Òsèré tíatà kan tún ti gba èkurujẹ lọ́wọ́ ẹbọra

Òsèré tíatà kan tún ti gba èkurujẹ lọ́wọ́ ẹbọra

Ọrẹ Òtìtíjù

Ọ̀kan lára àwọn òṣèré tíatà yorùbá, Dayọ Adewunmi, ẹni táwọn èeyàn mọ̀ sí Sule Suebebe jáde láyé , Iyalẹnu niroyin iku ọkunrin yii jẹ fun ọpọ awọn eeyan. Idi ni pe loootọ ni ara rẹ ko ya, ṣugbọn ọkunrin naa ti n gbadun daadaa, ti awọn ololufẹ rẹ si ti ro pe o ti yi kinni naa jẹ niyẹn. Nitori ọpọ eeyan lo dide iranlọwọ owo fun un lọdun to kọja, nigba ti wọn kọko ṣafihan rẹ pe o wa lori idubulẹ asian nla kan.

Ohun ti a gbọ nipe ileewosan ijọba kan to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lo dakẹ si laaarọ kutukutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu yii.

Pasitọ Ademọla Amuṣan, ẹni tawọn eeyan mọ si Agbala Gabriel, ẹni to n sa sọtun-un sosi lori iwosan rẹ latigba ti oloogbe naa ti wa lori idubulẹ asian nla kan lo tufọ iku rẹ faraye gbọ lọjọ Wẹsidee pe Oloogbe Sule Suebebe ti jade laye ni ọsibitu kan to ti n gba itọju lọwọ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Bẹ o ba gbagbe, gbogbo ọna ni Pasitọ Agbala Gabriel yii gba lati jẹ ki awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ orileede Naijiria nilẹ yii ati l’Oke-Okun dide iranlọwọ owo fun un nigba to wa lori aisan. Ṣugbọn to jẹ pe aisan naa lo pada waa gbẹmi rẹ nigbẹyin.

Ẹgbẹ oṣere tiata, TANPAM, ti oloogbe naa jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ wọn ti n ba awọn ẹbi, ara, ọmọ ati ojulumọ ti oṣere yii fi silẹ saye lọ kẹdun eeyan wọn to jade laye.

Lara awọn fiimu ti Dayọ Adewumi, to tun figba kan jẹ onkọrin juju ṣe ko too ku ni awọn bii: Ṣuku ṣuku bam-bam, ‘Pero sọkọ’, ‘Aago kan oru’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here