Kò dára láti jẹ oúnjẹ ṣíṣe inú firiiji tayọ ọjọ kejì, ó léwu gidi- NAFDAC

Kò dára láti jẹ oúnjẹ ṣíṣe inú firiiji tayọ ọjọ kejì, ó léwu gidi- NAFDAC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá àgbà pátápátá fún ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó oúnjẹ jíjẹ àti òògùn lílò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ‘National Agency For Food And Administration And Control’ (NAFDAC), Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisọla Adeyẹye, ti ṣèkìlọ pàtàkì fáwọn ọmọ Nàìjíríà pé wọ́n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan àwọn oúnjẹ ṣíṣe gbogbo tí wọ́n bá ti gbé sínú firiiji fún ọjọ́ mẹ́ta mọ́, nítorí pé ó lè ṣe ìpalára gidi fún ìlera wọn lọ́jọ́ iwájú.

Ó ní bíi ẹni pé èèyàn ń ṣẹwọ siku aitọjọ ni béèyàn bá ń jẹ oúnjẹ ṣíṣè tí wọ́n gbé sínú fíríìjì fún ọjọ́ mẹ́ta ṣe jẹ́, nítorí pé ikú àìtọ, àrùn àìtó oṣù, ló máa padà ṣe ònítọhùn.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù yìí, ló sọrọ náà lásìkò ayẹyẹ àyájọ oúnjẹ lágbàáyé tọdún yìí, èyí tó wáyé l’Abuja, tí í ṣe olú ilẹ̀ wa. Nínú àtẹ̀jade kan tí Alukoro ètò ìròyìn fún àjọ náà, Ọ̀gbẹ́ni Ṣayọ Akintọla, fọwọ́ sí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ni ọ̀gá àgbà àjọ náà ti ṣèkìlọ̀ pàtàkì ọ̀hún fáwọn aráàlú pé kí wọ́n yé jẹ oúnjẹ sísè tí wọ́n gbé sínú fíríìjiì fún ọjọ́ mẹ́ta mọ́, nítorí ìpalára gidi ló rọ̀ mọ́ ọ.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún lọ báyìí pé, ‘ Ọ̀gá àgbà àjọ NAFDAC orílẹ-èdè yìí rọ àwọn aráàlú pé kí wọ́n jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn oúnjẹ gbogbo tí wọ́n gbé sínú fíríìji fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ní ó ṣeé ṣe kí àwọn kòkòrò àìrí (Bacteria) kọ̀ọ̀kan ti sápamọ́ sínú irúfẹ́ oúnjẹ bẹ́ẹ̀, ó sì lè ṣàkóbá gidi fún ìlera wọn bí wọ́n bá jẹ ẹ́ . Àkóbá náà sì lè padà já sí ikú fún ọ̀pọ̀ èèyàn bí wọn kò bá tètè rí ìtọjú gidi gbà nílé ìwòsàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Adeyẹye ní ìdí pàtàkì táwọn ṣe ń ṣèpolongo yìí ni pé jíjẹ́ ojúlówó oúnjẹ gidi kìí ṣe fún ìlera àwọn aráàlú nìkan, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì púpọ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú orílẹ-èdè lápapọ̀ ni.

Ó wáá rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n fọwọ́-sowọ́-pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ orílẹ-èdè yìí, kí èròngbà wọn láti fòpin sí ikú àìtọ́jọ́ tó lè wáyé nídìí àwọn oúnjẹ tí kò bójúmu rárá lè wá sí ìmúṣẹ .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here