Ìmáàmù Ogbomoso sọrọ lórí ìwé ìfisùn tí Soun fi ránṣẹ́ sí i
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìmáàmù àgbà ìlú Ogbomọṣọ, Sheikh Taliat Yunus Oluṣina Ayilara ti sọrọ lórí ìròyìn tó ní pé Kábíyèsí Soun ti ìlú Ogbomoso, Ọba Ghandi Ọlaoye, ti fi ìwé ìfisùn ránṣẹ́ sí i pé kó wa sàlàyé ara rẹ̀ lórí bí ó ṣe rìnrìn àjò lọ sí Saudi Arabia fún Hajj láì gba àṣẹ lọwọ́ Kábíyèsí náà.
Sheikh Ayilara sọ fún àwọn akọròyìn lórí fóònù pé ”gẹgẹ bi ẹni tí ó mọ òfin ti kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ pa idà òfin lójú, gbogbo ọrọ̀ tó bá wà nílé ẹjọ́, ẹni tó bá lóye kò gbọdọ̀ sọ nkankan lórí rẹ̀.
Nítorí náà, èmi ò ní ohun kankan láti sọ lórí ọrọ̀ yìí títí tí ilé ẹjọ́ yóò fi sọ ohun tó yẹ lórí rẹ̀.
Gbogbo ọrọ tó bá wà láàrin emi àti Kábíyèsí,ààrín wa ló wà, kìí ṣe ohun tó kan ẹnìkan.
Kò sí ẹni tó lè sọ fún mi pe ohun ti èmi àti Kábíyèsí jọ sọ nìyí.
Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ọrọ wa nile ẹjọ, Ọlọrun yoo tọ ile ẹjọ sọna lati sọ ohun to dara.’’
Ọpọ ìwé ìròyìn lo ti gbe awọn iroyin kan jade wi pe Imaamu Ayilara ti da Soun lohun pe kabiyesi ko laṣẹ lati sọ fun oun pe ki oun wa gbaṣẹ ki oun to le rinrin ajo lọ si Hajj.
Àmọ́, Sheikh Yunus sọ pé òun kò ní sọrọ torí ọrọ̀ náà wà nílé ẹjọ́.