Mi ò bè̩rù láti bè̩rè̩ isé̩ mi, ni Danny Young so̩

Mi ò bè̩rù láti bè̩rè̩ isé̩ mi, ni Danny Young so̩

Mary Fágbohùn

Olorin, Danny Young, ti safihan pe oun ko foya lati bere ise oun leekan sii, koda leyin aaye isinmi ti o ni fun iwon igba die lati lo ko nipa orin si.

Olorin naa, ti a mo fun asepe ati igboya re, so pe eru je ohun kan ti o maa n so eniyan di apadanu.

“Mo je alasepe, mo si gbagbo ninu ara mi ati pataki iwadii ati agbeyewo,” ni Danny Young so. “Niwon igba ti mo ba ti mo nnkan ti mo fe se, maa bere ni, maa si fi eyi toku le Olorun lowo.”

Nigba to n soro lori aaye re, Danny Young salaye pe aaye isinmi naa fun oun ni anfaani lati se akiyesi bi ile ise orin se sun siwaju ati awon nnkan ti won n se lowo, o si fi dani loju pe ipadabo wa oun yoo ni ipa rere.

O yo ero naa pe asiko ti oun ko fi sise naa le pa aseyori oun lara kuro, o tokasi pe gbogbo iran ni o ni iriri isubu ati idide orisiirisii olorin.

“Awon olorin maa n wa won si n lo ni gbogbo iran,” o tesiwaju. “Sugbon mo mo pe pelu igbaradi ati iran ti o han kedere, ipadabo wa mi le e je ti alagbara. Ko si eru fun mi.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here