Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé obìnrin mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Oyo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọwọ́ ti tẹ afurasí ajínigbé obìnrin mẹ́ta ní ìlú Ìkòyí Ilé, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Oríire, níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade ti alukoro wọn, CSP Ayanlade Olayinka fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Awọn afurasi yii ti orukọ wọn n jẹ Nurudeen Fathia, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Fatai Taiwo, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Munirat Saliu, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni ọwọ tẹ lẹyin akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.
Alukoro Ayanlade ninu atẹjade ọhun ṣalaye wi pe ọlọpaa ipinle Oyo gbe igbesẹ lẹyin ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Islamiat Omowunmi fi to awọn leti pe awọn afurasi yii n dunkoko mọ ohun.
Omowunmi to n ṣiṣẹ alapata tun ṣalaye wi pe awọn afurasi wọnyii beere fun ẹya ara eniyan ati millionu mẹwaa naira lọwọ oun.
Nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn afurasi ajinigbe yii jẹwọ pe otitọ lawọn beere fawọn nnkan naa, amọ ere lawọn n ṣe.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Femi Haruna dupẹ lọwọ ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlopaa Naijiria IGP Kayode Egbetokun fun atilẹyin rẹ lati pese eto aabo to peye ni ipinlẹ naa.
O tun ṣalaye wi pe awọn yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin naa ni ọlọpaa rọ awọn ara ilu lati maa fi ọrọ eto aabo agbegbe wọn to ileeṣẹ ọlọpaa leti paapaa julọ ti wọn ba fura si ẹnikẹni.









