Igbe èmi ló kàn pẹ̀lú orin ọpẹ́ ló gba ẹnu ọba lọ́la Ọlákùlẹ́yìn, ó ní òun ti ṣetán láti gorí ìtẹ́ Olúbàdàn.

Igbe èmi ló kàn pẹ̀lú orin ọpẹ́ ló gba ẹnu ọba lọ́la Ọlákùlẹ́yìn, ó ní òun ti ṣetán láti gorí ìtẹ́ Olúbàdàn.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Alàgbà Owólabí Ọlákùlẹ́yìn ẹni tí ìrètí wà fún pé òun ni yóò jọba ìlú Ìbàdàn; ti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé tàbí ṣùgbón kankan kò sí òun ni ipò Olúbàdàn kàn báyìí. Ó wí pé ’Olúwa ti sọ pé èmi nipò Olúbàdàn kàn, mo sì mọ̀ dájú pé èmi ló kàn’’

Lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2024 yìí, ni Ọlákùlẹ́yìn sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tí ikọ̀ alábẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ Gómìnà Ṣèyí Mákindé lọ kí baba náà nílé rẹ̀ lágbègbè Alálùbọ́sà, níbàdàn ló ti sọ bẹ́ẹ̀.

Alàgbà Ọlakulẹyin ní ọpẹ́ ló kàn lọ́rọ̀ òun àti pé òun ti ṣetán láti gun orí ìtẹ́, ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn tó já geere sí ìyàlẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀. Ó’ ní “ Inú òun dùn
láti rí àwọn ikọ̀ alábẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ Gómìnà. Ó ṣàlàyé pé “Nígbà tí wọ́n ti sọ fún òun pé àwọn ikọ̀ alábẹ̀wò ń bọ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sọ fáwọn olóyè mi pé kí wọ́n máa bọ̀, kí wọ́n jẹ́ ká jọ gbà yín lálejò. Ó tẹ̀ṣíwájú nínú àlàyé rẹ̀, ó pé “Inú mi dùn pé àwọn èèyàn mi wà níbí pẹ̀lú mi”. Òun sì ti ṣetán pátápátá láti jọba, ó ní “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn mi, ó ti sọ pé èmi ni ipò Olúbàdàn kàn, èmi náà sì mọ̀ lódodo pé èmi ló kan, àsìkò mi rèé.’’ Bàbá lóun kò ní í já àwọn èèyàn kulẹ̀, àti pé gbogbo àjọ̀ṣepọ̀ rere tó n gbé ilẹ̀ Ìbàdàn ró làwọn yóò jọ jèrè rẹ̀. Kò ní í bàjẹ́ láéláé.

Alága ikọ̀ tó ṣàbẹ̀wò náà, Amòfin àgbà Bólájí Ayọ̀ríndè, ṣàlàyé pé lẹ́yìn táwọn afọbajẹ ti fi orúkọ ọmọ oyè Owólabí Ọlákùlẹ́yìn ráńṣẹ́, ó lẹ́tọ̀ kí àbẹ̀wò tọ́ si i láti ọ̀dọ̀ ìjọba. Ayọ̀ríndè sọ pé Gómìnà fúnra rẹ̀ ni kò bá wá pàápàá, bí kò ṣe pé ó wà ní ìrìn àjò kan ni. Ó ní tí Gómìnà Mákindé bá ti dé, yóò wáá yọjú sí ọba Ìbàdàn tó kàn yìí láti ṣe Bàbá kẹ́ ẹ pẹ́ sí i. Orúkọ àwọn yòókù tí wọ́n kọ́wọ́ọ́rìn síbi àbẹ̀wò náà pẹ̀lú Amòfin Ayọ̀ríndè ni Ọ̀gbẹ́ni Ṣẹ́gun Ọláyíwọlá àti Sẹnetọ Mònsúrá Sùnmọ́nù.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here