“Shadow Government”, tí Pat Utomi gbé kalẹ̀ láti tako ìjọba Tinubu túmọ̀ sí……
Fẹ́mi Akínṣọla
Ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ni àgbà èèkàn lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé, tó tún jẹ́ olóṣèlú Pat Utomi kéde pé àwọn ti gbé ètò ìṣèjọba míràn kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ kan, tí wọ́n ń pè ní “Shadow government”.
Pat Utomi sọ pé àwọn ṣàgbékalẹ̀ ìjọba òdìkejì náà tó pe orúkọ rẹ̀ ní “Big Tent Coalition Shadow Government” lórí ayélujára.
Ó ní àwọn gbé ìjọba náà kalẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ alátakò tí gbá múṣé láti máa ṣàfihàn àwọn ìjákulẹ̀ ètò ìjọba lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Bol Ahmed Tinubu àti láti máa pèsè àwọn ìmọ̀ràn tó yẹ fún ìjọba lórí àwọn ìgbésẹ̀ wọn.
Ó sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ àti ètò ìjọba ló ń dákún ìṣòro àti ebi fáwọn ọmọ Nàìjíríà, tó sì ń mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ kógbá sílé, tó sì tún dákún ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Benue àti Plateau.
Ó fi kun pé àìsí ààbò àti ìwà àjẹbánu náà ń fi ojoojúmọ́ pọ̀ sí ní orílẹ̀ èdè yìí.
Ṣùgbọ́n ìjọba àpapọ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu Pat Utomi pé ìgbésẹ̀ náà kò bá ìlànà ìṣèjọba tí Nàìjíríà ń lò mú.
Mínísítà fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀, Mohammed Idris nínú èsì rẹ̀ sọ pé gbígbé ìjọba ìdàkejì dìde lásìkò tí Nàìjíríà ń palẹ̀mọ́ láti ṣayẹyẹ ọdún Kẹrìndínlọ́gbọ̀n tí a ti ń bá ètò ìṣèjọba àwaarawa bọ̀, jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà rárá.
Idris ní Nàìjíríà kò lo ètò ìjọba irúfẹ́ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó fi ààyè gba ètò ìjọba “shadow government” àti pé òfin Nàìjíríà kò fààyè gbà á.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ìṣèjọba àwaarawa fààyè gba àtakò, ó gbọ́dọ̀ wáyé lọ́nà tó bá òfin mu.
Àgbà Amòfin ní Nàìjíríà, Ahmed Raji ṣàlàyé fún bí BBC News Yoruba pé:
“Shadow Government” dàbí ìjọba òdìkejì léyìí tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí orílẹ̀ èdè kan bá ń lo ètò ìjọba tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ń darí, èyí tí wọ́n ń pè ní “parliamentary system of government”.
Amòfin Raji ní ètò ìṣèjọba tí à ń lò lọ́wọ́ ní Nàìjíríà, tí a ní ìgbìmọ̀ aṣòfin méjì. ìyẹn ilé aṣòfin àgbà àti asọjúṣòfin, kò fi ààyè sílẹ̀ fún “shadow government rárá.
“Ohun tó ń jẹ́ “shadow government” ni pé, a máa ní ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìjọba àti ẹgbẹ́ alátakò.
Ẹgbẹ́ alátakò yẹn náà ma wá ní ètò sílẹ̀ bí ẹni pé ìgbàkígbà ni àwọn le de ìjọba.
Ó ní gbogbo olùdarí tí ìjọba tó wà lóde bá yàn náà ni ìjọba òdìkejì náà máa ní bíi mínísítà fétò ìdájọ́, ètò, ọ̀gbìn, ètò ẹ̀kọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó wòye pé ètò ìjọba tí Nàìjíríà ń lò báyìí tó jẹ́ “Presidential system of government” ni kò sí ètò fún irúfẹ́ ètò bẹ́ẹ̀ lábẹ́ òfin yìí.
Amòfin Raji ṣàlàyé pé kò sí òfin kankan tó gbé ìjìyà kalẹ̀ fún ẹni tó bá gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí dìde.
“Mi ò rò pé ó yẹ kí ìjìyà kankan yẹ kó dìde níbí ohun tó yẹ káwọn èèyàn mọ̀ ni pé èyí tí Pat Utomi ṣe yìí dàbí àwọn tí a lè ṣe àpèjúwe bíi èyí tó ń ta ìjọba jí sáwọn ojúṣe rẹ̀.
“Nítorí gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ kò lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, wọn lè máa pe àkíyèsí àléébù ìjọba sáwọn èèyàn.
Ẹni tó bá dẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tí wọ́n bá ń sọ a gbọ́ wọn, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ sí wọn, a máa lọ.”
“Èmi ò lérò pé ó yẹ kí ìjọba fẹ́ fi ìyà jẹ wọ́n fún nǹkankan, tí ìjọba bá ṣe ìyẹn, wọ́n fẹ́ máa pèrò sórí nǹkan tí wọ́n ń ṣe nìyẹn. Kí ìjọba máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ ti wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan.”
Lára nǹkan tí Pat Utomi ní ìgbìmọ̀ ìṣèjọba òun yóò máa ṣe ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ètò tí yóò mú ìrúgọ́gọ́ bá ètò ọrẹ̀ ajé Nàìjíríà, bí ètò ààbò máa ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti àtúntò ìwé òfin òfin Nàìjíríà.
Bákan náà ló ní àwọn yóò rí sí ọ̀rọ̀ ìlera, ẹ̀kọ́, òfin, ìdàgbàsókè àwọn ohun amáyédẹ́rùn àti ṣíṣe àmójútọ àwọn ètò ìjọba.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí Pat Utomi ṣe ní àwọn fi gbé ìjọba òdìkejì náà sílẹ̀, Amòfin Raji ní lábẹ́ ètò ìṣèjọba àwaarawa tí Nàìjíríà ń lò, kò sí ẹni tí kò lè pe àkíyèsí ìjọba sáwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó bá ń wáyé.
Ó ní èèyàn kò nílò láti pè é ní ìjọba òdìkejì “shadow government” kó tó le ṣe gbogbo àwọn nǹkan tí Pat Utomi sọ náà.
Ó wòye pé ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ní Nàìjíríà ló ń sọ̀rọ̀ sí gbogbo ìgbésẹ̀ àti ètò ìjọba pàápàá láwọn ọ̀nà tó ń gbà kó ìpalára bá àwọn aráàlú.
“Gbogbo àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ló ń sọ̀rọ̀, ẹgbẹ́ òkè ọya wọ́n ń sọ̀rọ̀, àwọn ẹgbk Afenifere wọ́n ń sọ̀rọ̀… kálukú ń sọ tẹnu rẹ̀, ẹni tí kò lẹ́gbẹ́ kankan náà lè sọ̀rọ̀.
“Lára nǹkan tí wọ́n ń wí ni pé ìwé òfin tí à ń lò yìí kò da, kò lè mú wa dé ibìkankan, gbogbo àwọn nǹkan yẹn ààyè wà fun lábẹ́ òfin, kálukú le sọ pé ìjọba kò ṣe eléyìí dáadáa, báyìí ni kí ẹ ṣe ṣé, ààyè ṣùgbọ́n kí a wá ní ìjọba ìdákọ́ńkọ́, kò sí ohun tó jọ ọ́.
Ṣáájú kí ètò ìṣèjọba àwaarawa tó padà sípò ní Nàìjíríà lọ́dún 1999, ìjọba “shadow government” máa ń wáyé lásìkò àwọn ológun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fìdí múlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ètò àti ìgbésẹ̀ àwọn ológun láwọn tí wọ́n ń ṣèjọba lábẹ́nú máa ń ní ipa le lórí tó fi mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Láwọn àsìkò yìí, àwọn kan tí wọ́n ní agbára lórí ètò ìlú máa ń dá sí ọ̀rọ̀ ìlú tí ọ̀rọ̀ wọn tàbí ìgbésẹ̀ wọn sì máa ń ní ipa gidi.
Ṣùgbọ́n ètò shadow government kìí ṣe àjòjì sáwọn ilẹ̀ Africa kan bíi Benin, Ghana, Kenya, Mozambique àti Zimbabwe.
Ní orílẹ̀ èdè Benin, Ààrẹ Patrice Talon wà lára àwọn tó jẹ́ olùdásílẹ̀ shadow government kó tó di ààrẹ orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 2016.