Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti Ìjọba fẹnukò lórí owó oṣù tuntun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti fẹnuko lórí àwọn àdéhùn tuntun tó níí ṣe nípa owó oṣù tuntun fún àwọn òṣìṣẹ́.
Àdéhùn tuntun náà wáyé níbi ìpàdé tí àwọn aṣojú ìjọba, àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe nílùú Àbùjá lọjọ Ajé.
Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà, ní agbarijọ pọ̀ NLC, TUC, NUJ, àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke.
Àkójọ ìròyìn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bíi Ogun, Osun, Oyo, Ekiti, Kwara àti Ondo fihàn pé títí pa ni àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba, tó fi mọ́ àwọn báńkì wà.
Ṣaájú ni ìjíròrò láàrin ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò so èso rere. Ìjíròrò tó kẹhin wáyé lọjọ Àìkú tó kọjá, pẹ̀lú àwọn olórí ilé aṣòfin.
Ìgbà kẹrin nìyí tí ìjọba dáàbá owó oṣù tó lè san – àkọ́kọ́ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta Náírà tí wọ́n kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta Náírà tí wọ́n mẹnuba lọjọ Ìṣẹgun, nígbà tí ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta náírà jẹ́ ìgbà kẹta, kó tó tún wá kan ẹgbẹrun lọ́nà ọgọta náírà tí wọ́n kọ láti tẹwọgba.
Nípa ìpàdé tí wọ́n ṣe lọjọ Ajé, ilé iṣẹ́ agbohunsafẹfẹ tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀, NTA, sọ pé Ààrẹ Bola Tinubu, ti buwọ́lù owó oṣù tó ju ẹgbẹrun lọ́nà ọgọta Náírà.
Nítorí owó oṣù tuntun tí ààrẹ buwọ́lù, ọjoojumọ ni ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ yóó má a ṣe ìpàdé fún ọsẹ kan gbáko, láti fẹnukò lórí owó oṣù tí ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ yóò faramọ́.
Nínú Àdéhùn ti wọ́n, àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ gbà láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka wọ́n ní kíákíá, láti gbé èròngbà ìjọba wò.
Bákan náà ló tún jẹyọ níbi ìpàdé náà pé, òṣìṣẹ́ kankan kò ní fojú winá ìjìyà tàbí ìdúnkookò mọ́, nínú wọn pé wọn kópa nínú ìyanṣẹ́lódì.