Ilé Ayé, ilé Àìyé

Ilé Ayé, ilé Àìyé

A ku ojo mẹta ẹyin alarojinle IWE IROYIN OWURỌ, iranti ile Aye ti o yẹ ko jẹ ile Aiye ni mo fẹ ki a jọ fi oju Arojinle wo lonii.

Gbogbo wa la jọ maa n wa ninu yara ikawe kan naa, idanilẹkọọ kan naa, ibawi kan naa, fifi olukọ se yẹyẹ ni ọpọ igba kan naa, fifun olukọ ni alajẹ ko jinna si ẹnu wa. Gbogbo wa jọ n jokoo pọ lai mọ ori olowo, a jọ n wo ankoo ileewe, ko si aga to yatọ si ara wọn bẹẹ naa ni gbogbo wa jọ n ni ero ọjọ iwaju to dara.

Ko si ninu wa to sọọ jade pe oun ko le lowo laye ni t’oun, ko si ẹni to tilẹ ro pe oun ko le ri isẹ gidi laye, paapaa julọ awọn to mọwe ninu wa ti han gedengbe pe awọn ti mu poro to mọ. O ti han pe awọn maa tete lowo laye siwaju awọn to ku diẹ kaa to ninu eto ẹkọ.

Sugbọn ile aye yatọ patapata si yara ikawe. Ile aye da bi igba ti eniyan n pidan, ti o ba wu ile aye, o le gbogo f’ọlẹ, ẹni to ya olodo ju ni yara ikawe le kọkọ lowo ju awọn to n gbe igba oroke ni yara ikawe lọ. Ile aye si tun le kọkọ fun ẹni to m’ọwe ju ni owo saaju gbogbo awọn to ku. Eyi tilẹ maa n jẹ ki ọpọ awọn ọmọ ode oni maa sọ pe Ẹ̀TÀN ati JÌBÌTÌ ni ileewe. Ti ẹ ba si ba wọn jiyan, ẹrọ ayelujara maa bẹrẹ si ni gbe orukọ jade iye iwe ti ẹni to lowo ju ka, bi wọn se le ẹni to lowo ju kuro ni ile iwe, bi ẹni to lowo ju nigba kan se gbe iwe ẹri to gbẹyin jade nile iwe to lọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ile Aiye ni Aye, ko si ẹni to le pe Eledua l’ẹjọ pe bawo ni ọmọ to y’olodo logun ọdun sẹyin se wa di olowo tabua bayii, abi bawo ni ọmọ to gọ ti gbogbo eniyan maa n fi se yẹyẹ se maa wa di oga ileesẹ nla. Eyi to wu ka wi, t’Ẹlẹda lasẹ. Ko si ẹni to ye ninu wa. Ọpọ iriri aye yii ko tilẹ jinna nigba miiran, bi awa se pari eto ẹkọ girama wa ni a ti n ri ninu awọn to mọ eto isiro ju ninu wa ti gba ẹnu ẹkọsẹ lọ nigba ti awọn obi ni ko si agbara lati tẹ siwaju ninu eto ẹkọ.

Bi o kuku se wu Oluwa lo n sọla rẹ, elomiran le lowo tabua lati ẹnu isẹ kikọ naa ti o je wi pe ede Gẹẹsi nikan I’ẹni to tẹ siwaju eto ẹkọ maa ni ju olowo lọ.

Ju gbogbo rẹ lọ, ẹ jẹ ki a maa se daadaa ni ibi gbogbo ti aye ba yi wa si nitori pe aye to n yi lọ si apa ọtun le tete pada si apa osi, gbogbo iranlọwọ ti a ba si le se fun ara wa, ẹ jẹ ki a see, ko si ẹni to m’ọla o.

Ipade tun di ọsẹ to n bọ l’asẹ Edumare.