Iná soro ní Computer village ti Ikeja
Ìròyìn òwúrọ̀
Ijamba ina sẹlẹ ni isọ to gbaju-gbaja ti wọn ti n ta gbogbo nnkan to jọ mọ foonu ati ẹrọ kọmputa.
Odidi ile alaja meji lo jo kanlẹ ti ọpọlọpọ ẹrọ kọmputa si wa ninu rẹ.
Ile yii wa ni opopona Somoye Osundairo ni Ikeja. Awọn dukia to le ni ọpọlọpọ miliọnu naira lo ba isẹlẹ buruku yii lọ.
Osan hangman ni ina naa soro ti ko si tii si eni to mo ohun to fa ijamba naa. Gbogbo itu meje ti ọdẹ n pa ninu Igbo ni awọn ajọ LASEMA (Lagos State Emergency Management Agency) pa lati le dẹkun ina naa lonii ogunjọ osu kin-in-ni ọdun 2026.
Ohun kan to yanju nibẹ ni pe ko mu ẹmi kankan lọwọ.









