Adájọ ní kí wọ́n fi ìwé wọ́ Gani Adams wa sí kóòtù lọ́nàkọnà
Ọrẹ Òtítọ́jù
Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá ò bá tíì tán, èèyàn nlá ò níín
tíì sinmi ẹjọ́ bí ó ṣe jẹ́ pé
kò ní í pẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní í jìnnà mọ́ báyìí, tí àwọn akọni ọmọ Yorùbá méjì nnì, Ààrẹ Ọ̀nà-Kakanfò ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams, àti ajìjàgbara fún ìran Yorùbá nnì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo ayé mọ̀ sí Sunday Igboho, yóò kojú ara wọn ní kóòtù pẹ̀lú bí ilé-ẹjọ́ ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìwé ìpẹ̀jọ́ pé Gani Adams wá sí kóòtù.
Sunday Igboho lo pe Gani Adams lẹjọ, o lọkunrin naa ba oun lorukọ jẹ, bi ibanikorukọjẹ ọhun si ṣe ba oun lọkan jẹ to loun ṣe fẹ ki wọn fiya jẹ oun naa to, nitori naa, ki ile-ẹjọ paṣẹ fun olujẹjọ naa, to tun jẹ ọga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, lati sanwo nla, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500 m).
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ohun ti olupẹjọ tori ẹ pẹjọ ko ṣẹyin akasilẹ ohun kan to jẹ itakurọsọ to waye laarin Gani Adams ati ọkunrin kan ti wọn pe ni Nuru Banjọ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021, eyi ti awọn oniroyin kan gbe sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii.
Ninu akasilẹ ohun naa la gbọ pe olujẹjọ ti ṣapejuwe olupẹjọ gẹgẹ bii apaayan to ṣokunfa iku gbajumọ oloṣelu kan lorileede yii, Oloye Bọla Ige.
Ṣugbọn Igboho sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọkunrin naa, n lo ba gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ fiya nla jẹ ọga awọn OPC naa fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Lati oṣu to kọja lolupẹjọ ti pẹjọ naa, o si yẹ ki igbẹjọ ti bẹrẹ lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ṣugbọn eyi ko ṣee ṣe nitori olujẹjọ ko fara han ni kootu, bẹẹ ni ko si agbẹjọro tabi ẹnikẹni to ṣoju ẹ nile-ẹjọ.
Nigba ti igbẹjọ ọhun tun waye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti akọda kootu ṣalaye pe oun ko lanfaani lati fun olujẹjọ niwee ipẹjọ, nitori naa, ko jọ pe ọkunrin naa mọ pe ẹnikẹni pe oun lẹjọ si kootu yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti mo dele olujẹjọ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja, l’Ekoo, aṣọna rẹ to yọju si mi lati inu ile sọ pe ọga oun (Gani Adams) ko si nile”.
Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ M.I. Sule, fun akọda ile-ẹjọ naa lanfaani lati lo ọnakọna mi-in to ba gba lati ri i pe iwe ipẹjọ ọhun tẹ ọga awọn OPC naa lọwọ.
Adajọ ni “Mo ti wo akọsilẹ gbogbo akitiyan akọda lati fun olujẹjọ funra rẹ niwee ipẹjọ, mo si ri i pe iwe ọhun ko ti i tẹ ẹ lọwọ nitori akọda ko ba a nile ẹ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja. Nitori naa, mo pa a laṣẹ pe ki wọn lo gbogbo ọna yoowu ti olujẹjọ yoo fi mọ pe oun lẹjọ i jẹ ni kootu yii, koda, bo gba ki wọn lẹ iwe ipẹjọ naa mọ geeti ile tabi ara ogiri ile ẹ”.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹfa, ọdun yii.