Ọkọ ìyàwó fósánlẹ̀ lóru jọ́kejì ìdùnú ìgbéyàwó

Ọkọ ìyàwó fósánlẹ̀ lóru jọ́kejì ìdùnú ìgbéyàwó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀jọ́ ẹyẹ ò ní-ín dọjọ́ ọ̀fọ̀ nílé e gbogbo wa ,àṣẹ.
Ṣùgbọn àdúrà yìí kò gbà tórí inú ìbànújẹ́ ńlá àti ìpòrúùru ọkàn làwọn ẹbí, ará àti ojúlùmọ̀ géńdé-kùnrin kan, Olóògbé Daniel Adole, tó kú lọ́jọ́ kejì tó ṣègbeyàwó alárinrin tán wà báyìí.

Oun tá a gbọ́ ni pé ọjọ́ ọdún Iléyá, ìyẹn ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ní olóògbé náà ṣegbeyawo pẹ̀lú ololufẹ rẹ̀ nílé àwọn òbí rẹ̀ tó wà lágbègbè Ochingini Adiko, nijọba ibilẹ Obi, nipinlẹ Benue. Ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ọjọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù yìí kan náà ní ariwo ẹkún ńlá sọ nílé rẹ̀, tí wọ́n sì kéde pé ọkọ tó ṣẹṣẹ ṣègbéyàwó alárinrin tán tifò sánlẹ, ó ti kú pátápátá.

Ohun tó jẹ́ k’ọrọ ikú olóògbé náà ya àwọn mọlẹbi rẹ̀ lẹnu ni pé, ọmọkùnrin náà kò ṣàìsàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àpẹẹrẹ àárẹ̀ kankan lára rẹ̀ lásìkò tó ń ṣayẹyẹ ìgbéyàwó rẹ̀ ọ̀hún, kokooko lara rẹ̀ le. Bó ṣe ń fò sókè, bẹ́ẹ̀ ló ń rẹrin-in sáwọn alábàáṣe gbogbo tí wọ́n wá bá a ṣàjọyọ pàtàkì náà. Ààrin òru ni nǹkan náà dédé kì í mọ́lẹ lójijì, tó sì kú sínú yàrá lẹgbẹẹ iyawo rẹ̀. Eré àti Àwàdà lásán nì yàwó rẹ̀ kọkọ pè é , ṣùgbọ́n nígbà tí kò dá a lóhùn mọ́ bó ṣe ń pè é nìyàwó figbe bọnu, táwọn aráalé sì sáré síta láti wáá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ tó gbọ́ nípa ikú olóògbé ọ̀hún ló n ṣe ní hàà-hiin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here