Ìdí tí Tinubu fi máa jáwé olúborí nínù ìbò 2027 – Donald Duke
Gomina tẹlẹ ri ni ipinle Cross River to tun je oludije du ipo Aare fun egbe PRP (People Redemption Party), Alagba Donald Duke lo n salaye fun awọn oniroyin ni ana ọjọ wẹside.
O ni “iyapa ẹnu to sẹlẹ laarin igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri ni orileede yii, Atiku Abubakar, Peter Obi to jẹ gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Anambra ati Kwankwaso lo fun Tinubu laye jẹ ni ọdun 2023, ti ẹnu ko ba tun ko fun ibo pdun 2027, a jẹ wi pe wiwọle Tinubu ti maa rọrun ju”.
O tẹsiwaju pe ti Atiku ati Obi ti wọn fẹrẹ maa leke ẹgbẹ alatako ba tun pin yẹlẹ-yẹlẹ, a je wi pe Tinubu maa wọle ẹlẹẹkeji niyẹn nitori imọ tara ẹni nikan to n ba wa ja”.
Donald Duke tun se afiwe orileede Amerika ti a n tele pẹlu eto oselu ati isejọba wọn pe “orileede Amerika ni ẹgbẹ oselu meji, ti awọn naa ba lọ tọwọ aye bọ ẹgbẹ oselu Democrats gẹgẹ bi apẹẹrẹ, ti wọn pin si meji tabi mẹta, a jẹ pe ẹgbẹ oselu Republicans maa selu lọ titi aye” gẹgẹ bi o se salaye ni ori ẹrọ tẹlifispọn Channels ni ori eto owurọ wọn.









