Ọmọ akẹ́kọ ọlọ́dúnkejì Federal University Dutse se kúpa ọmọ rẹ̀.

Ọmọ akẹ́kọ ọlọ́dúnkejì Federal University Dutse se kúpa ọmọ rẹ̀.

Ọrẹ Òtìtíjù
Nítorí pé ẹni tó fun lóyún kò gbà a lọ́wọ́ rẹ̀, akẹ́kọọ-bìnrin iléewe gíga fasiti ‘Federal University’ of Dutse (FUD), kan tò wa lagbegbe Dutse, nipinlẹ Jigawa, to fibinu pa ọmọ ikoko kan to ṣẹṣẹ bi. Aipẹ yii ni akẹkọọ ileewe fasiti ọhun bimọ obinrin kan, ṣugbọn ti ẹni to fun un loyun ko gba a lọwọ rẹ, gbogbo akitiyan akẹkọọ naa lati bẹ afẹsọna rẹ yii pe ko gba ọmọ naa lọwọ oun lo ja si pabo, ṣe ni onitọhun t’oun naa jẹ akẹkọọ ileewe fasiti yii kan naa ni ki i ṣe oun loun loyun naa rara.

A gbọ pe ni aipẹ yii iya ikoko ọhun ba fibinu ju ọmọ ọwọ rẹ silẹ lati ori aja meji kan to n gbe ninu ọgba ileewe naa. Loju-ẹsẹ t’ọmọ naa fori dolẹ lo ti ku, ṣugbọn awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sare gbe ọmọ ikoko ọhun digbadigba lọ sileewosan ijọba kan ti wọn n pe ni ‘Rasheed Shekoni Teaching Hospitals’, to wa lagbegbe naa, awọn dokita ti wọn wa lẹnu iṣẹ lọjọ naa ni wọn sọ pe oku ọmọ naa ni wọn gbe wa sileewosan awọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa D.S.P Lawal Shiisu Adam, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun yii, sọ pe loootọ ni akẹkọọ-binrin ileewe ‘Federal University kan to wa niluu Dutse, to wa ni ipele ọdun keji nileewe naa foyun inu rẹ bimọ obinrin kan, ṣugbọn nigba ti ẹni to bimọ naa fun ko gba a lọwọ rẹ, lo ba fibinu ju ọmọ ọwọ rẹ bọ silẹ lati ori oke ile to n gbe. Awọn akẹkọọ kan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ni wọn gbe iya ati ọmọ naa lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa, ṣugbọn oku ọmọ naa ni wọn gbe de ọsibitu naa.

Alukoro ni awọn n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun lọwọ, awọn si maa too jabọ iwadii awọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here