Atiku àti Obi ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ mi láti àtìmọ́lé Kuje – Sowore
Omoyele Sowore to jẹ gbajugbaja fun jija fun ẹtọ ọmọniyan ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ di ni papa mọra fun ẹsun ibani-lorukọ-jẹ. Sowore pe Aare Bola Tinubu ni ọdaran ni eyi to dọran sii lọrun. Ile-ẹjọ ni ko lọ f’asọ penpe roko Ọba ni ọgba ẹwọn Kuje.
Ọjọ mẹsan-an gbako ni Sowore lo ni atimọle ki wọn to gba beeli rẹ pẹlu miliọnu lọna igba pẹlu oniduro ti o ni ile to kajuẹ, ti owo ori ẹni naa pe, ti ẹni naa si jẹun kanu to tun rẹsẹ walẹ pẹlu ori ade kan.
Ọjọ kẹsan-an ti Sowore jade lo tun ti bẹrẹ si ni ba awọn oniroyin sọrọ lori ohun toju ri latimọle.
“Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuye (DSS) lo f’ọwọ sinkun ofin mu mi, wọn kọkọ da mi duro fun wakati kan gbako lai si nnkankan. Wọn gbe mi si inu ọkọ dudu wọn, wọn si bẹrẹ si ni f’ibọn dun ikoko mọ mi, mo jẹ ki wọn mọ pe, a ki n pohun magogo lẹnu, ẹ ti se eleyii ri ti ko ge iyẹ apa mi, kin le wa n dara yin laamu fun? Mo mọ pe gbogbo idun kooko yi ko sẹyin ọga awọn ọtẹlẹmuyẹ, Ọgbẹni Tosin Ajayi.”
“Gbogbo nnkan maa n sisẹ fun ara wọn ni, to ba jẹ Atiku tabi Obi lo wa ni atimọle bẹẹ maa ti ko awọn eniyan sodi lati gba wọn silẹ sugbọn wọn ko le se bẹẹ fun emi. Atimọle yii naa ni mo wa ti wọn tun ti n ransẹ si mi pe ijọba ti da ẹgbẹ awọn nu. Mo jẹ ko ye wọn pe emi ti mo wa latimọle ko le ja fun wọn, mo ni ki wọn yanju ara wọn.”









