Nítorí ipò Olúbàdàn: Ẹgbẹ́ ọmọbàdàn bínú sí Gomina Seyi Makinde

Nítorí ipò Olúbàdàn: Ẹgbẹ́ ọmọbàdàn bínú sí Gomina Seyi Makinde

Ọrẹ Òtìtíjù

Pẹ̀lú bó ti ṣe di oṣù mẹ́ta báyii tí orí ìtẹ̀ Olúbdàn ilẹ̀ Ìbàdàn tí ṣófo, tí ọba mi-in kò sì ti i gorí ìtẹ́, ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ yoruba kaakiri agbaye, Yoruba Youth Socio-Cultural Association (YYSA), ati ẹgbẹ awọn ọmọ ibilẹ Ibadan, Ibilẹ G-7, ti naka aleebu si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, wọn loun lo n mọ-ọn-mọ fi asiko falẹ lati fi ẹni ti ipo Olubadan kan bayii jọba.

Nigba to n ba akọroyin sọrọ n’Ibadan, Aarẹ ẹgbẹ YYSA, Ọgbẹni Ọlalekan Hammed, sọ pe, “ejo ti fẹẹ maa lọwọ ninu lori ọrọ ifọbajẹ Olubadan lasiko yii.

“Nilẹ toni to mọ yii, o yẹ ka ti mọ ọjọ ti gomina maa gbe ọpa aṣẹ le Ọba Ọlakulẹhin ti ipo Olubadan kan bayii lọwọ. Ohun ti wọn sọ tẹlẹ ni pe nibi ayẹyẹ oku Ọba Lekan Balogun (Olubadan to gbesẹ) ni wọn yoo ti kede igba ti eto iwuye yoo bẹrẹ, ṣugbọn iru iroyin bẹẹ ko jẹ yọ ninu ọrọ ti gomina sọ nibi ayẹyẹ ọjọ Satide yẹn.

“Eyi tumọ si pe a o ti i mọ ọjọ, oṣu tabi ọdun ti Ibadan too maa lọba bayii, bẹẹ, Ibadan ti ni eto to daa ti wọn fi n jọba, ẹni ti ipo ọba kan ko ruju, awọn afọbajẹ ti yan an, wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba lati oṣu meji sẹyin.

“Nitori naa, a rọ Gomina Makinde lati ma ṣe fi eto yii falẹ mọ, fun alaafia ati idagbasoke ilu Ibadan”.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, l’Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, waja sileewosan UCH, ti wọn si sinku ẹ nirọlẹ ọjọ keji.

Ipapoda Ọba Balogun lo sun Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye Ọlakulẹhin, siwaju gẹgẹ bii ẹni to kan bayii lati gori itẹ nla naa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n to oye ọba ilu awọn akọni ilẹ Yoruba naa.

Aarin oṣu kan lẹyin ti ori apere ṣófo lo yẹ ki eto gbogbo ti pari, ki wọn sì gbe ẹni tí ipò ọba ọhun kan gori itẹ, paapaa lẹyin ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ti awọn afọbajẹ Ibadan ti fa Ọba Ọlakulẹhin kalẹ gẹgẹ bii ọmọ oye Olubadan, ti wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Lọjọ Abamẹta, Satidé, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lariya aṣekagba ayẹyẹ isinku Ọba Balogun waye ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ, to wa l’Oke-Ado, n’Ibadan. Nibẹ lawọn eeyan nireti pe gomina yoo ti kede igba ti wọn yoo fi Olubadan tuntun jẹ.

Ṣugbọn òtúbáńtẹ́ nireti awọn ara Ibadan ja si nigba ti gomina naa sọrọ, to ni o digba ti Ọba Ọlakulẹhin, ẹni ti ko ṣaisan, ti ko fara pa, ba too gbadun, ti ara rẹ ba too mokun daadaa, ki oun too le bẹrẹ eto lati gbe ọpa aṣẹ le baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) naa lọwọ gẹgẹ bii ojulowo ọba.

Lati ọjọ Satide, ti gomina ti sọrọ yii lawọn eeyan, titi dori awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti n bu ẹnu atẹ lu u.

Ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ Ibilẹ G-7, Pasitọ Lanre Ogundipẹ, ati Ọgbẹni Jide Ọlaniyọnu, ti i ṣe akọwe ẹgbẹ naa, fi ṣọwọ sawọn oniroyin, wọn ní ọrọ ti Makide sọ nibi oku Olubadan to fori itẹ silẹ fi han pe gomina naa ko ti i ṣetan lati fi Ọlakulẹhin jọba ni.

Wọn ni, “Loootọ ni gomina fidi ẹ mulẹ pe oun ti fara mọ Ọlakulẹhin ti awọn afọbajẹ fi ranṣẹ si oun, ati pe ilana to yẹ ki wọn tẹle naa ni wọn tẹlẹ lati yan an. Ẹ gbọ, ki lo tun wa n da a duro lati ṣeto bi baba naa yoo ṣe gori itẹ?

“Nigba ti Ọba Balogun ṣẹṣẹ waja loriṣiiriṣii awuyewuye wa lori ọrọ oye Olubadan tuntun. Ṣugbọn lẹyin ti gbogbo awuyewuye wọnyi ti kọja sẹyin, ti ọkan gbogbo eeyan ti balẹ pe ọba tuntun maa gori itẹ, lasiko yii ni Gomina Makinde waa lọọ sọ iru ọrọ yii, pe o digba ti ara Ọba Ọlakulẹhin ba too mokun daadaa ki oun too fi wọn jẹ Olubadan.

“Ki Ọba Ọlakulẹhin gori itẹ Olubadan lai fi akoko ṣofo rara mọ lo pọn Gomina Makinde le lasiko yii. Eyi paapaa ni yoo ṣafihan ifẹ to ni si ilu Ibadan ati ipo ọba Olubadan”.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here