Adájọ́ da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Bàbà Ìjẹ̀ṣà pè nù, wọ́n ní dandan ni kó lo ọdún márùn-ún lẹ́wọ̀n

Adájọ́ da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Bàbà Ìjẹ̀ṣà pè nù, wọ́n ní dandan ni kó lo ọdún márùn-ún lẹ́wọ̀n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹsẹ̀ kò gbèrò nílé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan tóo wà nílùú Ìkejà, níìpínlẹ̀ Èkó, lásìkò ìgbẹ́jọ́ ti adẹ́rìn-ín-pòṣónú nnì, Ọ̀gbẹ́ni Ọlanrewaju James, ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí Bàbá Ìjesha pè, láti dín iye ọdún tí Onídàájọ́ Oluwatoyin Taiwo jù ú sí lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kẹjọ, ọdún 2022 kù.

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ni wọn ba Baba Ijesha ṣẹjọ lori ẹsun iwa ti ko bofin mu wọn fi kan an pe o n ba ọmọde kan tọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹrinla lọ ṣere egele. Iwaju Onidaajọ Oluwatoyin Taiwo, tile-ẹjọ akanṣe kan to n ri si lilo ọmọde nilokulo ati fifipa ba awọn obinrin sun, ‘Special Offences Court’, to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn wọ Baba Ijesha lọ nigba naa lọhun-un. Ẹsun mẹfa ọtọọtọ, ninu eyi ti igbiyanju lati ba ọmọde ni nnkan pọ, lilo ọmọde nilokulo ati bẹẹ bẹẹ lọ wa ni wọn fi kan oṣere yii. Lẹyin gbogbo atotonu oun ati ti lọọya rẹ, adajọ ju u sẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko.

Nigba ti igbẹjọ rẹ waye l’Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, Onidaajọ Fọlashade Ojo to ṣaaju ikọ adajọ ẹlẹni mẹta kan to n gbọ ẹjọ rẹ ni ko si awijare kankan fun olujẹjọ nipa ẹjọ kotẹmilọrun to pe. Pe o gbọdọ lo iye ọdun ti Onidaajọ Abilekọ Taiwo da fun un lọgba ẹwọn.

O ni ọrọ to sọ lọdọ awọn ọlọpaa Sabo, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ati lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, nipa ipa to ko ninu ẹsun ti wọn fi kan an ko yatọ rara.

Pẹ̀lú ìdájọ́ yìí, ìrètí Bàbá ljẹṣa láti tètè kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ti já sí pàbó, àfi bó bá tún gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ nílẹ̀ wa ló kù.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here