Ìwọ́de àjọ òsìsẹ́ wáyé jákè jádò orílèèdè yìí lónìí
Yinka Alabi
Ajọ awọn osisẹ ti orileede yii (NLC) tẹ̀síwájú pẹ̀lú iwọde wọn pẹlu gbogbo ipade ti wọn se pẹlu Ààrẹ Bola Tinubu ní alẹ́ ọjọ́ Ìsẹ́gun.
Àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sọ pé ìpàdé náà kò tó láti dá iwọde dúró. Nítorí náà, Ààrẹ NLC, Joe Ajaero, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mìíràn àti àwọn ẹgbẹ́ awùjọ, péjọ sí Ilé-iṣẹ́ NLC ní Abuja láti bẹ̀rẹ̀ iwọde náà.
Aja fẹtọ omoniyan to tun dije du ipo Aare ri ni orileede yii, Omoyele Sowore, àti ẹgbẹ́ Revolution Now Movement tún darapọ̀ mọ́ iwọde náà. Sowore sọ pé orílẹ̀-èdè yii wa ninu ibanujẹ nítorí àìlera ààbò, tí ìjọba sì ti kùnà láti dáàbò bo àwọn aráàlú.
Ó tún ṣàlàyé pé ìjìyà ìfipa-gbé ènìyàn ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, paápàá ní ilé ìjosìn, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọde ṣi wà ní ìgbèkùn ní Ìpínlẹ̀ Niger, àti pé àní àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà kan tún ti gba wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Burkina Faso. Ó sọ pé àkókò ti tó kí ará Nàìjíríà sọ pé, “Ó tó bẹ́ẹ̀.”
Ìròyìn tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé iwọde náà ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Lagos, Enugu, Rivers, àti Abuja, níbi tí àwọn olórí NLC ti ń bẹ ìjọba pé kí wọ́n mu ààbò ẹ̀mí àti ohun-ini aráàlú lokunkundun.









