Jeriq: Ìgboro ni mí
Mary Fágbohùn
Olorin takasufe Naijiria Jeremiah Chukwuebuka, eni ti a mo si Jeriq ti pe ara re ni ohun igboro.
Ninu iforo-jomi-toro oro to se laipe yi pelu Apple Music 1, Jeriq soro lori ibeere ise orin re ati eto ti o ni lati se ere ni gbagede.
“Nibi ti mo ti wa, mo je ohun igboro—mo je akoni ni ilu mi. Mo feran igboro; igboro ni mo ti wa, nitori naa mo le ni asopo pelu awon elomiran. Ti mo ba je olooto pelu re, igboro lo so mi da ohun ti mo da yi. Mi o le se nnkan lai si igboro, nitori naa mo n pinnu lati se ere ni gbagede ni osu kokanla, iru nnkan ti mo se seyin. Mo n so di nla.”
Lori bi o se bere ise orin re, o wi pe, “Mo bere orin ninu [ijo Aguda] ile ijosin. Mo wa ninu egbe akorin, nigba naa ni mo ti n ni asopo pelu orin fun igba akoko. Baba mi maa n fi orin Emeka Morocco si etigbo wa, orin yi ati orin ile ijosin ni mo n gbo nigba ti mo n dagba. Nigba ti mo setan ni ile iwe—ni 2015—mo fo si yara igborin mo si ko orin kan. Mo ti n ko orin sile tele, sugbon igba naa ni mo se igbasile orin akoko mi ti mo si gbe jade.”