ lọjọ kọkanle lógbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Nipa onka awọn akẹkọọ ti wọn ni wọn ṣe èrú ninu idanwo naa, Wushishi ṣalaye pe:

“Onka awọn akẹkọọ to ṣe magomago ninu idanwo ọdun 2025 yii jẹ 3,878. Eyi dinku si 10,094 to waye ni 2024. ”
Gẹgẹ bi alaye ajọ NECO, ida ọgọta (60%) akẹkọọ lo yege daadaa ninu idanwo naa.

Apapọ akẹkọọ to fi orukọ silẹ lati ṣe idanwo ọhun jẹ 1,367,210, ọkunrin jẹ 685,514, awọn akẹkọọ obinrin si jẹ 681,696.

NECO kede pe awọn to pada jokoo ṣe idanwo naa jẹ 1,358,339, ọkunrin 680,292 , obinrin 678,047.

Wọn fi kun un pe awọn ti wọn gba isọri maaki ti a mọ si credit, marun-un soke ti wọn si tun yege ninu Iṣiro ati ede Gẹẹsi, jẹ 818,492. Wọn jẹ ida 60.26 % lapapọ.

Awọn ti wọn gba maaki credit yii to ju marun-un lọ, yala wọn yege Iṣiro ati ede Gẹẹsi tabi wọn ko yege, jẹ 1,144,496. Ida 84.26% ni awọn.
Akọsilẹ ajọ NECO fi han pe awọn akẹkọọ ti eya ara pe nija ,(Awọn ti wọn ni ipenija eti) to ṣe idanwo ọdun 2025 yii jẹ 1,622. Ọkunrin inu wọn jẹ 586, awọn obinrin si jẹ 355.

Ni abala awọn akẹkọọ ti wọn ni ipenija oju, ọkunrin 111 ni wọn bi NECO ṣe kede, awọn obinrin wọn si jẹ ọgorin (80)

Awọn ti wọn jẹ àfín jẹ ọkunrin mẹtadinlaadọta (47), obinrin wọn si jẹ mẹtalelaadọta (53).

Bakan naa ni awọn akanda akẹkọọ ti ohun to n ṣe wọn n ti inu ọpọlọ wa, ti wọn ko le sọrọ tabi rin daadaa (Autism), jẹ ọkunrin mejilelọgọta (62), obinrin mẹtalelọgbọn (33).

Akẹkọọ ọgọrun-un kan le mẹwaa, (110) ni wọn ni iriran wọn ko ja gaara to, nigba ti awọn akẹkọọ ti ọwọ, ẹsẹ, atẹlẹwọ, ika ọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko pe fun (dermatoglyphia ni wọn n pe ailera naa), jẹ ọkunrin mọkandinlaadọrun-un( 89), obinrin mẹrindinlọgọrun-un( 96 )

Ajọ NECO sọ pe ileewe mejidinlogoji (38) ni awọn mu ti wọn lọwọ si magomago lasiko idanwo ọdun 2025 yii.

Wọn ni ipinlẹ mẹtala ni wọn ti ṣe èrú naa ju, awọn yoo si pe wọn lati waa wi ti ẹnu wọn ki ajọ NECO too gbe igbesẹ ijiya lorii wọn.

Ajọ naa sọ pe awọn le yọ awọn alaboojuto idanwo kan danu – mẹta lati ipinlẹ Rivers, ọkan lati Niger, mẹta lati Abuja, ọkan lati Kano, ati ẹyọkan lati ipinlẹ Osun.

NECO kede pe oun ko ti I fi esi awọn ile ẹkọ mẹjọ kan sita nijọba ibilẹ Lamorde, ipinlẹ Adamawa.

Wọn ni eyi ri bẹẹ nitori ija ẹlẹyamẹya to waye nibẹ, ti wọn ko fi le ṣe idanwo lati ọjọ keje si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025.
Atẹjade kan loju opo NECO, kede pe bi akẹkọọ ba fẹẹ wo esi idanwo rẹ, kinni kan ti wọn n pe ni “Result checker token”, ni yoo lo.

Eyi jẹ bii kọkọrọ ti yoo ṣilẹkun oju opo ti esi idanwo naa wa.

Ẹẹmarun-un ni wọn ni akẹkọọ le lo o ko too ma ṣiṣẹ mọ.

Eyi tumọ si pe bi wọn ba fẹẹ tun esi kan naa wo ni igba kẹfa, wọn yoo nilo ‘token’ tuntun.

Bẹẹ ni ajọ naa kede.

Gómìnà Fubara balẹ̀ sí Port Harcourt

Gómìnà Fubara balẹ̀ sí Port Harcourt

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Siminalayi Fubara ti balẹ̀ sí ìlú Port Harcourt, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán kọjá ogún ìṣẹ́jú ni Gómìnà Fubara balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Port Harcourt níbi tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ti fi orin àti ijó pàdé rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin, ọ̀dọ́, tó fi mọ́ àwọn alátìlẹyìn Fubar ani wọ́n tò sáwọn òpópónà ní Port Harcourt tí wọ́n sì ń kí i káàbọ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́.

Níṣe ni àwọn èrò náà ń kọrin, jó káàkiri gbogbo òpópónà ní Port Harcourt lórí bí òpin ṣe ìlú ò fararọ tí ààrẹ kéde níbẹ̀ àti ìpadà sípò ìjọba àwaarawa ìpínlẹ̀ náà.

Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹsàn-án ni àwọn èèyàn pàápàá àwọn olólùfẹ́ Gómìnà Fubara ti ń retí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà àmọ́ tí kò yọjú sí ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Níṣe ni àwọn èrò tó tò sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers láti gbàlejò Gómìnà Fubara lọ́jọ́rú ṣùgbọ́n tí wọ́n padà sílé nígbà tí wọn kò rí i kó wá sí kó padà sẹ́nu iṣẹ́.
Ẹ ó rántí pé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlógún ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde pé ìlú ò fararọ tí wọ́n kéde ní ìpínlẹ̀ náà ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn ti parí àti pé kí gómìnà, igbákejì rẹ̀ àtàwọn aṣòfin padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn.

Nígbà tí àwọn aṣòfin wọlé padà fún ìjòkòó ilé lọ́jọ́bọ̀, Gómìnà Fubara kò yọjú sí ilé ìjọba pẹ̀lú gbogbo bí àwọn èrò ṣe ti tò kalẹ̀ láti gbàlejò rẹ̀.

Ní gbọ̀ngàn tó wà ní ilé ìgbé àwọn aṣòfin náà èyí tó wà ní Aba road, Port Harcourt ni ìjòkòó àwọn aṣòfin ọ̀hún ti wáyé.

Àwọn aṣòfin náà tún sọ fún Gómìnà Fubara láti forúkọ àwọn tó fẹ́ yàn sípò Kọmíṣánnà ṣọwọ́ fún àyẹ̀wò àti ìbuwọ́lù.

Àwọn aṣòfin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló kópa níbi ìjòkòó náà nígbà tí àwọn mẹ́ta – tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n súnmọ́ gómìnà Fubara – kò yọjú.

Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìlélógún ni ìjòkòó míì yóò tún wáyé.

Ẹ̀wẹ̀, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike, tí òun náà wà lára ọ̀kan lára àwọn tó ṣokùnfà bí ààrẹ ṣe kéde ìlú ò fararọ sọ pé kò pọn dandan kí gómìnà Fubara wọlé padà sẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ tí Ààrẹ ní kó padà.

Àwọn olóṣùgbó yarí ní Ijebu-Ode wọ́n fi ìlànà lélẹ̀ fún ọba tó kàn

Àwọn olóṣùgbó yarí ní Ijebu-Ode wọ́n fi ìlànà lélẹ̀ fún ọba tó kàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àgbáríjọpọ̀ àwọn oṣùgbó nílùú Ìjẹ̀bú-òde, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ti ṣe ìwọ́de lórí bí wọ́n kò ṣe sin òkú Awujale Ìjèbú, Ọba Sikiri Adetona, tó wàjà láìpẹ́ yìí.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu Keje, ọdun 2025 ni oriade naa darapọ mọ awọn babanla rẹ, lẹyin to ti lo ọdun marundinlaadọrin lori itẹ.

Bi iku rẹ ṣe dun ọpọ ọmọbibi ilẹ Ijẹbu, naa lo tun fa awuyewuye laaarin awọn kan.

Eyi ni ko ṣẹyin bi awọn Alfa ẹlẹsin musulumi ṣe sinku ọba naa, tako ireti ọpọ eeyan pe, awọn alawo ni yoo sinku rẹ.

Lati igba naa si ni ọrọ ọhun ti n fa wahala ati ifẹhonuhan lati ọdọ awọn ẹgbẹ ẹlẹsin ibilẹ loriṣiriṣi.
Ọkan lara awọn ẹgbẹ naa to tun ti jade bayii ni awọn Osugbo, pẹlu iwọde ti wọn ṣe.

Ninu ifọwọwerọ pẹlu akọroyin, olori ẹgbẹ naa, Folashade Olowolayemo, sọ pe ko boju mu bi wọn ko ṣe pe awọn sibi isinku ọba naa.

O ni dandan ni ki Awujale tuntun fọwọ si iwe adehun pẹlu awọn, eyi ti yoo ni ibuwọlu Agba Agbẹjọro, pe oun gba

Bakan naa ni Oshotegun Alawiye, Iya Oriṣa ilẹ Ijẹbu sọ pe, Awujale tuntun gbọdọ ṣe iwe fun gbogbo awọn oniṣẹṣe pe, oun ko ni doju iṣẹṣe delẹ.

Ẹwẹ, ẹnikan lara awọn olori ilu, Emmanuel Ademuyiwa naa sọ pe, dandan ni igbesẹ naa jẹ bayii, “ẹni ti ko ba si ti le ṣe e , ko ni i le jọba”.

Ṣugbọn ṣa, Lisa ti ilu Ijebu-Ode, Ọba Rasheed Adesanya sọ pe lootọ ni ijọba ti ṣe ofin pe, ọba lẹtọọ lati yan ẹsin to ba fẹ ko sin oku rẹ, o ni amọ ki iru ọba bẹẹ ṣe eto to yẹ lati mọ riri tabi fun awọn oniṣẹṣe ni nnkan to tọ si wọn lasiko isinku

Gomina Fubara padà sípò lẹ́yìn oṣù mẹ́fà

Gomina Fubara padà sípò lẹ́yìn oṣù mẹ́fà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Òní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2025 ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Siminalayi Fubara, tó yẹ̀bá nípò lósù mẹ́fà sẹ́yìn yóò padà sípò náà, lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Tinubu fagilé ìkéde ìlú kò fararọ tó ṣe lórí Rivers lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta ọdún yìí.

Ẹ o ranti pe ikede ilu o fararọ to le Fubara kuro nipo, waye latari ija oṣelu to waye laaarin rẹ ati Nyesom Wike, Minisita olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Nigba to si di ojumọ kan aroye kan ni Aarẹ paṣẹ pe ki Fubara fipo silẹ na, to si fi Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas, ṣe Alabojuto ipinlẹ Rivers fun oṣu mẹfa.

Oriṣiiriṣii iṣẹlẹ lo waye laaarin oṣu mẹfa naa, ninu rẹ ni Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas ti yan awọn eeyan ti yoo bojuto ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa ni Rivers lati ba a ṣiṣẹ.

Ninu rẹ ni Fubara ati Wike ti ni awon ti pari ija, iyẹn loṣu Kẹfa ọdun yii, ti wọn ṣepade pẹlu Aarẹ Tinubu l’Abuja.
Wọn yan alabojuto eto idibo ipinlẹ Rivers loṣu Kẹfa naa, o mu ariwo dani nitori wọn ni Ọmọwe Micheal Odey ti wọn yan sipo naa ki i ṣe ọmọ ipinlẹ Rivers, wọn ni Cross River lo ti wa.

Odey bẹrẹ iṣẹ rẹ loṣu Keje, o si kede pe ibo ijọba ibilẹ yoo waye yoo waye ni ọgbọnjo oṣu Kẹjọ.

Wọn dibo naa bo tilẹ jẹ pe awuyewuye pọ lori rẹ, ẹgbẹ APC lo si wọle ni ijọba ibilẹ ogun ninu mẹtalelogun.

Wọn bura fun awọn alaga ibilẹ wọle si ọfiisi, Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe si bura fun awọn igbimọ ileeṣẹ ijọba kan.

Nigba to ku ọjọ diẹ ki iṣakoso Ibok-Ete Ekwe Ibas pari, o ṣeto kan to fi ka iye oṣiṣẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹfẹyinti ni Rivers, titi kan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas si kede pe oun ri i pe wọn fi kun owo oṣu awọn eeyan kan ju iye to yẹ kijọba maa san jade lọ.

O ni oun ṣe atunṣe si eyi, oun si ri owo to le ni biliọnu marun-un naira fi pamọ fun ipinlẹ naa.

Ṣugbọn ọpọ oṣiṣẹ ijọba lo tako eyi, wọn ni awọn ko ri owo oṣu Kẹjọ gba, titi kan owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹfẹyinti.

Adele olori oṣiṣẹ to ba wọn sọrọ, rọ wọn lati fi to ọga agba ileeṣẹ wọn leti fun atunṣe.

Ṣaa, Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas, sọ pe oun yin ara oun fun iṣẹ toun ṣe ni Rivers lasiko idilemu naa.
Ireti ọtun pọ fun awọn eeyan ipinlẹ Rivers bi Fubara ṣe n gba ipo rẹ pada lẹyin oṣu mẹfa, ti awọn ile igbimọ aṣofin ibẹ naa yoo ṣe bẹrẹ iṣẹ pada.

Awọn ẹka kan bii Center for Human Rights and Accountability Network (CHRAN) ti ni ki Gomina Fubara gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo tọpinpin bi wọn ṣe nawo ilu lasiko oṣu mẹfa ti Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas fi di ile mu.

Adari CHRAN, Otuekong Franklyn Isong, sọ pe bi Aarẹ Tinubu ṣe da Fubara duro ko ba ofin mu.

O ni abala 305 ofin ilẹ Naijiria ti ọdun 1999 ko fun Aarẹ lagabra lati da gomina ti wọn dibo yan duro ati awọn igbimo ile aṣofin.

O fi kun un pe o yẹ ki Fubara fi idaduro oṣu mẹfa naa kun saa rẹ ni, o si yẹ ki ile ẹjọ to ga julọ da si I ki iru nnkan bẹẹ too tun waye.

Ṣugbọn awoye ati onimọ oṣelu, Olalekan Ige, sọ pe iyẹn kọ lo kan fun wọn ni Rivers bayii, o ni ohun to kan ni ki Fubara gbajumọ iṣẹ rẹ to ṣeṣẹ gba pada.

Ige ṣalaye pe iṣẹ pọ nilẹ fun gomina yii lati ṣe, awọn aṣepati iṣẹ to fi silẹ lasiko idaduro rẹ lo ni o yẹ ko lọọ bẹrẹ pada.

Ati bi idagbasoke yoo ṣe ba Rivers ju ti tẹlẹ lọ.

Awoye oṣelu naa ṣọ pe 2025 lo n tan lọ yii, 2026 ko si ni nnkan mi-in ti oloṣelu yoo fi ṣe ju imurasilẹ ibo 2027 lọ.

O ni yẹ ki gomina yii mọ pe oun ko ni asiko, ko si gbọdọ fi ti araalu naa ṣofo pẹlu.

Ṣugbọn ko tete bẹrẹ awọn eto ti yoo mu aye awọn eeyan ipinlẹ Rivers daa ju ti tẹlẹ lọ.