Abilékọ kan figbeta níwájú adájọ́ n’Ílọrin: “Mo fẹ́ kọ̀ ọ́ lọ́kọ kò sí ààbò f’ẹ́mìí mi mọ́”
Fẹ́mi Akínṣọlá
Iwájú Onídàájọ́ Sakariyau Abdulrasak, tilé-ẹjọ́ kọkọ-kọkọ kan tó wà ní agbègbè Akérébíata, niluu Ìlọrin, tí í ṣe olú ìl ipinlẹ Kwara, làwọn tọkọ-taya méjì kan, Abilékọ Ajara Taofeek àti Ọ̀gbẹ́ni Taofeek Abdulrasheed, wọ́ ara wọn lọ. Abilékọ Ajara ló gbé ẹjọ́ ọkọ rẹ̀ lọ sílé-ẹjọ́ ọ̀hún pé kí adájọ́ bá òun tú ìgbéyàwó ọdún gbọọrọ tó wà láàrin àwọn méjèèjì ká, kí kálùkù àwọn lè máa lọ láyọ̀ àti àlàáfíà báyìí.
Ninu ọrọ rẹ nile-ẹjọ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, inu mi maa dun gidi bẹ ẹ ba le tu igbeyawo ọdun gbọọrọ to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi yii ka, ẹmi mi ti fẹẹ pin, ko si aabo fun ẹmi mi mọ o, mi o si fẹẹ foju sunkun ọmọ mi mọ.
‘‘Ọmọ marun-un ni mo bi fun baba ọmọ mi yii, ọkan si ti ku, wọn ṣẹ ku mẹrin. Nitori ẹmi mi atawọn ọmọ mi, mi o fẹẹ foju sunkun ọmọ kankan mọ, Oluwa mi, ẹ ba mi bẹẹ ko yọnda mi”.
Olujẹjọ, Taofeek Abdulrasheed, sọ fun ile-ẹjọ pe, ‘’Iyawo mi ko ri ẹsun kankan ka si mi lọrun pe ohun ti mo ṣe ree, o kan ni oun ko ṣe mọ ni, ṣugbọn emi ko ṣetan lati kọ iyawo mi, mo si nifẹẹ rẹ.
“Obinrin gidi niyawo mi, ni asiko to rẹ mi, ti ẹṣẹ mi da, o duro ti mi, ṣaaṣa lobinrin to le duro ti ọkọ lọjọ iṣoro, koda, oun lo n gbọ gbogbo bukaata ile, ṣugbọn ara mi ti ya, emi naa si ti n ṣiṣẹ bayii.
Gbogbo igbiyanju adajọ lati mọ idi pataki ti Abilekọ Ajara, fi ni oun ko ṣe mọ lo ja si pabo, ‘ko si ifẹ mọ, ẹmi mi ti pin’ ni orin ti obinrin naa n kọ.
Adajọ Sakariyau sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2024.