Nńkan ò ṣe mi o, mo wà láàyè -King Sunny Ade
Fẹ́mi Akínṣọlá
Lẹ̀yìn awuyewuye tó gbòde nípa àlàáfíà rẹ̀ àti pé wọ́n kò rí i, Ọba orin, Ọ̀mọ̀wé Sunday Adeniyi-Adegeye táwọn èèyàn mọ̀ sí KSA, ti ní àlàáfíà lòun wà.
Loju opo Instagram rẹ ni KSA ṣalaye ọrọ si lọjọ keji iroyin to kọkọ jade nipa alaafia rẹ, ati pe wọn ko ri i.
Ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Damilola Esther Adeniyi-Adegeye,lo gbe e jade pe awọn ko ri Sunny mọ, ati pe awọn ko mọ ipo tao wa.
Nigba to n tako iroyin naa, Sunny Ade sọ pe:
”Lodi si iroyin to jade lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, 2025, lati ọwọ Damilola Esther Adeniyi-Adegeye atawọn alajọṣe ẹ ti wọn kede pe mo sọnu, mo n fi asiko yii kede pe:
”Emi Ọmọwe Sunday Adeniyi-Adegeye (MFR), tawọn eeyan tun mọ si King Sunny Ade, mo wa laye, mo wa ni alaafia.
”Irọ patapata ni iroyin ti Damilola Esther Adeniyi-Adegeye atawọn ẹgbẹ rẹ gbe jade.
” Mo wa laye, mo wa lalaafia mo si n dupẹ fun ifẹ ati aajo ẹyin ololufẹmi.
”O ṣe pataki lati yanju irọ ti Damilola Esther Adeniyi-Adegeye atawọn tiẹ pa naa, ki n si fi da gbogbo ilu loju pe mo wa laye, kinni kan o ṣe mi”
Lakotan ọrọ rẹ, KSA kilọ fun awọn oniroyin ofege to n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ jade.
O ni ki wọn ma fi tiwọn ba orukọ rere toun ṣiṣẹ fun jẹ, ai jẹ bẹẹ, ki wọn mura lati foju wina ofin
Ibeere ti Damilola Esther ọkan lara awọn ọmọ agbaọjẹ olorin Juju n ni, Sunday Adeniyi Adegeye ti ọpọ mọ si King Sunny Ade, beere pe nibo ni gbajugbaja olorin naa wa ti da awuyewuye silẹ lori ayelujara.
Esther kọ oriṣiiriṣii nnkan soju opo Instagram rẹ pe oun ko le ba baba oun sọrọ tori oun ko mọ ibi to wa gan an.
Koda, o tun fẹsun kan Dayo to jẹ ọkan lara awọn ọmọkunrin King Sunny Ade wi pe oun lo gbe baba awọn pamọ.
Esther ni oun fẹ ki awọn agbofinro mu Dayo tori oun lo gbe Ọba orin Juju naa pamọ.
”Baba sọ fun Dayo pe awọn fẹ pada lọ sile. Amọ, nibo ni wọn wa bayii?
Nibo lawọn foonu wọn wa tori wọn o gbe ipe lori ago mọ? Nibo ni wọn wa gan an?
Mo fẹ ki awọn ọlọpaa mu Dayo, mo si fẹ ko ko gbogbo owo to ti n ji gba lọwọ baba wa silẹ.
Dayo ro pe oun le salọ nigba kugba tori o ni fisa lati salọ si orilẹede UK,” Esther lo sọ bẹẹ.
Esther ni ọpọ ọmọ King Sunny Ade ni ko lanfaani lati ri i ba sọrọ tori lati ile itura kan si omiran ni baba awọn n lọ.
O ni KSA ko si ni ọfiisi rẹ mọ tori ni gbogbo igba lo n lọ ṣere ni ibikan tabi omiran.
Esther ni Dayo to n ṣe bii mọnija KSA ko jẹ ki agba olorin naa si mi.
Ọmọbinrin naa sọ pe KSA ni lati simi tori o ni oogun to n lo ti dokita fun un, ati pe dokita tun ti sọ fun un ko maa sinmi tori o ti dagba nitori ẹni ọdun mejidinlọgọrin ni i ṣe.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn ọmọkunrin King Sunny Ade, Ademola Adegeye ti sọ fun akọroyin pe ṣaka lara ọba orin Juju naa da.
Ademola ṣalaye pe ko si nnkankan to ṣe King Sunday Ade, ko si si ẹnikan to ji baba awọn gbe.
O ni ilu oyinbo ni Esther to sọrọ lori ayelujara wi pe oun ko lanfaani lati baba oun sọrọ n gbe.
Ademola ni iṣẹ ni ko jẹ ki King Sunday Ade raye rara tori lati ode kan ni wọn ti maa n lọ si omiran.
”Mo le fidi rẹ mulẹ fun yin wi pe King Sunny Ade si ṣere lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.
Lati akoko yii to fi di ipari ọdun ni baba ti ni ibi ti wọn ti maa lọ ṣere fawọn eeyan.
Koda, wọn si maa ṣere ni ọjọ kinni oṣu Karun un ọdun yii l’Ọjọbọ niluu Akure.
Iṣẹ ni ko fun baba laye ni ọpọ eeyan ko fi lanfaani lati maa ri wọn.
Fun apẹẹrẹ, ọjo meji ni wọn maa n fi to irinṣẹ wọn nibi ti wọn ba ti fẹ ṣere.
Awọn naa a si fẹ sinmi lẹyin ti wọn ba ṣere tan ki wọn to tun lọ fun ere mii,” Ademola ṣalaye.
Ademola ni asiko ọjọ ibi King Sunday Ade nikan ni wọn fi silẹ ti wọn o gba ode kankan lati lọ ṣere.
O ni ahesọ ọrọ lasan ni Esther n sọ lori ayelujara pe Dayo ti gbe King Sunny Ade pamọ.
Ademola ni ko ṣee ṣe ki ọmọ ji baba rẹ gbe lọ pamọ.
Nigba ti iwe iroyin Punch naa ba Dayo ti Esther fẹsun kan sọrọ, o ni ṣaka lara King Sunny Ade da.
O sọ fun Punch pe oun kọ ni mọnija baba oun wi pe oun kan n ṣeranwọ fun wọn ni.
Dayo sọ fun Punch pe King Sunny si ṣere nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ẹnikan ni ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja niluu Eko.
O ni isọkusọ ni Esther n sọ kiri lori ayelujara wi pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Dayo ni Esther pe oun lọjọ Ajinde to kọja pe oun fẹ ba King Sunny Ade sọrọ, oun si gbe foonu fun baba, wọn si jọ sọrọ fun bii ọgbọn iṣẹju.
O ni lẹyin naa loun sọ fun Esther wi pe ko wa si Naijiria lati oke okun to ba fẹ ri baba awọn loju koroju.
Dayo sọ pe ati igba to ti bẹrẹ si ni sọrọ oriṣiiriṣii nipa baba awọn lori ayelujara ni o ti ṣe aṣeju ati aṣetẹ
Dayo sọ pe King Sunny Ade funra rẹ yoo fi ọrọ lede laipẹ lori awọn nnkan ti Esther sọ loju opo Instagram rẹ.