Ó mà se o! Ikú pojú igbákejì gómìnà Bayelsa dé

Ó mà se o! Ikú pojú igbákejì gómìnà Bayelsa dé

Ìròyìn òwúrọ̀

Aisan lo se wo, a o ri t’Ọlọjọ se. Lawrence Ewhrudjakpo to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa lo subu to si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe.
Igbakeji gomina yii sẹsẹ pari ipade pẹlu awọn ajọ UNICEF ni o ba ni ki ohun pada si ofiisi lo ba dede subu, awọn to tẹlee sare du ẹmi rẹ lọ si ile iwosan
Federal Medical Centre (FMC) to wa ni Yenagoa.
Ile iwosan naa ni dokita ti jẹ ki o ye wọn pe igbakeji gomina ti dagbere f’aye.
Bi Douye Diri to jẹ gomina ipinlẹ naa se gbọ lo ti sare tẹ ọkọ leti lati oke okun, ni eyi to jẹ ki o wa lọna bayii.
Ewhrudjakpo daye ni ọjọ karun-un osu kẹsan-an ọdun 1965 ki iku to poju rẹ de lonii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here