Nnkan ko sẹnu re ninu ẹbi ọdọmọdekunrin Albert gẹgẹ bi itan ayelujara se gbe e.
Wọn ni ọrọ ileewe gan-an ko si ninu ero ẹbi Albert nigba ti ko sowo.
Bi oju ogun se wa le to naa nigba naa, wọn ni ẹrin Albert o ni isẹ ati osi ninu. Ẹrin naa ko ni adọgbọn-rin ninu. O maa n rin-in bi Eledua se da ọmọ naa.
Bi ere bi awada ni enikan gba ẹrin naa silẹ ti o si bẹrẹ si ni rin titi to fi sọ ẹbi Albert di oloriire.









