Temi Nkem jẹ mílíònù 160 nairà pẹ̀lú mọ́tò SUV ni BBNaija
Arabinrin ẹni ọdun mọkanlelogun di miliọnia lojiji. Temitope Chigbue to kopa ninu idije Big Brother Naija Season 11 lo ti gbade idije naa nigba to na awọn mẹjọ to ku ti wọn jọ yege wọ idije asekagba.
Awọn mẹrinlelogun lo bẹrẹ idije yii ninu osu keje ọdun yii ki o to wa ku oun, Aikou, Barry, Bluethopia, Flora, Oyin, Richy, Sheba ati Tram.
Temi ti jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ SUV pẹlu miliọnu ọgọjọ naira.
Nigba ti idije yii bẹrẹ ni ọpọ ti ni awọn rii pe ọjọ iwaju wa fun un. O salaye ara rẹ bi ẹni ti ko see tete foju parẹ, o ni oun ni igboya, oun si tun fẹran lati maa sọ nnkan bo ba se ri.
Temi ni oun fẹran lati maa rin irin afẹ, sọrọ ati jẹun ni igba ti owo ba dilẹ. O ni oun tun kundun lati maa fi ọrọ ọlọrọ se arikọgbọn nitori pe oun maa n farabalẹ gbọ tẹnikeji.









