Aláàfin fìtàn balẹ̀ lórí Seyi Tinubu

Aláàfin fìtàn balẹ̀ lórí Seyi Tinubu

Yínká Àlàbí

Alaafin ti ilu Oyo, Oba Akeem Owoade fitan balẹ ni ilu Oyo ni ọjọ kọkanlelogun, osu kejila ọdun 2025.
O gbe oye Ọkanlọmọ ti ilẹ Yoruba le Seyi Tinubu lori. Seyi ni ọmọ bibi Aarẹ Bọla Tinubu. Iru oye bẹẹ ko tii waye ri.
Seyi ati iyawo rẹ tete de si Aafin Oyo nitori ayẹyẹ naa pẹlu aabo to gbopan.
Tolori tẹlẹmu lo peju Sibi oye naa, latori Aarẹ ile igbimọ asofin agba, Godswill Akpabio; gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ,Otunba Gbenga Daniel; igbakeji Aarẹ ile igbimọ asofin kekere Benjamin Kalu, Minisita ina mọnamọna, Chief Bayo Adelabu; Minisita eto isuna ati ọrọ aje, Olawale Edun; Minisita eto isiro, Adeyemo Adeniran ati Sẹneto Teslim Folarin pẹlu gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Kano to tun jẹ agba ẹgbẹ, Abdullahi Ganduje. Koda awọn eniyan pataki tun wa lati orileede Benin.
Ẹni ti ko le rin ni ki wọn gbe oun nibi ti ilu Oyo gbalejo de.
Ewe oye a mọri ni adura ti gbogbo awọn alejo ati onile n se fun Seyi ni ọjọ iwuye naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here