Aarẹ orileede yii, Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu lo n salaye yii fun gomina Ademola Adeleke to tun pade wọle ibo l’Ọṣun.
Ademola Adeleke sabẹwo si Aarẹ lati f’ẹmi imoore han nipa bi eto idibo Ọṣun se lọ.
Ibẹ ni Aarẹ ti n salaye fun gomina ati awọn ikọ rẹ pe ki o se ijọba rẹ daadaa. Ki o jẹ ki awọn ara ipinlẹ Ọṣun mọ idi ti wọn fi lọ to lati dibo fun un.
Aarẹ tun fi kun un pe “loootọ lo ti jawe olubori nibi ibo, ma rii bi ẹni to jagun to si rẹyin awọn ọta rẹ. Sise pọ pẹlu awọn alatako rẹ ki ẹ le gbe ipinlẹ Ọṣun de ebute ogo”.
Aarẹ tẹsiwaju pe “ko si bi ẹgbẹ alatako ko se ni maa topinpin tabi ṣe enini ijọba rẹ sugbọn ma wo ibẹ, koju si isejọba rẹ ki awọn ara ipinlẹ le jẹ mundun-mundun ijọba tiwa-n-tiwa”.
Ibi abẹwo naa ni Aarẹ tun ti salaye pe ” olori ẹgbẹ alatako kan ni ti oun ba wọle ibo Aarẹ ni 2027, oun maa da owo iranwọ epo pada ki ara le dẹ gbogbo eniyan. Eyi jọmi loju pe alaimọkan-mọkan ni awọn oloselu kan. Owo iranwọ-epo ti ko jẹ ki gomina mẹtadinlọgbọn (27) ri owo osu osisẹ san ninu ipinlẹ mẹrindinligoji (36) ti a ni lorileede yii”.
Aarẹ tun ni “ninu owo osu ti awọn eniyan fi n bọ ẹbi ati ara wọn, ti wọn ti n san owo ile ati ti ileewe. Awọn ipinlẹ kan tilẹ n san ilaji owo osu kanrin ki n to de, iyalẹnu nla lo je nigba ti mo tun gbọ ti ẹnikan tun ni ti oun ba wọle ibo Aarẹ, oun tun maa dawa pada sẹyin”.
Gbogbo awọn alaye ati imọran yii lo jade ninu abẹwo gomina Ademola Adeleke ni ogunjọ osu yii ni ilu Abuja.









