Ilé E̩lé̩gbò̩n-ó̩n Àgbà Naijiria abala ke̩sàn-án : ‘Chinwe lè lo̩ sùgbó̩n mi ò ní lo̩ pè̩lú re̩’ – E̩nìkejì, Zion

Ilé E̩lé̩gbò̩n-ó̩n Àgbà Naijiria abala ke̩sàn-án : ‘Chinwe lè lo̩ sùgbó̩n mi ò ní lo̩ pè̩lú re̩’ – E̩nìkejì, Zion

 

Oludije Ile Elegbon Agba Naijiria abala kesan-an, Zion ti so pe orebinrin oun teleri ati enikeji re le e kuro lori eto naa sugbon oun ko ni tele bi o ti le je pe won jo wa sori eto naa ni.

Irohin jade pe Chinwe hale lati kuro ni ori eto naa ni ale Ojobo leyin ti o fi esun kan orekunrin ati enikeji re lori eto naa, Zion, pe o n te oun loju mole lati le e te awon omole to ku lorun.

Ni aaro ojo Eti, o so fun omole kan Michky pe oun ti so ipinnu oun fun Biggie lati kuro ni ori eto naa.

Leyin ihale re, Zion ni oun ko ni tele oro Chinwe lati jade sugbon o seleri lati fehonu han ti Biggie ba pinnu lati fi ipa lee jade kuro lori eto naa nitori ofin ti o de abala naa, eyi ti awon oludije ti n figagbaga ni meji meji.

Ninu iforowero pelu Anita, Zion wi pe, “Ose keji niyi, mi o gbodo da omi pa eefin ina, sugbon iye tumo si pe o ti gbagbe idi ti a fi wa nibi. Ko si idi ti o ko fi le pada si ile.

“Ti o ba fe lo, o le e lo, loooto, a jo wa sibi ni, ko tumo si wi pe a gbodo jade papo. Ti o ba lo si odo Biggie, e je ko so pe oun fe lo, mi o so pe mo fe lo si ile.

“Mo le yo baaji ZinWe kuro, Zion yoo wa ninu ile. Ko mu ogbon wa pe ki o fi ti ara re pa temi lara. A jo wa nibi ni, ka si jo lo papo, ka ran ara wa lowo ninu ere naa. Gbogbo ipo yi yoo ran wa lowo lati dagba, ko ye ki o mu wa pinya.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here