Alága onímọ́tò Oṣòdì yarí mọ́ àwọn onímọ́tò tó ń gbé àdúgbò N200 ní N500 lọ́wọ́

Alága onímọ́tò Oṣòdi yarí mọ́ àwọn onímọ́tò tó ń gbé àdúgbò N200 ní N500 lọ́wọ́

Yínká Àlàbí

“Gbogbo ọmọ Naijiria lo maa n wa baba”. Lasiko ọdun bayii ni awọn oke okun, gbogbo owo ọja lo maa n dinwo. Orisiirisii puromo lo maa n waye lati le jẹ ki ara rọ araale ati arooko, sugbọn atoripodi ni o jẹ ni orileede yii.
Lasiko ọdun bayii ni awọn kan maa n fẹ jẹ ere ajẹpajude. Eyi gẹlẹ lo sẹlẹ ni Oṣodi to wa ni ilu Eko. Nigba ti ọga awọn onimọto ilu naa gbọ pe wọn ti n gbe Oṣodi si Muṣin isalẹ ọja ni N500 dipo N200.
Alaga yii bọ si ita, o ni ki awọn onimọto bẹru Ọlọrun, “nigba ti epo n wale ni ẹyin wa tun n fi kun owo mọto.”
Ọ̀gbẹ́ni Saka to jẹ Alaga na yari mọ awọn onimọto lọwọ pe owo mọto adugbo naa ko gbọdọ ju igba naira ti wọn n gbee tẹlẹ lọ. Funra Alaga yii lo n sọ fun awọn ero pe wọn ko gbọdọ san ju N200 lọ.
Ti gbogbo wa ba le se eleyii nibi ti agbara wa ba mọ, boya ilu yii ko ba ti dara ju bayii lọ.

https://www.facebook.com/share/1G3hBp6AfN/

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here